Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 103

Jésù Fọ Tẹ́ńpìlì Mọ́ Lẹ́ẹ̀kan Sí I

Jésù Fọ Tẹ́ńpìlì Mọ́ Lẹ́ẹ̀kan Sí I

MÁTÍÙ 21:12, 13, 18, 19 MÁÀKÙ 11:12-18 LÚÙKÙ 19:45-48 JÒHÁNÙ 12:20-27

  • JÉSÙ GÉGÙN-ÚN FÚN IGI Ọ̀PỌ̀TỌ́ KAN, Ó TÚN FỌ TẸ́ŃPÌLÌ MỌ́

  • JÉSÙ GBỌ́DỌ̀ KÚ KÓ TÓ LÈ FÚN Ọ̀PỌ̀ ÈÈYÀN NÍ ÌYÈ

Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ ti lo ọjọ́ mẹ́ta ní Bẹ́tánì lẹ́yìn tí wọ́n dé láti Jẹ́ríkò. Nígbà tó di àárọ̀ Monday Nísàn 10, wọ́n lọ sí Jerúsálẹ́mù. Bí wọ́n ṣe ń lọ, ebi ń pa Jésù. Torí náà, nígbà tó rí igi ọ̀pọ̀tọ́ kan, ó lọ sídìí ẹ̀. Kí ló wá bá lórí igi náà?

Oṣù March ń parí lọ lásìkò yẹn, ó ṣì di oṣù June kí igi ọ̀pọ̀tọ́ tó sèso. Àmọ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ tí Jésù rí yìí tètè rúwé ní tiẹ̀, torí náà Jésù rò pé òun máa rí èso lórí ẹ̀. Nígbà tó débẹ̀ kò rí èso kankan bó ti wù kó kéré mọ. Ṣe làwọn ewé tó wà lórí igi yẹn kàn jẹ́ kó dà bíi pé èso ti wà lórí ẹ̀. Jésù wá sọ pé: “Kí ẹnì kankan má ṣe jẹ èso lórí rẹ mọ́ títí láé.” (Máàkù 11:14) Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni igi náà bẹ̀rẹ̀ sí í wọ́wé, àmọ́ àárọ̀ ọjọ́ kejì làwọn ọmọ ẹ̀yìn ṣẹ̀ṣẹ̀ lóye ohun tí Jésù sọ.

Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ dé Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì lọ sínú tẹ́ńpìlì. Lọ́jọ́ tó ṣáájú ọjọ́ yẹn, Jésù lọ ṣàyẹ̀wò ohun tó ń lọ nínú tẹ́ńpìlì. Àmọ́ ní báyìí, kì í ṣe pé ó kàn ṣàyẹ̀wò tẹ́ńpìlì nìkan, ohun tó ṣe lọ́dún mẹ́ta sẹ́yìn nígbà Ìrékọjá ọdún 30 S.K. ló tún ṣe nígbà tó débẹ̀. (Jòhánù 2:14-16) Lọ́tẹ̀ yìí, ó lé “àwọn tó ń tajà àti àwọn tó ń rajà nínú tẹ́ńpìlì síta, ó sì dojú tábìlì àwọn tó ń pààrọ̀ owó dé àti bẹ́ǹṣì àwọn tó ń ta àdàbà.” (Máàkù 11:15) Kódà, kò gbà káwọn tó ń gbé nǹkan bọ̀ látinú ìlú yẹn gba àgbàlá tẹ́ńpìlì kọjá lọ síbòmíì.

Kí nìdí tó fi jẹ́ pé ọwọ́ tó le tóyẹn ni Jésù fi mú àwọn tó ń pààrọ̀ owó àtàwọn tó ń ta ẹran nínú tẹ́ńpìlì? Jésù sọ pé: “Ṣebí a ti kọ ọ́ pé, ‘A ó máa pe ilé mi ní ilé àdúrà fún gbogbo orílẹ̀-èdè’? Àmọ́ ẹ ti sọ ọ́ di ihò àwọn olè.” (Máàkù 11:17) Kí nìdí tí Jésù fi pè wọ́n lólè? Ìdí ni pé owó gọbọi ni wọ́n máa ń gbà lọ́wọ́ àwọn tó fẹ́ ra ẹran tí wọ́n máa fi ṣètùtù. Jésù gbà pé ìwà wọn ò yàtọ̀ sí ti olè.

