Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀWỌN OHUN PÀTÀKÌ TÓ ṢẸLẸ̀ LỌ́DÚN TÓ KỌJÁ

Iroyin​​—Nipa Awon Ara Wa

Iroyin​​—Nipa Awon Ara Wa

Àwọn Míì Jàǹfààní Látinú Ohun Tí Wọ́n Wà Jáde

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò tíì fi bẹ́ẹ̀ sí Íńtánẹ́ẹ̀tì ní erékùṣù Cuba, èèyàn lè rí i lò báyìí láwọn ìsọ̀ tí àwọn ilé iṣẹ́ tẹlifóònù bá ṣí. Àmọ́ owó gọbọi lẹni tó bá fẹ́ lò ó máa san. Kí àwọn ará lè máa jàǹfààní àwọn ohun tó wà lórí ìkànnì jw.org, ẹ̀ka ọ́fíìsì rọ àwọn ìjọ pé kí wọ́n yan akéde kan táá máa wa àwọn ìtẹ̀jáde, àwọn ohùn tá a gbà sílẹ̀ àtàwọn fídíò látorí Ìkànnì wa, kó sì máa pín in fún àwọn ará yòókù nínú ìjọ. Ètò yìí ń méso rere jáde.

Wọ́n Yan Iṣẹ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba Láàyò Ju Fóònù Alágbèéká Lọ

Orílẹ̀-èdè Jọ́jíà ni Teona tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́wàá àti àbúrò rẹ̀ obìnrin tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́jọ ń gbé. Àwọn ọmọ yìí fẹ́ ra fóònù alágbèéká. Ìyá wọn àgbà sì ṣèlérí pé òun máa fún wọn lára owó ìfẹ̀yìntì tí òun ń gbà lóṣooṣù kí wọ́n lè fi rà á. Ó bani nínú jẹ́ pé ìyá wọn àgbà kú lójijì. Síbẹ̀ àwọn ẹbí fún àwọn ọmọbìnrin yìí ní owó ìfẹ̀yìntì tí ìyá àgbà gbà kẹ́yìn kí wọ́n lè ra fóònù náà. Lẹ́yìn táwọn ọmọ yìí ronú jinlẹ̀, wọ́n kọ̀wé sí ìjọ wọn pé: “A mọ̀ pé iṣẹ́ kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun máa bẹ̀rẹ̀ ní ọ̀sẹ̀ méjì sí i ní abúlé T’erjola wa yìí. Kí ìyá wa àgbà tó kú, ó wù ú pé kó lọ́wọ́ sí iṣẹ́ náà, ìdí nìyẹn tá a ṣe kúkú fẹ́ fún ìjọ ní gbogbo owó ìfẹ̀yìntì tí wọ́n san fún ìyá wa àgbà kẹ́yìn dípò ká fi ra fóònù alágbèéká. Ẹ jọ̀wọ́, Gbọ̀ngàn Ìjọba tó dáa ni kí ẹ kọ́ fún wa o!”

Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì ti Èdè Tetum

Ní January 17 ọdún 2014, nílùú Dili lórílẹ̀-èdè Timor-Leste, Arákùnrin Geoffrey Jackson tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí mú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì ní Ìtumọ̀ Ayé Titun jáde lédè Tetum tó jẹ́ èdè tí wọ́n ń sọ jákèjádò orílẹ̀-èdè náà. Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì nìkan ló ń tẹ ẹ̀dà Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì ti èdè Tetum tẹ́lẹ̀, àwọn náà ló sì ń pín in, àmọ́ wọn kò tà á fún àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tàbí àwọn tí wọ́n fura sí pé à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ìtumọ̀ Bíbélì Kátólíìkì náà kò péye, wọ́n fo ọ̀pọ̀ nǹkan níbẹ̀, àwọn ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ kò bóde mu, wọn ò sì tẹ̀ ẹ́ dáadáa. Àmọ́ Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun kò rí bẹ́ẹ̀. Arákùnrin Darren tó jẹ́ míṣọ́nnárì lórílẹ̀-èdè Timor-Leste sọ pé: “Bí Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ṣe péye gan-an máa ń wú àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè Timor-Leste lórí gan-an, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n sì máa ń ní ká fún àwọn. Wọ́n rí i pé ó rọrùn láti kà, wọ́n fẹ́ràn lẹ́tà gàdàgbà tí wọ́n fi tẹ̀ ẹ́, torí pé ọ̀pọ̀ ilé ni kò ní iná mànàmáná tó dáa. Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó gba Bíbélì náà ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì báyìí.”

