Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 65

Jésù Ń Kóni Nígbà Tó Ń Lọ sí Jerúsálẹ́mù

Jésù Ń Kóni Nígbà Tó Ń Lọ sí Jerúsálẹ́mù

MÁTÍÙ 8:19-22 LÚÙKÙ 9:51-62 JÒHÁNÙ 7:2-10

  • OHUN TÁWỌN ARÁKÙNRIN JÉSÙ RÒ NÍPA RẸ̀

  • BÁWO NI Ọ̀RỌ̀ ÌJỌBA ỌLỌ́RUN ṢE ṢE PÀTÀKÌ TÓ?

Jésù lo èyí tó pọ̀ jù lára àkókò rẹ̀ ní Gálílì torí pé àwọn èèyàn ibẹ̀ fetí sí i ju àwọn ará Jùdíà lọ. Yàtọ̀ síyẹn, ṣe ni ‘àwọn Júù túbọ̀ ń wá bí wọ́n ṣe máa pa á’ lẹ́yìn tó wo ọkùnrin kan sàn lọ́jọ́ Sábáàtì nígbà tó wà ní Jerúsálẹ́mù.—Jòhánù 5:18; 7:1.

Àsìkò ìkórè ọdún 32 S.K. ti tó, àwọn Júù sì ti ń múra sílẹ̀ fún Àjọyọ̀ Àwọn Àgọ́ Ìjọsìn (tàbí Àjọyọ̀ Àtíbàbà). Ọjọ́ méje ni wọ́n fi ń ṣe Àjọyọ̀ náà, àpéjọ ọlọ́wọ̀ ni wọ́n sì máa ń ṣe ní ọjọ́ kẹjọ. Àjọyọ̀ yẹn ni wọ́n fi máa ń kádìí iṣẹ́ ọ̀gbìn tí wọ́n ṣe lọ́dún, àsìkò ayọ̀ àti ìdúpẹ́ ló sì máa ń jẹ́.

Àwọn arákùnrin Jésù, ìyẹn Jémíìsì, Símónì, Jósẹ́fù àti Júdásì sọ fún un pé: “Kúrò níbí, kí o sì lọ sí Jùdíà.” Torí pé Jerúsálẹ́mù ni tẹ́ńpìlì wà, àwọn èèyàn máa ń pọ̀ gan-an níbẹ̀ tí wọ́n bá ń ṣe àjọyọ̀ lẹ́ẹ̀mẹ́ta lọ́dún. Àwọn arákùnrin Jésù wá ronú pé: “Kò sí ẹni tí á máa ṣe ohunkóhun ní ìkọ̀kọ̀ tó bá fẹ́ kí wọ́n mọ òun ní gbangba. Tí o bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí, fi ara rẹ han ayé.”—Jòhánù 7:3, 4.

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn arákùnrin Jésù mẹ́rẹ̀ẹ̀rin yìí “ò gbà” pé òun ni Mèsáyà, wọ́n fẹ́ káwọn èèyàn tó wá síbi àjọyọ̀ náà rí àwọn iṣẹ́ ìyanu tó ń ṣe. Torí pé Jésù mọ ohun tó lè ṣẹlẹ̀ tóun bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó sọ fún wọn pé: “Ayé ò ní ìdí kankan láti kórìíra yín, àmọ́ ó kórìíra mi, torí mò ń jẹ́rìí nípa rẹ̀ pé àwọn iṣẹ́ rẹ̀ burú. Ẹ̀yin ẹ máa lọ síbi àjọyọ̀ náà; kò tíì yá fún mi láti lọ síbi àjọyọ̀ yìí, torí àkókò mi ò tíì tó ní kíkún.”—Jòhánù 7:5-8.

