ORÍ 105
Jésù Fi Igi Ọ̀pọ̀tọ́ Kan Kọ́ Wọn Lẹ́kọ̀ọ́ Nípa Ìgbàgbọ́
MÁTÍÙ 21:19-27 MÁÀKÙ 11:19-33 LÚÙKÙ 20:1-8
-
OHUN TÍ IGI Ọ̀PỌ̀TỌ́ TÓ GBẸ KỌ́ WA NÍPA ÌGBÀGBỌ́
-
ÀWỌN ÈÈYÀN BÉÈRÈ ẸNI TÓ FÚN JÉSÙ LÁṢẸ TÓ FI Ń ṢE NǸKAN
Nígbà tí Jésù kúrò ní Jerúsálẹ́mù lọ́sàn-án ọjọ́ Monday, ó pa dà sí Bẹ́tánì tó wà ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ ìlà oòrùn Òkè Ólífì. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ilé Lásárù, Màríà àti Màtá tí wọ́n jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ ló sùn mọ́jú.
Láàárọ̀ Nísàn 11, Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tún bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò wọn. Wọ́n pa dà sí Jerúsálẹ́mù, ọjọ́ yẹn ni Jésù máa dé tẹ́ńpìlì gbẹ̀yìn. Ọjọ́ yẹn kan náà ló máa lò kẹ́yìn lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, lẹ́yìn náà wọ́n máa ṣe Ìrékọjá, ó máa dá Ìrántí Ikú rẹ̀ sílẹ̀, wọ́n máa gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀, wọ́n sì máa pa á.
Bí wọ́n ṣe ń gba Òkè Ólífì kọjá lọ láti Bẹ́tánì sí Jerúsálẹ́mù, Pétérù rí igi tí Jésù gégùn-ún fún láàárọ̀ ọjọ́ tó ṣáájú ọjọ́ yẹn. Ó yà á lẹ́nu, ó wá sọ pé: “Rábì, wò ó! igi ọ̀pọ̀tọ́ tí o gégùn-ún fún ti gbẹ.”—Máàkù 11:21.
Àmọ́ kí nìdí tí Jésù fi ní kí igi náà gbẹ? Ohun tó sọ lẹ́yìn náà jẹ́ ká mọ ìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀, ó ní: “Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, tí ẹ bá ní ìgbàgbọ́, tí ẹ ò sì ṣiyèméjì, ohun tí mo ṣe sí igi ọ̀pọ̀tọ́ náà nìkan kọ́ lẹ máa lè ṣe, àmọ́ tí ẹ bá sọ fún òkè yìí pé, ‘Dìde, wọnú òkun,’ ó máa ṣẹlẹ̀. Gbogbo ohun tí ẹ bá sì béèrè nínú àdúrà, tí ẹ bá ní ìgbàgbọ́, ẹ máa rí i gbà.” (Mátíù 21:21, 22) Ohun tó sọ yìí fi hàn pé ó fẹ́ tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ tó ti sọ tẹ́lẹ̀ nípa bí ìgbàgbọ́ ṣe lè mú kí òkè kúrò níbì kan lọ síbòmíì.—Mátíù 17:20.
Torí náà, bí Jésù ṣe mú kí igi yẹn gbẹ fi hàn pé ó fẹ́ kí wọ́n mọ bó ti ṣe pàtàkì tó láti nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run. Ó ní: “Gbogbo ohun tí ẹ bá gbàdúrà fún, tí ẹ sì béèrè, ẹ ní ìgbàgbọ́ pé ẹ ti rí i gbà, ó sì máa jẹ́ tiyín.” (Máàkù 11:24) Ẹ̀kọ́ pàtàkì lèyí jẹ́ fún gbogbo àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù! Ní pàtàkì, fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀, torí wọ́n máa tó kojú àdánwò tó lágbára. Àmọ́, ẹ̀kọ́ míì wà tá a tún lè rí kọ́ nínú bí igi yẹn ṣe rọ.
Bíi ti igi yẹn, ó lè dà bíi pé orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì nígbàgbọ́. Torí Ọlọ́run bá wọn dá májẹ̀mú, èèyàn lè máa wò wọ́n bí ẹni tó ń pa Òfin Ọlọ́run mọ́. Àmọ́ orílẹ̀-èdè yẹn lápapọ̀ ti fi hàn pé àwọn ò nígbàgbọ́, wọn ò sì méso jáde. Kódà, wọ́n kọ̀ láti gba Ọmọ Ọlọ́run gbọ́! Torí náà, bí Jésù ṣe mú kí igi tí kò méso jáde yẹn gbẹ, ṣe ló ń ṣàpèjúwe ohun tó máa gbẹ̀yìn orílẹ̀-èdè yẹn, torí pé wọn ò méso jáde, wọn ò sì nígbàgbọ́.
Kò pẹ́ sígbà yẹn, Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ dé Jerúsálẹ́mù. Bó ṣe máa ń ṣe, ó lọ sí tẹ́ńpìlì, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn èèyàn. Àwọn olórí àlùfáà àtàwọn àgbààgbà lọ bá Jésù, ó ṣeé ṣe kí wọ́n ṣì máa ronú lórí ohun tó ṣe lọ́jọ́ kan ṣáájú ìgbà yẹn. Wọ́n bi í pé: “Àṣẹ wo lo fi ń ṣe àwọn nǹkan yìí? Àbí ta ló fún ọ ní àṣẹ yìí pé kí o máa ṣe àwọn nǹkan yìí?”—Máàkù 11:28.
Jésù dá wọn lóhùn pé: “Èmi náà á bi yín ní ìbéèrè kan. Tí ẹ bá dá mi lóhùn, màá wá sọ àṣẹ tí mo fi ń ṣe àwọn nǹkan yìí fún yín. Ṣé láti ọ̀run ni ìrìbọmi tí Jòhánù ṣe fún àwọn èèyàn ti wá àbí látọ̀dọ̀ èèyàn? Ẹ dá mi lóhùn.” Lọ̀rọ̀ bá pèsì jẹ. Wọ́n wá forí korí kí wọ́n lè dáhùn ìbéèrè yìí, wọ́n sọ láàárín ara wọn pé: “Tí a bá sọ pé, ‘Láti ọ̀run,’ ó máa sọ pé, ‘Kí ló wá dé tí ẹ ò gbà á gbọ́?’ Àmọ́, ṣé a lè sọ pé, ‘Látọ̀dọ̀ èèyàn’?” Ẹ̀rù àwọn èèyàn tó wà lọ́dọ̀ Jésù ló ba àwọn alátakò yẹn tí wọ́n fi ń sọ bẹ́ẹ̀, “torí gbogbo àwọn yìí gbà pé wòlíì ni Jòhánù lóòótọ́.”—Máàkù 11:29-32.
Àwọn alátakò yẹn ò rí ohunkóhun sọ sí ìbéèrè tí Jésù bi wọ́n. Ni wọ́n bá dá a lóhùn pé: “A ò mọ̀.” Jésù náà dá wọn lóhùn, ó ní: “Èmi náà ò ní sọ àṣẹ tí mo fi ń ṣe àwọn nǹkan yìí fún yín.”—Máàkù 11:33.