Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍLẸ̀-ÈDÈ DOMINICAN

Won Da Wa Sile, Won Tun Fofin De Wa

Won Da Wa Sile, Won Tun Fofin De Wa

Òmìnira Wọlé Dé

Àwọn aláṣẹ pa Manuel Hierrezuelo nígbà tí wọ́n ń fọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò

Ní gbogbo ọdún tí wọ́n fi fòfin de iṣẹ́ wa, tí nǹkan sì le koko, Lennart àti Virginia Johnson pẹ̀lú Roy àti Juanita Brandt kò fi iṣẹ́ míṣọ́nnárì wọn sílẹ̀. Lennart sọ pé: “Wọ́n pe èmi àti Roy Brandt lọ sí ọ́fíìsì ìjọba láti fọ̀rọ̀ wá wa lẹ́nu wò. Àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba Trujillo ti kọ́kọ́ sọ fún Arákùnrin Manuel Hierrezuelo pé kó wá rí wọn.” Ó ṣeni láàánú pé wọ́n pa Arákùnrin Manuel nígbà tí wọ́n ń gbọ́ tẹnu ẹ̀. Ó pa ìwà títọ́ rẹ̀ mọ́ títí dópin. Kí ló wá ṣẹlẹ̀ sí Lennart àti Roy? Lennart sọ pé: “Bá a ṣe ń débẹ̀, wọ́n da ìbéèrè bò wá lọ́tọ̀ọ̀tọ̀, wọ́n sì fi ẹ̀rọ gba ohun tí kálukú wa sọ sílẹ̀. A ò gbọ́ nǹkan kan mọ́ lẹ́yìn ìyẹn, àmọ́ lẹ́yìn oṣù méjì, ó jáde nínú àwọn ìwé ìròyìn pé ìjọba Trujillo ti mú òfin tí wọ́n fi de iṣẹ́ Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kúrò àti pé a lè pa dà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ wa.”

Kí ìfòfindè náà tó bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1950, igba àti mọ́kànlélọ́gọ́ta [261] ni iye akéde tó ń wàásù ní Orílẹ̀-èdè Dominican. Àmọ́ ní oṣù August ọdún 1956 tí wọ́n mú ìfòfindè náà kúrò, iye wọn ti di ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta àti méjìlélógún [522]. Inú àwọn ará dùn láti mọ̀ pé àwọn máa pa dà lómìnira láti máa wàásù fàlàlà lẹ́yìn ọdún mẹ́fà tí wọ́n ti ń fi wọ́n sẹ́wọ̀n, tí wọ́n ń ká wọn lọ́wọ́ kò, tí wọ́n sì ń ṣọ́ wọn lọ́wọ́ lẹ́sẹ̀.

Kí làwọn èèyàn Jèhófà wá ṣe nígbà tí nǹkan ṣàdédé yí pa dà? Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n pa dà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣètò iṣẹ́ náà! Wọ́n wá ibi tí wọ́n ti lè máa ṣèpàdé, wọ́n ya àwòrán ìpínlẹ̀ ìwàásù tuntun, wọ́n sì ṣe àwọn fáìlì ìjọ. Inú àwọn ará dùn gan-an pé àwọn á lè béèrè fún ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́, àwọn á sì rí i gbà. Wọ́n fìtara lo òmìnira tí wọ́n ní yìí láti wàásù. Torí náà, nígbà tó fi máa di oṣù November ọdún 1956, oṣù mẹ́ta péré lẹ́yìn tí wọ́n dòmìnira, iye akéde ti di ẹgbẹ̀ta àti méjìlá [612].

Àwọn Aṣáájú Ẹ̀sìn Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Gbógun

Ìwé tí Toledano fi ṣàlàyé ọgbọ́n tó fẹ́ fi dínà mọ́ àwọn ìwé wa kí wọ́n má bàa wọ orílẹ̀-èdè náà mọ́

Kò pẹ́ rárá táwọn aṣáájú ẹ̀sìn Kátólíìkì fi bẹ̀rẹ̀ sí í gbìmọ̀ pọ̀ láti ba àwa Ẹlẹ́rìí lórúkọ jẹ́. Orí àdéhùn tí Ọ̀gbẹ́ni Trujillo bá Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ṣe ni àwọn àlùfáà náà gùn lé. Wọ́n koná mọ́ ìsapá wọn láti yí ìjọba lérò pa dà pé kí wọ́n fòpin sí iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì, Oscar Robles Toledano kọ̀wé ránṣẹ́ sí Akọ̀wé Ìjọba Tó Ń Bójú Tó Ọ̀rọ̀ Abẹ́lé, ìyẹn Virgilio Álvarez Pina pé kó ti òun lẹ́yìn kóun lè “ta àwọn èèyàn Orílẹ̀-èdè Dominican jí kí wọ́n lè rí ewu tó bùáyà tí ẹ̀ya ẹ̀sìn àwọn ‘Ẹlẹ́rìí Jèhófà’ fẹ́ kó wọn sí.”

