ÀWỌN OHUN PÀTÀKÌ TÓ ṢẸLẸ̀ LỌ́DÚN TÓ KỌJÁ
Ikorajo Awa Elerii Jehofa Ti Ero Po si Ju Lo
NÍ ỌJỌ́ Sátidé, October 5, ọdún 2013, ọ̀kẹ́ méjìlá ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàásàn-án, igba àti mẹ́rìnléláàádọ́rùn-ún [257,294] èèyàn láti ilẹ̀ mọ́kànlélógún [21] ló pésẹ̀ síbi ìpàdé ọdọọdún, ìkọkàndínláàádóje [129] irú rẹ̀, ti àjọ Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania. Àwọn kan wà níbẹ̀, àwọn míì sì wò ó bó ṣe ń lọ lọ́wọ́ nípasẹ̀ ẹ̀rọ alátagbà. Ní òpin ọ̀sẹ̀ yẹn kan náà, àwọn míì tún wò ó nígbà tí a tún gbé e sáfẹ́fẹ́. Àròpọ̀ iye àwọn tó pésẹ̀ jẹ́ mílíọ̀nù kan, ẹgbẹ̀rún lọ́nà ìrínwó àti mẹ́tàlá, ẹgbẹ̀ta àti mẹ́rìndínlọ́gọ́rin [1,413,676] láti ilẹ̀ mọ́kànlélọ́gbọ̀n [31]. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò tíì pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ rí níbi ìkórajọ wa!
Láti ọdún 1922 làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń lo tẹlifóònù àti rédíò láti ṣe àtagbà àwọn àpéjọ wa láti orílẹ̀-èdè kan sí òmíràn.
Ní báyìí, Íńtánẹ́ẹ̀tì ti mú kó ṣeé ṣe fún àwọn tó wà níbi tó jìnnà láti gbọ́ ohun tó ń lọ, kí wọ́n sì máa wò ó lójú ẹsẹ̀ tàbí kété lẹ́yìn tó wáyé.Ó lé ní ọdún kan tí àwọn ará láti onírúurú ẹ̀ka ọ́fíìsì fi ṣiṣẹ́ lórí bí wọ́n á ṣe fi Íńtánẹ́ẹ̀tì ṣe àtagbà ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà. Lópin ọ̀sẹ̀ tí wọ́n ṣe àtagbà náà, ìlú Brooklyn, ìpínlẹ̀ New York, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni àwọn amojú ẹ̀rọ wa ti bójú tó ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà. Tọ̀sán tòru ni wọ́n fi ń gbaṣẹ́ lọ́wọ́ ara wọn bí wọ́n ṣe ń gbé ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà sáfẹ́fẹ́ ní ibi mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí àkókò wọn yàtọ̀ síra.