Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Tàǹsáníà: Àwọn èèyàn tó ń lọ tó ń bọ̀ yà láti wo àwọn ìwé tá a pàtẹ nílùú Dar es Salaam

ÀWỌN OHUN PÀTÀKÌ TÓ ṢẸLẸ̀ LỌ́DÚN TÓ KỌJÁ

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Dé Ọ̀dọ̀ Àwọn Tí A Kì Í Bá Nílé

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Dé Ọ̀dọ̀ Àwọn Tí A Kì Í Bá Nílé

LÓÒÓTỌ́, wíwàásù láti ilé dé ilé ló gbawájú lára àwọn ọ̀nà táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà ń mú ìhìn rere tọ àwọn èèyàn lọ. Àmọ́, a tún máa ń pàtẹ àwọn ìwé wa tó jẹ́ àrímáleèlọ sórí tábìlì àtàwọn kẹ̀kẹ́ tó ṣeé tì kiri, àwọn ọ̀nà yìí sì ń jẹ́ wa lọ́wọ́ gan-an débi pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń gbọ́ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. (Mát. 24:14) Àwọn tó ń wàásù Ìjọba Ọlọ́run ti lo àwọn káńtà, tábìlì àtàwọn nǹkan míì láti wàásù fáwọn èèyàn níbi térò pọ̀ sí. Láfikùn síyẹn, ètò Ọlọ́run ti fi àwọn kẹ̀kẹ́ tá a fi ń pàtẹ àwọn ìwé wa tó tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún méjì ó lé àádọ́ta [250,000] ránṣẹ̀ sáwọn ìjọ kárí ayé. Ǹjẹ́ àwọn ètò yìí tíẹ̀ méso jáde?

Lọ́dún 2014 a bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù lákànṣe níbi táwọn èrò pọ̀ sí nílùú Dar es Salaam, lórílẹ̀-èdè Tàǹsáníà. Èyí tá à ń wí yìí pẹ́, àwọn bí ọgọ́rùn-ún méje [700] èèyàn ló ní ká wá máa kọ́ àwọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ọ̀pọ̀ tó nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́ Bíbélì ti ń wá sáwọn ìpàdé wa, wọ́n sì túbọ̀ ń sún mọ́ Ọlọ́run. Lọ́dún kan péré, iye ìwé táwọn aláwọ̀ dúdú àtàwọ̀n tó wá látòkè òkun mú láwọn ibi ìpàtẹ wa lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún méjì ó lé àádọ́ta [250,000].

Àwọn erékùṣù tó para pọ̀ jẹ́ Solomon Islands lé ní ọgọ́rùn-ún mẹ́ta [300], àwọn ará wa tó sì ń wàásù níbẹ̀ kò tó ẹgbẹ̀rún méjì [2000]. Torí náà, wọ́n máa ń pàtẹ àwọn ìwé wa lákànṣe síbi táwọn èrò pọ̀ sí, èyí sì mú kí wọ́n tan irúgbìn òtítọ́ náà kiri. Ní Honiara tó jẹ́ olú-ìlú orílẹ̀-èdè náà, ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún kan àti mẹ́rin [104,000] ìwé ìròyìn àti ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlélógún ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́fà [23,600] ìwé pẹlẹbẹ làwọn ará wa pín fáwọn èèyàn, tí ọ̀pọ̀ wọn ń gbé níbi tí kò sí Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Lọ́sàn-án ọjọ́ kan ṣoṣo, ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? tàwọn èèyàn gbà tó ọgọ́rùn-ún mẹ́rin [400]. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn èèyàn bí ọgọ́ta [60] ló ní ká wá máa kọ́ àwọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Láàárọ̀ ọjọ́ kan tí Michael àti Linda tó jẹ́ tọkọtaya aṣáájú-ọ̀nà déédéé ń to àwọn ìwé wa sórí àtẹ nítòsí etíkun erékùṣù Margarita Island, lórílẹ̀-èdè Fẹnẹsúélà, ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Aníbal wá sọ́dọ̀ wọn ó sì gba ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni. Ó sọ fún wọn pé ọdún méje rèé tí bàbá òun kú sí etíkun yẹn àti pé àtìgbà yẹn ni màmá òun kò ti gbádùn. Lọ́sẹ̀ tó tẹ̀ le e, Aníbal tún wá sétíkun yẹn ó sì sọ fún Michael àti Linda pé ọjọ́ yẹn ni àyájọ́ ọjọ́ tí bàbá òun kú. Ó wá yọ fóònù rẹ̀ jáde, ó pe màmá rẹ̀ ó sì ní kí Michael jọ̀ọ́ bá òun sọ̀rọ̀ ìtùnú fún màmá òun, arákùnrin wa sì ṣe bẹ́ẹ̀. Látìgbà yẹn ni màmá náà ti máa ń pe Michael àti Linda lórí fóònù, àwọn náà sì máa ń fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tù ú nínú. Obìnrin náà kọ ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ lórí fóònù, ó sọ pé, “Mo dúpẹ́, ojoojúmọ́ lara mi ń le sí i torí pé àwọn ọ̀rọ̀ yín ń tù mí nínú, ẹ sì ti mú kí ìgbàgbọ́ mi túbọ̀ lágbára.”

Lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, a pàtẹ àwọn ìwé wa lákànṣe sílùú mẹ́rìnlá [14] níbi térò pọ̀ sí, àmọ́ tá a bá ka ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tá a pàtẹ sí, ó tó mẹ́tàdínláàádóje [127]. Láàárín oṣù méje àkọ́kọ́ lọ́dún iṣẹ́ ìsìn 2015, ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tá a bẹ̀rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ ọgọ́rùn-ún mẹ́rin àti márùndínláàádọ́ta [8,445]! Ọ̀nà tá à ń gbà wàásù yìí ti mú ká ṣalábàápàdé àwọn tó ti wà nínú òtítọ́ rí, ó sì ti jẹ́ ká ran irú àwọn bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ láti pa dà máa jọ́sìn Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Terry wá síbi tá a pàtẹ ìwé wa sí nílùú Los Angeles, ní ìpínlẹ̀ California. Tọkọtaya Ẹlẹ́rìí tó dúró sídìí ìpàtẹ náà wá bi í bóyá ó tí ka àwọn ìwé wa rí. Ó sọ fún wọn pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà lòun náà àmọ́ ó ti ń lọ sọ́dún mẹ́rin báyìí tóun dara pọ̀ kẹ́yìn. Tọkọtaya náà wá bá a jíròrò ohun tó wà nínú ìwé Ìsíkíẹ́lì 34:11, níbi tí Jèhófà ti sọ pé: ‘Èmi yóò wá àwọn àgùntàn mi, èmi yóò sì bójú tó wọn dájúdájú.’ Wọ́n tún sọ fún un nípa ìkànnì wa àti Ètò Tẹlifíṣọ̀n JW. Láàárọ̀ ọjọ́ kejì, Terry fi lẹ́tà ránṣẹ́ sárákùnrin náà lórí fóònù, ó ṣàlàyé pé kó tó di pé òun wá bá wọn níbi ìpàtẹ náà, òun bẹ Jèhófà pé kó jọ̀ọ́, kó dárí ji òun pé òun pa ìpàdé ìjọ tì. Ó sọ pé òun tún bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kóun lè túbọ̀ sún mọ́ ọn. Terry wá sọ pé, “Kí ni mo dọ́dọ̀ yín sí, ẹ kí mi tẹ̀rín tọ̀yàyà, ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tẹ́ ẹ kà fún mi níṣìírí gan-an, ẹ sì jẹ́ kí n mọ ohun tí màá ṣe láti pa dà sínú ètò Jèhófà. Kí n sòótọ́, ẹ̀yin ni Jèhófà lò láti dáhùn àdúrà mi.”

Ibi mẹ́rin lára ibi táwọn èrò máa ń pọ̀ sí nílùú Addis Ababa, lórílẹ̀-èdè Etiópíà la pàtẹ àwọn ìwé wa sí lákànṣe. Lẹ́nu oṣù mẹ́ta péré, ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlógójì ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó dín mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [37,275] ìwé wa làwọn èèyàn gbà, tí àwọn èèyàn ọgọ́rùn-ún mẹ́fà ó lé mọ́kàndínlọ́gbọ̀n [629] sì fẹ́ ká wá máa kọ́ àwọn lẹ́kọ̀ọ́. Lára àwọn tó gba ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni ni bàbá àgbàlagbà kan. Gbàrà tó gba ìwé náà lo ti bẹ̀rẹ̀ sí í kà á. Ó ti lọ sílé ẹ̀kọ́ àwọn àlùfáà, ọ̀pọ̀ nǹkan ló sì fẹ́ mọ̀ nípa Jésù àti Ìjọba Ọlọ́run. Torí bẹ́ẹ̀, lọ́jọ́ kejì, ó wá síbi táwọn ará wa pàtẹ sí kó lè rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè rẹ̀. Lọ́jọ́ kẹta, ó gbà kí wọ́n wá máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, nígbà tọ́sẹ̀ yẹn fi máa parí, ó bẹ̀rẹ̀ sí í wá sípàdé wa. Ní báyìí, kì í pa ìpàdé kankan jẹ, ó sì ń tẹ̀ síwájú gan-an.

Etiópíà: Àwọn ìwé wa lédè Amharic la pàtẹ yìí nílùú Addis Ababa

Ọkùnrin kan tó jẹ́ Júù wá síbi tá a pàtẹ àwọn ìwé wa sí lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò ó sì ní káwọn arákùnrin méjì tó wà ńbẹ̀ fún òun níwèé tó sọ̀rọ̀ nípa ikú. Wọ́n sọ fún un pé irú ìwé bẹ́ẹ̀ ti tán lọ́wọ́ àwọn, àmọ́ wọ́n ni kó gba èyí tó sọ̀rọ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la. Ọkùnrin náà gbá arákùnrin wa lápá mú, ó sì sọ fún un pé: “Mi ò bá ẹ sọ̀rọ̀ ọjọ́ ọ̀la. Bí màá ṣe pa ara mi ni mò ń wá.” Kí ló sọ bẹ́ẹ̀ sí, ló bá bẹ̀rẹ̀ sí i sunkún. Wọ́n wá béèrè ìdí tó fi fẹ́ pa ara rẹ̀. Ó dáhùn tàánútàánú pé kò pẹ́ tọ́mọkùnrin òun kú. Làwọn arákùnrin wa bá fi orí 7 ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni hàn án. Wọ́n ka ìpínrọ̀ méjì tó wà lábẹ́ ìsọ̀rí ọ̀rọ̀ tó sọ pé “Nígbà Téèyàn Ẹni Bá Kú”, wọ́n sì tún ka apá ìparí nínú orí náà, tó sọ ìrètí tó wà fáwọn to ti kú. Ara tu ọkùnrin náà, ló bá tún di apá arákùnrin wa mú, ó sì wí pé, “Ṣé ohun tó o kà yìí á sì rí bẹ́ẹ̀?” Àwọn arákùnrin náà mú kó dá a lójú pé awí-bẹ́ẹ̀-ṣe-bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà. Ó wá bi wọ́n pé, “Kí ni màá ṣe kí n lè tún rí ọmọkùnrin mi?” Wọ́n ṣètò pé àwọn á wá bá a nílé. Nígbà tí wọ́n máa délé ọkùnrin náà, wọ́n rí i pé o ti wà ní sẹpẹ́, tó ń dúró dè wọ́n kí wọ́n lè kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Alábòójútó arìnrìn-àjò kan tó ran àwọn ìjọ lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ àkànṣe ìwàásù láwọn ìlú tí èrò pọ̀ sí nílùú New York sọ bó ṣe rí lára rẹ̀, pé “Ẹ wo bí Jèhófà ti bù kún ìṣètò yìí! Inú wa dùn pé ó jẹ́ ká lè wàásù fún àìmọye èèyàn, àmọ́ èyí tó pabanbarì ni pé ó jẹ́ ká ṣalábàápàdé àwọn àgùntàn Jèhófà tó ti sọnù, ìyẹn àwọn tó fi ètò Jèhófà sílẹ̀ àtàwọn tá a yọ lẹ́gbẹ́, tá a sì tipa bẹ́ẹ̀ ràn wọ́n lọ́wọ́ láti pa dà sínú agbo.”Ìsíkíẹ́lì 34:15, 16.