Ọ̀gbẹ́ni Toledano ṣàlàyé pé olórí ohun tí òun fẹ́ ṣe ni pé kí òun “sọ iṣẹ́ ìwàásù àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà dasán.” Ó tún dábàá nínú ìwé náà pé kí ìjọba má ṣe jẹ́ ká kó àwọn ìwé wa wọ orílẹ̀-èdè náà mọ́, “ní pàtàkì ìwé ‘Otitọ Yio Sọ Nyin Di Ominira’ àtàwọn ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́.”

Ìjọba Tún Fòfin De Iṣẹ́ Wa

Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn àtàwọn tí wọ́n jọ lẹ̀dí àpò pọ̀ nínú ìjọba Trujillo wà lára àwọn tó di rìkíṣí láti gbógun tì wá. Ọ̀gbẹ́ni Francisco Prats-Ramírez, ààrẹ Ẹgbẹ́ Òṣèlú Dominican kọ̀wé sí Ọ̀gbẹ́ni Trujillo ní oṣù June ọdún 1957, ó ní: “Mo ti ń ṣètò onírúurú àpérò láti fi wéwèé bá a ṣe fẹ́ gbógun ti àwọn olubi tí ò nífẹ̀ẹ́ ìjọba tí wọ́n pera wọn ní Ẹlẹ́rìí Jèhófà.”

Ìwé kan tó dá lórí ìṣàkóso Trujillo, tí wọ́n pè ní Trujillo—Little Caesar of the Caribbean jẹ́ ká mọ̀ pé kò pẹ́ rárá tí ẹnu àwọn ọ̀tá yìí fi bẹ̀rẹ̀ sí í ranlẹ̀, ó ní: “Nígbà ẹ̀rùn ọdún 1957, àwọn ìwé ìròyìn ilẹ̀ Dominican bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ onírúurú ẹ̀sùn tí àwọn lọ́gàálọ́gàá lẹ́nu iṣẹ́ Ìjọba wọ́n fi kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jáde. Wọ́n ní ‘olubi tó ń dìtẹ̀ ìjọba’ ni wọ́n. Ọ̀rọ̀ yìí tún fẹjú sí i lọ́jọ́ tí àlùfáà ọmọ ẹgbẹ́ ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì kan tó ń jẹ́ Mariano Vásquez Sanz bu ẹnu àtẹ́ lu àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó kà wọ́n sí ẹ̀ya ẹ̀sìn nínú ọ̀rọ̀ tí wọ́n gbé sáfẹ́fẹ́ láti ilé iṣẹ́ rédíò alátagbà kan tó jẹ́ ti Ọ̀gbẹ́ni Trujillo. Wọ́n pe ilé iṣẹ́ rédíò náà ní La Voz Dominicana [Ohùn Àwọn Èèyàn Ilẹ̀ Dominican]. Ó sọ pé ìránṣẹ́ ìjọba Kọ́múníìsì ni wọ́n àti pé gbogbo wọn jẹ́ ‘alákatakítí, oníbékebèke, ọ̀daràn àti ọ̀dàlẹ̀.’ Látàrí ìyẹn, nínú lẹ́tà táwọn Bíṣọ́ọ̀bù Àgbà tó ń jẹ́ Ricardo Pittini àti Octavio Antonio Beras kọ, wọ́n sọ fún ẹgbẹ́ àlùfáà wọn pé kí wọ́n kìlọ̀ fún àwọn ọmọ ìjọ wọn láti ṣọ́ra fún ọ̀rọ̀ àwọn ‘ẹlẹ́kọ̀ọ́ èké tó burú jáì’ yìí.”

Bí àwọn aṣáájú ẹ̀sìn àtàwọn olóṣèlú tó lẹ̀dí àpò pọ̀ ṣe fẹ́ kó rí bẹ́ẹ̀ náà ló rí. Lóṣù July, Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ilẹ̀ Dominican gbé òfin kan kalẹ̀ láti fi pa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́nu mọ́. Kò sì pẹ́ táwọn ọlọ́pàá fi bẹ̀rẹ̀ sí í lu àwọn ará wa tí wọ́n sì ń fojú wọn rí màbo. Lápapọ̀, àádọ́jọ [150] ni wọ́n mú lára àwọn ará wa.