Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 64

Ìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Dárí Jini

Ìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Dárí Jini

MÁTÍÙ 18:21-35

  • ṢÉ ÌGBÀ MÉJE LA LÈ DÁRÍ JI ẸNI TÓ ṢẸ̀ WÁ?

  • ÀPÈJÚWE ẸRÚ TÍ KÒ LÁÀÁNÚ

Pétérù gbọ́ nígbà tí Jésù sọ pé ó yẹ kẹ́nì kan wá bó ṣe máa yanjú èdèkòyédè pẹ̀lú arákùnrin rẹ̀. Àmọ́, ó jọ pé ó wu Pétérù kó mọ iye ìgbà tó yẹ kéèyàn ṣe bẹ́ẹ̀.

Pétérù wá béèrè pé: “Olúwa, ìgbà mélòó ni arákùnrin mi máa ṣẹ̀ mí, tí màá sì dárí jì í? Ṣé kó tó ìgbà méje?” Ó ṣe tán, àwọn aṣáájú ẹ̀sìn kan máa ń kọ́ni pé ẹ̀ẹ̀mẹ́ta péré léèyàn lẹ́tọ̀ọ́ láti dárí ji ẹni tó bá ṣẹ̀ ẹ́. Torí náà, Pétérù lè máa rò ó pé òun láàánú tóun bá dárí ji arákùnrin òun ní “ìgbà méje.”—Mátíù 18:21.

Àmọ́, irú èrò yìí yàtọ̀ pátápátá sí ohun tí Jésù ń kọ́ àwọn èèyàn. Torí náà, Jésù ṣàlàyé fún Pétérù pé: “Mò ń sọ fún ọ pé, kì í ṣe ìgbà méje, àmọ́ kó tó ìgbà àádọ́rin lé méje (77).” (Mátíù 18:22) Lédè míì, gbogbo ìgbà ló yẹ ká máa dárí ji ẹni tó bá ṣẹ̀ wá, torí náà kò yẹ kí Pétérù máa ronú pé ìgbà kan máa wà tí arákùnrin kan máa ṣẹ òun, tí òun ò sì ní dárí jì í.

Jésù wá sọ àpèjúwe kan fún Pétérù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn tó kù kí wọ́n lè mọ ìdí tó fi yẹ kí wọ́n máa dárí ji àwọn míì. Ó lo àpèjúwe ẹrú kan tí kò tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ọ̀gá rẹ̀ tó jẹ́ aláàánú. Ọba ni ọ̀gá ẹrú náà, ó sì fẹ́ yanjú ọ̀rọ̀ owó pẹ̀lú àwọn ẹrú rẹ̀. Ni wọ́n bá mú ẹrú kan tó jẹ ẹ́ ní òbítíbitì owó wá, ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) tálẹ́ńtì [60,000,000 owó dínárì] ni ẹrú náà jẹ ẹ́. Ó dájú pé kò sí bí ẹrú yẹn ṣe lè san gbèsè náà pa dà. Ọba wá ní kí wọ́n ta ẹrú náà pẹ̀lú ìyàwó àtàwọn ọmọ ẹ̀ kí wọ́n lè san gbèsè tó jẹ. Ni ẹrú yìí bá wólẹ̀ síbi ẹsẹ̀ ọ̀gá rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ̀ ẹ́ pé: “Ní sùúrù fún mi, màá sì san gbogbo rẹ̀ pa dà fún ọ.”—Mátíù 18:26.

Àánú ẹrú yìí ṣe ọba náà, ló bá fagi lé gbogbo gbèsè tó jẹ. Lẹ́yìn náà, ẹrú yìí rí ẹrú bíi tiẹ̀ tó jẹ ẹ́ ní gbèsè ọgọ́rùn-ún (100) owó dínárì péré. Ó wá rá a mú, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í fún un lọ́rùn, ó sọ pé: “San gbogbo gbèsè tí o jẹ pa dà.” Àmọ́ ẹrú kejì náà wólẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ̀ ẹ́, ó sọ fún un pé: “Ní sùúrù fún mi, màá sì san án pa dà fún ọ.” (Mátíù 18:28, 29) Ẹrú tí ọba dárí jì náà ò dà bí ọ̀gá rẹ̀, ṣe ló ní kí wọ́n mú ẹrú tó jẹ òun ní gbèsè yẹn, kí wọ́n sì jù ú sẹ́wọ̀n títí tó fi máa san gbèsè tó jẹ.

Lẹ́yìn náà, Jésù sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí àwọn ẹrú tó kù ròyìn ohun tí ẹrú náà ṣe fún ọ̀gá wọn. Inú bí ọ̀gá yẹn, ó wá ránṣé pè é, ó sì sọ fún un pé: “Ẹrú burúkú, mo fagi lé gbogbo gbèsè yẹn fún ọ nígbà tí o bẹ̀ mí. Ṣé kò yẹ kí ìwọ náà ṣàánú ẹrú ẹlẹgbẹ́ rẹ bí mo ṣe ṣàánú rẹ?” Inú bí ọba náà gan-an, ló bá ní kí wọ́n lọ sọ ẹrú tí kò láàánú náà sẹ́wọ̀n títí tó fi máa san gbogbo gbèsè tó jẹ. Jésù wá parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Bẹ́ẹ̀ náà ni Baba mi ọ̀run máa ṣe sí yín tí kálukú yín kò bá dárí ji arákùnrin rẹ̀ látọkàn wá.”—Mátíù 18:32-35.

Ẹ ò rí i pé ẹ̀kọ́ pàtàkì nìyẹn tó bá kan ká máa dárí jini! Ọlọ́run ti dárí ẹ̀ṣẹ̀ tó pọ̀ gan-an jì wá. Ẹ̀ṣẹ̀ yòówù kí arákùnrin wa ṣẹ̀ wá, ìyẹn ò tó nǹkan kan tá a bá fi wé èyí tí Ọlọ́run dárí rẹ̀ jì wá. Bákan náà, ẹ̀ẹ̀kan kọ́ ni Jèhófà dárí jì wá, àìmọye ìgbà ló máa ń ṣe bẹ́ẹ̀. Ṣé kò wá yẹ ká máa dárí ji àwọn arákùnrin wa, ká tiẹ̀ gbà pé wọ́n ṣẹ̀ wá lóòótọ́? Bí Jésù sì ṣe sọ nínú Ìwàásù orí Òkè, Ọlọ́run máa “dárí àwọn gbèsè wa jì wá, bí àwa náà ṣe dárí ji àwọn tó jẹ wá ní gbèsè.”—Mátíù 6:12.