ORÍLẸ̀-ÈDÈ DOMINICAN
Atako Lilekoko
“Wọ́n Máa Fikú Ṣèfà Jẹ”
Wọ́n ṣì fòfin de iṣẹ́ ìwàásù wa nígbà tí Borbonio Aybar ṣèrìbọmi ní January 19, ọdún 1955. Lẹ́yìn tó ṣèrìbọmi, ọ̀pọ̀ èèyàn ló kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní ìlú Monte Adentro àti ní Santiago. Ìyàwó rẹ̀ àti àwọn kan lára àwọn tó kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ náà sì ṣèrìbọmi lọ́dún 1956 tí wọ́n mú ìfòfindè náà kúrò.
Ní nǹkan bí ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù July, ọdún 1957, àwọn aláṣẹ ìjọba pàdé nílùú Salcedo láti bu ẹnu àtẹ́ lu àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Arákùnrin Aybar sọ pé: “Francisco Prats-Ramírez ni abẹnugan láàárín wọn.” Ó ní: “Prats-Ramírez sọ pé, ‘Láàárín ọjọ́ mélòó kan sí i, wọ́n máa fikú ṣèfà jẹ.’” Ní ọjọ́ mélòó kan lẹ́yìn náà, ìyẹn ní July 19, 1957, àwọn ọlọ́pàá mú gbogbo Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nílùú Blanco Arriba, El Jobo, Los Cacaos àti Monte Adentro.
Arákùnrin Aybar sọ pé: “Mo wà lára àwọn tí wọ́n mú. Wọ́n kó wa lọ sí oríléeṣẹ́ àwọn ológun ní Salcedo. Bá a ṣe ń débẹ̀ báyìí, ọ̀gágun àgbà kan tó ń jẹ́ Saladín bẹ̀rẹ̀ sí í lù mí. Ńṣe lojú rẹ̀ ń pọ́n fòò bó ṣe ń halẹ̀ mọ́ wa. Lẹ́yìn náà, wọ́n ní ká tò sórí ìlà méjì, ọkùnrin lọ́tọ̀ obìnrin lọ́tọ̀. Àwọn ẹ̀ṣọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í fi igi ọwọ́ wọn gún àwa ọkùnrin, wọ́n fi ń lù wá, wọ́n sì tún ń là á mọ́ àwọn obìnrin. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń sọ pé, ‘Ẹlẹ́sìn Kátólíìkì ni mí, àmọ́ mò ń pààyàn.’”
“Mo ti ka Bíbélì, mo sì mọ̀ pé Jèhófà ni Ọlọ́run”
Wọ́n ní kí Arákùnrin Aybar sanwó ìtanràn kó sì ṣẹ̀wọ̀n oṣù mẹ́ta. Ó sọ pé: “Nígbà tá a wà lẹ́wọ̀n, olórí ogun tó ń jẹ́ Santos Mélido Marte wá bẹ̀ wá wò. Ó sọ fún wa pé: ‘Mo ti ka Bíbélì, mo sì mọ̀ pé Jèhófà ni Ọlọ́run. Ẹ̀wọ̀n tẹ́ ẹ wà yìí kò tọ́ sí yín rárá, àmọ́ kò sóhun tí
mo lè ṣe nípa rẹ̀ torí pé àwọn bíṣọ́ọ̀bù Kátólíìkì ló wà nídìí ọ̀rọ̀ yìí. Àwọn bíṣọ́ọ̀bù yẹn tàbí jefe (tó túmọ̀ sí “ọ̀gá àgbà,” ìyẹn Trujillo) ni wọ́n sì lè dín iye ọdún tẹ́ ẹ máa fi ṣẹ̀wọ̀n kù.’”“Ṣéwọ Lọ̀gá?”
Àwọn ọmọ Arábìnrin Fidelia Jiménez àtàwọn ọmọ àbúrò rẹ̀ tí gbogbo wọ́n jẹ́ obìnrin wà lára àwọn tí wọ́n mú. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò mú Fidelia tó kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó lọ fa ara rẹ̀ kalẹ̀ fáwọn aláṣẹ pé kí wọ́n fi òun sẹ́wọ̀n kí ìyẹn lè jẹ́ ìṣírí fáwọn tó ti wà lẹ́wọ̀n. Nígbà yẹn, Ludovino Fernández, ọ̀gá àgbà àwọn ológun táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa pé ó burú gan-an ṣèbẹ̀wò sí ọgbà ẹ̀wọ̀n náà. Ó ní kí wọ́n pe Fidelia wá, ó sì bi í pé, “Ṣéwọ lọ̀gá?”
Fidelia fèsì pé: “Rárá o, gbogbo yín pátá lọ̀gá.”
Fernández dá a lóhùn pé: “Ó dáa, ìwọ ni pásítọ̀.”
Fidelia sọ pé: “Rárá o, Jésù ni pásítọ̀.”
Fernández wá bi í pé: “Ìwọ lo fà á táwọn èèyàn yìí fi dèrò ẹ̀wọ̀n, àbíwọ kọ́ lo kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́?”
Fidelia sọ pé: “Rárá o, torí pé wọ́n ń tẹ̀ lé ohun tí wọ́n kọ́ nínú Bíbélì ni wọ́n ṣe fi wọ́n sẹ́wọ̀n.”
Bí wọ́n ṣe ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ ni àwọn arákùnrin méjì kọjá, ìyẹn Pedro Germán àti Negro Jiménez, tí wọ́n jẹ́ ọmọ ẹ̀gbọ́n bàbá Fidelia. Wọ́n ń mú wọn kúrò ní àtìmọ́lé tí wọ́n wà tẹ́lẹ̀ lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n. Ẹ̀jẹ̀ ti gan mọ́ ẹ̀wù Negro, ojú Pedro sì wú gan-an. Nígbà tí Fidelia rí bí wọ́n ṣe lù wọ́n ní àlùbami, ó bi ọ̀gá àwọn ológun náà pé, “Ṣé ohun tẹ́ ẹ máa ń ṣe sáwọn olóòótọ́ èèyàn, tí wọ́n jẹ́ ọmọlúwàbí, tí wọ́n sì bẹ̀rù Ọlọ́run rèé?” Nígbà tí Fernández rí i pé ọ̀rọ̀ òun kò ba Fidelia lẹ́rù rárá, ó sọ pé kí wọ́n mú un pa dà sẹ́wọ̀n.
Àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà nílò ìgboyà láti kojú irú àtakò lílekoko yìí. Wọ́n sì jẹ́ onígboyà lóòótọ́! Kódà, àwọn aláṣẹ ìjọba náà mọ̀ bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ní July 31, ọdún 1957, Luis Arzeno Colón tó jẹ́ aṣojú ààrẹ kọ̀wé sí aṣojú ìjọba nínú ọ̀ràn ilẹ̀ òkèèrè, ó ṣàròyé pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé òfin tí wọ́n gbé jáde níbi Àpérò Ìjọba sọ pé ẹ̀sìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tá a mọ̀ sí ẹ̀ya ẹ̀sìn kò bófin mu, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ wọn ni kò jáwọ́ nínú ẹ̀sìn náà.”