Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 66

Jésù Lọ sí Jerúsálẹ́mù Nígbà Àjọyọ̀ Àwọn Àgọ́ Ìjọsìn

Jésù Lọ sí Jerúsálẹ́mù Nígbà Àjọyọ̀ Àwọn Àgọ́ Ìjọsìn

JÒHÁNÙ 7:11-32

  • JÉSÙ Ń KỌ́NI NÍNÚ TẸ́ŃPÌLÌ

Àtìgbà tí Jésù ti ṣèrìbọmi làwọn èèyàn ti mọ irú ẹni tó jẹ́. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Júù ló ti rí iṣẹ́ ìyanu tó ṣe, ìròyìn nípa rẹ̀ sì ti tàn délé dóko ní gbogbo ilẹ̀ náà. Ní báyìí, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń wá a ní Jerúsálẹ́mù nígbà Àjọyọ̀ Àwọn Àgọ́ Ìjọsìn (tàbí Àjọyọ̀ Àtíbàbà).

Oríṣiríṣi èrò làwọn èèyàn ní nípa irú ẹni tí Jésù jẹ́. Àwọn kan sọ pé: “Èèyàn dáadáa ni.” Àwọn míì sì sọ pé: “Irọ́ ni. Ṣe ló ń tan àwọn èèyàn jẹ.” (Jòhánù 7:12) Irú àwọn ọ̀rọ̀ yìí làwọn èèyàn ń sọ ṣáájú ọjọ́ àjọyọ̀ náà. Síbẹ̀ kò sẹ́ni tó jẹ́ gbójú gbóyà sọ̀rọ̀ Jésù ní gbangba, torí àwọn èèyàn náà ń bẹ̀rù ohun táwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù máa ṣe.

Nígbà tí àjọyọ̀ náà ń lọ lọ́wọ́, Jésù wá sí tẹ́ńpìlì. Ó ya ọ̀pọ̀ èèyàn lẹ́nu bí Jésù ṣe ń kọ́ni lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Àmọ́ torí pé kò lọ sí ilé ẹ̀kọ́ àwọn rábì, àwọn Júù sọ pé: “Báwo ni ọkùnrin yìí ṣe mọ Ìwé Mímọ́ tó báyìí láìjẹ́ pé ó lọ sáwọn ilé ẹ̀kọ́?”—Jòhánù 7:15.

Jésù wá ṣàlàyé fún wọn pé: “Ohun tí mo fi ń kọ́ni kì í ṣe tèmi, àmọ́ ó jẹ́ ti ẹni tó rán mi. Tí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ ṣe ìfẹ́ Rẹ̀, ó máa mọ̀ bóyá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ẹ̀kọ́ náà ti wá àbí èrò ara mi ni mò ń sọ.” (Jòhánù 7:16, 17) Torí pé ohun tí Jésù ń kọ́ àwọn èèyàn bá òfin Ọlọ́run mu, kò yani lẹ́nu pé Ọlọ́run ló ń darí ògo sí, kì í ṣe ara rẹ̀.

Lẹ́yìn náà Jésù sọ pé: “Mósè fún yín ní Òfin, àbí kò fún yín? Àmọ́ kò sí ìkankan nínú yín tó ń ṣègbọràn sí Òfin náà. Kí ló dé tí ẹ̀ ń wá bí ẹ ṣe máa pa mí?” Ó ya àwọn kan lẹ́nu pé ẹnì kan lè fẹ́ pa Jésù, bóyá torí pé wọ́n jẹ́ àlejò ni wọn ò ṣe mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀. Wọ́n wò ó pé kò sẹ́ni tó máa fẹ́ pa irú olùkọ́ tó mọ̀ọ̀yàn kọ́ bíi tiẹ̀. Torí náà, wọ́n gbà pé Jésù ò mọ ohun tó ń sọ. Wọ́n wá sọ fún un pé “Ẹlẹ́mìí èṣù ni ọ́. Ta ló fẹ́ pa ọ́?”—Jòhánù 7:19, 20.