‘Jèhófà Pọ́n Mi Lé’

Orílẹ̀-Èdè Makedóníà: Wọ́n ń lo àwọn ìtẹ̀jáde èdè Romany lóde ẹ̀rí

Ní oṣù January ọdún 2014, ìtẹ̀síwájú mánigbàgbé dé bá iṣẹ́ ìtúmọ̀ èdè Romany tí wọ́n ń sọ lórílẹ̀-èdè Makedóníà. Ìgbà yẹn ni àwùjọ àwọn atúmọ̀ èdè náà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní pẹrẹu. Ìgbìmọ̀ Olùdarí sì fọwọ́ sí i pé ká máa fi àwọn álífábẹ́ẹ̀tì Cyrillic tẹ ìwé jáde láfikún sí lílo lẹ́tà ábídí ti àwọn ará Róòmù. Èyí ti ran àwọn tọ́ ń sọ èdè Romany lọ́wọ́ gidigidi torí pé àwọn álífábẹ́ẹ̀tì Cyrillic tí wọ́n fi ń kọ̀wé lórílẹ̀-èdè Makedóníà ti mọ́ wọn lára.

Bí ètò Jèhófà ṣe ń tẹ ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ lédè Romany wú ọ̀pọ̀ àwọn tó ń sọ èdè náà lórí gan-an. Arábìnrin kan sọ pé: “Èdè Romany ni mo máa ń sọ, ó sábà máa ń ṣe mí bíi pé àwọn tó wá láti ẹ̀yà míì ń fojú tẹ́ńbẹ́lú mi. Torí náà, mo dúpẹ́ gidigidi lọ́wọ́ Jèhófà pé ó pọ́n mi lé, ó jẹ́ kí n máa rí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ gbà lédè mi. Èyí ti jẹ́ kí n túbọ̀ sún mọ́ ọn.”

“Mo dúpẹ́ gidigidi lọ́wọ́ Jèhófà pé ó pọ́n mi lé, ó jẹ́ kí n máa rí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ gbà lédè mi”

Ìyípadà Wáyé

Bẹ̀rẹ̀ láti February 1, 2014, ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà bẹ̀rẹ̀ sí í bójú tó àwọn ìpínlẹ̀ ìwàásù àtàwọn ìjọ tó wà ní orílẹ̀-èdè Jàmáíkà àti Àwọn Erékùṣù Cayman. Ẹ wo bí ìṣọ̀kan tó wà láàárín àwọn akéde tó lé ní mílíọ̀nù kan àti ọ̀kẹ́ mẹ́wàá láwọn ìpínlẹ̀ ìwàásù tí ẹ̀ka ọ́fíìsì orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ń bójú tó ṣe máa pọ̀ tó! Lára àwọn ìpínlẹ̀ náà ni àádọ́ta [50] ìpínlẹ̀ ti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, erékùṣù Bahamas, Bermuda, Puerto Rico, Turks àti Caicos títí kan erékùṣù Virgin ti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti erékùṣù Virgin ti Amẹ́ríkà.

Àwọn Aṣáájú-Ọ̀nà Lórílẹ̀-Èdè Japan

Àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin lórílẹ̀-èdè Japan túbọ̀ ń fi ìtara lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Orílẹ̀-èdè yìí sì ni orílẹ̀-èdè kẹrin tó ní àwọn aṣáájú-ọ̀nà tó pọ̀ jù láyé. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún iṣẹ́ ìsìn 2014, ẹgbẹ̀rún méjì àti ẹgbẹ̀ta ó lé mẹ́rìndínláàádọ́ta [2,646] làwọn tó tún ṣẹ̀ṣẹ̀ di aṣáájú-ọ̀nà. Látàrí èyí, iye aṣáájú-ọ̀nà lórílẹ̀-èdè náà ti di ẹgbẹ̀rún márùndínláàádọ́rin, ẹgbẹ̀ta àti méjìínláàádọ́rin [65,668]. Ní oṣù March 2014, ó lé ní ìdajì gbogbo akéde orílẹ̀-èdè náà tó kópa nínú irú iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà kan tàbí òmíràn.