Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

APÁ 5

Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Tí Jésù Pa Dà Ṣe ní Ìlà Oòrùn Jọ́dánì

“Ọ̀pọ̀ èèyàn sì gbà á gbọ́.”—Jòhánù 10:42

Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Tí Jésù Pa Dà Ṣe ní Ìlà Oòrùn Jọ́dánì

NÍ APÁ YÌÍ

ORÍ 82

Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Jésù ní Pèríà

Jésù ń ṣàlàyé ohun tó yẹ kéèyàn ṣe tó bá fẹ́ rí ìgbàlà fáwọn olùgbọ́ rẹ̀. Ìmọ̀ràn yẹn wúlò gan-an nígbà yẹn. Ṣé ìmọ̀ràn náà ṣì wúlò lónìí?

ORÍ 83

Àwọn Tí Ọlọ́run Pè Síbi Àsè Kan

Nígbà tí Jésù ń jẹun nílé Farisí kan, ó sọ àpèjúwe nípa àsè oúnjẹ alẹ́ kan. Gbogbo àwa èèyàn Ọlọ́run la lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ nínú àpèjúwe náà. Kí ni ẹ̀kọ́ náà?

ORÍ 84

Iṣẹ́ Kékeré Kọ́ Lẹnì Kan Máa Ṣe Kó Tó Lè Di Ọmọ Ẹ̀yìn

Ohun kékeré kọ́ ló máa ná ẹni tó bá fẹ́ di ọmọ ẹ̀yìn Kristi. Jésù sọ ohun tí ìyẹn máa gbà. Ó ṣeé ṣe kí ohun tó sọ ya àwọn tó fẹ́ di ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lẹ́nu.

ORÍ 85

Àwọn Áńgẹ́lì Máa Ń Yọ̀ Tí Ẹlẹ́ṣẹ̀ Kan Bá Ronú Pìwà Dà

Àwọn Farisí àtàwọn akọ̀wé Òfin ń rí sí Jésù torí pé ó wà lọ́dọ̀ àwọn tí wọn ò kà sí. Jésù fi àpèjúwe méjì dá wọn lóhùn kí wọ́n lè rí bí ọ̀rọ̀ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ṣe máa ń rí lára Ọlọ́run.

ORÍ 86

Ọmọ Tó Sọ Nù Pa Dà Wálé

Kí la rí kọ́ látinú àpèjúwe ọmọ onínàákúnàá?

ORÍ 87

Múra Sílẹ̀, Kó O sì Jẹ́ Ọlọ́gbọ́n

Jésù lo àpèjúwe ìríjú kan tó jẹ́ ọlọ́gbọ́n ẹ̀wẹ́ àti aláìṣòótọ́ láti kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà tó yani lẹ́nu.

ORÍ 88

Nǹkan Yí Pa Dà fún Ọkùnrin Ọlọ́rọ̀ Kan àti Lásárù

A máa lóye àpèjúwe Jésù yìí tá a bá mọ àwọn méjì tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa wọn nínú àpèjúwe náà.

ORÍ 89

Ó Ń Kọ́ni ní Pèríà Bó Ṣe Ń Lọ sí Jùdíà

Jésù tẹnu mọ́ ànímọ́ kan tó máa ràn wá lọ́wọ́ láti máa dárí ji àwọn míì títí kan àwọn tó bá ṣẹ̀ wá léraléra.

ORÍ 90

“Àjíǹde àti Ìyè”

Kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé àwọn tó bá nígbàgbọ́ nínú òun “kò ní kú láé”?

ORÍ 91

Jésù Jí Lásárù Dìde

Ohun méjì tó ṣàrà ọ̀tọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ni ò jẹ́ káwọn tó ń ta ko Jésù sẹ́ pé iṣẹ́ ìyanu náà ṣẹlẹ̀.

ORÍ 92

Jésù Wo Adẹ́tẹ̀ Mẹ́wàá Sàn, Ọ̀kan Pa Dà Wá Dúpẹ́

Kì í ṣe Jésù nìkan ni ọkùnrin adẹ́tẹ̀ náà dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀, ó tún dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹlòmíì.

ORÍ 93

Ọlọ́run Máa Ṣí Ọmọ Èèyàn Payá

Báwo ni Jésù ṣe máa pa dà wá bí ìgbà tí mànàmáná bá kọ lójú ọ̀run?

ORÍ 94

Ohun Méjì Tó Ṣe Pàtàkì—Àdúrà àti Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀

Nínú àpèjúwe kan tí Jésù sọ nípa adájọ́ tó burú àti opó kan, Jésù jẹ́ ká rí bí ànímọ́ kan ṣe ṣe pàtàkì tó.

ORÍ 95

Jésù Sọ̀rọ̀ Nípa Ìkọ̀sílẹ̀, Ó sì Fìfẹ́ Hàn Sáwọn Ọmọdé

Ojú tí Jésù fi ń wo àwọn ọmọdé yàtọ̀ pátápátá sí ojú táwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ fi ń wò wọ́n. Kí nìdí?

ORÍ 96

Jésù Dáhùn Ìbéèrè Ọ̀dọ́kùnrin Ọlọ́rọ̀ Kan

Kí ló mú kí Jésù sọ pé ó máa rọrùn fún ràkúnmí láti gba ojú abẹ́rẹ́ kọjá ju fún ọlọ́rọ̀ láti wọ Ìjọba Ọlọ́run?

ORÍ 97

Àpèjúwe Àwọn Òṣìṣẹ́ Ọgbà Àjàrà

Báwo làwọn ẹni àkọ́kọ́ ṣe máa di ẹni ìkẹyìn, tí àwọn ẹni ìkẹyìn sì máa di ẹni àkọ́kọ́?

ORÍ 98

Àwọn Àpọ́sítélì Tún Ń Wá Ipò Ọlá

Jémíìsì àti Jòhánù ń bẹ̀bẹ̀ fún ipò ńlá nínú Ìjọba Kristi, àmọ́ àwọn nìkan kọ́ ló fẹ́ ẹ.

ORÍ 99

Jésù La Ojú Àwọn Afọ́jú, Ó sì Ran Sákéù Lọ́wọ́

Báwo la ṣe lè ṣàlàyé ìtàn tó wà nínú Bíbélì nípa bí Jésù ṣe la ojú ọkùnrin afọ́jú kan nítòsí Jẹ́ríkò, tó bá tiẹ̀ dà bíi pé ìtàn náà ta kora?

ORÍ 100

Àpèjúwe Mínà Mẹ́wàá

Kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé: “Gbogbo ẹni tó bá ní, a máa fi kún èyí tó ní, àmọ́ ẹni tí kò bá ní, a máa gba èyí tó ní pàápàá lọ́wọ́ rẹ̀”?