Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 58

Ó Mú Kí Búrẹ́dì Pọ̀, Ó sì Kìlọ̀ Nípa Ìwúkàrà

Ó Mú Kí Búrẹ́dì Pọ̀, Ó sì Kìlọ̀ Nípa Ìwúkàrà

MÁTÍÙ 15:32–16:12 MÁÀKÙ 8:1-21

  • JÉSÙ BỌ́ ẸGBẸ̀RÚN MẸ́RIN (4,000) ỌKÙNRIN

  • Ó NÍ KÁWỌN ỌMỌ Ẹ̀YÌN ṢỌ́RA FÚN ÌWÚKÀRÀ ÀWỌN FARISÍ

Èrò rẹpẹtẹ wá sọ́dọ̀ Jésù láti agbègbè Dekapólì ní apá ìlà oòrùn Òkun Gálílì. Àwọn èèyàn náà gbé apẹ̀rẹ̀ ńlá tó kún fún oúnjẹ dání kí wọ́n lè rí nǹkan jẹ. Wọ́n ń lọ sọ́dọ̀ Jésù kí wọ́n lè gbọ́rọ̀ ẹ̀, kó sì mú wọn lára dá.

Nígbà tó yá, Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ pé: “Àánú àwọn èèyàn yìí ń ṣe mí, torí ọjọ́ kẹta nìyí tí wọ́n ti wà lọ́dọ̀ mi, tí wọn ò sì ní ohunkóhun tí wọ́n máa jẹ. Tí n bá ní kí wọ́n máa lọ sílé láìjẹun, okun wọn máa tán lójú ọ̀nà, ibi tó jìnnà sì ni àwọn kan lára wọn ti wá.” Àmọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bi í pé: “Ibo lèèyàn ti máa rí oúnjẹ tó máa tó bọ́ àwọn èèyàn yìí ní àdádó yìí?”—Máàkù 8:2-4.

Jésù wá béèrè pé: “Búrẹ́dì mélòó lẹ ní?” Àwọn ọmọ ẹ̀yìn sọ pé: “Méje àti ẹja wẹ́wẹ́ díẹ̀.” (Mátíù 15:34) Jésù sọ fáwọn èèyàn náà pé kí wọ́n jókòó sílẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó mú búrẹ́dì àti ẹja náà, ó dúpẹ́, ó sì fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, àwọn ọmọ ẹ̀yìn wá pín in fún àwọn èèyàn náà. Ó yani lẹ́nu pé gbogbo wọn jẹ, wọ́n yó, kódà, ohun tó ṣẹ́ kù kún apẹ̀rẹ̀ ńlá méje bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹgbẹ̀rún mẹ́rin (4,000) ọkùnrin ló jẹun títí kan àwọn obìnrin àtàwọn ọmọdé!

Lẹ́yìn tí Jésù ní káwọn èèyàn náà máa lọ, òun àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ wọ ọkọ̀ ojú omi lọ sí Mágádánì ní apá ìwọ̀ oòrùn Òkun Gálílì. Àwọn Farisí àtàwọn kan lára àwọn Sadusí wá bá a níbẹ̀ kí wọ́n lè dán an wò, wọ́n ní kó fi àmì kan han àwọn láti ọ̀run.

Jésù mọ ohun tí wọ́n ní lọ́kàn, torí náà ó sọ fún wọn pé: “Tó bá di ìrọ̀lẹ́, ẹ máa ń sọ pé, ‘Ojú ọjọ́ máa dáa, torí ojú ọ̀run pọ́n bí iná,’ tó bá sì di àárọ̀, ẹ máa ń sọ pé ‘Ojú ọjọ́ máa tutù, òjò sì máa rọ̀ lónìí, torí ojú ọ̀run pọ́n bí iná, àmọ́ ó ṣú dùdù.’ Ẹ mọ bí wọ́n ṣe ń túmọ̀ ojú ọjọ́, àmọ́ ẹ ò lè túmọ̀ àwọn àmì àkókò.” (Mátíù 16:2, 3) Jésù wá sọ fáwọn Farisí àtàwọn Sadusí náà pé òun ò ní fi àmì kankan hàn wọ́n àfi àmì Jónà.

Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ wá wọnú ọkọ̀, wọ́n sì forí lé Bẹtisáídà ní apá àríwá ìlà oòrùn òkun náà. Nígbà tí wọ́n wà lójú ọ̀nà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rí i pé búrẹ́dì kan ṣoṣo làwọn mú dání, wọ́n ti gbà gbé láti mú èyí tó máa tó wọn. Jésù wá kìlọ̀ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ nípa àwọn Farisí àtàwọn Sadusí tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Hẹ́rọ́dù tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá dán an wò, ó ní: “Ẹ la ojú yín sílẹ̀; kí ẹ ṣọ́ra fún ìwúkàrà àwọn Farisí àti ìwúkàrà Hẹ́rọ́dù.” Ṣe làwọn ọmọ ẹ̀yìn rò pé ọ̀rọ̀ búrẹ́dì táwọn gbàgbé ló ń bá àwọn sọ, àmọ́ ohun tó ń sọ kọ́ nìyẹn. Jésù mọ̀ pé wọn ò lóye ohun tóun sọ, ó wá sọ fún wọn pé: “Kí ló dé tí ẹ fi ń jiyàn torí pé ẹ ò ní búrẹ́dì?”—Máàkù 8:15-17.

Ó yẹ káwọn ọmọ ẹ̀yìn mọ̀ pé kì í ṣe ọ̀rọ̀ búrẹ́dì ni Jésù ń sọ torí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ fi búrẹ́dì bọ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn tán ni. Jésù wá bi wọ́n pé: “Ṣé ẹ ò rántí ni, nígbà tí mo bu búrẹ́dì márùn-ún fún ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) ọkùnrin, ẹ̀kún apẹ̀rẹ̀ mélòó lẹ kó jọ látinú ohun tó ṣẹ́ kù?” Wọ́n ní: “Méjìlá (12).” Jésù tún béèrè pé: “Nígbà tí mo bu búrẹ́dì méje fún ẹgbẹ̀rún mẹ́rin (4,000) ọkùnrin, ẹ̀kún apẹ̀rẹ̀ ńlá mélòó lẹ kó jọ látinú ohun tó ṣẹ́ kù?” Wọ́n ní: “Méje.”—Máàkù 8:18-20.

Jésù tún bi wọ́n pé: “Kí nìdí tí kò fi yé yín pé ọ̀rọ̀ búrẹ́dì kọ́ ni mò ń bá yín sọ?” Ó wá sọ pé: “Ẹ ṣọ́ra fún ìwúkàrà àwọn Farisí àti àwọn Sadusí.”—Mátíù 16:11.

Ìgbà yẹn ni wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ wá lóye ohun tí Jésù ń sọ. Ṣe ni ìwúkàrà máa ń sọ nǹkan di kíkan, ó sì máa ń mú kí búrẹ́dì wú. Torí náà, ìwúkàrà tí Jésù ń sọ ṣàpẹẹrẹ ìwà ìbàjẹ́ táwọn Farisí àtàwọn Sadusí ń hù. Ó wá kìlọ̀ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ pé kí wọ́n ṣọ́ra fún “ẹ̀kọ́ àwọn Farisí àti àwọn Sadusí” torí irú àwọn ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ máa ń sọni dìdàkudà.—Mátíù 16:12.