Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun Tá A Fẹ́ Kí Àwọn Tó Wá Sí Àpéjọ Yìí Mọ̀

Ohun Tá A Fẹ́ Kí Àwọn Tó Wá Sí Àpéjọ Yìí Mọ̀

ÌPÀDÉ ÀKÀNṢE

ILÉ Ẹ̀KỌ́ ÀWỌN AJÍHÌNRERE ÌJỌBA ỌLỌ́RUN Kí àwọn aṣáájú-ọ̀nà tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín ọdún mẹ́tàlélógún [23] sí márùndínláàádọ́rin [65], tí wọ́n fẹ́ túbọ̀ tẹ̀ síwájú lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wọn, wá sí ìpàdé tá a ṣètò fún àwọn tó fẹ́ lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere Ìjọba Ọlọ́run tí a máa ṣe ní òwúrọ̀ Sunday. A máa ṣe ìfilọ̀ ibi tá a ti máa ṣe ìpàdé yìí àti àkókò tó máa bẹ̀rẹ̀.

OHUN TÁ A FẸ́ KÍ ÀWỌN TÓ WÁ SÍ ÀPÉJỌ YÌÍ MỌ̀

ÀWỌN TÓ Ń BÓJÚ TÓ ÈRÒ Iṣẹ́ àwọn tó ń bójú tó èrò ni láti ràn ẹ́ lọ́wọ́. Jọ̀wọ́, fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú wọn nípa gbígbé ọkọ̀ rẹ síbi tí wọ́n bá ní kó o gbé e sí, gba ibi tí wọ́n bá ní kó o gbà, sì tẹ̀ lé ohun tí wọ́n bá sọ nípa àyè ìjókòó àtàwọn ohun mìíràn.

ÌRÌBỌMI Àwọn ìjókòó tó wà níwájú pèpéle la yà sọ́tọ̀ fún àwọn tó fẹ́ ṣèrìbọmi, àyàfi tá a bá ṣe ìfilọ̀ míì tó yàtọ̀ sí èyí. Kí àwọn tó fẹ́ ṣèrìbọmi ti jókòó síbẹ̀ kí àsọyé ìrìbọmi tó bẹ̀rẹ̀ láàárọ̀ Saturday. Kí olúkúlùkù mú aṣọ ìnura àti aṣọ tó bójú mu tó máa fi ṣèrìbọmi dání.

ỌRẸ Owó kékeré kọ́ la ná láti pèsè ìjókòó tó pọ̀ tó, ẹ̀rọ tó ń gbóhùn sáfẹ́fẹ́, ẹ̀rọ tó ń ṣàfihàn fídíò àtàwọn nǹkan míì tó mú kí àpéjọ yìí gbádùn mọ́ni, kí á sì lè túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Ọrẹ àtinúwá tó o bá ṣe jẹ́ ara ohun tá a ó fi kájú àwọn ìnáwó yìí, á sì tún jẹ́ ìtìlẹ́yìn fún iṣẹ́ ìwàásù kárí ayé tá à ń ṣe. Kó lè rọ̀ ẹ́ lọ́rùn, a ti gbé àwọn àpótí ọrẹ tá a kọ “Contributions” sí lára sí ọ̀pọ̀ ibi káàkiri Gbọ̀ngàn Àpéjọ yìí. A mọrírì gbogbo ọrẹ tá a bá rí. Ìgbìmọ̀ Olùdarí sì dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ fún ìtìlẹ́yìn ọlọ́làwọ́ tó o bá ṣe nítorí iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run.

ÌTỌ́JÚ RÁŃPẸ́ Jọ̀wọ́ rántí pé ÌTỌ́JÚ PÀJÁWÌRÌ NÌKAN ni ẹ̀ka yìí wà fún.

ÀWỌN OHUN TÓ SỌ NÙ TÁ A RÍ HE Gbogbo ohun tó o bá rí he ni kó o mú lọ sí Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Àwọn Ohun Tó Sọ Nù Tá A Rí He. Bó o bá sọ ohunkóhun nù, lọ wò ó ní ẹ̀ka yìí. Tó o bá rí ọmọ kékeré tó ń rìn kiri tí kò sì mọ ibi táwọn òbí rẹ̀ jókòó sí, mú un lọ sí ẹ̀ka yìí. Àmọ́, kì í ṣe pé ká kúkú wá sọ ẹ̀ka yìí di ilé ìtọ́jú àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ o! Jọ̀wọ́ bójú tó àwọn ọmọ rẹ, kó o sì jẹ́ kí wọ́n máa wà lọ́dọ̀ rẹ nígbà gbogbo.

ÌJÓKÒÓ Jọ̀wọ́ ro tàwọn ẹlòmíì mọ́ tìẹ. Rántí pé kìkì àwọn tẹ́ ẹ jọ wọkọ̀ kan náà àtàwọn tẹ́ ẹ jọ ń gbélé tàbí ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìkan lo lè gba àyè sílẹ̀ fún. Jọ̀wọ́ má ṣe gbé ohunkóhun sórí ìjókòó, àfi tó o bá fẹ́ gba ayé náà sílẹ̀ fún ẹnì kan.

IṢẸ́ ÌYỌ̀ǸDA ARA ẸNI Bó o bá fẹ́ yọ̀ǹda ara rẹ láti ṣe lára iṣẹ́ tó ní ín ṣe pẹ̀lú àpéjọ yìí, jọ̀wọ́ lọ sí Ẹ̀ka Ìsọfúnni àti Ìyọ̀ǹda Ara Ẹni.

Tí Ìgbìmọ̀ Olùdarí Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ṣètò