ORÍ 95
Jésù Sọ̀rọ̀ Nípa Ìkọ̀sílẹ̀, Ó sì Fìfẹ́ Hàn Sáwọn Ọmọdé
MÁTÍÙ 19:1-15 MÁÀKÙ 10:1-16 LÚÙKÙ 18:15-17
-
JÉSÙ KỌ́ ÀWỌN ÈÈYÀN NÍPA OJÚ TÍ ỌLỌ́RUN FI Ń WO ÌKỌ̀SÍLẸ̀
-
Ẹ̀BÙN WÍWÀ LÁÌLỌ́KỌ TÀBÍ LÁÌLÁYA
-
ÌDÍ TÓ FI YẸ KÉÈYÀN DÀ BÍ ỌMỌDÉ
Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ kúrò ní Gálílì, wọ́n wá sọdá Odò Jọ́dánì, wọ́n sì gba agbègbè Pèríà kọjá lọ sí apá gúúsù. Nígbà tí Jésù wá sí Pèríà gbẹ̀yìn, ó jẹ́ káwọn Farisí mọ ohun tí Ọlọ́run sọ nípa ìkọ̀sílẹ̀. (Lúùkù 16:18) Ní báyìí, wọ́n tún béèrè ọ̀rọ̀ yẹn lọ́wọ́ Jésù kí wọ́n lè dán an wò.
Òfin Mósè sọ pé ọkùnrin kan lè kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ tó bá ṣe “ohun kan tí kò dáa.” (Diutarónómì 24:1) Èrò wọn lórí ọ̀rọ̀ yẹn sì yàtọ̀ síra. Kódà, àwọn kan gbà pé ọ̀rọ̀ tí ò tó nǹkan lè mú kí ọkùnrin kan kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀. Torí náà, àwọn Farisí béèrè pé: “Ṣé ó bófin mu fún ọkùnrin láti kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ lórí gbogbo ẹ̀sùn?”—Mátíù 19:3.
Dípò tí Jésù á fi máa bá wọn jiyàn, ṣe ló tọ́ka sí ìlànà tí Ọlọ́run fi lelẹ̀ nígbà tó dá ìgbéyàwó sílẹ̀. Ó ní: “Ṣé ẹ ò kà á pé ẹni tó dá wọn ní ìbẹ̀rẹ̀ dá wọn ní akọ àti abo, ó sì sọ pé, ‘Torí èyí, ọkùnrin á fi bàbá rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, á sì fà mọ́ ìyàwó rẹ̀, àwọn méjèèjì á sì di ara kan’? Tó fi jẹ́ pé wọn kì í ṣe méjì mọ́, àmọ́ wọ́n jẹ́ ara kan. Torí náà, ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí èèyàn kankan má ṣe yà á.” (Mátíù 19:4-6) Èyí fi hàn pé nígbà tí Ọlọ́run dá Ádámù àti Éfà, ohun tó fẹ́ ni pé kí wọ́n jọ wà pa pọ̀ títí láé. Ọlọ́run ò ṣètò pé kí wọ́n kọ ara wọn sílẹ̀.
Ohun tí Jésù sọ yìí ò tẹ́ àwọn Farisí lọ́rùn, ni wọ́n bá tún sọ pé: “Kí ló wá dé tí Mósè fi sọ pé ká fún un ní ìwé ẹ̀rí láti lé e lọ, ká sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀?” (Mátíù 19:7) Jésù dá wọn lóhùn pé: “Torí pé ọkàn yín le ni Mósè ṣe yọ̀ǹda fún yín láti kọ ìyàwó yín sílẹ̀, àmọ́ kò rí bẹ́ẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀.” (Mátíù 19:8) Ìgbà tí Ọlọ́run dá ìgbéyàwó sílẹ̀ nínú ọgbà Édẹ́nì ni “ìbẹ̀rẹ̀” tí Jésù ń sọ yìí, kì í ṣe ìgbà ayé Mósè.
Jésù wá sọ òótọ́ ọ̀rọ̀ kan fún wọn, ó ní: “Mò ń sọ fún yín pé ẹnikẹ́ni tó bá kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀, àfi tó bá jẹ́ torí ìṣekúṣe [por·neiʹa lédè Gíríìkì], tó sì fẹ́ ẹlòmíì ti ṣe àgbèrè.” (Mátíù 19:9) Èyí fi hàn pé ìṣekúṣe nìkan ni Ìwé Mímọ́ sọ pé ó lè mú kí ẹnì kan kọ ọkọ tàbí ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀.
Ọ̀rọ̀ Jésù yẹn mú káwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ sọ pé: “Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ ọkùnrin àti ìyàwó rẹ̀ rí, ó sàn kéèyàn má tiẹ̀ níyàwó.” (Mátíù 19:10) Ó dájú pé ọkùnrin àti obìnrin tó bá ń ronú àtiṣe ìgbéyàwó gbọ́dọ̀ gbà pé títí láé làwọn á fi wà pa pọ̀!
Jésù wá sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó wà láìlọ́kọ tàbí láìláya, ó ṣàlàyé pé a bí àwọn kan ní ìwẹ̀fà, ìyẹn ni pé wọn ò lè ní ìbálòpọ̀. Ṣe ni wọ́n sì sọ àwọn míì di ìwẹ̀fà kí wọ́n má bàa lè ní ìbálòpọ̀. Síbẹ̀ àwọn kan pa ìfẹ́ láti ní ìbálòpọ̀ mọ́ra. Ìdí tí wọ́n sì fi ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé wọ́n fẹ́ gbájú mọ́ ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run. Jésù wá sọ pé: “Kí ẹni tó bá lè wá àyè fún un [láti wà láìlọ́kọ tàbí láìláya] wá àyè fún un.”—Mátíù 19:12.
Lẹ́yìn náà, àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í mú àwọn ọmọ wọn kéékèèké lọ sọ́dọ̀ Jésù. Àmọ́, àwọn ọmọ ẹ̀yìn ń bá wọn wí, bóyá torí kí wọ́n má bàa da Jésù láàmú. Ohun tí wọ́n ṣe yẹn múnú bí Jésù, torí náà ó sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọdé wá sọ́dọ̀ mi; ẹ má sì dá wọn dúró, torí Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ ti irú wọn. Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ó dájú pé ẹnikẹ́ni tí kò bá gba Ìjọba Ọlọ́run bí ọmọdé kò ní wọnú rẹ̀.”—Máàkù 10:14, 15; Lúùkù 18:15.
Ẹ ò rí i pé ẹ̀kọ́ pàtàkì nìyẹn! Tá a bá fẹ́ wà nínú Ìjọba Ọlọ́run, a gbọ́dọ̀ lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, ká sì jẹ́ ẹni tó rọrùn kọ́ bíi tàwọn ọmọdé. Jésù wá fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ yẹn nígbà tó gbé wọn mọ́ra tó sì súre fún wọn. Irú ìfẹ́ yẹn náà ló ní sí gbogbo àwọn tó “gba Ìjọba Ọlọ́run bí ọmọdé.”—Lúùkù 18:17.