Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍLẸ̀-ÈDÈ DOMINICAN

Awon Mejilelogun Fi Soosi Sile

Awon Mejilelogun Fi Soosi Sile

Ọ̀GBẸ́NI German Gomera ni ìkẹwàá nínú ọmọ mọ́kànlá táwọn òbí rẹ̀ bí. Lẹ́yìn tí bàbá rẹ̀, ẹ̀gbọ́n rẹ̀ obìnrin àti èyí àbígbẹ̀yìn kú, Luisa, ìyá wọn àtàwọn yòókù kó lọ sí ìgboro. Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì àwọn kan tó yapa kúrò nínú ẹ̀sìn Pùròtẹ́sítáǹtì, ìyẹn àwọn Mẹ́nónáìtì. Ibẹ̀ làwọn ẹ̀gbọ́n Luisa, àtàwọn ẹbí wọn ń lọ tẹ́lẹ̀.

German sọ pé: “Ní ọdún 1962, tọkọtaya aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe kan dé sí ìlú náà. Àwọn èèyàn wá bẹ̀rẹ̀ sí í sọ pé ṣe ni wọ́n ń fi ‘ẹ̀kọ́ nípa èṣù’ dojú ìgbàgbọ́ àwọn aráàlú dé. Àmọ́ nígbà tí tọkọtaya yìí wá sí ilé àwọn Piña, wọ́n ní kí wọ́n wọlé. Àwọn tó wà nínú ìdílé Piña náà pọ̀ díẹ̀. Wọ́n tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́ sí ọ̀rọ̀ àwọn aṣáájú-ọ̀nà yìí torí pé inúure wọn àti bí wọ́n ṣe kóni mọra wú wọn lórí gan-an. Èyí mú kí ìdílé Piña àti mẹ́ta lára àwọn ẹ̀gbọ́n mi obìnrin bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.”

German ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Lọ́jọ́ kan tí àwọn aṣáájú-ọ̀nà yẹn wá sọ́dọ̀ àwọn Piña, wọ́n pe màmá mi wá síbẹ̀. Wọ́n ka àwọn ẹsẹ Bíbélì tó sọ̀rọ̀ nípa wíwà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé. Màmá mi wá bi wọ́n pé, ‘Kí wá nìdí tí wọ́n fi máa ń sọ ní ṣọ́ọ̀ṣì wa pé ọ̀run là ń lọ?’ Lẹ́yìn tí arákùnrin náà fi Bíbélì dáhùn ìbéèrè yìí, tó sì ṣàlàyé ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa àjíǹde sórí ilẹ̀ ayé, ọ̀rọ̀ yẹn yé màmá mi, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ohun tó kọ́ yìí fáwọn èèyàn.”

“Nígbà táwọn pásítọ̀ Ṣọ́ọ̀ṣì Mẹ́nónáìtì rí i pé àwọn ọmọ ìjọ wọn ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n gbìyànjú láti dá wọn dúró. Wọ́n torí rẹ kanra mọ́ àwọn èèyàn wọn, wọ́n sì halẹ̀ mọ́ wọn. Màmá àwọn Piña, ìyẹn Maximina, sọ fún wọn pé, ‘Ẹ wò ó! Mo ti dàgbà, mo sì ti tó dá ìpinnu ṣe.’”

German sọ pé: “Nígbà tó yá, ẹni méjìlélógún [22] ló fi ṣọ́ọ̀ṣì náà sílẹ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í wá sípàdé ìjọ tá à ń ṣe nílé kan tá a háyà. Ọdún 1965 ni màmá mi ṣèrìbọmi, èmi náà sì ṣèrìbọmi ní ọdún mẹ́rin lẹ́yìn náà, ìyẹn ọdún 1969, nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́tàlá [13].”

German àtàwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ obìnrin rèé. Gbogbo wọn ń sin Jèhófà tọkàntọkàn