Lóòótọ́, àwọn aṣáájú Júù yẹn ti ń wá bí wọ́n ṣe máa pa Jésù ní nǹkan bí ọdún kan sẹ́yìn torí pé ó wo ọkùnrin kan sàn lọ́jọ́ Sábáàtì. Torí náà Jésù sọ ohun tó lè mú kí wọ́n ronú jinlẹ̀, kó lè fi hàn pé èrò wọn ò tọ̀nà. Jésù rán wọn létí ohun tí Òfin sọ pé kí wọ́n dádọ̀dọ́ ọmọkùnrin kan ní ọjọ́ kẹjọ, kódà tó bá tiẹ̀ jẹ́ ọjọ́ Sábáàtì. Lẹ́yìn náà ó sọ pé: “Tí ọkùnrin kan bá dádọ̀dọ́ ní sábáàtì torí kó má bàa rú Òfin Mósè, ṣé ẹ wá ń bínú gidigidi sí mi ni, torí pé mo wo ọkùnrin kan sàn pátápátá ní sábáàtì? Ẹ yéé fi ìrísí òde ṣe ìdájọ́, àmọ́ ẹ máa dá ẹjọ́ òdodo.”—Jòhánù 7:23, 24.

Làwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù tí wọ́n lóye ohun tó ń ṣẹlẹ̀ bá sọ pé: “Ọkùnrin tí [àwọn alákòóso] ń wá bí wọ́n ṣe fẹ́ pa nìyí, àbí òun kọ́? Ẹ wò ó! òun ló ń sọ̀rọ̀ ní gbangba yìí, wọn ò sì sọ nǹkan kan sí i. Ṣé ó ti dá àwọn alákòóso lójú pé Kristi nìyí ni?” Kí wá nìdí táwọn èèyàn náà ò fi gbà pé Jésù ni Kristi? Wọ́n sọ pé: “A mọ ibi tí ọkùnrin yìí ti wá; àmọ́ tí Kristi bá dé, kò sí ẹni tó máa mọ ibi tó ti wá.”—Jòhánù 7:25-27.

Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Jésù dá wọn lóhùn pé: “Ẹ mọ̀ mí, ẹ sì mọ ibi tí mo ti wá. Èmi kọ́ ni mo rán ara mi, àmọ́ ẹni gidi ni Ẹni tó rán mi, ẹ ò sì mọ̀ ọ́n. Èmi mọ̀ ọ́n, torí pé aṣojú látọ̀dọ̀ rẹ̀ ni mí, Ẹni yẹn ló sì rán mi jáde.” (Jòhánù 7:28, 29) Ohun táwọn èèyàn náà ṣe lẹ́yìn tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí fi hàn pé ara wọn kọ òótọ́ ọ̀rọ̀, ṣe ni wọ́n ń wá bí wọ́n ṣe máa mú Jésù, bóyá kí wọ́n lè fi í sẹ́wọ̀n tàbí kí wọ́n lè pa á. Àmọ́ pàbó ni gbogbo ìsapá wọn já sí, torí àsìkò ikú Jésù ò tíì tó.

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló nígbàgbọ́ nínú Jésù, ohun tó sì yẹ kí gbogbo wọn ṣe nìyẹn. Ó ṣe tán, Jésù rìn lórí omi, ó mú kí ìjì òkun pa rọ́rọ́, ó fi búrẹ́dì àti ẹja díẹ̀ bọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́nà ìyanu, ó mú àwọn aláìsàn lára dá, ó mú kí àwọn arọ rìn, ó la ojú àwọn afọ́jú, ó wo àwọn adẹ́tẹ̀ sàn, kódà ó tún jí òkú dìde. Ká sòótọ́, ó yẹ káwọn èèyàn náà béèrè lọ́wọ́ ara wọn pé: “Tí Kristi bá dé, ṣé ó máa ṣe iṣẹ́ àmì tó ju èyí tí ọkùnrin yìí ti ṣe lọ ni?”—Jòhánù 7:31.

Lẹ́yìn táwọn Farisí gbọ́ ohun táwọn èèyàn náà ń sọ nípa Jésù, ṣe làwọn àtàwọn olórí àlùfáà rán àwọn òṣìṣẹ́ láti lọ mú Jésù.