Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 45

Agbára Jésù Ju Ti Àwọn Ẹ̀mí Èṣù Lọ

Agbára Jésù Ju Ti Àwọn Ẹ̀mí Èṣù Lọ

MÁTÍÙ 8:28-34 MÁÀKÙ 5:1-20 LÚÙKÙ 8:26-39

  • Ó LÉ ÀWỌN Ẹ̀MÍ ÈṢÙ JÁDE SÍNÚ ÀWỌN ẸLẸ́DẸ̀

Nígbà táwọn ọmọ ẹ̀yìn dé èbúté lẹ́yìn gbogbo ohun tójú wọn ti rí lórí òkun, ohun tí wọ́n rí yà wọ́n lẹ́nu gan-an. Wọ́n rí ọkùnrin méjì tí ẹ̀mí èṣù ń dà láàmú, tí ìrísí wọn sì ń bani lẹ́rù. Àwọn méjèèjì ń jáde bọ̀ látinú ibojì, wọ́n sì ń sáré bọ̀ wá pàdé Jésù. Àmọ́, ọ̀kan lára wọn gbàfiyèsí bóyá torí pé ó burú ju èkejì lọ tàbí torí pé ó ti pẹ́ táwọn ẹ̀mí èṣù ti ń dà á láàmú.

Ọkùnrin táwọn ẹ̀mí èṣù ti sọ dìdàkudà yìí kì í wọṣọ. Tọ̀sántòru ló fi ń “ké . . . láwọn ibojì àti àwọn òkè, ó sì máa ń fi àwọn òkúta ya ara rẹ̀ yánnayànna.” (Máàkù 5:5) Ó burú débi pé ṣe lẹ̀rù máa ń ba àwọn èèyàn láti gba ọ̀nà yẹn kọjá. Àwọn kan ti fi ẹ̀wọ̀n dè é, wọ́n sì fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ sí i lẹ́sẹ̀, àmọ́ ṣe ló máa ń já ẹ̀wọ̀n náà pàrà, tó sì máa já ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ náà sí wẹ́wẹ́. Kò sẹ́ni tó lè kò ó lójú.

Bí ọkùnrin náà ṣe ń sún mọ́ Jésù, ó forí balẹ̀ níbi ẹsẹ̀ rẹ̀, ẹ̀mí èṣù tó ń darí ẹ̀ sì pariwo pé: “Kí ló pa wá pọ̀, Jésù Ọmọ Ọlọ́run Gíga Jù Lọ? Fi Ọlọ́run búra fún mi pé o ò ní dá mi lóró.” Jésù ṣe ohun tó fi hàn pé ó láṣẹ lórí àwọn ẹ̀mí èṣù nígbà tó sọ pé: “Jáde nínú ọkùnrin náà, ìwọ ẹ̀mí àìmọ́.”—Máàkù 5:7, 8.

Òótọ́ ibẹ̀ ni pé àwọn ẹ̀mí èṣù tó wà nínú ọkùnrin náà pọ̀ gan-an. Báwo la ṣe mọ̀? Nígbà tí Jésù bi í pé, “Kí ni orúkọ rẹ?” Ó fèsì pé: “Líjíónì lorúkọ mi, torí a pọ̀.” (Máàkù 5:9) Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọmọ ogun ló máa ń wà nínú líjíónì àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Róòmù, torí náà àwọn ẹ̀mí burúkú tó ń da ọkùnrin náà láàmú pọ̀ gan-an, inú wọn sì ń dùn bí ọkùnrin náà ṣe ń jìyà. Wọ́n bẹ Jésù pé “kó má pàṣẹ fún àwọn láti lọ sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀.” Ìdí sì ni pé wọ́n ti mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí àwọn àti Sátánì olórí wọn láìpẹ́.—Lúùkù 8:31.

Àwọn ẹlẹ́dẹ̀ tó tó ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ń jẹko nítòsí. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, lábẹ́ Òfin Mósè, ẹran tí kò mọ́ ni ẹlẹ́dẹ̀, kódà àwọn Júù ò gbọ́dọ̀ sìn ín. Àwọn ẹ̀mí èṣù náà wá sọ pé: “Lé wa lọ sọ́dọ̀ àwọn ẹlẹ́dẹ̀ náà, ká lè wọnú wọn.” (Máàkù 5:12) Jésù wá ní kí wọ́n lọ, wọ́n sì kó sínú àwọn ẹlẹ́dẹ̀ náà. Bó ṣe di pé gbogbo ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ẹlẹ́dẹ̀ rọ́ kọjá ní etí òkè tó wà níbẹ̀ nìyẹn, tí wọ́n sì kú sínú òkun tó wà nísàlẹ̀.

Nígbà táwọn tó ń tọ́jú àwọn ẹlẹ́dẹ̀ náà rí ohun tó ṣẹlẹ̀, wọ́n sáré lọ sọ fáwọn tó wà nínú ìlú àti láwọn ìgbèríko. Bó ṣe di pé àwọn èèyàn jáde wá wo ohun tó ṣẹlẹ̀ nìyẹn. Bí wọ́n ṣe ń dé, wọ́n rí i pé ara ọkùnrin tí ẹ̀mí èṣù ń dà láàmú náà ti yá, orí ẹ̀ sì ti pé. Báwo ni wọ́n ṣe mọ̀? Wọ́n rí i pé ó ti wọṣọ, ó sì jókòó síbi ẹsẹ̀ Jésù!

Ẹ̀rù ba àwọn tó gbọ́ ìròyìn náà àtàwọn tó rí ọkùnrin náà torí wọn ò mọ nǹkan míì tí Jésù máa ṣe. Torí náà, wọ́n bẹ Jésù pé kó kúrò lágbègbè àwọn. Bí Jésù ṣe ń wọnú ọkọ̀ kó lè máa lọ, ọkùnrin tó lẹ́mìí èṣù tẹ́lẹ̀ náà bẹ Jésù pé kó jẹ́ kóun tẹ̀ lé e. Àmọ́ Jésù sọ fún un pé: “Máa lọ sílé lọ́dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ, kí o sì ròyìn fún wọn gbogbo ohun tí Jèhófà ti ṣe fún ọ àti bó ṣe ṣàánú rẹ.”—Máàkù 5:19.

Jésù sábà máa ń sọ fáwọn tó bá wò sàn pé kí wọ́n má sọ fún ẹnikẹ́ni torí kò fẹ́ káwọn èèyàn kàn máa sọ ohun tí wọ́n rò nípa òun àtàwọn iṣẹ́ ìyanu tóun ṣe. Àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí, báwọn èèyàn bá ṣe ń rí ọkùnrin tí Jésù lé ẹ̀mí èṣù jáde lára ẹ̀, wọ́n á gbà pé ó láṣẹ lórí àwọn ẹ̀mí èṣù, ìyẹn á sì jẹ́ ẹ̀rí fáwọn tí Jésù ò ní lè wàásù fún. Yàtọ̀ síyẹn, ó ṣeé ṣe kí ohun tí ọkùnrin yẹn máa sọ pa àwọn alátakò lẹ́nu mọ́, torí wọ́n lè máa ṣàríwísí nípa àwọn ẹlẹ́dẹ̀ náà. Bó ṣe di pé ọkùnrin yẹn ń pòkìkí ohun tí Jésù ṣe ní gbogbo agbègbè Dekapólì nìyẹn o.