Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 80

Olùṣọ́ Àgùntàn Àtàtà àti Agbo Àgùntàn

Olùṣọ́ Àgùntàn Àtàtà àti Agbo Àgùntàn

JÒHÁNÙ 10:1-21

  • JÉSÙ SỌ̀RỌ̀ NÍPA OLÙṢỌ́ ÀGÙNTÀN ÀTÀTÀ ÀTI AGBO ÀGÙNTÀN

Jùdíà ni Jésù ṣì wà níbi tó ti ń kọ́ àwọn èèyàn, lọ́tẹ̀ yìí ó yí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pa dà sí ohun táwọn tó wà níbẹ̀ mọ̀ dáadáa, ó sọ̀rọ̀ nípa àgùntàn àti agbo àgùntàn. Àmọ́ àpèjúwe lásán ló ń fi wọ́n ṣe. Ó ṣeé ṣe kí èyí mú káwọn Júù yẹn rántí ọ̀rọ̀ Dáfídì, tó sọ pé: “Jèhófà ni Olùṣọ́ Àgùntàn mi. Èmi kì yóò ṣaláìní. Ó mú mi dùbúlẹ̀ ní ibi ìjẹko tútù.” (Sáàmù 23:1, 2) Nínú sáàmù míì, Dáfídì sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ẹ jẹ́ ká kúnlẹ̀ níwájú Jèhófà Ẹni tó dá wa. Nítorí òun ni Ọlọ́run wa, àwa sì ni èèyàn ibi ìjẹko rẹ̀.” (Sáàmù 95:6, 7) Torí náà, ọjọ́ pẹ́ tí wọ́n ti máa ń fi àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wé agbo àgùntàn.

Àwọn “àgùntàn” yìí ti wà nínú “agbo àgùntàn” látilẹ̀, torí pé Òfin Mósè kì í ṣe tuntun sí wọn. Òfin yẹn dà bí ògiri tó ń dáàbò bò wọ́n káwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká má bàa kó èèràn ràn wọ́n. Síbẹ̀, àwọn kan lára wọn hùwà ìkà sáwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run. Jésù wá sọ pé: “Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ẹni tí kò bá gba ẹnu ọ̀nà wọ ọgbà àgùntàn, àmọ́ tó gba ibòmíì gòkè wọlé, olè àti akónilẹ́rù ni ẹni yẹn. Àmọ́ ẹni tó bá gba ẹnu ọ̀nà wọlé ni olùṣọ́ àgùntàn.”—Jòhánù 10:1, 2.

Ó ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yìí mú káwọn tó wà níbẹ̀ rántí àwọn kan tó ti pe ara wọn ní Mèsáyà rí tàbí Kristi. Àwọn ni Jésù fi wé olè àti akónilẹ́rù. Kì í ṣe irú àwọn afàwọ̀rajà bẹ́ẹ̀ ló yẹ káwọn èèyàn yẹn máa tẹ̀ lé. Kàkà bẹ́ẹ̀, “olùṣọ́ àgùntàn” tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ló yẹ kí wọ́n tẹ̀ lé, Jésù wá sọ pé:

“Aṣọ́nà ṣílẹ̀kùn fún ẹni yìí, àwọn àgùntàn sì fetí sí ohùn rẹ̀. Ó ń fi orúkọ pe àwọn àgùntàn rẹ̀, ó sì ń kó wọn jáde. Tó bá ti kó gbogbo àwọn tirẹ̀ jáde, ó máa ń lọ níwájú wọn, àwọn àgùntàn á sì tẹ̀ lé e, torí wọ́n mọ ohùn rẹ̀. Ó dájú pé wọn ò ní tẹ̀ lé àjèjì, ṣe ni wọ́n máa sá fún un, torí wọn ò mọ ohùn àwọn àjèjì.”—Jòhánù 10:3-5.

Jòhánù Arinibọmi tó dà bí aṣọ́nà fún Jésù ti jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé Jésù ni ẹni tó yẹ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wà lábẹ́ Òfin Mósè máa tẹ̀ lé. Àwọn àgùntàn Jésù kan ní Gálílì àti ní Jùdíà ti wá dá ohùn rẹ̀ mọ̀. Ibo ni Jésù ń “kó wọn jáde” lọ? Àǹfààní wo ló máa ṣe wọ́n tí wọ́n bá tẹ̀ lé Jésù? Àwọn ìbéèrè yìí ló ṣeé ṣe kó wà lọ́kàn àwọn tó ń fetí sí àpèjúwe rẹ̀, torí pé “ohun tó ń sọ fún wọn ò yé wọn.”—Jòhánù 10:6.

