INDONÉṢÍÀ
Àwọn Míṣọ́nnárì Míì Tún Dé
Ní July 9, 1964, Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́ ti orílẹ̀-èdè Indonéṣíà fi orúkọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sílẹ̀ lábẹ́ ofin. Orúkọ tí wọ́n lò ni Ẹgbẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àmọ́ káwọn ará tó lè lo àǹfààní òmìnira ẹ̀sìn wọn lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́, wọ́n gbọ́dọ̀ forúkọ sílẹ̀ lọ́dọ̀ Ilé Iṣẹ́ Ètò Ẹ̀sìn. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ọ̀dọ̀ Ilé Iṣẹ́ Ètò Àwọn Kristẹni, ìyẹn Directorate General of Christian Community Guidance ni Ilé Iṣẹ́ Ètò Ẹ̀sìn ti sábà máa ń gbàmọ̀ràn. Àwọn ògbóǹkangí oníṣọ́ọ́ṣì tí wọ́n kóríìra àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló sì ń darí Ilé Iṣẹ́ Ètò Àwọn Kristẹni.
Lọ́jọ́ kan, arákùnrin kan pàdé ọ̀gá kan tó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú mínísítà fún Ilé Iṣẹ́ Ètò Ẹ̀sìn. Ibi tí wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ ni wọ́n ti mọ̀ pé abúlé kan náà làwọn ti wá, ni wọ́n bá
bẹ̀rẹ̀ sí í sọ èdè ìbílẹ̀ wọn. Arákùnrin wa sọ ìṣòro táwa Ẹlẹ́rìí ń dojú kọ lọ́dọ̀ Ilé Iṣẹ́ Ètò Àwọn Kristẹni. Ọ̀gá yìí wá ṣètò pé kí àwọn arákùnrin mẹ́ta lọ pàdé mínísítà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Mùsùlùmí ni mínísítà yìí, èèyàn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ tó ń gba tẹni rò ni. Ní May 11, ọdún 1968, mínísítà yìí fún wa ní ìwé àṣẹ pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà di ẹ̀sìn tí ìjọba fọwọ́ sí, bá a ṣe lómira láti máa bá iṣẹ́ wa lọ ní Indonéṣíà nìyẹn o.Ọ̀gá yẹn tún ṣèrànwọ́ bí àwọn míṣọ́nnárì láti orílẹ̀-èdè míì ṣe rí ìwé ìrìnnà gbà láì jẹ́ kí ó gba ọ̀dọ̀ Ilé Iṣẹ́ Ètò Àwọn Kristẹni kọjá. Ọlá ọ̀gá rere yìí la jẹ́ tá a fi rí míṣọ́nnárì mẹ́rìnlélọ́gọ́ta [64] mú wọ Indonéṣíà láàárín ọdún mélòó kan.
Nígbà tó fi máa di ọdún 1968, ọg̣ọ́rùn-ún mẹ́ta [300] míṣọ́nnárì àti ẹgbẹ̀fà [1,200] aṣáájú-ọ̀nà ló ń wàásù káàkiri Indonéṣíà. Àwọn míṣọ́nnárì yìí ran àwọn arakùnrin tó ń gbé ní Indonéṣíà lọ́wọ láti di ọ̀jáfáfá kí òtítọ́ sì jinlẹ̀ nínú wọn. Ìrànlọ́wọ́ yìí sì bọ́ sí àkókò torí pé òjò inúnibíni ò ní pẹ́ rọ̀ lé àwọn ará lórí ní orílẹ̀-èdè náà.
“Ẹ̀bùn Ọdún Kérésì” fáwọn Àlùfáà Ṣọ́ọ̀ṣì
Lọ́dún 1974, Ilé Iṣẹ́ Ètò Àwọn Kristẹni tún bẹ̀rẹ̀ sí í fínná mọ́ àwọn ìjọba pé kí wọ́n fòfin de àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Olùdarí Ilé Iṣẹ́ Ètò Àwọn Kristẹni kọ̀wé sí gbogbo ẹ̀ká Ilé Iṣẹ́ Ètò Ẹ̀sìn pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò sí lára ẹ̀sìn tí ìjọba fọwọ́ sí, torí nàà bí Ẹlẹ́rìí èyíkéyìí bá fa “ìdíwọ́” fún wọn, kí wọ́n gbógun tì wá. Lọ́rọ̀ kan, ohun táwọn alùfáà yìí ń sọ ni pé kí ìjọba ṣe inúnibíni sí àwọn èèyàn Jèhófà. Ọ̀pọ̀ àwọn aláṣẹ tó gbọ́rọ̀ náà kàn gbé lẹ́tà yẹn sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan ni, àmọ́ àwọn míì fìyẹn kẹ́wọ́ láti fòfin de àwọn ìpàdé wa àti ìwàásù ilé-dé-ilé.
Lákòókò yẹn náà ni Ìgbìmọ̀ Ṣọ́ọ̀ṣì Àgbáyé (WCC) ń múra láti ṣe àpéjọ wọn ní Jakarta, àmọ́ àwọn Mùsùlùmí sọ pé àfàìmọ̀ kí àpéjọ yẹn má dá wàhálà sílẹ̀ nítorí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn tó ń jà ràn-ìn. Èyí mú kí Ìgbìmọ̀ Ṣọ́ọ̀ṣì Àgbáyé wọgí lé àpéjọ náà. Nǹkan ò rọgbọ nílùú lásìkò tá à ń sọ yìí. Ìdí sì ni pé bí àwọn ẹlẹ́sìn Kristẹni ṣe ń sọ àwọn èèyàn di Kristẹni ti dariwo nílùú. Torí bẹ́ẹ̀, ẹ̀rù ń ba ọ̀pọ̀ àwọn olóṣèlú pé nǹkan lè yíwọ́. Bíi ti àtẹ̀yìnwá, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì dẹ̀bi rù, pé ìwàásù tá à ń ṣe kiri ló fẹ́ dá wàhálà sílẹ̀. Làwọn aláṣẹ ìjọba bá bẹ̀rẹ̀ sí í fojú òbálújẹ́ wò wá.
Gbogbo nǹkan ṣáà ń le sí i. Nígbà tó di December 1975, orílẹ̀-èdè Indonéṣíà lọ kógun ja East Timor tá a wá mọ̀ sí Timor-Leste lónìí, tó wà lábẹ́ àkoso orílẹ̀-èdè Potogí tẹ́lẹ̀. Lẹ́yìn oṣù méje, East Timor bọ́ sọ́wọ́ Indonéṣíà, èyí sì fa ìjà abẹ́lé jákèjádò orílẹ̀-èdè Indonéṣíà. Àwọn ará wa kò bá wọn dá sí rògbòdìyàn ìṣèlú yìí, wọ́n sì kọ̀ láti jagun tàbí kí àsíá, èyí múnú bí àwọn ọ̀gá ológun. (Mát. 4:10; Jòh. 18:36) Báwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì ṣe lo àǹfààní yẹn láti mú kí ìjọba fòfin de àwa Ẹlẹ́rìí nìyẹn. Ìgbà tí ìjọba kéde ní December 1976 pé wọ́n ti fòfin de àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ṣé ló dà bíi pé àwọn alùfáà ṣọ́ọ̀ṣì gba “Ẹ̀bun Ọdún Kérésì.”