Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 96

Jésù Dáhùn Ìbéèrè Ọ̀dọ́kùnrin Ọlọ́rọ̀ Kan

Jésù Dáhùn Ìbéèrè Ọ̀dọ́kùnrin Ọlọ́rọ̀ Kan

MÁTÍÙ 19:16-30 MÁÀKÙ 10:17-31 LÚÙKÙ 18:18-30

  • ỌKÙNRIN ỌLỌ́RỌ̀ KAN BÉÈRÈ BÍ ÒUN ṢE LÈ NÍ ÌYÈ ÀÌNÍPẸ̀KUN

Ojú ọ̀nà Jerúsálẹ́mù ni Jésù ṣì wà, agbègbè Pèríà ló sì ń gbà kọjá. Bó ṣe ń lọ, ọ̀dọ́kùnrin ọlọ́rọ̀ kan sáré wá bá a, ó sì kúnlẹ̀ síwájú rẹ̀. “Ọ̀kan lára àwọn alákòóso” ni ọkùnrin yẹn, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ alága sínágọ́gù tàbí kó wà nínú ìgbìmọ̀ Sàhẹ́ndìrìn. Ó bi Jésù pé: “Olùkọ́ Rere, kí ni mo gbọ́dọ̀ ṣe kí n lè jogún ìyè àìnípẹ̀kun?”—Lúùkù 8:41; 18:18; 24:20.

Jésù dá a lóhùn pé: “Kí ló dé tí o fi pè mí ní ẹni rere? Kò sí ẹni rere kankan, àfi Ọlọ́run nìkan.” Ó ṣeé ṣe kí ọkùnrin náà pe Jésù ní “ẹni rere” torí pé ohun tí wọ́n sábà máa ń pe àwọn rábì nìyẹn. Jésù mọ èèyàn kọ́ lóòótọ́, síbẹ̀ ó jẹ́ kí ọkùnrin náà mọ̀ pé Ọlọ́run nìkan lèèyàn lè pè ní “Ẹni Rere.”

Jésù wá sọ fún un pé: “Àmọ́ o, tí o bá fẹ́ jogún ìyè, máa pa àwọn àṣẹ mọ́ nígbà gbogbo.” Ni ọkùnrin yẹn bá bi Jésù pé: “Àwọn àṣẹ wo?” Jésù mẹ́nu ba márùn-ún lára Òfin Mẹ́wàá, ìyẹn òfin tó sọ̀rọ̀ nípa ẹni tó pààyàn, tó ṣe àgbèrè, tó jalè, ẹni tó jẹ́rìí èké àti òfin tó sọ pé kéèyàn bọlá fáwọn òbí rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó fi òfin pàtàkì kan kún un, ó ní: “Kí o nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ bí ara rẹ.”—Mátíù 19:17-19.

Ọkùnrin náà sọ fún Jésù pé: “Mo ti ń ṣe gbogbo nǹkan yìí; kí ló kù tí mi ò tíì ṣe?” (Mátíù 19:20) Ọkùnrin yẹn lè máa rò ó pé ó ṣì láwọn nǹkan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ tóun máa ní láti ṣe kóun lè rí ìyè àìnípẹ̀kun. Bí Jésù ṣe rí i pé tọkàntọkàn ló fi ń béèrè ìbéèrè yìí, ‘ó nífẹ̀ẹ́’ ọkùnrin náà. (Máàkù 10:21) Àmọ́ ohun kan wà tó máa dí ọkùnrin yẹn lọ́wọ́.

Jésù rí i pé ojú ọkùnrin yìí ò kúrò lára àwọn ohun tó ní, torí náà Jésù sọ fún un pé: “Ohun kan wà tí o ò tíì ṣe: Lọ, kí o ta àwọn ohun tí o ní, kí o fún àwọn aláìní, wàá sì ní ìṣúra ní ọ̀run; kí o wá máa tẹ̀ lé mi.” Lóòótọ́, tí ọkùnrin yẹn bá pín àwọn ohun ìní rẹ̀ fáwọn tálákà tí wọn ò ní ohunkóhun láti san pa dà, ó máa rọrùn fún un láti di ọmọ ẹ̀yìn Jésù. Àmọ́ kò ṣe bẹ́ẹ̀. Ó ṣeé ṣe kí Jésù káàánú ẹ̀ bó ṣe rí i tó dìde kúrò níwájú òun, tí inú ẹ̀ sì bà jẹ́. Ìṣòro ọkùnrin yẹn ni pé “ohun ìní rẹ̀ pọ̀,” ó sì nífẹ̀ẹ́ wọn gan-an, ìdí nìyẹn tí kò fi gbà pé ohun míì tún wà tó ṣeyebíye ju àwọn ohun tó ní lọ. (Máàkù 10:21, 22) Jésù wá sọ pé: “Ẹ wo bó ṣe máa ṣòro tó fún àwọn olówó láti rí ọ̀nà wọ Ìjọba Ọlọ́run!”—Lúùkù 18:24.

