ORÍ 46
Obìnrin Kan Rí Ìwòsàn Nígbà Tó Fọwọ́ Kan Aṣọ Jésù
MÁTÍÙ 9:18-22 MÁÀKÙ 5:21-34 LÚÙKÙ 8:40-48
-
OBÌNRIN KAN FỌWỌ́ KAN AṢỌ JÉSÙ, Ó SÌ RÍ ÌWÒSÀN
Nígbà tí Jésù dé láti Dekapólì, àwọn Júù tó ń gbé ní apá àríwá Òkun Gálílì gbọ́ nípa ẹ̀. Ó ṣeé ṣe kí ọ̀pọ̀ lára wọn ti gbọ́ nípa bí Jésù ṣe mú kí ìjì dáwọ́ dúró tí omi òkun sì pa rọ́rọ́. Ó tiẹ̀ ṣeé ṣe káwọn kan gbọ́ pé ó wo àwọn ọkùnrin kan tó ní ẹ̀mí èṣù sàn. Abájọ tí “èrò rẹpẹtẹ” fi pé jọ sí etíkun kí wọ́n lè kí Jésù káàbọ̀, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ ní agbègbè Kápánáúmù. (Máàkù 5:21) Bí Jésù ṣe bọ́ sílẹ̀ látinú ọkọ̀, ara àwọn èèyàn náà ti wà lọ́nà láti rí àwọn ohun tó fẹ́ ṣe.
Ọ̀kan lára àwọn tó fẹ́ rí Jésù lójú méjèèjì ni Jáírù, ìyẹn ọkùnrin kan tó jẹ́ alága sínágọ́gù tó ṣeé ṣe kó wà ní Kápánáúmù. Ó wólẹ̀ síbi ẹsẹ̀ Jésù, ó sì ń bẹ̀ ẹ́ léraléra pé: “Ọmọbìnrin mi kékeré ń ṣàìsàn gidigidi. Jọ̀ọ́, wá gbé ọwọ́ rẹ lé e kí ara rẹ̀ lè yá, kó má sì kú.” (Máàkù 5:23) Ọmọ ọdún méjìlá (12) yìí nìkan ni Jáírù ní, ó sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an. Kí ni Jésù máa ṣe bí Jáírù ṣe ń fìtara bẹ̀ ẹ́ pé kó ran ọmọ òun lọ́wọ́?—Lúùkù 8:42.
Nígbà tí Jésù ń lọ sílé Jáírù, ohun kan ṣẹlẹ̀ tó fi bó ṣe jẹ́ aláàánú hàn. Inú ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ń tẹ̀ lé Jésù ń dùn, wọ́n sì ń wò ó bóyá á ṣe iṣẹ́ ìyanu míì lójú àwọn. Àmọ́, obìnrin kan wà láàárín wọn tó jẹ́ pé torí àìsàn tó ń dà á láàmú ló ṣe wá.
Odindi ọdún méjìlá (12) ni obìnrin yìí ti ń ní ìsun ẹ̀jẹ̀. Bó ṣe ń kúrò lọ́dọ̀ dókítà kan ló ń lọ sọ́dọ̀ òmíì, ó sì ti ná gbogbo owó ẹ̀ tán sórí àìsàn náà. Síbẹ̀, pàbó ni gbogbo ẹ̀ já sí. Kódà, ṣe ni àìsàn náà ń “burú sí i.”—Máàkù 5:26.
Ẹ̀yin náà mọ̀ pé irú àìsàn yìí máa ń mú kó rẹni gan-an, ó sì máa ń dójú tini. Yàtọ̀ síyẹn, kì í rọrùn láti sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ ní gbangba. Ìyẹn nìkan kọ́ o, lábẹ́ Òfin Mósè, aláìmọ́ ni obìnrin tó bá ní ìsun ẹ̀jẹ̀. Ẹnikẹ́ni tó bá sì fọwọ́ kan obìnrin náà tàbí aṣọ rẹ̀ máa di aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.—Léfítíkù 15:25-27.
Obìnrin yìí ti gbọ́ ìròyìn nípa Jésù, torí náà ó wá a kàn. Torí pé àìsàn yìí máa ń sọni di aláìmọ́, ṣe ló rọra ń gba àárín àwọn èèyàn kọjá kí wọ́n má bàa fura sí i. Ó ń sọ fún ara ẹ̀ pé: “Tí mo bá fọwọ́ kan aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀ lásán, ara mi á yá.” Bó ṣe fọwọ́ kan etí aṣọ Jésù báyìí ni ìsun ẹ̀jẹ̀ náà dáwọ́ dúró! Lóòótọ́, ‘àìsàn burúkú tó ń ṣe é ti lọ.’—Máàkù 5:27-29.
Jésù wá sọ pé: “Ta ló fọwọ́ kàn mí?” Kí lẹ rò pé obìnrin náà á máa rò nígbà tó gbọ́ ohun tí Jésù sọ yìí? Ó jọ pé Pétérù bá Jésù wí nígbà tó sọ pé: “Àwọn èrò ń há ọ mọ́, wọ́n sì ń fún mọ́ ọ.” Kí ló wá dé tí Jésù fi béèrè pé, “Ta ló fọwọ́ kàn mí?” Jésù sọ pé: “Ẹnì kan fọwọ́ kàn mí, torí mo mọ̀ pé agbára jáde lára mi.” (Lúùkù 8:45, 46) Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí túbọ̀ jẹ́ ká rí bí agbára Jésù ṣe pọ̀ tó.
Nígbà tí obìnrin náà rí i pé òun ò mú un jẹ, ẹ̀rù bà á, jìnnìjìnnì sì bò ó, ó wá wólẹ̀ síbi ẹsẹ̀ Jésù. Ìṣojú àwọn èèyàn tó wà níbẹ̀ ló ti sọ gbogbo ohun tí àìsàn náà ti fojú ẹ̀ rí, ó sì sọ fún wọn pé òun ti rí ìwòsàn. Jésù wá fi í lọ́kàn balẹ̀, ó ní: “Ọmọbìnrin, ìgbàgbọ́ rẹ ti mú ọ lára dá. Máa lọ ní àlàáfíà, kí àìsàn burúkú tó ń ṣe ọ́ sì lọ.”—Máàkù 5:34.
Ó ṣe kedere pé ẹni tó nífẹ̀ẹ́ tó sì ń gba tẹni rò ni Jèhófà yàn pé kó ṣàkóso ayé yìí. Kì í ṣe pé ó máa ń ṣàánú àwọn èèyàn nìkan ni, ó tún lágbára láti ràn wọ́n lọ́wọ́!