Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 29

Ṣé Èèyàn Lè Ṣe Ohun Tó Dáa Lọ́jọ́ Sábáàtì?

Ṣé Èèyàn Lè Ṣe Ohun Tó Dáa Lọ́jọ́ Sábáàtì?

JÒHÁNÙ 5:1-16

  • JÉSÙ WÀÁSÙ NÍ JÙDÍÀ

  • Ó MÚ ỌKÙNRIN TÓ Ń ṢÀÌSÀN LÁRA DÁ NÍBI ODÒ KAN

Ọ̀pọ̀ nǹkan ni Jésù gbé ṣe lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ní Gálílì. Àmọ́, kì í ṣe Gálílì nìkan ni Jésù ti máa wàásù, ó sì hàn nínú ohun tó sọ pé, “Mo tún gbọ́dọ̀ kéde ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún àwọn ìlú míì.” Ìdí nìyẹn tó fi lọ “wàásù nínú àwọn sínágọ́gù Jùdíà.” (Lúùkù 4:43, 44) Èyí bọ́gbọ́n mu torí pé ó ti ń bọ́ sí àsìkò ìrúwé, wọ́n sì máa tó ṣe àjọyọ̀ kan ní Jerúsálẹ́mù.

Ohun tá a rí kà nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù ní Jùdíà kò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ tá a bá fi wé ohun tí àwọn ìwé Ìhìn Rere sọ nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ní Gálílì. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ lára àwọn ará Jùdíà ni kò fi bẹ́ẹ̀ kọbi ara sí Ìhìn Rere, Jésù ò jẹ́ kíyẹn paná ìtara òun, bó ṣe ń wàásù bẹ́ẹ̀ ló ń ṣe ohun tó dáa ní gbogbo ibi tó dé.

Jésù ò ní pẹ́ lọ sí Jerúsálẹ́mù tó jẹ́ olú ìlú Jùdíà fún Ìrékọjá ti ọdún 31 S.K. Àbáwọlé kan wà tí wọ́n ń pè ní Ibodè Àgùntàn, àwọn èèyàn sábà máa ń pọ̀ níbẹ̀ gan-an. Ìtòsí ibodè yìí ni adágún omi kan wà tí wọ́n ń pè ní Bẹtisátà. Àwọn aláìsàn, àwọn afọ́jú àtàwọn arọ máa ń wà níbẹ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé ọ̀pọ̀ gbà pé àwọn máa rí ìwòsàn táwọn bá ti wọ inú omi náà nígbà tó bá ń ru gùdù.

Lọ́jọ́ Sábáàtì kan tí Jésù wá síbẹ̀, ó rí ọkùnrin kan tó ti ń ṣàìsàn fún ọdún méjìdínlógójì (38). Jésù wá béèrè lọ́wọ́ ẹ̀ pé: “Ṣé o fẹ́ kí ara rẹ yá?” Ọkùnrin náà fèsì pé: “Ọ̀gá, mi ò lẹ́ni tó lè gbé mi sínú adágún omi náà tó bá ti rú, torí tí n bá ti ń lọ síbẹ̀, ẹlòmíì á ti sọ̀ kalẹ̀ ṣáájú mi.”—Jòhánù 5:6, 7.

Jésù wá sọ ohun kan tó dájú pé ó máa ya ọkùnrin yẹn àtàwọn míì lẹ́nu, ó ní: “Dìde! Gbé ẹní rẹ, kí o sì máa rìn.” (Jòhánù 5:8) Ohun tí ọkùnrin yẹn sì ṣe gẹ́lẹ́ nìyẹn. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ lara ẹ̀ yá, ó ká ẹni rẹ̀ ńlẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í rìn!

Dípò táwọn Júù tó rí iṣẹ́ ìyanu tó ṣẹlẹ̀ yẹn á fi bá ọkùnrin náà yọ̀, ṣe ni wọ́n dá a lẹ́jọ́, wọ́n sọ pé: “Sábáàtì nìyí, kò sì bófin mu fún ọ láti gbé ẹní náà.” Ọkùnrin yẹn wá dá wọn lóhùn pé: “Ẹni tó wò mí sàn náà ló sọ fún mi pé, ‘Gbé ẹní rẹ, kí o sì máa rìn.’” (Jòhánù 5:10, 11) Ṣe làwọn Júù yẹn máa ń dẹ́bi fún ẹni tó bá ṣe ìwòsàn lọ́jọ́ Sábáàtì.

Wọ́n bi ọkùnrin náà pé: “Ta lẹni tó sọ fún ọ pé, ‘Gbé e, kí o sì máa rìn’?” Kí nìdí tí wọ́n fi béèrè? Ìdí ni pé Jésù “ti wọ àárín àwọn èrò tó wà níbẹ̀,” ọkùnrin náà ò sì mọ orúkọ ẹni tó wò ó sàn. (Jòhánù 5:12, 13) Bó ti wù kó rí, ọkùnrin yẹn ṣì máa bá Jésù pàdé. Nígbà tó yá, ó rí Jésù nínú tẹ́ńpìlì, ìgbà yẹn ló wá mọ orúkọ ẹni tó wò ó sàn.

Ọkùnrin náà lọ bá àwọn Júù tó bi í léèrè ọ̀rọ̀, ó sì jẹ́ kí wọ́n mọ ẹni tó wo òun sàn. Ó sọ fún wọn pé Jésù ló wo òun sàn. Kí làwọn Júù gbọ́yẹn sí, wọ́n gbéra, ó di ọ̀dọ̀ Jésù. Ṣé torí kí wọ́n lè mọ bí Jésù ṣe ṣe iṣẹ́ ìyanu yẹn ni? Rárá. Wọ́n lọ kí wọ́n lè fẹ̀sùn kàn án pé ó ń ṣe iṣẹ́ ìyanu lọ́jọ́ Sábáàtì. Wọn ò fi mọ síbẹ̀ o, kódà wọ́n tún ṣenúnibíni sí i!