Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 107

Ọba Kan Pe Àwọn Èèyàn Wá Síbi Ayẹyẹ Ìgbéyàwó

Ọba Kan Pe Àwọn Èèyàn Wá Síbi Ayẹyẹ Ìgbéyàwó

MÁTÍÙ 22:1-14

  • ÀPÈJÚWE NÍPA AYẸYẸ ÌGBÉYÀWÓ

Bí iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù ṣe ń parí lọ, ó túbọ̀ ń lo àpèjúwe láti tú àṣírí àwọn akọ̀wé òfin àtàwọn olórí àlùfáà. Torí náà, wọ́n ń wá bí wọ́n ṣe máa pa á. (Lúùkù 20:19) Àmọ́, Jésù ò tíì parí ọ̀rọ̀ ẹ̀. Ó tún lo àpèjúwe míì láti tú àṣírí wọn, ó ní:

“A lè fi Ìjọba ọ̀run wé ọba kan tó se àsè ìgbéyàwó fún ọmọkùnrin rẹ̀. Ó wá rán àwọn ẹrú rẹ̀ kí wọ́n lọ pe àwọn tí wọ́n pè síbi àsè ìgbéyàwó náà wá, àmọ́ wọn ò fẹ́ wá.” (Mátíù 22:2, 3) Ọ̀rọ̀ nípa “Ìjọba ọ̀run” ni Jésù fi bẹ̀rẹ̀ àpèjúwe yìí. Torí náà, ó bọ́gbọ́n mu láti gbà pé Jèhófà ni “ọba” yẹn. Ta wá ni ọmọ ọba àtàwọn tí wọ́n pè wá síbi ayẹyẹ ìgbéyàwó náà? Ìbéèrè yìí náà ò le, Ọmọ Jèhófà ló dúró fún ọmọ ọba, àwọn tó sì máa wà pẹ̀lú Ọmọ yìí nínú Ìjọba ọ̀run làwọn tí wọ́n pè síbi ayẹyẹ náà.

Àwọn wo ni wọ́n kọ́kọ́ pè síbi ayẹyẹ náà? Rò ó ná! Àwọn wo ni Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ń wàásù Ìjọba Ọlọ́run fún? Àwọn Júù ni! (Mátíù 10:6, 7; 15:24) Ọdún 1513 Ṣ.S.K. ni orílẹ̀-èdè yẹn gba Májẹ̀mú Òfin, ìyẹn ló sì mú kí wọ́n di ẹni àkọ́kọ́ tó máa wà nínú “ìjọba àwọn àlùfáà.” (Ẹ́kísódù 19:5-8) Àmọ́ ìgbà wo ni wọ́n pè wọ́n síbi “àsè ìgbéyàwó náà”? Kò sí iyèméjì pé ọdún 29 S.K. ni, torí pé ìgbà yẹn ni Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù nípa Ìjọba ọ̀run.

Kí ni ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe nígbà tí wọ́n pè wọ́n? Bí Jésù ṣe sọ, “wọn ò fẹ́ wá.” Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn èèyàn yẹn àtàwọn aṣáájú ẹ̀sìn ni ò gbà pé òun ni Mèsáyà tí Ọlọ́run yàn láti di Ọba.

Jésù jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé àǹfààní míì ṣì wà fáwọn Júù, ó ní: “[Ọba] tún rán àwọn ẹrú míì, ó sọ pé, ‘Ẹ sọ fún àwọn tí a pè, pé: “Ẹ wò ó! Mo ti pèsè oúnjẹ alẹ́ mi sílẹ̀, mo ti pa àwọn akọ màlúù mi àtàwọn ẹran mi tó sanra, gbogbo nǹkan sì ti wà ní sẹpẹ́. Ẹ wá síbi àsè ìgbéyàwó náà.”’ Àmọ́ wọn ò kà á sí, wọ́n jáde lọ, ọ̀kan lọ sí oko rẹ̀, òmíràn lọ síbi òwò rẹ̀; àmọ́ àwọn tó kù gbá àwọn ẹrú rẹ̀ mú, wọ́n kàn wọ́n lábùkù, wọ́n sì pa wọ́n.” (Mátíù 22:4-6) Èyí jọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ nígbà tí wọ́n bá dá ìjọ Kristẹni sílẹ̀. Nígbà yẹn, àwọn Júù tún máa láǹfààní láti wà nínú Ìjọba yẹn, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ lára wọn ò ní gba ìkésíni náà, kódà ṣe ni wọ́n máa kan ‘àwọn ẹrú ọba’ náà lábùkù.—Ìṣe 4:13-18; 7:54, 58.

