Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 48

Jésù Ṣe Iṣẹ́ Ìyanu, àmọ́ Àwọn Ará Násárẹ́tì Kò Gbà Á Gbọ́

Jésù Ṣe Iṣẹ́ Ìyanu, àmọ́ Àwọn Ará Násárẹ́tì Kò Gbà Á Gbọ́

MÁTÍÙ 9:27-34; 13:54-58 MÁÀKÙ 6:1-6

  • JÉSÙ WO AFỌ́JÚ MÉJÌ ÀTI ODI KAN SÀN

  • ÀWỌN ARÁ NÁSÁRẸ́TÌ Ò GBÀ Á GBỌ́

Àtàárọ̀ lọwọ́ Jésù ti dí. Lẹ́yìn tó kúrò ní Dekapólì, ó wo obìnrin kan tó ní ìsun ẹ̀jẹ̀ sàn, ó sì tún jí ọmọbìnrin Jáírù dìde. Àmọ́ Jésù ò tíì parí iṣẹ́ rẹ̀. Bó ṣe ń kúrò nílé Jáírù, àwọn ọkùnrin afọ́jú méjì tẹ̀ lé e, wọ́n sì ń kígbe pé: “Ṣàánú wa, Ọmọ Dáfídì.”—Mátíù 9:27.

Bí àwọn ọkùnrin náà ṣe pe Jésù ní “Ọmọ Dáfídì” fi hàn pé wọ́n gbà pé Jésù ló máa jogún ìtẹ́ Dáfídì, wọ́n sì gbà pé òun ni Mèsáyà. Jésù kọ́kọ́ ṣe bíi pé òun ò gbọ́, torí ó fẹ́ mọ̀ bóyá wọ́n nígbàgbọ́ nínú òun. Síbẹ̀ àwọn ọkùnrin yẹn ò jẹ́ kó sú àwọn. Nígbà tí Jésù wọnú ilé kan, àwọn ọkùnrin náà tẹ̀ lé e wọlé. Jésù wá bi wọ́n pé: “Ṣé ẹ nígbàgbọ́ pé mo lè ṣe é?” Wọ́n fi ìdánilójú sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa.” Jésù wá fọwọ́ kan ojú wọn, ó sì sọ pé: “Kó rí bẹ́ẹ̀ fún yín gẹ́gẹ́ bí ìgbàgbọ́ yín.”—Mátíù 9:28, 29.

Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ lojú àwọn ọkùnrin náà là! Bí Jésù ṣe sábà máa ń sọ fáwọn tó wò sàn, ó sọ fáwọn ọkùnrin méjì náà pé kí wọ́n má sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ náà fún ẹnikẹ́ni. Àmọ́ torí pé inú ẹni kì í dùn ká pa á mọ́ra, ṣe ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ohun tí Jésù ṣe káàkiri.

Bí àwọn ọkùnrin yẹn ṣe ń kúrò lọ́dọ̀ Jésù, àwọn èèyàn mú ọkùnrin kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Ọkùnrin náà ò lè sọ̀rọ̀ torí pé ó ní ẹ̀mí èṣù. Jésù wá lé ẹ̀mí èṣù náà jáde, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ọkùnrin náà bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀. Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ fáwọn èèyàn tó wà níbẹ̀, wọ́n sì ń sọ pé: “A ò tíì rí irú èyí rí ní Ísírẹ́lì.” Kódà àwọn Farisí wà níbẹ̀ lọ́jọ́ náà. Wọn ò sì lè sọ pé iṣẹ́ ìyanu náà ò ṣẹlẹ̀, síbẹ̀ ṣe ni wọ́n tún fẹ̀sùn kàn án, wọ́n sọ pé: “Agbára alákòóso àwọn ẹ̀mí èṣù ló fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde.”—Mátíù 9:33, 34.

Kò pẹ́ sígbà yẹn, Jésù pa dà sí Násárẹ́tì tó jẹ́ ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sì wà pẹ̀lú rẹ̀. Ní nǹkan bí ọdún kan sẹ́yìn, Jésù kọ́ àwọn èèyàn nínú sínágọ́gù tó wà ní Násárẹ́tì. Ẹnu ya àwọn èèyàn nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ, àmọ́ nígbà tó yá inú bí wọn, wọ́n sì fẹ́ pa á. Àmọ́ ní báyìí, Jésù ń wá bó ṣe máa ràn wọ́n lọ́wọ́.

Nígbà tó di ọjọ́ Sábáàtì, Jésù lọ sínú sínágọ́gù, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wọn. Ẹnu ya ọ̀pọ̀ lára àwọn tó wà níbẹ̀, wọ́n sì ń béèrè pé: “Ibo ni ọkùnrin yìí ti rí ọgbọ́n yìí àti àwọn iṣẹ́ agbára yìí? Àbí ọmọ káfíńtà kọ́ nìyí? Ṣebí Màríà lorúkọ ìyá rẹ̀, Jémíìsì, Jósẹ́fù, Símónì àti Júdásì sì ni àwọn arákùnrin rẹ̀? Ṣebí gbogbo àwọn arábìnrin rẹ̀ ló wà pẹ̀lú wa? Ibo ló ti wá rí gbogbo èyí?”—Mátíù 13:54-56.

Àwọn èèyàn náà gbà pé àwọn mọ Jésù dáadáa. Wọ́n ń sọ pé ‘ìṣojú wa ni wọ́n ṣe bí i, ìṣojú wa ló sì ṣe dàgbà, báwo ló ṣe máa wá jẹ́ Mèsáyà?’ Láìka àwọn ẹ̀rí tí wọ́n rí àti bí ọgbọ́n ẹ̀ ṣe pọ̀ tó títí kan àwọn iṣẹ́ ìyanu tó ṣe, wọn ò nígbàgbọ́ nínú rẹ̀. Kódà, àwọn mọ̀lẹ́bí ẹ̀ gan-an ò nígbàgbọ́ nínú ẹ̀ torí pé wọ́n mọ̀ ọ́n dáadáa. Jésù wá sọ fún wọn pé: “Wòlíì máa ń níyì, àmọ́ kì í gbayì ní ìlú rẹ̀ àti ní ilé òun fúnra rẹ̀.”—Mátíù 13:57.

Ó ya Jésù lẹ́nu pé àwọn èèyàn náà ò nígbàgbọ́ nínú òun. Nítorí náà, kò ṣe iṣẹ́ agbára kankan níbẹ̀, “ó kàn gbé ọwọ́ rẹ̀ lé díẹ̀ lára àwọn aláìsàn, ó sì wò wọ́n sàn.”—Máàkù 6:5, 6.