Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ibi ayẹyẹ ìgbéyàwó la ti máa ń ṣe àpéjọ

INDONÉṢÍÀ

Wọ́n Ò fi Ọ̀rọ̀ Ìpàdé Ṣeré

Wọ́n Ò fi Ọ̀rọ̀ Ìpàdé Ṣeré

Ní gbogbo ìgbà tí wọ́n fòfin dè iṣẹ́ wa, ọ̀pọ̀ àwọn ará ló ṣì ń pàdé pọ̀ ní àwọn ilé àdáni láti jọ́sìn Jèhófà. Àmọ́ wọn kì í kọrin nígbà ìpàdé kí ẹnikẹ́ni má bàa fura sí wọn. Àwọn ìgbà kan wà táwọn aláṣẹ da ìpàdé wọn rú, àmọ́ ìyẹn ò kó ṣìbáṣìbo bá àwọn ará.

Nígbà míì àwọn ará máa ń lo àkókó tí wọ́n ń ṣe ayẹyẹ ìgbéyàwó tàbí ìpàdé ẹbí láti ṣe àpéjọ àyíká àti ti àgbègbè. Arákùnrin Tagor Hutasoit sọ pé: “Táwọn tọkọtaya bá ti forúkọ ìgbéyàwó wọn sílẹ̀ lọ́dọ̀ ìjọba ni wọ́n á ti gbàṣẹ lọ́dọ̀ àwọn ọlọ́pàá pé àwọn fẹ́ ṣe àwẹ̀jẹ àwẹ̀mu tó rinlẹ̀. Níbi ayẹyẹ àwẹ̀jẹ àwẹ̀mu náà, tọkọtaya máa jókòó sórí pèpéle, àwọn arákùnrin á sì máa wá sọ àsọyé Bíbélì lónírúurú.”

Ní àpéjọ kan, ọlọ́pàá kan pe Arákùnrin Tagor sẹ́gbẹ̀ẹ́, ó ní:

“Ábà, ṣebí ayẹyẹ ìgbéyàwó kì í ju wákàtí méjì sí mẹ́ta lọ, kí wá ló dé tẹ́ ẹ fi máa ń ṣe tiyín látàárọ̀ ṣúlẹ̀?”

Arákùnrin Tagor fèsì pé: “Ìṣòro táwọn lọ́kọláya kan ní kọjá bẹ́ẹ̀, tórí náà àfi ká fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbà wọ́n níyànjú kí wọ́n lè mọ ohun tó yẹ ní ṣíṣe.”

Ọlọ́pàá náà mi orí, ó ní: “Ó sì tún ríyẹn sọ.”

Lọ́dún 1983, a kóra jọ pé à ń ṣe ìgbéyàwó àwọn ará wa kan ní pápá ìṣeré ńlá kan nílùú Jakarta, a wá ń lò àǹfààní yẹn láti gbádùn ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àpéjọ Àgbègbè “Ìṣọ̀kan Ìjọba” tá a ṣe lọ́dún yẹn. Àwọn ará àtàwọn olùfìfẹ́hàn tó pé jọ fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún mẹ́rin [4,000], àwọn márùnlélọ́gọ́fà [125] la sì ṣèrìbọmi fún ní bòókẹ́lẹ́ kí àpéjọ náà tó bẹ̀rẹ̀. Nígbà tó yá, àwọn aláṣẹ bẹ̀rẹ̀ sí í dẹwọ́ lórí ọ̀ràn ìfòfindè iṣẹ́ wa. Èyí jẹ́ kí àwọn ará lè ṣe àwọn àpéjọ ńlá míì, kódà ọ̀kan tiẹ̀ wà tí èèyàn tó pé jọ lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15,000]!

