Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 86

Ọmọ Tó Sọ Nù Pa Dà Wálé

Ọmọ Tó Sọ Nù Pa Dà Wálé

LÚÙKÙ 15:11-32

  • ÀPÈJÚWE ỌMỌ TÓ SỌ NÙ

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Pèríà tó wà ní apá ìlà oòrùn Odò Jọ́dánì ni Jésù ṣì wà nígbà tó sọ àpèjúwe nípa àgùntàn tó sọ nù àti owó dírákímà tó sọ nù. Ohun tí àpèjúwe méjèèjì kọ́ wa ni pé ó yẹ kínú wa máa dùn nígbà tí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan bá ronú pìwà dà, tó sì pa dà sọ́dọ̀ Ọlọ́run. Àwọn Farisí àtàwọn akọ̀wé òfin ti ń rí sí Jésù torí pé ó ń kó irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ mọ́ra. Àmọ́ ṣé àwọn tó ń rí sí Jésù rí ẹ̀kọ́ kankan kọ́ látinú àpèjúwe méjì tí Jésù ṣe yẹn? Ṣé wọ́n lóye bó ṣe máa ń rí lára Baba wa ọ̀run tí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan bá ronú pìwà dà? Jésù tún wá lo àpèjúwe míì tó wọni lọ́kàn láti túbọ̀ tẹnu mọ́ ẹ̀kọ́ pàtàkì yìí.

Bàbá kan àtàwọn ọmọkùnrin rẹ̀ méjì ni Jésù sọ̀rọ̀ nípa wọn, èyí àbúrò ni àpèjúwe náà sì dá lé. Ó yẹ káwọn Farisí àtàwọn akọ̀wé òfin títí kan àwọn míì tó ń gbọ́rọ̀ Jésù rí ẹ̀kọ́ kọ́ látinú ohun tí ọmọ náà ṣe. Àmọ́ ó tún yẹ kí wọ́n ronú lórí ohun tí bàbá àti ẹ̀gbọ́n ọmọ náà ṣe, torí pé a lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ lára àwọn náà. Torí náà, máa ronú nípa ohun táwọn ọkùnrin mẹ́ta yìí ṣe bí Jésù ṣe ń sọ àpèjúwe náà:

Jésù sọ pé: “Ọkùnrin kan ní ọmọkùnrin méjì. Èyí àbúrò sọ fún bàbá rẹ̀ pé, ‘Bàbá, fún mi ní ìpín tó yẹ kó jẹ́ tèmi nínú ohun ìní rẹ.’ Ó wá pín àwọn ohun ìní rẹ̀ fún wọn.” (Lúùkù 15:11, 12) Ẹ kíyè sí i pé kì í ṣe torí pé bàbá wọn ti kú ni ọmọ náà ṣe fẹ́ gba ìpín tiẹ̀. Bàbá wọn ṣì wà láàyè. Àmọ́ ọmọ yìí fẹ́ gba ìpín tiẹ̀ báyìí kó lè ná an bó ṣe wù ú. Kí ló fẹ́ fi ṣe?

Jésù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Lẹ́yìn ọjọ́ mélòó kan, èyí àbúrò kó gbogbo ohun tó jẹ́ tirẹ̀ jọ, ó sì rìnrìn àjò lọ sí ilẹ̀ tó jìnnà gan-an, ibẹ̀ ló ti ń gbé ìgbésí ayé oníwà pálapàla, tó sì lo àwọn ohun ìní rẹ̀ nílòkulò.” (Lúùkù 15:13) Dípò kí ọmọ yẹn máa gbé lọ́dọ̀ bàbá rẹ̀, kí bàbá rẹ̀ lè máa bójú tó o, kó sì máa pèsè ohun tó nílò fún un, ṣe ló yàn láti lọ máa gbé níbòmíì. Ó ná gbogbo ohun tó ní ní ìná àpà, ó sì ń ṣe ìṣekúṣe. Nígbà tó yá, nǹkan nira fún un, Jésù sọ pé:

“Nígbà tó ti ná gbogbo rẹ̀ tán, ìyàn mú gan-an ní gbogbo ilẹ̀ yẹn, ó sì di aláìní. Ó tiẹ̀ lọ fi ara rẹ̀ sọ́dọ̀ ọ̀kan nínú àwọn aráàlú yẹn, ẹni yẹn sì rán an lọ sínú àwọn pápá rẹ̀ pé kó máa tọ́jú àwọn ẹlẹ́dẹ̀. Ó sì máa ń wù ú kó jẹ èèpo èso kárọ́ọ̀bù tí àwọn ẹlẹ́dẹ̀ ń jẹ, àmọ́ ẹnì kankan kì í fún un ní ohunkóhun.”—Lúùkù 15:14-16.