Lẹ́yìn ọjọ́ bíi mélòó kan táwọn arákùnrin Jésù pẹ̀lú àwọn arìnrìn àjò tó kù ti wà lójú ọ̀nà sí Jerúsálẹ́mù, Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ gbéra ní bòókẹ́lẹ́ káwọn èèyàn má bàa rí wọn. Wọ́n gba ọ̀nà Samáríà tó ṣe tààràtà dípò kí wọ́n gba ọ̀nà Jọ́dánì tí ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń gbà. Jésù àtàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ máa nílò ibi tí wọ́n máa sùn tí wọ́n bá dé Samáríà, torí náà Jésù rán àwọn èèyàn ṣáájú láti lọ ṣètò ibì kan sílẹ̀ fún wọn. Nígbà tí wọ́n dé ìlú kan, àwọn èèyàn ibẹ̀ ò gbà wọ́n lálejò torí pé Jerúsálẹ́mù ni Jésù ń lọ láti lọ ṣe àjọyọ̀ àwọn Júù. Ni Jémíìsì àti Jòhánù bá bi í pé: “Olúwa, ṣé o fẹ́ ká pe iná sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run, kó sì pa wọ́n run?” (Lúùkù 9:54) Àmọ́ Jésù bá wọn wí, gbogbo wọn sì ń bá ìrìn àjò wọn lọ.

Bí wọ́n ṣe ń lọ, akọ̀wé òfin kan sọ fún Jésù pé: “Olùkọ́, màá tẹ̀ lé ọ lọ ibikíbi tí o bá lọ.” Jésù dá a lóhùn pé: “Àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ní ihò, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ní ìtẹ́, àmọ́ Ọmọ èèyàn kò ní ibì kankan tó máa gbé orí rẹ̀ lé.” (Mátíù 8:19, 20) Ohun tí Jésù ń sọ ni pé ọkùnrin náà máa kojú ọ̀pọ̀ ìṣòro tó bá di ọmọ ẹ̀yìn òun. Ohun tí akọ̀wé òfin náà ṣe fi hàn pé ìgbéraga ò lè jẹ́ kó gbé irú ìgbésí ayé tí Jésù ń gbé. Ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lè bi ara rẹ̀ pé, ‘Ṣé èmi náà múra tán láti tẹ̀ lé Jésù?’

Jésù tún sọ fún ọkùnrin míì pé: “Máa tẹ̀ lé mi.” Àmọ́ ọkùnrin náà fèsì pé: “Olúwa, gbà mí láyè kí n kọ́kọ́ lọ sìnkú bàbá mi.” Torí pé Jésù lóye ohun tí ọkùnrin náà ní lọ́kàn, ó sọ fún un pé: “Jẹ́ kí àwọn òkú máa sin òkú wọn, àmọ́ ìwọ lọ, kí o sì máa kéde Ìjọba Ọlọ́run káàkiri.” (Lúùkù 9:59, 60) Kì í ṣe pé bàbá ọkùnrin náà ti kú o. Torí kò jọ pé ọkùnrin náà máa ráyè bá Jésù sọ̀rọ̀ ká sọ pé bàbá ẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ kú. Ìṣòro ọkùnrin náà ni pé kò ṣe tán láti fi Ìjọba Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé rẹ̀.

Bí wọ́n ṣe ń bá ọ̀nà wọn lọ sí Jerúsálẹ́mù, ọkùnrin míì tún sọ fún Jésù pé: “Màá tẹ̀ lé ọ, Olúwa, àmọ́ kọ́kọ́ gbà mí láyè láti dágbére fún àwọn ará ilé mi pé ó dìgbòóṣe.” Jésù dá a lóhùn pé: “Ẹnikẹ́ni tó bá fi ọwọ́ rẹ̀ lé ohun ìtúlẹ̀, tó wá wo àwọn ohun tó wà lẹ́yìn, kò yẹ fún Ìjọba Ọlọ́run.”—Lúùkù 9:61, 62.

Àwọn tó bá fẹ́ di ọmọ ẹ̀yìn Jésù gbọdọ̀ gbájú mọ́ ohun tó jẹ mọ́ Ìjọba náà. Tẹ́ni tó ń kọbè ò bá fojú sí ohun tó ń ṣe, ebè yẹn lè wọ́. Tó bá sì ń wẹ̀yìn bó ṣe ń bá iṣẹ́ lọ, kò ní tètè parí iṣẹ́ yẹn. Bákan náà, tí ẹnikẹ́ni bá lọ ń bojú wẹ̀yìn nínú ayé burúkú yìí, ẹni náà lè kọsẹ̀ kó sì kúrò lójú ọ̀nà tó lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun.