Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 62

Ẹ̀kọ́ Pàtàkì Nípa Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀

Ẹ̀kọ́ Pàtàkì Nípa Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀

MÁTÍÙ 17:22–18:5 MÁÀKÙ 9:30-37 LÚÙKÙ 9:43-48

  • JÉSÙ TÚN PA DÀ SỌ ÀSỌTẸ́LẸ̀ NÍPA IKÚ RẸ̀

  • Ó FI OWÓ ẸNU ẸJA SAN OWÓ ORÍ

  • TA LÓ MÁA TÓBI JÙ NÍNÚ ÌJỌBA Ọ̀RUN?

Lẹ́yìn tí Ọlọ́run fi ìran ìyípadà ológo han díẹ̀ lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn, tí Jésù sì wo ọmọkùnrin tí ẹ̀mí èṣù ń yọ lẹ́nu sàn ní Kesaréà ti Fílípì, ó rìnrìn àjò lọ sí agbègbè Kápánáúmù. Òun àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nìkan ló lọ, kí ọ̀pọ̀ èèyàn má bàa “mọ̀ nípa rẹ̀.” (Máàkù 9:30) Èyí mú kó ṣeé ṣe fún un láti sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn nípa ikú rẹ̀, kó sì múra wọn sílẹ̀ fún iṣẹ́ tí wọ́n máa ṣe lẹ́yìn náà. Ó ṣàlàyé fún wọn pé; “A máa fi Ọmọ èèyàn lé àwọn èèyàn lọ́wọ́, wọ́n máa pa á, a sì máa jí i dìde ní ọjọ́ kẹta.”—Mátíù 17:22, 23.

Kò yẹ kí ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ tuntun sáwọn ọmọ ẹ̀yìn. Torí ṣáájú ìgbà yẹn ni Jésù ti sọ̀rọ̀ nípa bí wọ́n ṣe máa pa òun, bó tiẹ̀ jẹ́ pé Pétérù ò gbà pé ó lè ṣẹlẹ̀. (Mátíù 16:21, 22) Bákan náà, mẹ́ta lára wọn ti rí ìyípadà ológo, wọ́n sì gbọ́ bí àwọn tó fara hàn nínú ìran náà ṣe ń sọ̀rọ̀ nípa “lílọ” Jésù. (Lúùkù 9:31) Bí ohun tí Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ò tiẹ̀ yé wọn dáadáa, ọ̀rọ̀ náà fa ìbànújẹ́ “gidigidi” fún wọn. (Mátíù 17:23) Ẹ̀rù bà wọ́n débi pé wọn ò lè béèrè síwájú sí i nípa ohun tó sọ.

Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ wọ́n dé Kápánáúmù, ìyẹn ibi tí Jésù ti lo ọ̀pọ̀ àkókò lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, tó sì jẹ́ ìlú ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Bí wọ́n ṣe dé ibẹ̀, àwọn ọkùnrin tó ń gba owó orí tẹ́ńpìlì lọ bá Pétérù. Kí wọ́n lè fẹ̀sùn kan Jésù pé kì í san owó orí, wọ́n bi Pétérù pé: “Ṣé olùkọ́ yín kì í san dírákímà méjì fún owó orí [tẹ́ńpìlì] ni?”—Mátíù 17:24.

Pétérù dá wọn lóhùn pé “Bẹ́ẹ̀ ni.” Torí pé Jésù ti mọ ohun tó ṣẹlẹ̀, kò dúró kí Pétérù kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀. Ó bi Pétérù pé: “Kí lèrò rẹ, Símónì? Ọwọ́ ta ni àwọn ọba ayé ti ń gba owó ibodè tàbí owó orí? Ṣé ọwọ́ àwọn ọmọ wọn ni àbí ọwọ́ àwọn àjèjì?” Pétérù dáhùn pé: “Ọwọ́ àwọn àjèjì ni.” Jésù wá sọ fún un pé: “Tó bá rí bẹ́ẹ̀, á jẹ́ pé àwọn ọmọ kì í san owó orí.”—Mátíù 17:25, 26.

Jèhófà tó jẹ́ Baba Jésù ni Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run, òun làwọn èèyàn sì ń jọ́sìn ní tẹ́ńpìlì. Torí náà, kò pọn dandan kí Jésù tó jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run san owó orí tẹ́ńpìlì. Jésù wá sọ pé: “Àmọ́ ká má bàa mú wọn kọsẹ̀, lọ sí òkun, ju ìwọ̀ ẹja kan, kí o sì mú ẹja tó bá kọ́kọ́ jáde, tí o bá la ẹnu rẹ̀, wàá rí ẹyọ owó fàdákà kan. Mú un, kí o sì fún wọn, kó jẹ́ tèmi àti tìrẹ.”—Mátíù 17:27.

