Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 94

Ohun Méjì Tó Ṣe Pàtàkì—Àdúrà àti Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀

Ohun Méjì Tó Ṣe Pàtàkì—Àdúrà àti Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀

LÚÙKÙ 18:1-14

  • ÀPÈJÚWE OPÓ TÍ KÒ JUWỌ́ SÍLẸ̀

  • FARISÍ ÀTI AGBOWÓ ORÍ

Jésù ti sọ àpèjúwe kan fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ kí wọ́n lè rí i pé kò yẹ kí wọ́n juwọ́ sílẹ̀ láti máa gbàdúrà. (Lúùkù 11:5-13) Ní báyìí tó ṣeé ṣe kó wà ní Samáríà tàbí Gálílì, ó tún sọ̀rọ̀ nípa ìdí tó fi yẹ kí wọ́n tẹra mọ́ àdúrà. Ó wá lo àpèjúwe míì láti ṣàlàyé.

Ó ní: “Ní ìlú kan, adájọ́ kan wà tí kò bẹ̀rù Ọlọ́run, tí kò sì ka àwọn èèyàn sí. Opó kan wà ní ìlú yẹn tó máa ń lọ sọ́dọ̀ adájọ́ náà ṣáá, ó máa ń sọ pé, ‘Rí i dájú pé o dá ẹjọ́ bó ṣe tọ́ láàárín èmi àti ẹni tó ń bá mi ṣẹjọ́.’ Adájọ́ náà ò kọ́kọ́ fẹ́ gbà, àmọ́ nígbà tó yá, ó sọ fún ara rẹ̀ pé, ‘Bí mi ò tiẹ̀ bẹ̀rù Ọlọ́run, tí mi ò sì ka èèyàn kankan sí, torí pé opó yìí ò yéé yọ mí lẹ́nu, màá rí i dájú pé a dá ẹjọ́ rẹ̀ bó ṣe tọ́, kó má bàa máa pa dà wá ṣáá, kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ má bàa sú mi torí ohun tó ń béèrè.’”—Lúùkù 18:2-5.

Kí àpèjúwe yẹn lè yé wọn, Jésù sọ pé: “Ẹ gbọ́ ohun tí adájọ́ náà sọ, bó tiẹ̀ jẹ́ pé aláìṣòdodo ni! Ṣé kò wá dájú pé Ọlọ́run máa mú kí a dájọ́ bó ṣe tọ́ fún àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ tí wọ́n ń ké pè é tọ̀sántòru, bó ṣe ń ní sùúrù fún wọn?” (Lúùkù 18:6, 7) Nínú àpèjúwe yìí, kí ni Jésù fẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ nípa Baba rẹ̀?

Jésù ò fi Jèhófà wé adájọ́ aláìṣòdodo yẹn. Ohun tó ń sọ ni pé tí èèyàn tó jẹ́ aláìṣòdodo bá lè ṣe ohun tẹ́nì kan fẹ́ torí pé ẹni náà ń wá sọ́dọ̀ rẹ̀ léraléra, ó dájú pé Ọlọ́run máa ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ. Olódodo ni, torí náà ó máa ṣe ohun táwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ń béèrè tí wọn ò bá jẹ́ kó sú wọn láti máa gbàdúrà. Ohun tí Jésù sọ tẹ̀ lé e jẹ́ ká rí i pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yẹn, ó sọ pé: “Mò ń sọ fún yín, [Ọlọ́run] máa mú kí a dá ẹjọ́ wọn bó ṣe tọ́ kíákíá.”—Lúùkù 18:8.

Àwọn èèyàn kì í sábà ṣojúure sáwọn ẹni rírẹlẹ̀ àtàwọn tálákà, bẹ́ẹ̀ sì rèé ojú ẹni iyì ni wọ́n fi ń wo àwọn olówó àtàwọn èèyàn jàǹkàn-jàǹkàn. Àmọ́ kì í ṣe bí Ọlọ́run ṣe ń wo àwa èèyàn nìyẹn. Nígbà tí àkókò bá tó lójú rẹ̀, ó máa fìyà jẹ àwọn èèyàn burúkú, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì máa rí ìyè àìnípẹ̀kun.