A Kọ́ Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Nígbà Ìfòfindè Náà

Láàárín ọdún 1980 sí 1999, léraléra ni ẹ̀ka ọ́fíìsì ń kọ̀wé sí ìjọba pé kí wọ́n mú ìfòfindè náà kúrò. Bẹ́ẹ̀ láwọn ará láti orílẹ̀-èdè míì ń kọ̀wé si ìjọba Indonéṣíà àtàwọn aṣojú ìjọba Indonéṣíà tó wà lórílẹ̀-èdè wọn pé kí wọ́n ṣàlàyé ohun tó fà á tí wọn fi fòfin dé iṣẹ́ wa. Ọ̀pọ̀ àwọn aláṣẹ ló fọwọ́ sí i pé kí ìjọba mú ìfòfinde náà kúrò, àmọ́ ńṣe ni ọ̀gá pátápátá tó ń ṣojú fún àwùjọ àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì, ìyẹn Directorate General of Christian Community Guidance, fàáké kọ́rí, ó lóun ò gbà.

Lọ́dún 1990, àwọn ará pinnu pé àwọn á dọ́gbọ́n kọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì tuntun síbi táwọn aláṣẹ ò ní fura sí. Lọ́dún yẹn kan náà, Ìgbìmọ̀ Olùdarí fọwọ́ sí i pé kí wọ́n ra ilẹ̀ kan nítòsí ìlú kékeré kan tí wọ́n ń pè ní Bogor tó wà ní gúúsù Jakarta. Àmọ́, àwọn ará tó mọ̀ nípa ilé kíkọ́ lórílẹ̀-èdè náà kò tó nǹkan. Báwo ni wọ́n a ṣe wá kọ́ ilé yìí?

Èyí tá à ń wí yìí pẹ́, àwọn ará láti àwọn orílẹ̀-èdè míì dìde ìrànwọ́. Ẹ̀ka tó ń bójú tó iṣẹ́ ìkọ́lé ní Brooklyn àti ẹ̀ka tó ń bójú tó iṣẹ́ ẹ̀rọ ní Ọsirélíà ya àwòrán ilé, wọ́n sì fi í ránṣẹ́. Láàárín ọdún méjì tí wọ́n fi kọ́ ilé náà, ọgọ́rùn-ún [100] àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ló yọ̀ǹda ara wọn láti àwọn orílẹ̀-èdè míì.

Arákùnrin Hosea Mansur tó ń gbé ní Indonéṣíà ló sábà máa ń gbẹ́nu sọ fún wa lọ́dọ̀ àwọn aláṣẹ iléeṣẹ́ ìjọba. O sọ pé: “Nígbà táwọn ọ̀gá iléeṣẹ́ ìjọba tí wọ́n jẹ́ Mùsùlùmí rí H.M. tí mo kọ sára akoto mi, wọ́n fi ọ̀wọ̀ wọ̀ mí gan-an. Àṣé lọ́kàn wọn, wọ́n rò pé H dúró fún Hájì, ìyẹn orúkọ tí wọ́n máa ń pe ẹni tó ti lọ́ sí Mẹ́kà bọ̀, ẹ kúkú mọ̀ pé ojú pàtàkì ni wọ́n fi máa ń wo àwọn tó ti lọ sí Mẹ́kà bọ̀. Torí bẹ́ẹ̀, ṣe ni wọ́n ń gbé mi gẹ̀gẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn lẹ́tà tó bẹ̀rẹ̀ orúkọ mi làwọn lẹ́tà náà dúró fún, ohun tí wọ́n rò yẹn ló mú kí ọ̀rọ̀ tí mo bá lọ́ sí ọ́fíìsì náà lójú.”

Nígbà ìfòfindè ni wọ́n kọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì yìí

July 19, 1996 la ya ẹ̀ka ọ́fíìsì tuntun yìí sí mímọ́. Arákùnrin John Barr tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí ló sì sọ àsọyé ìyàsímímọ́ náà. Àwọn ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó dín mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [285] ló pé jọ lọ́jọ́ náà, lára wọn ni àwọn aṣojú láti àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì míì àtàwọn míṣọ́nnárì láti orílẹ̀-èdè míì tí gbogbo wọn jẹ́ méjìdínlọ́gọ́fà [118], bẹ́ẹ̀ náà làwọn mọ́kàndínlọ́gọ́ta [59] tó jẹ́ ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì kò gbẹ́yìn. Ní ọjọ́ méjì tó tẹ̀ lé e, wọ́n ṣe Àpéjọ Àgbègbè “Àwọn Ońṣẹ́ Àlàáfíà Ọlọ́run” ní Jakarta, àwọn tó pé jọ sí jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ, ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ ó dín méje [8,793].

