Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 121

“Ẹ Mọ́kàn Le! Mo Ti Ṣẹ́gun Ayé”

“Ẹ Mọ́kàn Le! Mo Ti Ṣẹ́gun Ayé”

JÒHÁNÙ 16:1-33

  • LÁÌPẸ́, ÀWỌN ÀPỌ́SÍTÉLÌ Ò NÍ RÍ JÉSÙ MỌ́

  • ÌBÀNÚJẸ́ ÀWỌN ÀPỌ́SÍTÉLÌ MÁA TÓ DI AYỌ̀

Ara àwọn àpọ́sítélì Jésù ti wà lọ́nà láti kúrò ní yàrá òkè níbi tí wọ́n ti ṣe ayẹyẹ Ìrékọjá. Lẹ́yìn tí Jésù fún wọn níṣìírí, ó sọ fún wọn pé: “Mo ti sọ àwọn nǹkan yìí fún yín, kí ẹ má bàa kọsẹ̀.” Kí nìdí tó fi fún wọn ní ìkìlọ̀ yìí? Ó sọ pé: “Àwọn èèyàn máa lé yín kúrò nínú sínágọ́gù. Kódà, wákàtí náà ń bọ̀, nígbà tí ẹnikẹ́ni tó bá pa yín máa rò pé ṣe lòun ń ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún Ọlọ́run.”—Jòhánù 16:1, 2.

Ó ṣeé ṣe kí ohun tí Jésù sọ yẹn mú kí ẹ̀rù bà wọ́n. Lóòótọ́ Jésù ti sọ fún wọn tẹ́lẹ̀ pé ayé máa kórìíra wọn, àmọ́ kò sọ fún wọn rí pé wọ́n máa pa wọ́n. Kí nìdí tí kò fi sọ fún wọn? Jésù sọ pé: “Mi ò kọ́kọ́ sọ àwọn nǹkan yìí fún yín, torí mo wà pẹ̀lú yín.” (Jòhánù 16:4) Ṣe ló ń múra wọn sílẹ̀ torí láìpẹ́ kò ní sí lọ́dọ̀ wọn mọ́. Bó ṣe sọ fún wọn yẹn ò ní jẹ́ kó bá wọn lójijì, wọn ò sì ní kọsẹ̀ lọ́jọ́ iwájú.

Lẹ́yìn náà, Jésù sọ pé: “Mò ń lọ sọ́dọ̀ Ẹni tó rán mi; síbẹ̀ ìkankan nínú yín ò bi mí pé, ‘Ibo lò ń lọ?’ ” Nírọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn, wọ́n ti ní kí Jésù sọ ibi tó ń lọ fún àwọn. (Jòhánù 13:36; 14:5; 16:5) Àmọ́ ní báyìí tí Jésù sọ pé wọ́n máa kojú inúnibíni, ẹ̀rù bẹ̀rẹ̀ sí í bà wọ́n. Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa ohun tójú wọn máa rí lọ́jọ́ iwájú, ìrònú sì sorí wọn kodò. Wọn ò tiẹ̀ rántí béèrè nípa irú ògo tí Jésù máa ní nígbà tó bá dé ọ̀run tàbí bí ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí i ṣe máa kan àwọn tó ń ṣe ìsìn tòótọ́. Jésù wá sọ pé: “Torí pé mo sọ àwọn nǹkan yìí fún yín, ẹ̀dùn ọkàn ti bá yín gidigidi.”—Jòhánù 16:6.

Lẹ́yìn náà, Jésù ṣàlàyé pé: “Torí yín ni mo ṣe ń lọ. Ìdí ni pé tí mi ò bá lọ, olùrànlọ́wọ́ náà ò ní wá sọ́dọ̀ yín; àmọ́ tí mo bá lọ, màá rán an sí yín.” (Jòhánù 16:7) Ó dìgbà tí Jésù bá kú, tó sì lọ sọ́run káwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tó lè gba ẹ̀bùn ẹ̀mí mímọ́ tó ṣèlérí fún wọn, ó sì dájú pé kò síbi táwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù wà láyé tí ẹ̀mí mímọ́ ò ti lè ràn wọ́n lọ́wọ́.

Ẹ̀mí mímọ́ tí Jésù ṣèlérí “máa fún ayé ní ẹ̀rí tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ nípa ẹ̀ṣẹ̀, nípa òdodo àti nípa ìdájọ́.” (Jòhánù 16:8) Ó máa hàn pé àwọn èèyàn kọ̀ láti nígbàgbọ́ nínú Ọmọ Ọlọ́run. Bí Jésù ṣe ń lọ sí ọ̀run máa jẹ́ kó hàn kedere pé olóòótọ́ ni, ìyẹn á sì jẹ́ ká rí ìdí tó fi yẹ kí Ọlọ́run mú ìdájọ́ tó lágbára wá sórí Sátánì tó jẹ́ “alákòóso ayé yìí.”—Jòhánù 16:11.

