Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 92

Jésù Wo Adẹ́tẹ̀ Mẹ́wàá Sàn, Ọ̀kan Pa Dà Wá Dúpẹ́

Jésù Wo Adẹ́tẹ̀ Mẹ́wàá Sàn, Ọ̀kan Pa Dà Wá Dúpẹ́

LÚÙKÙ 17:11-19

  • JÉSÙ WO ADẸ́TẸ̀ MẸ́WÀÁ SÀN

Jésù ti mọ̀ pé àwọn Sàhẹ́ndìrìn ń wá bí wọ́n ṣe máa pa òun, torí náà ó lọ sí ìlú Éfúrémù, tó wà lápá àríwá ìlà oòrùn Jerúsálẹ́mù. Òun àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ lọ síbẹ̀ kí ọwọ́ àwọn ọ̀tá ẹ̀ má bàa tẹ̀ ẹ́. (Jòhánù 11:54) Àmọ́, àsìkò Ìrékọjá ọdún 33 S.K. ti ń sún mọ́, torí náà kò pẹ́ tí Jésù tún fi kúrò níbẹ̀. Ó wá gba apá àríwá, ó sì gba Samáríà kọjá lọ sí Gálílì. Ìgbà yẹn ló sì débẹ̀ kẹ́yìn kó tó kú.

Nígbà tí Jésù bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò yìí, bó ṣe ń ti abúlé kan bọ́ sí òmíì, ó rí àwọn ọkùnrin mẹ́wàá tó ní àrùn ẹ̀tẹ̀. Nígbà míì, àrùn ẹ̀tẹ̀ máa ń le débi pé àwọn ẹ̀yà ara kan á máa jẹ díẹ̀díẹ̀, irú bí ìka ọwọ́, ìka ẹsẹ̀ àti etí. (Nọ́ńbà 12:10-12) Òfin Ọlọ́run sọ pé kí ẹni tó bá ní àrùn ẹ̀tẹ̀ máa ké jáde pé, “Aláìmọ́, aláìmọ́!” kó má sì gbé láàárín àwọn èèyàn.—Léfítíkù 13:45, 46.

Ohun táwọn adẹ́tẹ̀ mẹ́wàá yẹn ṣe nìyẹn, wọn ò sún mọ́ ibi tí Jésù wà. Àmọ́ wọ́n ń pariwo pé: “Jésù, Olùkọ́, ṣàánú wa!” Nígbà tí Jésù rí wọn, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ lọ fi ara yín han àwọn àlùfáà.” (Lúùkù 17:13, 14) Ohun tí Jésù ṣe yìí fi hàn pé ó ka Òfin Ọlọ́run sí, torí ohun tí òfin sọ ni pé tí ara adẹ́tẹ̀ kan bá ti yá, kí àlùfáà kéde pé ó ti mọ́. Ìgbà yẹn ni wọ́n á tó lè gbé láàárín àwọn èèyàn tó kù.—Léfítíkù 13:9-17.

Àwọn adẹ́tẹ̀ mẹ́wàá yìí nígbàgbọ́ pé Jésù lágbára láti wo àwọn sàn. Kódà, ara wọn ò tíì yá tí wọ́n fi gba ọ̀dọ̀ àwọn àlùfáà lọ. Ojú ọ̀nà ni wọ́n ṣì wà tí ara wọn fi yá torí ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nínú Jésù. Wọ́n kíyè sí i pé àrùn tó ń ṣe àwọn ti lọ!

Mẹ́sàn-án lára àwọn adẹ́tẹ̀ tí Jésù wò sàn bá tiwọn lọ. Àmọ́, ọ̀kan nínú wọn tó jẹ́ ará Samáríà pa dà lọ bá Jésù. Kí nìdí tó fi pa dà? Ó mọyì ohun tí Jésù ṣe fún un gan-an. Ṣe ló “gbóhùn sókè, ó [sì] yin Ọlọ́run lógo,” torí ó mọ̀ pé Ọlọ́run ló wo òun sàn. (Lúùkù 17:15) Nígbà tó rí Jésù, ó kúnlẹ̀ síwájú ẹ̀, ó sì ń dúpẹ́.

Jésù wá sọ fún àwọn tó wà níbẹ̀ pé: “Àwọn mẹ́wẹ̀ẹ̀wá la wẹ̀ mọ́, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Ibo làwọn mẹ́sàn-án yòókù wà? Ṣé kò sí ẹlòmíì tó pa dà wá yin Ọlọ́run lógo yàtọ̀ sí ọkùnrin yìí tó wá láti orílẹ̀-èdè míì ni?” Jésù wá sọ fún ọkùnrin yẹn pé: “Dìde, kí o sì máa lọ; ìgbàgbọ́ rẹ ti mú ọ lára dá.”—Lúùkù 17:17-19.

Bí Jésù ṣe wo àwọn adẹ́tẹ̀ mẹ́wàá náà sàn fi hàn pé Jèhófà Ọlọ́run wà lẹ́yìn rẹ̀. Kì í ṣe pé ọkùnrin yìí rí ìwòsàn nìkan ni, ó tún ṣeé ṣe kó di ọmọ ẹ̀yìn Jésù kó lè rí ìyè. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé lásìkò wa yìí, Ọlọ́run ò lo Jésù láti ṣe irú àwọn iṣẹ́ ìyanu bẹ́ẹ̀ mọ́. Síbẹ̀, tá a bá nígbàgbọ́ nínú Jésù, a lè rí ìyè àìnípẹ̀kun. Àmọ́ ṣé a máa ń fi hàn pé a moore bíi ti ọkùnrin ará Samáríà yẹn?