Àwọn wo ló nírú ìgbàgbọ́ tí obìnrin opó yẹn ní? Èèyàn mélòó ló gbà lóòótọ́ pé Ọlọ́run ‘máa mú kí a dá ẹjọ́ òun bó ṣe tọ́ kíákíá’? Jésù ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ àpèjúwe kan nípa ìdí tó fi yẹ kí wọ́n tẹra mọ́ àdúrà ni. Ó wá bi wọ́n pé: “Tí Ọmọ èèyàn bá dé, ṣé ó máa bá ìgbàgbọ́ yìí ní ayé lóòótọ́?” (Lúùkù 18:8) Ohun tó sọ yìí fi hàn pé nígbà tí Kristi bá dé, àwọn èèyàn ò ní gbà pé àdúrà ṣì lágbára.

Àwọn kan wà níbi tí Jésù ti ń sọ̀rọ̀ yìí tí wọ́n gbà pé àwọn nígbàgbọ́. Wọ́n dára wọn lójú jù, wọ́n sì gbà pé olódodo làwọn, síbẹ̀ wọ́n máa ń fojú pa àwọn míì rẹ́. Torí náà, Jésù sọ àpèjúwe míì.

Ó ní: “Ọkùnrin méjì gòkè lọ sínú tẹ́ńpìlì láti gbàdúrà, ọ̀kan jẹ́ Farisí, ìkejì sì jẹ́ agbowó orí. Farisí náà dúró, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà, ó ń dá sọ àwọn nǹkan yìí pé, ‘Ọlọ́run, mo dúpẹ́ pé mi ò dà bíi gbogbo àwọn èèyàn yòókù, àwọn tó ń fipá gba tọwọ́ àwọn èèyàn, àwọn aláìṣòdodo, àwọn alágbèrè, kódà mi ò dà bí agbowó orí yìí. Ẹ̀ẹ̀mejì lọ́sẹ̀ ni mò ń gbààwẹ̀; mò ń san ìdá mẹ́wàá gbogbo ohun tí mo ní.’”—Lúùkù 18:10-12.

Àwọn Farisí máa ń ṣe àṣehàn, wọ́n sì máa ń fẹ́ káwọn èèyàn kà wọ́n sí olódodo. Wọ́n sábà máa ń gbààwẹ̀ lọ́jọ́ Monday àti Thursday káwọn èèyàn lè rí wọn, torí ọjọ́ yẹn làwọn ọjà ńlá máa ń kún fọ́fọ́. Kódà, wọ́n tún máa ń san ìdá mẹ́wàá lórí àwọn ewébẹ̀ kéékèèké. (Lúùkù 11:42) Ní oṣù mélòó kan ṣáájú ìgbà yẹn, wọ́n fi hàn pé àwọn ò ka àwọn èèyàn sí, wọ́n sọ pé: “[Lójú àwọn Farisí] ẹni ègún ni àwọn èèyàn yìí tí wọn ò mọ Òfin.”—Jòhánù 7:49.

Jésù wá ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó ní: “Àmọ́ agbowó orí náà dúró ní ọ̀ọ́kán, kò fẹ́ gbé ojú rẹ̀ sókè láti wo ọ̀run pàápàá, ṣùgbọ́n ó ń lu àyà rẹ̀ ṣáá, ó ń sọ pé, ‘Ọlọ́run, ṣàánú mi, ẹlẹ́ṣẹ̀ ni mí.’” Ṣe ni agbowó orí yẹn fìrẹ̀lẹ̀ gbà pé ẹlẹ́ṣẹ̀ lòun. Jésù wá sọ pé: “Mo sọ fún yín, ọkùnrin yìí sọ̀ kalẹ̀ lọ sílé rẹ̀, a sì kà á sí olódodo ju Farisí yẹn lọ. Torí pé gbogbo ẹni tó bá gbé ara rẹ̀ ga, a máa rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀, àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, a máa gbé e ga.”—Lúùkù 18:13, 14.

Ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ ká rí i pé ó yẹ kéèyàn lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. Ìmọ̀ràn yẹn wúlò fáwọn ọmọ ẹ̀yìn torí pé àtikékeré ni wọ́n ti ń rí àwọn Farisí yìí, tí wọ́n ka ara wọn sí olódodo, tó sì jẹ́ pé bí wọ́n ṣe máa gbayì lójú àwọn èèyàn ni wọ́n ń wá. Ìmọ̀ràn yẹn wúlò fún gbogbo àwa ọmọlẹ́yìn Jésù lónìí.