Jésù wá sọ pé: “Mo ṣì ní ọ̀pọ̀ nǹkan tí mo fẹ́ sọ fún yín, àmọ́ ẹ ò ní lè gbà á báyìí.” Ṣùgbọ́n nígbà tí Jésù bá tú ẹ̀mí mímọ́ jáde sórí wọn, ó máa ràn wọ́n lọ́wọ́ láti lóye “gbogbo òtítọ́,” ìyẹn á sì mú kó ṣeé ṣe fún wọn láti máa fí òtítọ́ yẹn sílò nígbèésí ayé wọn.—Jòhánù 16:12, 13.

Ohun tí Jésù sọ lẹ́yìn ìyẹn tún da gbogbo ọ̀rọ̀ rú mọ́ àwọn àpọ́sítélì yẹn lójú, ó sọ pé: “Ní ìgbà díẹ̀ sí i, ẹ ò ní rí mi mọ́, bákan náà, ní ìgbà díẹ̀ sí i, ẹ máa rí mi.” Ni wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí í béèrè ohun tí ọ̀rọ̀ Jésù túmọ̀ sí láàárín ara wọn. Jésù rí i pé ó ṣeé ṣe kí wọ́n fẹ́ béèrè lọ́wọ́ òun, torí náà ó ṣàlàyé fún wọn pé: “Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ẹ máa sunkún, ẹ sì máa pohùn réré ẹkún, àmọ́ ayé máa yọ̀; ẹ̀dùn ọkàn máa bá yín, àmọ́ ẹ̀dùn ọkàn yín máa di ayọ̀.” (Jòhánù 16:16, 20) Nígbà tí wọ́n pa Jésù, ṣe ni inú àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ń dùn, àmọ́ ṣe làwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ń ṣọ̀fọ̀ ní tiwọn. Ẹ̀dùn ọkàn wọn yẹn wá pa dà di ayọ̀ nígbà tí Ọlọ́run jí Jésù dìde. Ayọ̀ yìí sì wá pọ̀ sí i nígbà tí Ọlọ́run tú ẹ̀mí mímọ́ sórí wọn nígbà tó yá.

Jésù fi ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sáwọn àpọ́sítélì yẹn wé ìgbà tí obìnrin kan bá ń rọbí, ó sọ pé: “Tí obìnrin kan bá fẹ́ bímọ, ẹ̀dùn ọkàn máa ń bá a torí pé wákàtí rẹ̀ ti tó, àmọ́ tó bá ti bí ọmọ náà, kò ní rántí ìpọ́njú náà mọ́ torí inú rẹ̀ máa dùn pé a ti bí èèyàn kan sí ayé.” Jésù wá fún wọn níṣìírí, ó ní: “Bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ̀yin, ẹ̀dùn ọkàn bá yín báyìí; àmọ́ màá tún rí yín, inú yín sì máa dùn, ẹnì kankan ò sì ní gba ayọ̀ yín mọ́ yín lọ́wọ́.”—Jòhánù 16:21, 22.

Títí dìgbà tí Jésù fi ń bá wọn sọ̀rọ̀ yìí, àwọn àpọ́sítélì yẹn ò béèrè ohunkóhun lọ́wọ́ Ọlọ́run nípasẹ̀ Jésù rí. Torí náà, Jésù sọ fún wọn pé: “Ní ọjọ́ yẹn, ẹ máa béèrè nǹkan lọ́wọ́ Baba ní orúkọ mi.” Kí nìdí tó fi sọ bẹ́ẹ̀? Kì í ṣe pé Baba ò ní dá wọn lóhùn tí wọ́n bá béèrè. Torí Jésù sọ pé: “Baba fúnra rẹ̀ ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún yín, torí pé ẹ ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún mi . . . bí aṣojú Ọlọ́run.”—Jòhánù 16:26, 27.

Ohun tí Jésù sọ yẹn mú kí ara tu àwọn àpọ́sítélì yẹn, ni wọ́n bá sọ fún un pé: “Èyí mú ká gbà gbọ́ pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run lo ti wá.” Àmọ́ àdánwò tó ń bọ̀ láìpẹ́ máa jẹ́ kó hàn bóyá ohun tí wọ́n sọ yẹn dá wọn lójú lóòótọ́. Jésù wá ṣàlàyé ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí wọn, ó ní: “Ẹ wò ó! Wákàtí náà ń bọ̀, ní tòótọ́, ó ti dé, nígbà tí wọ́n máa tú ẹnì kọ̀ọ̀kan yín ká sí ilé rẹ̀, ẹ sì máa fi èmi nìkan sílẹ̀.” Síbẹ̀, ó fi dá wọn lójú pé: “Mo ti sọ àwọn nǹkan yìí fún yín kí ẹ lè ní àlàáfíà nípasẹ̀ mi. Ẹ máa ní ìpọ́njú nínú ayé, àmọ́ ẹ mọ́kàn le! Mo ti ṣẹ́gun ayé.” (Jòhánù 16:30-33) Kì í ṣe pé Jésù máa pa wọ́n tì. Ó dá a lójú pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun máa ṣẹ́gun ayé bí òun náà ṣe ṣẹ́gun ayé, ó mọ̀ pé wọ́n máa ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́ tọkàntọkàn láìka pé Sátánì àti ayé tó wà lábẹ́ ìdarí rẹ̀ máa gbìyànjú láti ba ìṣòtítọ́ wọn jẹ́.