Ohun àìmọ́ ni Òfin Ọlọ́run ka ẹlẹ́dẹ̀ sí, síbẹ̀ àwọn ẹlẹ́dẹ̀ yẹn ni ọmọ yìí ní láti máa tọ́jú. Ebi ti fojú ẹ̀ rí màbo débi pé oúnjẹ táwọn ẹlẹ́dẹ̀ ń jẹ ló wá ń wù ú jẹ. Nígbà tí gbogbo nǹkan wá dojú rú fún un, tí ìdààmú náà pọ̀ lápọ̀jù, ó pe ‘orí ara ẹ̀ wálé.’ Kí ló wá ṣe? Ó sọ lọ́kàn ara ẹ̀ pé: “Àìmọye àwọn alágbàṣe bàbá mi ló ní oúnjẹ ní àníṣẹ́kù, ebi wá ń pa èmi kú lọ níbí! Jẹ́ kí n kúkú dìde, kí n rìnrìn àjò lọ sọ́dọ̀ bàbá mi, kí n sì sọ fún un pé: ‘Bàbá, mo ti ṣẹ̀ sí ọ̀run, mo sì ti ṣẹ̀ ọ́. Mi ò yẹ lẹ́ni tí o lè pè ní ọmọ rẹ mọ́. Jẹ́ kí n dà bí ọ̀kan lára àwọn alágbàṣe rẹ.’” Lẹ́yìn náà, ó pa dà sọ́dọ̀ bàbá rẹ̀.—Lúùkù 15:17-20.

Kí ni bàbá ẹ̀ máa ṣe tó bá rí i? Ṣé ó máa bínú sí i ni, táá sì sọ̀rọ̀ burúkú sí i torí pé ó filé sílẹ̀? Àbí ṣe láá kàn máa wò ó bíi pé òun ò tiẹ̀ mọ̀ ọ́n rí? Tó bá jẹ́ ìwọ ni, kí lo máa ṣe? Kí lo máa ṣe ká sọ pé ọmọ rẹ̀ ló ṣe bẹ́ẹ̀?

ỌMỌ TÓ SỌ NÙ PA DÀ WÁLÉ

Jésù sọ bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára bàbá yẹn àtohun tó ṣe nígbà tó rí ọmọ ẹ̀, ó ní: “[Bí ọmọ náà] ṣe ń bọ̀ ní òkèèrè ni bàbá rẹ̀ tajú kán rí i, àánú rẹ̀ ṣe é, ó wá sáré lọ dì mọ́ ọn, ó sì rọra fi ẹnu kò ó lẹ́nu.” (Lúùkù 15:20) Ká tiẹ̀ ní bàbá yẹn ti gbọ́ gbogbo ohun tọ́mọ ẹ̀ ṣe níbi tó lọ, kò fi hùwà sí i, kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ló kí i káàbọ̀. Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù ń sọ pé àwọn mọ Ọlọ́run àti pé àwọn ń sìn ín, àmọ́ ṣé àpèjúwe yìí máa jẹ́ kí wọ́n mọ bó ṣe máa ń rí lára Ọlọ́run táwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ bá ronú pìwà dà? Ṣé wọ́n máa lóye pé ohun kan náà ni Jésù ń ṣe?

Ó ṣeé ṣe kí bàbá yẹn ti rí i lójú ọmọ rẹ̀ pé ó ti ronú pìwà dà. Torí náà, bó ṣe lọ pàdé ọmọ ẹ̀ tó sì gbá a mọ́ra jẹ́ kọ́ rọrùn fún ọmọ náà láti jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀. Jésù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó ní: “Ọmọkùnrin náà wá sọ fún un pé, ‘Bàbá, mo ti ṣẹ̀ sí ọ̀run, mo sì ti ṣẹ̀ ọ́. Mi ò yẹ lẹ́ni tí o lè pè ní ọmọ rẹ mọ́.’”—Lúùkù 15:21.

Bàbá yẹn wá sọ fáwọn ẹrú rẹ̀ pé: “Ó yá! ẹ mú aṣọ wá, aṣọ tó dáa jù, kí ẹ wọ̀ ọ́ fún un, kí ẹ fi òrùka sí i lọ́wọ́, kí ẹ sì wọ bàtà sí i lẹ́sẹ̀. Kí ẹ tún mú ọmọ màlúù tó sanra wá, kí ẹ dúńbú rẹ̀, ká jọ jẹun, ká sì yọ̀, torí pé ọmọ mi yìí kú, àmọ́ ó ti pa dà wà láàyè; ó sọ nù, a sì rí i.” Ni gbogbo wọn bá bẹ̀rẹ̀ sí í “gbádùn ara wọn.”—Lúùkù 15:22-24.