Jésù wá ṣàlàyé pé: “Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, èmi ni ẹnu ọ̀nà fún àwọn àgùntàn. Olè àti akónilẹ́rù ni gbogbo àwọn tó wá dípò mi; àmọ́ àwọn àgùntàn ò fetí sí wọn. Èmi ni ẹnu ọ̀nà; ẹnikẹ́ni tó bá gba ọ̀dọ̀ mi wọlé máa rí ìgbàlà, ẹni yẹn máa wọlé, ó máa jáde, ó sì máa rí ibi ìjẹko.”—Jòhánù 10:7-9.

Ó ṣe kedere pé ohun tuntun kan ni Jésù fẹ́ kí wọ́n mọ̀. Àwọn tó wà níbẹ̀ mọ̀ pé ipasẹ̀ Jésù kọ́ làwọn fi rí Òfin Mósè gbà, torí Òfin yẹn ti wà láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn. Torí náà, ohun tí Jésù ń sọ ni pé àwọn àgùntàn tí òun ń ‘kó jáde’ máa di agbo àgùntàn míì. Kí nìyẹn máa wá yọrí sí?

Jésù ṣàlàyé síwájú sí i nípa ohun tó fẹ́ ṣe, ó ní: “Èmi wá, kí wọ́n lè ní ìyè, kí wọ́n sì ní in lọ́pọ̀ rẹpẹtẹ. Èmi ni olùṣọ́ àgùntàn àtàtà; olùṣọ́ àgùntàn àtàtà máa ń fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn àgùntàn.” (Jòhánù 10:10, 11) Jésù ti kọ́kọ́ tu àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nínú nígbà tó sọ pé: “Má bẹ̀rù, agbo kékeré, torí Baba yín ti fọwọ́ sí i láti fún yín ní Ìjọba náà.” (Lúùkù 12:32) Torí náà, àwọn tó para pọ̀ di “agbo kékeré” yìí ni Jésù máa kó jáde láti di agbo àgùntàn míì “kí wọ́n lè ní ìyè, kí wọ́n sì ní in lọ́pọ̀ rẹpẹtẹ.” Ìbùkún àrà ọ̀tọ̀ ló máa jẹ́ fún wọn láti wà lára agbo kékeré yìí!

Jésù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó ní: “Mo ní àwọn àgùntàn mìíràn, tí kò sí lára ọ̀wọ́ yìí; mo gbọ́dọ̀ mú àwọn yẹn náà wá, wọ́n á fetí sí ohùn mi, wọ́n á sì di agbo kan, olùṣọ́ àgùntàn kan.” (Jòhánù 10:16) Jésù jẹ́ kó ṣe kedere pé “àwọn àgùntàn mìíràn” yìí “kò sí lára ọ̀wọ́ yìí.” Tó túmọ̀ sí pé ọ̀wọ́ míì ni wọ́n, wọ́n yàtọ̀ sí “agbo kékeré” tó máa bá Jésù jọba. Nǹkan ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló máa ṣẹlẹ̀ sí agbo àgùntàn méjèèjì yìí lọ́jọ́ iwájú. Àmọ́ gbogbo wọn ló máa jàǹfààní nínú ohun tí Jésù máa ṣe. Jésù wá sọ pé: “Ìdí nìyí tí Baba fi nífẹ̀ẹ́ mi, torí pé mo fi ẹ̀mí mi lélẹ̀.”—Jòhánù 10:17.

Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ń gbọ́rọ̀ Jésù sọ pé: “Ẹlẹ́mìí èṣù ni, orí rẹ̀ sì ti yí.” Síbẹ̀ àwọn kan láàárín wọn ṣì ń fọkàn bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó sì wù wọ́n láti tẹ̀ lé Olùṣọ́ Àgùntàn Àtàtà náà. Àwọn yìí sọ pé: “Àwọn ọ̀rọ̀ yìí kì í ṣe ti ẹlẹ́mìí èṣù. Ẹ̀mí èṣù ò lè la ojú afọ́jú, àbí ó lè là á?” (Jòhánù 10:20, 21) Iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe nígbà tó la ojú ọkùnrin kan tí wọ́n bí ní afọ́jú làwọn èèyàn náà ń tọ́ka sí.