Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 37

Jésù Jí Ọmọ Opó Kan Dìde

Jésù Jí Ọmọ Opó Kan Dìde

LÚÙKÙ 7:11-17

  • JÉSÙ JÍ ẸNÌ KAN DÌDE NÍ NÁÍNÌ

Kété lẹ́yìn tí Jésù wo ìránṣẹ́ ọ̀gágun kan sàn, ó kúrò ní Kápánáúmù, ó sì forí lé ìlú Náínì tó wà ní ohun tó lé ní ogún (20) máìlì lápá gúúsù. Àmọ́ òun nìkan kọ́ lọ́ ń lọ, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ àtàwọn èrò míì náà tẹ̀ lé e. Ó ṣeé ṣe kó ti bọ́ sọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́ nígbà tí wọ́n fi máa dé ìtòsí ìlú Náínì. Wọ́n pàdé àwọn tó gbé òkú ọ̀dọ́kùnrin kan tí wọ́n fẹ́ lọ sin, èrò rẹpẹtẹ sì tẹ̀ lé wọn.

Ìyá ọmọkùnrin náà ni ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ jù láàárín wọn. Opó ni, ọmọ kan ṣoṣo tó ní ló tún fò ṣánlẹ̀ tó sì kú yìí. Nígbà tí ọkọ ẹ̀ kú, ó ṣeé ṣe kó máa tu ara ẹ̀ nínú pé ọmọ òun ṣì wà pẹ̀lú òun. Ó dájú pé ó máa nífẹ̀ẹ́ ọmọ náà gan-an torí ó gbà pé òun ló máa tọ́jú òun bóun ṣe ń dàgbà. Ọmọ náà ló wá kú yìí. Ta ni obìnrin náà máa fojú jọ báyìí, ta ló sì máa tọ́jú ẹ̀ tó bá darúgbó?

Nígbà tí Jésù rí bí obìnrin náà ṣe ń sunkún torí ọ̀fọ̀ tó ṣẹ̀ ẹ́, àánú ẹ̀ ṣe é. Jésù wá sọ̀rọ̀ ìtùnú fún un, ó sì sọ tàánútàánú pé: “Má sunkún mọ́.” Àmọ́ kò fi mọ síbẹ̀. Ó sún mọ́ àwọn tó gbé òkú náà, ó sì fọwọ́ kan ohun tí wọ́n fi gbé e. (Lúùkù 7:13, 14) Ohun tó ṣe yìí mú káwọn èèyàn tó ń ṣọ̀fọ̀ náà dúró lẹ́ẹ̀kan náà. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n máa ronú pé, ‘Kí nìdí tó fi dá àwọn tó gbé òkú náà dúró, kí ló fẹ́ ṣe gan-an?’

Kí ló ṣeé ṣe káwọn tó tẹ̀ lé Jésù máa rò? Wọ́n mọ̀ pé Jésù lè wo aláìsàn sàn torí pé ọ̀pọ̀ ló ti wò sàn lójú wọn. Àmọ́ kò jọ pé Jésù jí ẹnì kankan dìde lójú wọn rí. Òótọ́ ni pé àwọn wòlíì kan ti jí òkú dìde láyé àtijọ́, àmọ́ ṣé Jésù lè ṣerú ẹ̀? (1 Àwọn Ọba 17:17-23; 2 Àwọn Ọba 4:32-37) Jésù pàṣẹ pé: “Ọ̀dọ́kùnrin, mo sọ fún ọ, dìde!” (Lúùkù 7:14) Ohun tó sì ṣẹlẹ̀ gẹ́lẹ́ nìyẹn. Ọ̀dọ́kùnrin náà dìde jókòó, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀! Ni Jésù bá fà á lé ìyá ẹ̀ lọ́wọ́. Inú obìnrin náà dùn gan-an torí pé kò tún ní dá wà mọ́.

Nígbà táwọn èrò náà rí i tí ọmọkùnrin náà dìde, wọ́n yin Jèhófà Olùfúnni-ní-Ìyè lógo, wọ́n sọ pé: “A ti gbé wòlíì ńlá kan dìde láàárín wa.” Àwọn míì sì gbà pé Jèhófà ló fún Jésù lágbára tó fi ṣe iṣẹ́ ìyanu náà, wọ́n sọ pé: “Ọlọ́run ti yíjú sí àwọn èèyàn rẹ̀.” (Lúùkù 7:16) Kíá ni ìròyìn yìí tàn káàkiri àwọn ìlú tó yí Náínì ká, ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kó dé Násárẹ́tì, ìyẹn ìlú ìbílẹ̀ Jésù tó wà ní nǹkan bíi máìlì mẹ́fà. Kódà, ìròyìn náà dé iyànníyàn Jùdíà.

Jòhánù Arinibọmi ṣì wà lẹ́wọ̀n, ó sì fẹ́ mọ̀ nípa àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ń ṣe. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jòhánù ròyìn àwọn ohun tí Jésù ṣe fún un. Kí ni Jòhánù wá ṣe?