ORÍ 1
Ìkéde Méjì Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run
-
ÁŃGẸ́LÌ GÉBÚRẸ́LÌ SỌ TẸ́LẸ̀ PÉ WỌ́N MÁA BÍ JÒHÁNÙ ARINIBỌMI
-
GÉBÚRẸ́LÌ SỌ FÚN MÀRÍÀ PÉ Ó MÁA BÍ JÉSÙ
Ọlọ́run ló fi Bíbélì jíǹkí wa, ọ̀rọ̀ rẹ̀ ló sì wà nínú ẹ̀. Ìdí tó fi fún wa ni pé ó fẹ́ kó máa tọ́ wa sọ́nà. Torí náà, ẹ jẹ́ ká wo ìkéde méjì pàtàkì tí áńgẹ́lì kan ṣe ní ohun tó lé ní ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ọdún sẹ́yìn. Gébúrẹ́lì lorúkọ áńgẹ́lì náà, òun ni ẹni “tó ń dúró nítòsí, níwájú Ọlọ́run.” (Lúùkù 1:19) Báwo ni nǹkan ṣe rí lára àwọn tí áńgẹ́lì náà jíṣẹ́ pàtàkì yẹn fún?
Nǹkan bí ọdún 3 Ṣ.S.K. ni Gébúrẹ́lì jíṣẹ́ àkọ́kọ́. Ibo ló ti jíṣẹ́ náà? Agbègbè Jùdíà ni, ó ṣeé ṣe kó má jìnnà sí Jerúsálẹ́mù. Ibẹ̀ ni àlùfáà Jèhófà kan tó ń jẹ́ Sekaráyà ń gbé. Òun àti Èlísábẹ́tì ìyàwó rẹ̀ ti dàgbà, wọn ò sì rọ́mọ bí. Nígbà tó kan Sekaráyà láti lọ ṣiṣẹ́ àlùfáà nínú tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù, Gébúrẹ́lì fara hàn án lójijì lẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ tùràrí.
Ẹ̀rù ba Sekaráyà, ó sì yẹ kẹ́rù bà á lóòótọ́. Àmọ́ áńgẹ́lì náà fi í lọ́kàn balẹ̀, ó ní: “Má bẹ̀rù, Sekaráyà, torí a ti ṣojúure sí ọ, a sì ti gbọ́ ẹ̀bẹ̀ rẹ, Èlísábẹ́tì ìyàwó rẹ máa bí ọmọkùnrin kan fún ọ, kí o pe orúkọ rẹ̀ ní Jòhánù.” Gébúrẹ́lì fi kún un pé “ẹni ńlá ló máa jẹ́ lójú Jèhófà,” ó sì máa “ṣètò àwọn èèyàn tí a ti múra sílẹ̀ fún Jèhófà.”—Lúùkù 1:13-17.
Ó ṣòro fún Sekaráyà láti gba ọ̀rọ̀ yẹn gbọ́. Kí ló fà á? Ohun tó fà á ni pé òun àti Èlísábẹ́tì ti dàgbà. Torí náà, Gébúrẹ́lì sọ fún un pé: “O ò ní lè sọ̀rọ̀, wàá sì ya odi títí di ọjọ́ tí àwọn nǹkan yìí máa ṣẹlẹ̀, torí pé o ò gba àwọn ọ̀rọ̀ mi gbọ́.”—Lúùkù 1:20.
Ní gbogbo àkókò yẹn, àwọn tó wà ní ìta tẹ́ńpìlì ń wò ó pé kí ló dé tí Sekaráyà fi pẹ́ tóyẹn. Nígbà tó yá, ó jáde, àmọ́ kò lè sọ̀rọ̀. Ó kàn ń fọwọ́ ṣàpèjúwe ni. Ó ṣe kedere pé ó ti rí nǹkan tó yà á lẹ́nu nínú tẹ́ńpìlì.
Nígbà tí Sekaráyà parí iṣẹ́ rẹ̀ nínú tẹ́ńpìlì, ó pa dà sílé. Kò pẹ́ sígbà yẹn ni Èlísábẹ́tì lóyún. Oṣù márùn-ún ni Èlísábẹ́tì fi wà nínú ilé, tí ò jẹ́ káwọn èèyàn rí òun, bó ṣe ń retí ìgbà tóun máa bímọ.
Gébúrẹ́lì wá lọ jíṣẹ́ kejì. Ta ló jẹ́ ẹ fún? Ọ̀dọ́bìnrin kan tí kò tíì lọ́kọ ni, Màríà lorúkọ ẹ̀, ìlú Násárẹ́tì lágbègbè Gálílì ló sì ń gbé. Kí ni áńgẹ́lì náà sọ fún un? Ó sọ pé: “O ti rí ojúure Ọlọ́run. Wò ó! o máa lóyún, o sì máa bí ọmọkùnrin kan, kí o pe orúkọ rẹ̀ ní Jésù.” Ó wá fi kún un pé: “Ẹni yìí máa jẹ́ ẹni ńlá, wọ́n á máa pè é ní Ọmọ Ẹni Gíga Jù Lọ, . . . ó máa jẹ Ọba lórí ilé Jékọ́bù títí láé, Ìjọba rẹ̀ ò sì ní lópin.”—Lúùkù 1:30-33.
Wo bí Gébúrẹ́lì ṣe máa mọyì àǹfààní tó ní láti lọ jíṣẹ́ méjèèjì yìí. Bá a ṣe ń ka ìtàn Jòhánù àti Jésù, a máa rí ìdí tí àwọn ìkéde méjì yìí fi ṣe pàtàkì gan-an.