Jèhófà Gba Àwọn Èèyàn Rẹ̀

Lọ́dún 1998, ààrẹ Soeharto (Suharto) tó tí ń ṣàkóso Indonéṣíà látọdún yìí wá kọ̀wé fipò rẹ̀ sílẹ̀, ni ẹlòmíì bá gorí àlééfà. Àwọn ará lo àǹfààní yìí láti fi jára mọ́ ìsapá wọn kí ìjọba tuntun yìí lè mú ìfòfindè náà kúrò.

Lọ́dún 2001, Akọ̀wé Ìjọba Àpapọ̀ Orílẹ̀-Èdè Indonéṣíà tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Djohan Effendi lọ sílùú New York, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Nígbà tó wà níbẹ̀, ó ṣèbẹ̀wò sí oríléeṣẹ́ wa ní Brooklyn, ó sì bá mẹ́ta lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí sọ̀rọ̀. Inú rẹ̀ dùn sí ohun tó rí, òun náà sì gbà pé èèyàn iyì làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà níbi gbogbo láyé. Ó sọ pé tí wọ́n bá fi lé tòun, kíá lòun á mú ìfòfindè náà kúrò, àmọ́ ó kù sọ́wọ́ Ọ̀gbẹ́ni  Marzuki Darusman tó jẹ́ adájọ́ àgbà lórílẹ̀-èdè Indonéṣíà.

Ó wu adájọ́ àgbà náà pẹ̀lú láti mú ìfòfindè náà kúrò, àmọ́ àwọn lọ́gàálọ́gàá tó wà lábẹ́ àṣẹ rẹ̀ ló ń fawọ́ aago sẹ́yìn, wọ́n mọ̀ pé adájọ́ náà kò ní pẹ́ fi iṣẹ́ sílẹ̀, tí ẹlòmíì á sì gbapò rẹ̀. Ọ̀rọ̀ náà dórí kókó ní June 1, 2001 nígbà tí adájọ́ àgbà náà ní kí Arákùnrin Tagor Hutasoit wá sí ọ́fíìsì òun. Kí ló ṣẹlẹ̀ lọ́hùn-ún? Arákùnrin Tagor sọ pé: “Mo rántí pé ní ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] sẹ́yìn, inú ọ́fíìsì yìí kan náà ni wọ́n ti fún mi níwèé pé wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àmọ́, lónìí tí i ṣe June 1, 2001, adájọ́ àgbà yẹn fún mi níwèé pé ìjọba ti mú ìfòfinde náà kúrò. Kẹ́ ẹ sì máa wò ó, òní gan-an ni adájọ́ yẹn máa lò kẹ́yìn ní ipò yẹn!”

Ní March 22, 2002, Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ọ̀rọ̀ Ẹ̀sìn fi orúkọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà silẹ̀ lábẹ́ òfin. Ẹni tó jẹ́ ọ̀gá pátápátá ẹ̀ka yìí sọ fun àwọn tó wá láti ẹ̀ka ọ́fíìsì pe: “Ìwé tá a fi forúkọ yín sílẹ̀ yìí kì í ṣe ìwé tó fún yín ní òmìnira láti máa jọ́sìn. Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ló fún yín lómìnira láti máa jọ́sìn. Ìwé yìí wulẹ̀ ń fi hàn pé ìjọba mọ̀ nípa ẹ̀sìn yín. Torí náà, gbogbo ẹ̀tọ́ tàwọn ẹ̀sìn tó kù ní lẹ̀yin náà ní, ẹ sì lè jàǹfààní lọ́dọ̀ ìjọba.”