Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 10

Jósẹ́fù àti Ìdílé Rẹ̀ Rìnrìn Àjò Lọ sí Jerúsálẹ́mù

Jósẹ́fù àti Ìdílé Rẹ̀ Rìnrìn Àjò Lọ sí Jerúsálẹ́mù

LÚÙKÙ 2:40-52

  • JÉSÙ ỌMỌ ỌDÚN MÉJÌLÁ Ń BI ÀWỌN OLÙKỌ́ NÍ ÌBÉÈRÈ

  • JÉSÙ PE JÈHÓFÀ NÍ “BABA MI”

Ìgbà ìrúwé ti dé báyìí, torí náà àkókò ti tó fún ìdílé Jósẹ́fù àtàwọn ọ̀rẹ́ wọn títí kan àwọn mọ̀lẹ́bí wọn láti rìnrìn àjò lọ sí Jerúsálẹ́mù bí wọ́n ṣe máa ń ṣe lọ́dọọdún. Àjọyọ̀ Ìrékọjá ni wọ́n máa ń lọ ṣe níbẹ̀ bí Òfin Mósè ṣe pa á láṣẹ. (Diutarónómì 16:16) Nǹkan bíi máìlì márùndínlọ́gọ́rin (75) ni Násárẹ́tì sí Jerúsálẹ́mù. Àsìkò àjọyọ̀ ni ìgbà yẹn máa ń jẹ́ fún wọn bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ nǹkan ni wọ́n máa ń múra sílẹ̀. Jésù ti pé ọmọ ọdún méjìlá (12) báyìí, ó sì ń wọ̀nà fún àjọyọ̀ yẹn torí pé inú ẹ̀ máa ń dùn láti lọ sí tẹ́ńpìlì Jèhófà.

Ìrékọjá kì í ṣe àjọyọ̀ ọjọ́ kan ṣoṣo fún ìdílé Jósẹ́fù. Ọjọ́ tó tẹ̀ lé Ìrékọjá ni wọ́n máa ń bẹ̀rẹ̀ Àjọyọ̀ Búrẹ́dì Aláìwú, ọjọ́ méje ni wọ́n sì fi máa ń ṣe é. (Máàkù 14:1) Wọ́n gbà pé àjọyọ̀ yìí wà lára àjọyọ̀ Ìrékọjá. Ìrìn àjò yìí máa ń gbà wọ́n ní ọ̀sẹ̀ méjì ó kéré tán. Ìdí ni pé wọ́n máa rìn láti Násárẹ́tì dé Jerúsálẹ́mù, wọ́n máa lo ọjọ́ díẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì tún máa rìn pa dà sílé. Àmọ́ lọ́dún yìí, ohun tí Jésù ṣe mú kí wọ́n lò ju àkókò yẹn lọ. Ìgbà tí wọ́n ń pa dà sílé ni wọ́n kíyè sí i pé nǹkan kan ti ṣẹlẹ̀.

Bí wọ́n ṣe ń pa dà sílé, Jósẹ́fù àti Màríà rò pé Jésù wà láàárín àwọn mọ̀lẹ́bí àtàwọn ọ̀rẹ́ tí wọ́n jọ ń rìnrìn àjò. Nígbà tí ilẹ̀ ṣú, wọ́n dúró láti wá ibì kan sùn, àmọ́ wọn ò rí Jésù. Wọ́n wá a láàárín gbogbo àwọn tí wọ́n jọ ń rìnrìn àjò, àmọ́ wọn ò rí i. Háà! Odindi ọmọ ló sọnù yìí! Bí Jósẹ́fù àti Màríà ṣe pa dà sí Jerúsálẹ́mù nìyẹn.

Odindi ọjọ́ kan ni wọ́n fi wá a, tí wọn ò sì rí i. Wọ́n tún wá a títí lọ́jọ́ kejì, síbẹ̀ wọn ò rí i. Àwọn gbọ̀ngàn tó wà nínú tẹ́ńpìlì yẹn pọ̀ gan-an, àmọ́ nígbà tí wọ́n wá a títí wọ́n rí i lọ́jọ́ kẹta. Wọ́n rí Jésù tó jókòó láàárín àwọn olùkọ́ Júù. Ó ń tẹ́tí sí wọn, ó sì ń béèrè ìbéèrè, kódà òye tó ní yà wọ́n lẹ́nu.

Màríà wá bi í pé: “Ọmọ, kí ló dé tí o fi ṣe báyìí sí wa? Wò ó, èmi àti bàbá rẹ ti dààmú gan-an bá a ṣe ń wá ọ kiri.”—Lúùkù 2:48.

Ó ya Jésù lẹ́nu pé wọn ò mọ ibi tí òun wà. Ó bi wọ́n pé: “Kí ló dé tí ẹ̀ ń wá mi? Ṣé ẹ ò mọ̀ pé mo gbọ́dọ̀ wà nínú ilé Baba mi ni?”—Lúùkù 2:49.

Ní báyìí tí Jósẹ́fù àti Màríà ti rí Jésù, wọ́n jọ pa dà sí Násárẹ́tì, Jésù sì ń gbọ́ràn sí wọn lẹ́nu. Bó ṣe ń dàgbà sí i, bẹ́ẹ̀ lọgbọ́n rẹ̀ ń pọ̀ sí i. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ṣì kéré, ó ń rí ojúure Ọlọ́run àti èèyàn. Kò sí àní-àní pé láti kékeré ni Jésù ti ń fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ ní ti pé ó fọwọ́ pàtàkì mú ìjọsìn Ọlọ́run, ó sì ń bọ̀wọ̀ fáwọn òbí rẹ̀.