Nígbà tó yá táwọn ọmọ ẹ̀yìn náà kóra jọ, wọ́n béèrè lọ́wọ́ Jésù nípa ẹni tó máa tóbi jù nínú Ìjọba Ọlọ́run. Kẹ́ ẹ sì máa wò ó, àwọn ọkùnrin yìí ló kọ́kọ́ ń bẹ̀rù láti béèrè lọ́wọ́ Jésù nípa bó ṣe máa kú, àmọ́ ní báyìí ẹ̀rù ò bà wọ́n láti béèrè nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí wọn lọ́jọ́ iwájú. Jésù lóye ohun tí wọ́n ní lọ́kàn, ó ṣe tán wọ́n ti ń jiyàn lórí ẹ̀ bí wọ́n ṣe ń lọ sí Kápánáúmù. Ni Jésù bá bi wọ́n pé: “Kí lẹ̀ ń jiyàn lé lórí lójú ọ̀nà?” (Máàkù 9:33) Ìtìjú ò jẹ́ kí wọ́n lè sọ ohunkóhun, torí ọ̀rọ̀ nípa ẹni tó tóbi jù ni wọ́n ń jiyàn lé lórí. Àmọ́ nígbà tó yá, àwọn àpọ́sítélì náà béèrè ọ̀rọ̀ yìí lọ́wọ́ Jésù, wọ́n ní: “Ní tòótọ́, ta ló tóbi jù lọ nínú Ìjọba ọ̀run?”—Mátíù 18:1.

Kàyéfì ńlá gbáà ni pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn tún lè máa fa ọ̀rọ̀ yìí lẹ́yìn nǹkan bí ọdún mẹ́ta tí wọ́n ti wà pẹ̀lú Jésù, tí wọ́n sì ń fetí sáwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀. Síbẹ̀ ó yẹ ká rántí pé aláìpé ni wọ́n, àárín àwọn tó ń gbé ẹ̀sìn lárugẹ tí ò sì fojú kéré ipò ńlá ni wọ́n gbé dàgbà. Ṣáájú ìgbà yẹn sì ni Jésù ti sọ fún Pétérù pé òun máa fún un ní “kọ́kọ́rọ́” Ìjọba náà. Ṣé ó ṣeé ṣe kíyẹn mú kí Pétérù máa rò pé òun sàn ju àwọn tó kù lọ? Ṣé ó sì ṣeé ṣe kí Jémíìsì àti Jòhánù gbà pé àwọn ṣe pàtàkì ju àwọn tó kù torí pé wọ́n wà pẹ̀lú Jésù nígbà tó yí pa dà, tó sì ní ìrísí ológo?

Èyí ó wù kó jẹ́, Jésù ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè ronú lọ́nà tó tọ́. Ó pe ọmọ kékeré kan, ó sì mú un dúró sáàárín wọn, ó wá sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn náà pé: “Láìjẹ́ pé ẹ yí pa dà, kí ẹ sì dà bí àwọn ọmọdé, ó dájú pé ẹ ò ní wọ Ìjọba ọ̀run. Torí náà, ẹnikẹ́ni tó bá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ bí ọmọ kékeré yìí ni ẹni tó tóbi jù lọ nínú Ìjọba ọ̀run; ẹnikẹ́ni tó bá sì gba irú ọmọ kékeré bẹ́ẹ̀ nítorí orúkọ mi gba èmi náà.”—Mátíù 18:3-5.

Ọ̀nà tí Jésù gbà kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ yẹn mà dára o! Kò kọ́kọ́ bínú sáwọn ọmọ ẹ̀yìn náà kó wá máa pè wọ́n ní olójúkòkòrò tàbí ẹni tó ń wá ipò ọlá. Dípò ìyẹn, ṣe ló lo ohun tó máa yé wọn dáadáa láti kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́. Àwọn ọmọdé kì í wá ipò ńlá tàbí wá bí wọ́n ṣe máa di gbajúmọ̀. Jésù wá sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé ó yẹ káwọn náà máa wo ara wọn bíi tàwọn ọmọdé. Lẹ́yìn náà, Jésù sọ ẹ̀kọ́ pàtàkì tó fẹ́ kọ́ wọn, ó ní: “Ẹni tó bá hùwà bí ẹni tó kéré láàárín gbogbo yín ni ẹni tó tóbi.”—Lúùkù 9:48.