Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

APÁ 1

Kí Jésù Tó Bẹ̀rẹ̀ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ̀

“Ẹni yìí máa jẹ́ ẹni ńlá.”—Lúùkù 1:32

Kí Jésù Tó Bẹ̀rẹ̀ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ̀

NÍ APÁ YÌÍ

ORÍ 1

Ìkéde Méjì Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run

Áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì jẹ́ iṣẹ́ méjì tó ṣòroó gbà gbọ́.

ORÍ 2

Wọ́n Pọ́n Jésù Lé Kí Wọ́n Tó Bí I

Báwo ni Èlísábẹ́tì àti ọmọ inú rẹ̀ ṣe pọ́n Jésù lé?

ORÍ 3

Wọ́n Bí Ẹni Tó Máa Ṣètò Ọ̀nà Sílẹ̀

Gbàrà tí Sekaráyà bẹ̀rẹ̀ sí í pa dà sọ̀rọ̀ lọ́nà ìyanu, ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ pàtàkì kan.

ORÍ 4

Màríà Lóyún Láìṣègbéyàwó

Nígbà tí Màríà sọ fún Jósẹ́fù pé ọkùnrin míì kọ́ ló fún òun lóyún, pé ẹ̀mí mímọ́ ló jẹ́ kí òun lóyún, ṣé Jósẹ́fù gbà á gbọ́?

ORÍ 5

Ìgbà Wo Ni Wọ́n Bí Jésù, Ibo sì Ni Wọ́n Bí I Sí?

Báwo la ṣe mọ̀ pé December 25 kọ́ ni wọ́n bí Jésù?

ORÍ 6

Ọmọ Tí Ọlọ́run Ṣèlérí

Nígbà tí Jósẹ́fù àti Màríà gbé Jésù ọmọ wọn jòjòló wá sí tẹ́ńpìlì, àwọn àgbàlagbà méjì kan tó jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì sọ tẹ́lẹ̀ nípa ohun tí Jésù máa ṣe.

ORÍ 7

Àwọn Awòràwọ̀ Wá Sọ́dọ̀ Jésù

Kí ló dé tó fi jẹ́ pé ọ̀dọ̀ Ọba Hẹ́rọ́dù apààyàn ni ìràwọ̀ tí wọ́n rí ní Ìlà Oòrùn kọ́kọ́ darí wọn lọ, tí kì í ṣe ọ̀dọ̀ Jésù?

ORÍ 8

Wọ́n Sá Lọ Mọ́ Ọba Burúkú Kan Lọ́wọ́

Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì mẹ́ta tó jẹ mọ́ Mèsáyà ṣẹ nígbà tí Jésù wà ní kékeré.

ORÍ 9

Ó Ń Dàgbà ní Násárẹ́tì

Àbúrò ọkùnrin àti obìnrin mélòó ni Jésù ní?

ORÍ 10

Jósẹ́fù àti Ìdílé Rẹ̀ Rìnrìn Àjò Lọ sí Jerúsálẹ́mù

Jósẹ́fù àti Màríà dààmú gan-an nígbà tí wọn ò rí Jésù, bẹ́ẹ̀, ẹnu ya Jésù pé wọn ò tètè mọ ibi tó yẹ kí wọ́n wá òun sí.

ORÍ 11

Jòhánù Arinibọmi Ṣètò Ọ̀nà Sílẹ̀

Nígbà tí àwọn Farisí àtàwọn Sadusí kan wá bá Jòhánù, ó dá wọn lẹ́bi. Kí ló fà á?