Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 24

Jésù Mú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ̀ Gbòòrò Sí I ní Gálílì

Jésù Mú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ̀ Gbòòrò Sí I ní Gálílì

MÁTÍÙ 4:23-25 MÁÀKÙ 1:35-39 LÚÙKÙ 4:42, 43

  • JÉSÙ ÀTÀWỌN ỌMỌLẸ́YÌN RẸ̀ MẸ́RIN RÌNRÌN ÀJÒ KÁÀKIRI GÁLÍLÌ

  • GBOGBO ÈÈYÀN LÓ GBỌ́ NÍPA IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ ÀTI IṢẸ́ ÌYANU TÓ ṢE

Jésù àtàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ mẹ́rin wà ní Kápánáúmù, ọwọ́ wọn sì dí gan-an. Nígbà tó di ìrọ̀lẹ́, àwọn ará Kápánáúmù bẹ̀rẹ̀ sí í mú gbogbo àwọn tó ń ṣàìsàn wá sọ́dọ̀ Jésù kó lè wò wọ́n sàn. Kódà, kò ráyè sinmi.

Kí ilẹ̀ tó mọ́ láàárọ̀ ọjọ́ kejì, Jésù dìde, ó sì jáde lọ síbi tó dá. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà sí Baba rẹ̀, àmọ́ kò pẹ́ níbẹ̀. Ìdí ni pé nígbà táwọn ọmọ ẹ̀yìn rí i pé Jésù ò sí pẹ̀lú àwọn, “Símónì àti àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀” wá a kàn. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Pétérù ló ṣíwájú wọn, torí pé ilé rẹ̀ ni Jésù wà.—Máàkù 1:36; Lúùkù 4:38.

Nígbà tí wọ́n rí Jésù, Pétérù sọ fún un pé: “Gbogbo èèyàn ti ń wá ọ.” (Máàkù 1:37) Ó dájú pé àwọn ará Kápánáúmù ò fẹ́ kí Jésù kúrò lọ́dọ̀ àwọn. Wọ́n mọyì ohun tó ṣe fún wọn, ìdí nìyẹn tí wọ́n fi gbìyànjú “láti dá a dúró kó má bàa kúrò lọ́dọ̀ wọn.” (Lúùkù 4:42) Àmọ́, ṣé torí iṣẹ́ ìyanu nìkan ni Jésù ṣe wá sáyé? Ṣé agbègbè yìí nìkan ló yẹ kó ti ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀? Kí ni Jésù wá sọ?

Jésù dá àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lóhùn pé: “Ẹ jẹ́ ká lọ síbòmíì, sí àwọn ìlú tó wà nítòsí, kí n lè wàásù níbẹ̀ náà, torí ìdí tí mo ṣe wá nìyí.” Kódà, Jésù sọ fún àwọn tí ò fẹ́ kó lọ pé: “Mo tún gbọ́dọ̀ kéde ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún àwọn ìlú míì, torí pé nítorí èyí la ṣe rán mi.”—Máàkù 1:38; Lúùkù 4:43.

Ìdí pàtàkì tí Jésù fi wá sáyé ni pé kó lè wàásù nípa Ìjọba Ọlọ́run. Ìjọba yẹn máa sọ orúkọ Baba rẹ̀ di mímọ́, á sì yanjú gbogbo ìṣòro èèyàn. Àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe jẹ́ ẹ̀rí pé Ọlọ́run ló rán an. Ní ọ̀pọ̀ ọdún ṣáájú ìgbà yẹn, Mósè náà ṣe àwọn iṣẹ́ àmì tó fi hàn pé òjíṣẹ́ Ọlọ́run ni.—Ẹ́kísódù 4:1-9, 30, 31.

Torí náà Jésù kúrò ní Kápánáúmù kó lè lọ wàásù ní àwọn ìlú míì, àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ mẹ́rin sì tẹ̀ lé e, ìyẹn Pétérù àti Áńdérù arákùnrin rẹ̀ pẹ̀lú Jòhánù àti Jémíìsì arákùnrin rẹ̀. Ó ti tó ọ̀sẹ̀ kan báyìí tí Jésù ti ní kí wọ́n di ọmọlẹ́yìn òun.

Iṣẹ́ ìwàásù tí Jésù àtàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ mẹ́rin ṣe ní Gálílì sèso rere. Kódà, ọ̀rọ̀ nípa Jésù délé dóko. Bíbélì sọ pé: “Òkìkí rẹ̀ kàn ká gbogbo Síríà” àtàwọn ìlú mẹ́wàá tí wọ́n ń pè ní Dekapólì títí dé òdì kejì Odò Jọ́dánì. (Mátíù 4:24, 25) Ọ̀pọ̀ èèyàn láti àwọn ìlú yẹn àti láti Jùdíà bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ̀ lé Jésù àtàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. Ọ̀pọ̀ ló ń mú àwọn tó ń ṣàìsàn wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Jésù ò sì já wọn kulẹ̀ torí pé gbogbo wọn ló wò sàn, ó sì mú àwọn tó ní ẹ̀mí èṣù lára dá.