Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 33

Jésù Mú Àsọtẹ́lẹ̀ Àìsáyà Ṣẹ

Jésù Mú Àsọtẹ́lẹ̀ Àìsáyà Ṣẹ

MÁTÍÙ 12:15-21 MÁÀKÙ 3:7-12

  • ÀWỌN ÈÈYÀN ṢÙRÙ BO JÉSÙ

  • Ó MÚ ÀSỌTẸ́LẸ̀ ÀÌSÁYÀ ṢẸ

Nígbà tí Jésù gbọ́ pé àwọn Farisí àtàwọn ọmọ ẹgbẹ́ Hẹ́rọ́dù fẹ́ pa òun, òun àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ sí Òkun Gálílì. Èrò rẹpẹtẹ ló wá sọ́dọ̀ ẹ̀ láti ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Wọ́n wá láti Gálílì, Tírè àti Sídónì tó wà létíkun, àwọn míì sì wá láti ìlà oòrùn Odò Jọ́dánì. Kódà àwọn kan wá láti Jerúsálẹ́mù àti Ídúmíà tó wà lápá gúúsù. Torí náà Jésù wo ọ̀pọ̀ èèyàn sàn, ìyẹn sì mú kí àwọn tó ní àìsàn tó le gan-an ṣùrù bò ó. Kódà, wọn ò lè mú sùúrù pé kó wá fọwọ́ kàn wọ́n, ṣe ni gbogbo wọn bẹ̀rẹ̀ sí í fọwọ́ kàn án.—Máàkù 3:9, 10.

Àwọn èèyàn náà pọ̀ débi pé Jésù ní láti sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ pé kí wọ́n ṣètò ọkọ̀ ojú omi kékeré kan fún òun kóun lè lọ sójú omi káwọn èèyàn má bàa há òun mọ́. Ìyẹn á tún mú kó lè kọ́ wọn látorí omi tàbí lọ síbòmíì létíkun yẹn láti ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́.

Mátíù tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn kíyè sí i pé ohun tí Jésù ṣe yìí mú “ohun tí a sọ nípasẹ̀ wòlíì Àìsáyà” ṣẹ. (Mátíù 12:17) Àmọ́, àsọtẹ́lẹ̀ wo ni Jésù mú ṣẹ níbí yìí?

Bíbélì sọ pé: “Wò ó! Ìránṣẹ́ mi tí mo yàn, àyànfẹ́ mi, ẹni tí mo tẹ́wọ́ gbà! Màá fi ẹ̀mí mi sára rẹ̀, ó sì máa jẹ́ kí ìdájọ́ òdodo ṣe kedere sí àwọn orílẹ̀-èdè. Kò ní jiyàn, kò ní pariwo, ẹnikẹ́ni ò sì ní gbọ́ ohùn rẹ̀ láwọn ọ̀nà tó wà ní gbangba. Kò ní fọ́ esùsú kankan tó ti ṣẹ́, kò sì ní pa òwú àtùpà kankan tó ń jó lọ́úlọ́ú, tí wọ́n fi ọ̀gbọ̀ ṣe, títí ó fi máa ṣe ìdájọ́ òdodo láṣeyọrí. Ní tòótọ́, àwọn orílẹ̀-èdè máa ní ìrètí nínú orúkọ rẹ̀.”—Mátíù 12:18-21; Àìsáyà 42:1-4.

Kò sí àní-àní pé Jésù ni àyànfẹ́ tí àsọtẹ́lẹ̀ yìí sọ pé Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà. Jésù mú kí ìdájọ́ òdodo ṣe kedere, èyí táwọn olórí ẹ̀sìn ti fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn nítorí àwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ wọn. Wọ́n ṣi Òfin Ọlọ́run lò kó lè bá ohun tí wọ́n fẹ́ mu. Bí àpẹẹrẹ, àwọn Farisí kì í ran ẹni tó bá ń ṣàìsàn lọ́wọ́ lọ́jọ́ Sábáàtì. Àmọ́ Jésù ní tiẹ̀ ò ṣe bẹ́ẹ̀. Ó jẹ́ kí wọ́n mọ ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run, ó sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ẹ̀mí Ọlọ́run wà lára òun. Nípa bẹ́ẹ̀, ó dá àwọn èèyàn nídè kúrò lábẹ́ àjàgà àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ wọn. Ìdí nìyẹn táwọn olórí ẹ̀sìn ṣe fẹ́ pa á. Ìyẹn mà burú jáì o!

Kí ló túmọ̀ sí pé “kò ní jiyàn, kò ní pariwo, ẹnikẹ́ni ò sì ní gbọ́ ohùn rẹ̀ láwọn ọ̀nà tó wà ní gbangba”? Tí Jésù bá wo àwọn èèyàn sàn, kì í jẹ́ káwọn tó wò sàn tàbí àwọn ẹ̀mí èṣù “jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ òun.” (Máàkù 3:12) Ìdí sì ni pé bí ìròyìn òkèèrè ò bá lé, ńṣe ló máa ń dín, kò sì fẹ́ kó jẹ́ pé ohun tí kì í ṣe òótọ́ làwọn èèyàn á gbọ́ nípa òun.

Bákan náà, Jésù sọ̀rọ̀ ìtùnú fáwọn tó dà bí esùsú tó ti ṣẹ́ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ táwọn èèyàn sì ti gbá dà nù. Wọ́n dà bí òwú àtùpà tí wọ́n fi ọ̀gbọ̀ ṣe tó ń jó lọ́úlọ́ú tó sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kú tán. Jésù ò ṣẹ́ esùsú kankan, kò sì pa àwọn àtùpà tó ń jó lọ́úlọ́ú náà. Dípò bẹ́ẹ̀, ó gba tàwọn onírẹ̀lẹ̀ rò, ó sì fìfẹ́ ràn wọ́n lọ́wọ́. Kò sí àní-àní pé Jésù lẹni táwọn èèyàn lè nírètí nínú rẹ̀!