INDONÉṢÍÀ
A Tẹ̀ Lé Ìtọ́ni—A Sì Yè!
Blasius da Gomes
-
WỌ́N BÍ I NÍ 1963
-
Ó ṢÈRÌBỌMI NÍ 1995
-
ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ Ọ̀kan lára àwọn alàgbà tó bójú tó àwọn ará nígbà ìjà ẹ̀sìn tó wáyé nílùú Ambon tó jẹ́ ara àwọn erékùṣù Maluku.
NÍ January 19, 1999, àìgbọ́ra-ẹni-ye tó ti wà láàárín àwọn Mùsùlùmí àtàwọn Kristẹni wá di ìjà ìgboro. Ibi tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ ìjà yìí ò ju nǹkan bí kìlómítà mẹ́ta sí ilé tí mò ń gbé. Ìjà tá à ń wí yìí gbóná, ó kọjá àfẹnusọ. *
Mo kọ́kọ́ dáàbò bo ìdílé mi, lẹ́yìn náà ni mo bẹ̀rẹ̀ sí í fóònù àwọn ará láti béèrè àlàáfíà wọn. Mo fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀, mo sì rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n má ṣe rìn lágbègbè ibi tí wàhálà náà ti ń ṣẹlẹ̀. Nígbà tó yá, àwọn alàgbà bẹ àwọn ará wò láti gbé wọn ró nípa tẹ̀mí, wọ́n sì tún rọ̀ wọ́n láti jọ́sìn pọ̀ ní àwùjọ kéékèèké.
Ẹ̀ka ọ́fíìsì náà tún rọ̀ wá pé ká ṣètò bí àwọn ará tó wà ní àgbègbè tó léwu ṣe máa kúrò níbẹ̀, a sì ṣètò bí ìsọfúnni náà ṣe máa dé ọ̀dọ̀ gbogbo ìdílé. Arákùnrin kan kọ̀ láti kúrò níbẹ̀. A pa dà gbọ́ pé àwọn jàǹdùkú náà pa á. Àmọ́ gbogbo àwọn ará tó tẹ̀ lé ìtọ́ni náà ló yè.
^ ìpínrọ̀ 1 Ìjà yìí gba gbogbo àgbègbè Maluku fún nǹkan bí ọdún méjì, ó sì mú kí ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn sá kúrò nílé.