Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 20

Iṣẹ́ Ìyanu Kejì ní Kánà

Iṣẹ́ Ìyanu Kejì ní Kánà

MÁÀKÙ 1:14, 15 LÚÙKÙ 4:14, 15 JÒHÁNÙ 4:43-54

  • JÉSÙ Ń WÀÁSÙ PÉ ‘ÌJỌBA ỌLỌ́RUN TI SÚN MỌ́LÉ’

  • Ó WO ỌMỌDÉKÙNRIN KAN SÀN LÁTI Ọ̀NÀ JÍJÌN

Lẹ́yìn tí Jésù lo nǹkan bí ọjọ́ méjì ní Samáríà, ó pa dà sí ìlú rẹ̀. Ó ti wàásù gan-an ní Jùdíà, àmọ́ kì í ṣe torí pé ó fẹ́ sinmi ló fi pa dà sílùú rẹ̀. Iṣẹ́ ìwàásù ló tún fẹ́ lọ ṣe níbẹ̀, èyí sì máa ṣàrà ọ̀tọ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lo. Ó ṣeé ṣe kí Jésù ti mọ̀ pé wọn ò ní gba òun tọwọ́ tẹsẹ̀, ó ṣe tán, òun náà ló sọ pé “wòlíì kì í gbayì ní ìlú rẹ̀.” (Jòhánù 4:44) Dípò káwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ dúró tì í, ṣe ni wọ́n pa dà sí ilé wọn, tí wọ́n sì ń bá iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wọn lọ.

Kí ni ìwàásù Jésù dá lé? Ó ń kọ́ni pé: ‘Ìjọba Ọlọ́run ti sún mọ́lé. Ẹ ronú pìwà dà, kí ẹ sì ní ìgbàgbọ́ nínú ìhìn rere.’ (Máàkù 1:15) Kí làwọn èèyàn wá ṣe lẹ́yìn tí wọ́n gbọ́ ìhìn rere náà? Ọ̀pọ̀ lára àwọn ará Gálílì tẹ́wọ́ gba Jésù, wọ́n sì bọlá fún un. Kì í ṣe torí ìwàásù rẹ̀ nìkan ni wọ́n fi ṣe bẹ́ẹ̀. Ìdí míì ni pé àwọn ará Gálílì kan wà níbi Ìrékọjá tí wọ́n ṣe ní Jerúsálẹ́mù ní oṣù díẹ̀ sẹ́yìn, wọ́n sì rí àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe.—Jòhánù 2:23.

Ibo gan-an ni Jésù ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù àrà ọ̀tọ̀ yìí ní Gálílì? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ní Kánà, níbi tó ti sọ omi di wáìnì níbi ìgbéyàwó kan. Ẹ̀ẹ̀kejì tí Jésù lọ síbẹ̀ nìyí, ó gbọ́ pé ọmọ kan ń ṣàìsàn, àìsàn náà sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ gbẹ̀mí rẹ̀. Ọmọ òṣìṣẹ́ Ọba Hẹ́rọ́dù Áńtípà ni, ìyẹn ọba tó pa Jòhánù Arinibọmi. Òṣìṣẹ́ ọba yìí gbọ́ pé Jésù ti kúrò ní Jùdíà wá sí Kánà. Torí náà, ó gbéra kúrò nílé ẹ̀ ní Kápánáúmù láti lọ wá Jésù ní Kánà. Ọkùnrin tó ń ṣọ̀fọ̀ náà sọ fún Jésù pé: “Olúwa, sọ̀ kalẹ̀ wá kí ọmọ mi kékeré tó kú.”—Jòhánù 4:49.

Ó ṣeé ṣe kí ohun tí Jésù sọ ya ọkùnrin náà lẹ́nu, Jésù ní: “Máa lọ; ọmọ rẹ ti yè.” (Jòhánù 4:50) Òṣìṣẹ́ ọba yìí gba Jésù gbọ́, ó sì pa dà sílé. Bó ṣe ń lọ, ó pàdè àwọn ẹrú ẹ̀ tí wọ́n ń bọ̀ wá bá a yọ̀. Wọ́n sọ fún un pé ara ọmọ ẹ̀ ti yá, pé kò kú mọ́! Ó wá bi wọ́n pé, ‘Ìgbà wo ni ara rẹ̀ yá?’ torí ó fẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà yé òun dáadáa.

Wọ́n dáhùn pé: “Wákàtí keje ni ibà náà fi í sílẹ̀ lánàá.”—Jòhánù 4:52.

Ọkùnrin yẹn wá mọ̀ pé ìgbà tí Jésù sọ pé: “Ọmọ rẹ ti yè” gangan ni ara ọmọ òun yá. Lẹ́yìn ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn, ọkùnrin yẹn àti agbo ilé rẹ̀ di ọmọlẹ́yìn Jésù.

Iṣẹ́ ìyanu méjì ni Jésù ṣe ní Kánà. Ó sọ omi di wáìnì, ó sì mú ọmọdékùnrin kan lára dá láti nǹkan bíi máìlì mẹ́rìndínlógún (16) síbi tọ́mọ náà wà. Kì í ṣe iṣẹ́ ìyanu méjì yìí nìkan ni Jésù ṣe, àmọ́ ti ọmọ tó wò sàn yẹn ṣàrà ọ̀tọ̀ torí ó jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé ó ti pa dà sí Gálílì. Ó dájú pé wòlíì Ọlọ́run ni Jésù. Àmọ́, báwo ni ‘wòlíì yìí ṣe máa gbayì tó ní ìlú rẹ̀?’

A máa rí ìdáhùn sí ìbéèrè yẹn nígbà tí Jésù bá lọ sí ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀ ní Násárẹ́tì. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí i níbẹ̀?