Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍLẸ̀-ÈDÈ DOMINICAN

“O Da Mi Loju Pe Ijoba Olorun Maa De”

Efraín De La Cruz

“O Da Mi Loju Pe Ijoba Olorun Maa De”
  • WỌ́N BÍ I NÍ 1918

  • Ó ṢÈRÌBỌMI NÍ 1949

  • ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ Ó rọ̀ mọ́ ìpinnu rẹ̀ láti máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n fi í sẹ́wọ̀n tí wọ́n sì lù ú ní àlùbami ní ọgbà ẹ̀wọ̀n méje ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.

LỌ́DÚN 1948, èmi àti Paula, ìyàwó mi pẹ̀lú ọmọ wa obìnrin bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sípàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Blanco Arriba. Ìrìn ogójì [40] kìlómítà la máa ń rìn ní àlọ àti àbọ̀, síbẹ̀ a kì í pa ìpàdé kankan jẹ. Èmi àti Paula ṣèrìbọmi ní January 3, ọdún 1949.

Ní oṣù mẹ́fà lẹ́yìn náà, wọ́n mú àwa kan nínú ìjọ wa, wọ́n sì fi wá sẹ́wọ̀n oṣù mẹ́ta. Ilẹ̀ẹ́lẹ̀ là ń sùn, oúnjẹ wa ò sì kọjá tíì àti ọ̀gẹ̀dẹ̀ dúdú lẹ́ẹ̀kan lójúmọ́. Nígbà tí wọ́n tú wa sílẹ̀, àwọn aláṣẹ ìjọba halẹ̀ mọ́ wa, wọ́n sì rò pé ìyẹn á mú ká dáwọ́ ìwàásù dúró. Àmọ́ nígbà tá a pa dà sílé, à ń dọ́gbọ́n wàásù, a sì ń ṣèpàdé ní ìkọ̀kọ̀. Inú ilé àdáni, oko kọfí tàbí àwọn oko míì la ti ń ṣèpàdé torí pé àwọn aláṣẹ ìjọba máa ń ṣọ́ wa lọ́wọ́ lẹ́sẹ̀. Dípò ká máa ṣèpàdé déédéé níbì kan náà, ìparí ìpàdé kọ̀ọ̀kan la máa ń sọ ibi tá a ti máa ṣe ìpàdé tó tẹ̀ lé e. Ṣe la máa ń dá wàásù; aṣọ iṣẹ́ là ń wọ̀, a kì í sì í mú ìtẹ̀jáde tàbí Bíbélì dání. Láìka gbogbo ọgbọ́n tá a dá yìí sí, ìgbà méje ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n jù mí sẹ́wọ̀n lọ́dún 1949 sí 1959, mo sì máa ń lò tó oṣù mẹ́ta sí mẹ́fà nígbà kọ̀ọ̀kan.

Mo máa ń ṣọ́ra gan-an torí pé díẹ̀ lára àwọn mọ̀lẹ́bí mi wà lára àwọn tó ń ṣenúnibíni sí mi. Bó tilẹ̀ jẹ pé mo máa ń lọ sùn sórí òkè tàbí sínú oko kí wọ́n má bàa mú mi, síbẹ̀ wọ́n ṣì máa ń rí mi mú. Ìgbà kan wà tí wọ́n fi mí sí ọgbà ẹ̀wọ̀n La Victoria nílùú Ciudad Trujillo, àádọ́ta [50] sí ọgọ́ta [60] èèyàn ni wọ́n máa ń fi sínú yàrá kan níbẹ̀. Oúnjẹ ẹ̀ẹ̀mejì ni wọ́n máa ń fún wa lóòjọ́. Wọ́n á fún wa ní túwó láàárọ̀, wọ́n á sì fún wa ní ìrẹsì àti ẹ̀wà díẹ̀ lọ́sàn-án. Gbogbo àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tá a wà níbẹ̀ la máa ń wàásù fún àwọn tá a jọ wà lẹ́wọ̀n, a sì máa ń ṣèpàdé déédéé. Láwọn ìpàdé náà, a máa ń ka Bíbélì lórí, a sì máa ń sọ àwọn ìrírí tá a ní lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù.

Nígbà tí wọ́n fi mí sẹ́wọ̀n kẹ́yìn, sójà kan fọ́ ìdí ìbọn mọ́ mi lórí, ó sì tún fọ́ ọ mọ́ egungun ìhà mi. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ṣì máa ń jẹ̀rora lílù yẹn àtàwọn ìyà míì tí wọ́n fi jẹ mí, àwọn àdánwò yẹn fún mi lókun, wọ́n jẹ́ kí n lè túbọ̀ ní ìfaradà, kí n sì lè rọ̀ mọ́ ìpinnu mi láti sin Jèhófà.

Mo ti pé ẹni ọdún mẹ́rìndínlọ́gọ́rùn-ún [96] báyìí, mo sì jẹ́ ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ nínú ìjọ. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé mi ò lè rin ọ̀nà jíjìn mọ́, mo máa ń jókòó síwájú ilé mi kí n lè máa wàásù fún gbogbo àwọn tó bá ń kọjá. Ó dá mi lójú gbangba pé Ìjọba Ọlọ́run máa dé. Ó ti lé ní ọgọ́ta [60] ọdún ti mo ti ń wàásù Ìjọba Ọlọ́run. Bó ṣe dá mi lójú pé ayé tuntun máa dé nígbà tí mo kọ́kọ́ gbọ́ nípa rẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe dá mi lójú títí dòní olónìí. *

^ ìpínrọ̀ 3 Ìgbà tá à ń kọ ìtàn yìí ni Efraín De La Cruz kú.