Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 6

Ọmọ Tí Ọlọ́run Ṣèlérí

Ọmọ Tí Ọlọ́run Ṣèlérí

LÚÙKÙ 2:21-39

  • WỌ́N DÁDỌ̀DỌ́ JÉSÙ, WỌ́N SÌ GBÉ E WÁ SÍNÚ TẸ́ŃPÌLÌ NÍGBÀ TÓ YÁ

Jósẹ́fù àti Màríà ò pa dà sí Násárẹ́tì, wọ́n dúró sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Nígbà tí Jésù pé ọmọ ọjọ́ mẹ́jọ, wọ́n dádọ̀dọ́ fún un, bí Òfin tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe sọ. (Léfítíkù 12:2, 3) Àṣà wọn sì ni pé ọjọ́ yẹn náà ni wọ́n máa sọ ọmọ tó bá jẹ́ ọkùnrin lórúkọ. Wọ́n sọ ọmọ náà ní Jésù bí áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì ṣe sọ.

Nígbà tí Jésù pé ọmọ ogójì (40) ọjọ́, àwọn òbí rẹ̀ gbé e lọ sí tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù. Ibẹ̀ ò ju máìlì mélòó kan síbi tí wọ́n ń gbé lọ. Ohun tí Òfin sọ ni pé tí obìnrin kan bá bí ọmọkùnrin, lẹ́yìn ogójì (40) ọjọ́, kó mú ọrẹ wá sí tẹ́ńpìlì láti fi ṣe ìwẹ̀mọ́.—Léfítíkù 12:4-8.

Ohun tí Màríà ṣe gan-an nìyẹn. Ó mú ẹyẹ kéékèèké méjì wá láti fi ṣe ọrẹ. Ìyẹn jẹ́ ká rí i pé Jósẹ́fù àti Màríà ò fi bẹ́ẹ̀ lówó. Bí Òfin ṣe sọ, ọmọ àgbò àti ẹyẹ ló yẹ kí ìyá ọmọ náà mú wá. Àmọ́ tí agbára rẹ̀ ò bá ká àgbò, Òfin sọ pé ó lè mú ẹyẹ oriri méjì tàbí ẹyẹlé méjì wá. Ẹyẹ méjì ni Màríà mú wá torí ohun tágbára rẹ̀ ká nìyẹn.

Nígbà tí Jósẹ́fù àti Màríà dé tẹ́ńpìlì, bàbá àgbàlagbà kan tó ń jẹ́ Síméónì wá bá wọn. Ọlọ́run ti jẹ́ kó mọ̀ pé kó tó kú, ó máa rí Kristi tàbí Mèsáyà tí Jèhófà ṣèlérí. Lọ́jọ́ yẹn, ẹ̀mí mímọ́ darí Síméónì lọ sí tẹ́ńpìlì, ó sì rí Jósẹ́fù àti Màríà pẹ̀lú ọmọ wọn jòjòló. Síméónì wá gbé ọmọ náà mọ́ra.

Bí Síméónì ṣe gbé Jésù dání, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, ó ní: “Ní báyìí, Olúwa Ọba Aláṣẹ, ò ń jẹ́ kí ẹrú rẹ lọ ní àlàáfíà bí o ṣe kéde, torí ojú mi ti rí ohun tí o máa fi gbani là, èyí tí o pèsè níṣojú gbogbo èèyàn, ìmọ́lẹ̀ láti mú ìbòjú kúrò lójú àwọn orílẹ̀-èdè àti ògo àwọn èèyàn rẹ Ísírẹ́lì.”—Lúùkù 2:29-32.

Ó ya Jósẹ́fù àti Màríà lẹ́nu láti gbọ́ ohun tí Síméónì sọ. Síméónì wá súre fún wọn, ó sì sọ fún Màríà pé “a ti yan ọmọ yìí kí ọ̀pọ̀ ní Ísírẹ́lì lè ṣubú, kí ọ̀pọ̀ sì tún dìde” àti pé ẹ̀dùn ọkàn máa bá Màríà, bí ìgbà tí wọ́n bá fi idà tó mú gún un.—Lúùkù 2:34.

Ẹlòmíì tún wà níbẹ̀ lọ́jọ́ yẹn. Wòlíì obìnrin kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ánà ni, ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́rin (84) sì ni. Kò sígbà tí kì í wá sí tẹ́ńpìlì. Ní wákàtí yẹn gan-an, ó wá bá Jósẹ́fù, Màríà àti Jésù. Ánà bẹ̀rẹ̀ sí í dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, ó sì ń sọ̀rọ̀ Jésù fún gbogbo àwọn tó ń gbọ́rọ̀ rẹ̀.

Fojú inú wo bí inú Jósẹ́fù àti Màríà ṣe máa dùn tó nítorí àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ nínú tẹ́ńpìlì lọ́jọ́ yẹn! Ó dájú pé gbogbo nǹkan yìí á jẹ́ kó túbọ̀ dá wọn lójú pé Jésù ọmọ wọn ni Ẹni Tí Ọlọ́run Ṣèlérí.