Ohun tí Jésù sọ yẹn ya àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ lẹ́nu. Àmọ́, ó tún wá sọ pé: “Ní tòótọ́, ó rọrùn fún ràkúnmí láti gba ojú abẹ́rẹ́ ìránṣọ kọjá ju fún ọlọ́rọ̀ láti wọ Ìjọba Ọlọ́run.” Ọ̀rọ̀ yìí tún ya àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà lẹ́nu, ni wọ́n bá béèrè pé: “Ta ló máa wá lè rígbàlà?” Ṣé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ àtirí ìgbàlà le tó ni débi tó fi máa nira fún ọlọ́rọ̀? Jésù wo àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀, ó sì dá wọn lóhùn pé: “Àwọn ohun tí kò ṣeé ṣe fún èèyàn ṣeé ṣe fún Ọlọ́run.”—Lúùkù 18:25-27.

Pétérù wá sọ ohun kan tó fi hàn pé ìpinnu táwọn ṣe yàtọ̀ sí ti ọkùnrin ọlọ́rọ̀ yẹn, ó ní: “Wò ó! A ti fi ohun gbogbo sílẹ̀, a sì tẹ̀ lé ọ; kí ló máa wá jẹ́ tiwa?” Jésù sọ ohun tó máa jẹ́ èrè wọn torí ohun tí wọ́n ṣe, ó sọ pé: “Nígbà àtúndá, tí Ọmọ èèyàn bá jókòó sórí ìtẹ́ ògo rẹ̀, ẹ̀yin tí ẹ ti tẹ̀ lé mi máa jókòó sórí ìtẹ́ méjìlá (12), ẹ sì máa ṣèdájọ́ ẹ̀yà méjìlá (12) Ísírẹ́lì.”—Mátíù 19:27, 28.

Ó dájú pé ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú ni Jésù ń sọ, nígbà tí gbogbo nǹkan máa pa dà sí bó ṣe wà nínú ọgbà Édẹ́nì. Pétérù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn yòókù máa bá Jésù ṣàkóso nígbà tí ayé bá di Párádísè, ìyẹn ló sì máa jẹ́ èrè wọn. Ohunkóhun tí wọn ì báà yááfì kí wọ́n lè máa tẹ̀ lé Jésù, tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ!

Kì í ṣe èrè ọjọ́ iwájú yẹn nìkan làwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù máa rí. Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, wọ́n ń gbádùn àwọn èrè kan. Jésù sọ fún wọn pé: “Kò sí ẹni tó fi ilé sílẹ̀ tàbí ìyàwó, àwọn arákùnrin, àwọn òbí tàbí àwọn ọmọ nítorí Ìjọba Ọlọ́run, tí kò ní gba ìlọ́po-ìlọ́po sí i lásìkò yìí àti ìyè àìnípẹ̀kun nínú ètò àwọn nǹkan tó ń bọ̀.”—Lúùkù 18:29, 30.

Òótọ́ sì ni, torí pé ibikíbi táwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù bá lọ, wọ́n máa ń gbádùn ìfẹ́ láàárín àwọn tí wọ́n jọ ń sin Ọlọ́run, okùn ìfẹ́ yìí sì yi ju èyí tó máa ń wà láàárín àwọn ọmọ ìyá lọ. Ó ṣeni láàánú pé ọ̀dọ́kùnrin ọlọ́rọ̀ yẹn lè má gbádùn àwọn ìbùkún yìí, ó sì lè má ní àǹfààní láti ṣàkóso pẹ̀lú Jésù lọ́run.

Jésù wá sọ pé: “Àmọ́ ọ̀pọ̀ àwọn ẹni àkọ́kọ́ máa di ẹni ìkẹyìn, àwọn ẹni ìkẹyìn sì máa di ẹni àkọ́kọ́.” (Mátíù 19:30) Kí ló ní lọ́kàn?

Ọ̀dọ́kùnrin ọlọ́rọ̀ yẹn wà lára àwọn “ẹni àkọ́kọ́,” torí pé ó jẹ́ ọ̀kan lára aṣáájú àwọn Júù. Ó máa ń pa òfin Ọlọ́run mọ́, torí ẹ̀, tó bá di ọmọ ẹ̀yìn Jésù, ó máa ṣe dáadáa, ìyẹn ò sì ní ya àwọn èèyàn lẹ́nu torí ohun tí wọ́n retí náà nìyẹn. Àmọ́ ọrọ̀ àtàwọn nǹkan tó ní ló ṣe pàtàkì jù sí i. Ní tàwọn èèyàn yòókù, wọ́n gbà pé òótọ́ làwọn ẹ̀kọ́ Jésù, àwọn ẹ̀kọ́ yìí ló sì máa jẹ́ káwọn rí ìyè. Àwọn yìí ni wọ́n kà sí “ẹni ìkẹyìn,” àmọ́ ní báyìí, wọ́n ti ń di “ẹni àkọ́kọ́.” Lọ́jọ́ iwájú, wọ́n máa bá Jésù jọba lọ́run, wọ́n á sì ṣàkóso lórí aráyé nínú Párádísè.