Kí ló wá ṣẹlẹ̀ sí orílẹ̀-èdè yẹn? Jésù sọ pé: “Inú bí ọba náà, ló bá rán àwọn ọmọ ogun rẹ̀ lọ pa àwọn apààyàn náà, ó sì dáná sun ìlú wọn.” (Mátíù 22:7) Ọdún 70 S.K. lohun tí Jésù sọ yìí ṣẹlẹ̀ nígbà tí àwọn ará Róòmù pa “ìlú wọn” run, ìyẹn Jerúsálẹ́mù.

Ṣé bí wọn ò ṣe jẹ́ ìpè ọba yẹn túmọ̀ sí pé àwọn míì ò lè wá síbi àsè náà? Ohun tí Jésù sọ kọ́ nìyẹn. Ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó ní: “[Ọba] wá sọ fún àwọn ẹrú rẹ̀ pé, ‘Àsè ìgbéyàwó náà ti wà ní sẹpẹ́, àmọ́ àwọn tí a pè kò yẹ. Torí náà, ẹ lọ sí àwọn ojú ọ̀nà tó jáde látinú ìlú, kí ẹ sì pe ẹnikẹ́ni tí ẹ bá rí wá síbi àsè ìgbéyàwó náà.’ Àwọn ẹrú náà ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n jáde lọ sí àwọn ojú ọ̀nà, wọ́n sì kó gbogbo àwọn tí wọ́n rí jọ, ẹni burúkú àti ẹni rere; àwọn tó ń jẹun sì kún inú yàrá tí wọ́n ti ń ṣe ayẹyẹ ìgbéyàwó náà.”—Mátíù 22:8-10.

Ó ṣe kedere pé ohun tí Jésù sọ yìí ṣẹlẹ̀ nígbà tí àpọ́sítélì Pétérù ran àwọn Kèfèrí lọ́wọ́, ìyẹn àwọn tí kì í ṣe Júù tàbí aláwọ̀ṣe, àwọn yìí sì di Kristẹni. Nígbà tó di ọdún 36 S.K., ẹ̀mí mímọ́ bà lé Kọ̀nílíù tó jẹ́ ọmọ ogun Róòmù àti ìdílé rẹ̀, ìyẹn sì mú kí wọ́n di ọ̀kan lára àwọn tó máa wà pẹ̀lú Jésù nínú Ìjọba ọ̀run.—Ìṣe 10:1, 34-48.

Jésù tún sọ pé kì í ṣe gbogbo àwọn tó bá wá síbi àsè náà ni inú “ọba” máa dùn sí. Ó ní: “Nígbà tí ọba náà wọlé wá wo àwọn àlejò, ó tajú kán rí ọkùnrin kan tí kò wọ aṣọ ìgbéyàwó. Ó wá bi í pé, ‘Ọ̀gbẹ́ni, báwo lo ṣe wọlé síbí láìwọ aṣọ ìgbéyàwó?’ Ọkùnrin náà ò lè sọ nǹkan kan. Ọba wá sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, ‘Ẹ dè é tọwọ́ tẹsẹ̀, kí ẹ sì jù ú sínú òkùnkùn níta. Ibẹ̀ lá ti máa sunkún, tí á sì ti máa payín keke.’ Torí ọ̀pọ̀ la pè, àmọ́ díẹ̀ la yàn.”—Mátíù 22:11-14.

Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn yẹn lè má lóye ohun tí Jésù ń sọ, wọ́n sì lè má mọ ibi tọ́rọ̀ náà máa já sí. Síbẹ̀ inú wọn ò dùn sí Jésù, kódà ṣe ni wọ́n túbọ̀ ń wá bí wọ́n ṣe máa pa á, torí pé ó ń kàn wọ́n lábùkù.