Ní gbogbo àsìkò yẹn, ẹ̀gbọ́n ọmọ náà wà lóko. Jésù wá sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ pé: “Bó . . . ṣe dé, tó sún mọ́ ilé, ó gbọ́ orin àti ijó. Torí náà, ó pe ọ̀kan nínú àwọn ìránṣẹ́ sọ́dọ̀, ó sì béèrè ohun tó ń ṣẹlẹ̀. Ìránṣẹ́ náà sọ fún un pé, ‘Àbúrò rẹ ti dé, bàbá rẹ sì dúńbú ọmọ màlúù tó sanra torí ó pa dà rí i ní àlàáfíà.’ Àmọ́ inú bí i, kò sì wọlé. Bàbá rẹ̀ wá jáde, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ̀ ẹ́. Ó sọ fún bàbá rẹ̀ pé, ‘Wò ó! Ọ̀pọ̀ ọdún yìí ni mo ti ń sìn ọ́, mi ò tàpá sí àṣẹ rẹ rí, síbẹ̀, o ò fún mi ní ọmọ ewúrẹ́ kan rí kí èmi àti àwọn ọ̀rẹ́ mi lè fi gbádùn ara wa. Àmọ́ gbàrà tí ọmọ rẹ yìí dé, ẹni tó lo àwọn ohun ìní rẹ nílòkulò pẹ̀lú àwọn aṣẹ́wó, o dúńbú ọmọ màlúù tó sanra fún un.’”—Lúùkù 15:25-30.

Àwọn wo ló ń ṣe bíi ti ẹ̀gbọ́n ọmọ yìí, tí wọ́n ń ṣàríwísí Jésù torí pé ó ń fàánú hàn sáwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tó sì tún ń gba tàwọn èèyàn rò? Àwọn akọ̀wé òfin àtàwọn Farisí ni. Torí pé wọ́n ń ṣàríwísí Jésù ni Jésù fi sọ àpèjúwe yìí. Torí náà, ó yẹ kí ẹnikẹ́ni tó bá ń bínú pé Ọlọ́run ń fàánú hàn sáwọn èèyàn ronú jinlẹ̀ nípa ẹ̀kọ́ tó wà nínú àpèjúwe yìí.

Ohun tí bàbá yẹn sọ láti bẹ ọmọ rẹ̀ àgbà ni Jésù fi parí àpèjúwe yìí, bàbá náà sọ pé: “Ọmọ mi, ìgbà gbogbo lo wà lọ́dọ̀ mi, ìwọ lo sì ni gbogbo ohun tó jẹ́ tèmi. Àmọ́ ó yẹ ká yọ̀, kí inú wa sì dùn, torí pé arákùnrin rẹ kú, àmọ́ ó ti wà láàyè; ó sọ nù, a sì rí i.”—Lúùkù 15:31, 32.

Jésù ò sọ ohun tí ẹ̀gbọ́n yẹn ṣe lẹ́yìn ìyẹn. Àmọ́ lẹ́yìn tí Jésù kú, tó sì jíǹde, “ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àlùfáà . . . bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ́wọ́ gba ìgbàgbọ́ náà.” (Ìṣe 6:7) Ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn tó wà níbẹ̀ nígbà tí Jésù sọ àpèjúwe ọmọ tó sọ nù yìí wà lára wọn. Bóyá àwọn náà pe orí ara wọn wálé, tí wọ́n ronú pìwà dà, tí wọ́n sì pa dà sọ́dọ̀ Ọlọ́run.

Àtìgbà yẹn ló yẹ káwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ti máa fi ẹ̀kọ́ tí wọ́n kọ́ látinú àpèjúwe yìí sọ́kàn. Ohun àkọ́kọ́ tí àpèjúwe yẹn kọ́ wa ni pé ó bọ́gbọ́n mu ká dúró síbi ààbò láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run, níbi tí Baba tó nífẹ̀ẹ́ wa á ti máa tọ́jú wa, táá sì máa fún wa láwọn ohun tá a nílò, dípò ká sọ pé a fẹ́ kọ́kọ́ jayé orí wa ná.

Ẹ̀kọ́ míì ni pé tí ẹnikẹ́ni nínú wa bá kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà, ó yẹ kẹ́ni náà lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, kó lè pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà, kó sì rí ojúure rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i.

A tún lè rí ẹ̀kọ́ pàtàkì míì kọ́ látinú bí bàbá yẹn ṣe dárí ji ọmọ rẹ̀ àmọ́ tí ẹ̀gbọ́n ẹ̀ ṣe ohun tó yàtọ̀ síyẹn. Ó dájú pé ó yẹ kí àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run máa dárí ji ẹni tó ronú pìwà dà lẹ́yìn tó ti ṣáko lọ, tó sì pa dà wá sí ‘ilé Baba rẹ̀.’ Ẹ jẹ́ kínú wa máa dùn láti gba àwọn ará wa tí wọ́n bá ronú pìwà dà, torí ṣe ló dà bíi pé wọ́n ‘kú, àmọ́ tí wọ́n pa dà wà láàyè,’ wọ́n ‘sọ nù, a sì rí wọn.’