Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 12

Jésù Ṣe Ìrìbọmi

Jésù Ṣe Ìrìbọmi

MÁTÍÙ 3:13-17 MÁÀKÙ 1:9-11 LÚÙKÙ 3:21, 22 JÒHÁNÙ 1:32-34

  • JÉSÙ ṢÈRÌBỌMI, ỌLỌ́RUN SÌ FI Ẹ̀MÍ MÍMỌ́ YÀN ÁN

  • JÈHÓFÀ KÉDE PÉ JÉSÙ NI ỌMỌ ÒUN

Lẹ́yìn nǹkan bí oṣù mẹ́fà tí Jòhánù Arinibọmi bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù, Jésù lọ bá a ní Odò Jọ́dánì. Lásìkò yẹn, Jésù ti tó nǹkan bí ẹni ọgbọ̀n (30) ọdún. Kí ni Jésù lọ bá a fún? Ṣé ó kàn lọ kí Jòhánù lásán ni, àbí ó kàn fẹ́ lọ wo ibi tí Jòhánù báṣẹ́ dé? Rárá o. Jésù lọ bá Jòhánù pé kó ṣèrìbọmi fún òun.

Kò yani lẹ́nu pé Jòhánù kọ̀, ó ní: “Ìwọ ló yẹ kí o ṣèrìbọmi fún mi, ṣé ọ̀dọ̀ mi lo wá ń bọ̀ ni?” (Mátíù 3:14) Jòhánù mọ̀ pé ààyò Ọmọ ni Jésù jẹ́ fún Ọlọ́run. Ẹ má gbàgbé pé nígbà tí Jòhánù ṣì wà nínú ikùn Èlísábẹ́tì ìyá rẹ̀, ayọ̀ mú kó sọ kúlú nígbà tí Màríà tó ti lóyún Jésù wá kí Èlísábẹ́tì. Ó dájú pé ìyá Jòhánù ti máa sọ fún un nípa ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn. Ó sì ti máa gbọ́ nípa bí áńgẹ́lì kan ṣe kéde fáwọn olùṣọ́ àgùntàn pé wọ́n ti bí Jésù àti bí ọ̀pọ̀ áńgẹ́lì ṣe yọ sí wọn lọ́jọ́ náà.

Jòhánù mọ̀ pé àwọn tó ronú pìwà dà ẹ̀ṣẹ̀ wọn lòun ń ṣèrìbọmi fún. Àmọ́ Jésù ò dá ẹ̀ṣẹ̀ kankan. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jòhánù ò fẹ́ ṣèrìbọmi fún un, Jésù sọ pé: “Jẹ́ kó rí bẹ́ẹ̀ lọ́tẹ̀ yìí, torí ọ̀nà yẹn ló yẹ ká gbà ṣe gbogbo ohun tó jẹ́ òdodo.”—Mátíù 3:15.

Kí nìdí tó fi yẹ kí Jésù ṣèrìbọmi? Kì í ṣe torí pé Jésù dẹ́sẹ̀, tó sì fẹ́ fi hàn pé òun ti ronú pìwà dà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ṣèrìbọmi kó lè fi hàn pé òun ti ṣe tán láti ṣe ìfẹ́ Bàbá òun. (Hébérù 10:5-7) Káfíńtà ni Jésù látilẹ̀, ṣùgbọ́n ní báyìí, àkókò ti tó fún un láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí Baba rẹ̀ ọ̀run tìtorí ẹ̀ rán an wá sáyé. Ṣé ẹ rò pé Jòhánù retí pé kí nǹkan àrà ọ̀tọ̀ ṣẹlẹ̀ tó bá ri Jésù bọmi?

Nígbà tó yá Jòhánù ròyìn pé: “Ẹni tó rán mi láti fi omi batisí sọ fún mi pé: ‘Ẹnikẹ́ni tí o bá rí tí ẹ̀mí ń sọ̀ kalẹ̀, tó sì bà lé, òun ni ẹni tó ń fi ẹ̀mí mímọ́ batisí.’” (Jòhánù 1:33) Ó dájú pé Jòhánù á máa retí pé ẹ̀mí Ọlọ́run máa bà lé ọ̀kan lára àwọn tí òun ń ṣèrìbọmi fún. Torí náà, gbàrà tí Jésù jáde nínú omi, ó ṣeé ṣe kó má yà á lẹ́nu nígbà tí “ẹ̀mí Ọlọ́run ń sọ̀ kalẹ̀ bí àdàbà bọ̀ wá sórí [Jésù].”—Mátíù 3:16.

Àmọ́, àwọn nǹkan míì tún ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jésù ṣèrìbọmi. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé: “Ọ̀run ṣí sílẹ̀.” Kí nìyẹn túmọ̀ sí? Ó ṣeé ṣe kó túmọ̀ sí pé, nígbà tí Jésù ṣèrìbọmi, ó rántí ìgbésí ayé rẹ̀ lọ́run kó tó wá sáyé. Torí náà, Jésù rántí pé áńgẹ́lì alágbára lòun ní ọ̀run àti pé ọmọ Jèhófà lòun. Ó sì rántí àwọn ohun tí Ọlọ́run ti kọ́ ọ ní ọ̀run kó tó wá sáyé.

Yàtọ̀ síyẹn, nígbà tí Jésù ṣèrìbọmi, ohùn kan láti ọ̀run kéde pé: “Èyí ni Ọmọ mi, àyànfẹ́, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà.” (Mátíù 3:17) Ohùn ta nìyẹn? Kò lè jẹ́ ohùn Jésù, torí ọ̀dọ̀ Jòhánù ló wà. Ó dájú pé ohùn Ọlọ́run ni. Ó ṣe kedere pé Jésù kọ́ ni Ọlọ́run, Ọmọ Ọlọ́run ni.

Ó yẹ ká fi sọ́kàn pé bí Jésù tiẹ̀ jẹ́ èèyàn, ọmọ Ọlọ́run ni, bí Ádámù ọkùnrin àkọ́kọ́ náà ṣe jẹ́ ọmọ Ọlọ́run. Lẹ́yìn tí Lúùkù sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà ìrìbọmi Jésù, ó sọ pé: “Nǹkan bí ẹni ọgbọ̀n (30) ọdún ni Jésù nígbà tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀, bí wọ́n sì ṣe rò, ó jẹ́ ọmọ Jósẹ́fù, ọmọ Hélì, . . . ọmọ Dáfídì, . . . ọmọ Ábúráhámù, . . . ọmọ Nóà, . . . ọmọ Ádámù, ọmọ Ọlọ́run.”—Lúùkù 3:23-38.

Bí Ádámù ṣe jẹ́ “ọmọ Ọlọ́run,” bẹ́ẹ̀ náà ni Jésù jẹ́ ọmọ Ọlọ́run. Nígbà tí Jésù ṣèrìbọmi, ó ní àjọṣe tuntun pẹ̀lú Ọlọ́run ní ti pé ó di Ọmọ Ọlọ́run nípa tẹ̀mí. Torí náà, Jésù lè kọ́ wa ní òtítọ́ tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, kó sì fọ̀nà ìyè hàn wá. Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, iṣẹ́ tí Jésù bẹ̀rẹ̀ yìí máa gba pé kó fi ẹ̀mí rẹ̀ rúbọ fún gbogbo aráyé ẹlẹ́ṣẹ̀.