Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 23

Jésù Ṣe Iṣẹ́ Ìyanu ní Kápánáúmù

Jésù Ṣe Iṣẹ́ Ìyanu ní Kápánáúmù

MÁTÍÙ 8:14-17 MÁÀKÙ 1:21-34 LÚÙKÙ 4:31-41

  • JÉSÙ LÉ Ẹ̀MÍ ÈṢÙ JÁDE

  • ARA ÌYÁ ÌYÀWÓ PÉTÉRÙ YÁ

Lẹ́yìn tí Jésù pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn mẹ́rin, ìyẹn Pétérù, Áńdérù, Jémíìsì àti Jòhánù láti wá di apẹja èèyàn, gbogbo wọn lọ sí sínágọ́gù tó wà ní Kápánáúmù lọ́jọ́ Sábáàtì. Jésù ń kọ́ni ní sínágọ́gù, ẹnu sì ń ya àwọn èèyàn torí ọ̀nà tó gbà ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́. Ó ń kọ́ wọn bí ẹni tó ní ọlá àṣẹ, kì í ṣe bí àwọn akọ̀wé òfin.

Ọkùnrin kan tó ní ẹ̀mí èṣù wà nínú sínágọ́gù lọ́jọ́ Sábáàtì yẹn. Ó wá kígbe pé: “Kí ló pa wá pọ̀, Jésù ará Násárẹ́tì? Ṣé o wá pa wá run ni? Mo mọ ẹni tí o jẹ́ gan-an, Ẹni Mímọ́ Ọlọ́run ni ọ́!” Àmọ́, Jésù bá ẹ̀mí èṣù náà wí, ó ní: “Dákẹ́, kí o sì jáde kúrò nínú rẹ̀!”—Máàkù 1:24, 25.

Ni ẹ̀mí burúkú náà bá bẹ̀rẹ̀ sí í kígbe lẹ́yìn tó gbé ọkùnrin náà ṣánlẹ̀. Ẹ̀yìn ìyẹn ló jáde kúrò lára ọkùnrin náà “láìṣe é léṣe.” (Lúùkù 4:35) Ńṣe lẹnu ya gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀. Wọ́n wá béèrè pé: “Kí nìyí? . . . Ó ń lo agbára tó ní láti pàṣẹ fún àwọn ẹ̀mí àìmọ́ pàápàá, wọ́n sì ń ṣègbọràn sí i.” (Máàkù 1:27) Abájọ tí ìròyìn nípa iṣẹ́ ìyanu náà fi tàn ká gbogbo ilẹ̀ Gálílì.

Nígbà tí Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ kúrò ní sínágọ́gù, ilé Símónì tá a tún ń pè ní Pétérù ni wọ́n lọ. Nígbà tí wọ́n débẹ̀, wọ́n rí ìyá ìyàwó Pétérù tó ní akọ ibà. Wọ́n wá bẹ Jésù pé kó wò ó sàn. Ni Jésù bá lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, ó di ọwọ́ rẹ̀ mú, ó sì gbé e dìde. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ lara rẹ̀ yá, ó sì dúró ti Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kó se oúnjẹ fún wọn pàápàá.

Nígbà tí oòrùn wọ̀, àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í mú àwọn tó ń ṣàìsàn wá sí ilé Pétérù. Ká tó ṣẹ́jú pẹ́, ṣe ló dà bíi pé gbogbo ìlú ti kóra jọ sí ẹnu ilẹ̀kùn. Kí nìdí? Ìdí ni pé wọ́n ń wá ẹni tó máa wò wọ́n sàn. Kódà, “gbogbo àwọn tí èèyàn wọn ń ṣàìsàn, tí wọ́n ní oríṣiríṣi àrùn, mú wọn wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Bó ṣe ń gbé ọwọ́ rẹ̀ lé ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn, ó ń wò wọ́n sàn.” (Lúùkù 4:40) Láìka irú àìsàn tó ń ṣe wọ́n sí, Jésù ràn wọ́n lọ́wọ́ bí Bíbélì ṣe sọ tẹ́lẹ̀. (Àìsáyà 53:4) Kódà, ó dá àwọn tó ní ẹ̀mí èṣù sílẹ̀. Bí àwọn ẹ̀mí burúkú náà ṣe ń jáde, wọ́n ń kígbe pé: “Ìwọ ni Ọmọ Ọlọ́run.” (Lúùkù 4:41) Àmọ́ Jésù bá wọn wí, kò sì jẹ́ kí wọ́n sọ̀rọ̀ mọ́. Wọ́n mọ̀ pé Jésù ni Kristi náà, kò sì fẹ́ kí àwọn ẹ̀mí èṣù yẹn máa ṣe bíi pé àwọn ń sin Ọlọ́run tòótọ́.