Nígbà táwọn olórí àlùfáà, àwọn akọ̀wé òfin àtàwọn èèyàn ńláńlá tó wà nílùú gbọ́ ohun tí Jésù ṣe, wọ́n tún pa dà sórí ọ̀rọ̀ bí wọ́n ṣe máa pa á. Àmọ́, ohun kan wà tó ń dí wọn lọ́wọ́. Wọn ò mọ bí wọ́n ṣe máa pa Jésù torí pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń tẹ̀ lé e kí wọ́n lè gbọ́rọ̀ ẹ̀.

Àwọn Júù nìkan kọ́ ló wá síbi Ìrékọjá yẹn, àwọn aláwọ̀ṣe náà wà níbẹ̀, ìyẹn àwọn tó gba ẹ̀sìn Júù. Lára wọn ni àwọn Gíríìkì tí wọ́n wá jọ́sìn Ọlọ́run níbi àjọyọ̀ náà. Wọ́n lọ bá Fílípì, bóyá torí pé orúkọ Gíríìkì ló ń jẹ́, wọ́n sọ fún un pé àwọn fẹ́ rí Jésù. Ó ṣeé ṣe kí Fílípì má mọ̀ bóyá wọ́n máa lè rí Jésù, torí náà ó fi ọ̀rọ̀ náà lọ Áńdérù. Làwọn méjèèjì bá lọ bá Jésù, torí ó ṣeé ṣe kó ṣì wà ní tẹ́ńpìlì nígbà yẹn.

Jésù mọ̀ pé ọjọ́ bíi mélòó kan ló kù fún òun láti kú, torí náà kì í ṣe àsìkò yìí ló yẹ kó máa wá bó ṣe máa ṣe ohun táwọn èèyàn fẹ́ tàbí kó máa wá bá á ṣe di gbajúmọ̀. Torí náà, ó sọ àpèjúwe kan fáwọn àpọ́sítélì méjèèjì yẹn, ó ní: “Wákàtí náà ti dé tí a máa ṣe Ọmọ èèyàn lógo. Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, láìjẹ́ pé hóró àlìkámà kan bọ́ sílẹ̀, kó sì kú, ó ṣì máa jẹ́ ẹyọ hóró kan ṣoṣo; àmọ́ tó bá kú, ìgbà yẹn ló máa so èso púpọ̀.”—Jòhánù 12:23, 24.

Hóró àlìkámà tàbí wíìtì kan lè dà bí ohun tí kò níye lórí. Síbẹ̀, tí wọ́n bá gbin hóró yìí, ó máa “kú,” á hù, á sì so. Torí pé Jésù jẹ́ èèyàn pípé, òun ló dà bíi hóró kan yẹn. Bó sì ṣe jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run títí tó fi kú, ó máa ṣeé ṣe fún ọ̀pọ̀ èèyàn láti rí ìyè tí wọ́n bá fayé wọn sin Ọlọ́run bíi tiẹ̀. Jésù wá sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ràn ẹ̀mí rẹ̀ ń pa á run, àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá kórìíra ẹ̀mí rẹ̀ nínú ayé yìí máa pa á mọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun.”—Jòhánù 12:25.

Ohun tí Jésù sọ lẹ́yìn èyí fi hàn pé kò ro tara ẹ̀ nìkan, torí ó sọ pé: “Tí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ ṣe ìránṣẹ́ fún mi, kó máa tẹ̀ lé mi, ibi tí mo bá sì wà ni ìránṣẹ́ mi náà máa wà. Tí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ ṣe ìránṣẹ́ fún mi, Baba máa bọlá fún un.” (Jòhánù 12:26) Ẹ ò rí i pé èrè ńlá nìyẹn! Àwọn tí Baba bá bọlá fún máa làǹfààní láti bá Kristi jọba.

Nígbà tí Jésù ronú nípa ìyà tó máa jẹ òun àti bí wọ́n ṣe máa pa òun nípa ìkà, ó sọ pé: “Ní báyìí, ìdààmú bá mi, kí sì ni kí n sọ? Baba, gbà mí kúrò nínú wákàtí yìí.” Àmọ́, Jésù fẹ́ kí ìfẹ́ Baba rẹ̀ ṣẹ, ó wá sọ pé: “Síbẹ̀, torí èyí ni mo fi wá sí wákàtí yìí.” (Jòhánù 12:27) Gbogbo ohun tí Ọlọ́run fẹ́ kó ṣẹlẹ̀ ló bá Jésù lára mu, títí kan bí wọ́n ṣe máa pa á kó lè fi ẹ̀mí rẹ̀ rúbọ.