Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 116

Jésù Kọ́ Wọn Lẹ́mìí Ìrẹ̀lẹ̀ Níbi Ìrékọjá Tó Ṣe Kẹ́yìn

Jésù Kọ́ Wọn Lẹ́mìí Ìrẹ̀lẹ̀ Níbi Ìrékọjá Tó Ṣe Kẹ́yìn

MÁTÍÙ 26:20 MÁÀKÙ 14:17 LÚÙKÙ 22:14-18 JÒHÁNÙ 13:1-17

  • JÉSÙ ÀTÀWỌN ÀPỌ́SÍTÉLÌ RẸ̀ JẸ ÌRÉKỌJÁ TÓ KẸ́YÌN

  • Ó KỌ́ ÀWỌN ÀPỌ́SÍTÉLÌ RẸ̀ LẸ́MÌÍ ÌRẸ̀LẸ̀ BÓ ṢE FỌ ẸSẸ̀ WỌN

Pétérù àti Jòhánù ti dé Jerúsálẹ́mù bí Jésù ṣe sọ fún wọn, kí wọ́n lè ṣètò Ìrékọjá. Ìgbà tó yá ni Jésù àtàwọn àpọ́sítélì mẹ́wàá yòókù wá bá wọn níbẹ̀ lọ́wọ́ ọ̀sán. Àmọ́, oòrùn ti ń rọjú díẹ̀díẹ̀ kí Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ tó sọ̀ kalẹ̀ látorí Òkè Ólífì. Jésù ò sì pa dà síbẹ̀ mọ́ títí tó fi kú, àfìgbà tó jíǹde.

Kò pẹ́ tí Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ fi dé Jerúsálẹ́mù, tí wọ́n sì forí lé ibi tí wọ́n ti fẹ́ jẹ Ìrékọjá. Nígbà tí wọ́n débẹ̀, wọ́n gòkè lọ sí yàrá ńlá tó wà lókè. Wọ́n rí i pé gbogbo ètò ti tò fún wọn láti jẹun láwọn nìkan. Jésù ti ń fojú sọ́nà fún àsìkò yìí, torí ó sọ pé: “Ó wù mí gan-an pé kí n jẹ Ìrékọjá yìí pẹ̀lú yín kí n tó jìyà.”—Lúùkù 22:15.

Ó pẹ́ tó ti jẹ́ àṣà àwọn Júù pé kí wọ́n máa gbé ife wáìnì láàárín ara wọn tí wọ́n bá ń jẹ Ìrékọjá. Wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ náà lọ́jọ́ yẹn, nígbà tí Jésù gba ife wáìnì kan, ó sọ pé: “Ẹ gbà, kí ẹ gbé e yí ká láàárín ara yín, torí mò ń sọ fún yín, láti ìsinsìnyí lọ, mi ò tún ní mu àwọn ohun tí wọ́n fi àjàrà ṣe mọ́ títí Ìjọba Ọlọ́run fi máa dé.” (Lúùkù 22:17, 18) Ó dájú pé ọjọ́ ikú ẹ̀ ti sún mọ́lé.

Bí wọ́n ṣe ń jẹ Ìrékọjá yẹn, ohun kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ ṣẹlẹ̀. Jésù dìde, ó bọ́ aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀ sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, ó sì mú aṣọ ìnura kan. Ó wá bu omi sínú abọ́ kan tó wà nítòsí. Bí wọ́n ṣe máa ń ṣe nígbà yẹn ni pé ẹni tó bá gbàlejò máa rán ìránṣẹ́ ẹ̀ pé kó fọ ẹsẹ̀ àwọn àlejò. (Lúùkù 7:44) Àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí, ẹni tó gbà wọ́n lálejò ò sí níbẹ̀, torí náà, Jésù ló ṣe iṣẹ́ yìí. Kò séyìí tí ò lè ṣiṣẹ́ yẹn nínú àwọn àpọ́sítélì, àmọ́ kò sẹ́ni tó dìde nínú wọn. Ṣé kì í ṣe torí pé wọ́n ṣì ní ara wọn sínú? Èyí ó wù kó jẹ́, ojú tì wọ́n nígbà tí wọ́n rí i tí Jésù ń fọ ẹsẹ̀ wọn.

Nígbà tí Jésù dé ọ̀dọ̀ Pétérù, kò fẹ́ gbà, ó ní: “O ò ní fọ ẹsẹ̀ mi láéláé.” Jésù wá sọ fún un pé: “Láìjẹ́ pé mo fọ ẹsẹ̀ rẹ, o ò ní ìpín kankan lọ́dọ̀ mi.” Ni Pétérù bá fi gbogbo ẹnu dáhùn pé: “Olúwa, kì í ṣe ẹsẹ̀ mi nìkan lo máa fọ̀, tún fọ ọwọ́ mi àti orí mi.” Àmọ́ ó yà á lẹ́nu nígbà tí Jésù sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tó bá ti wẹ̀, kò nílò ju ká fọ ẹsẹ̀ rẹ̀ lọ, torí ó mọ́ látòkè délẹ̀. Ẹ̀yin mọ́, àmọ́ kì í ṣe gbogbo yín.”—Jòhánù 13:8-10.

Gbogbo wọn ni Jésù fọ ẹsẹ̀ wọn, títí kan Júdásì Ìsìkáríọ́tù. Lẹ́yìn náà, Jésù wọ aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀ pa dà, ó sì jókòó sídìí tábìlì, ó wá bi wọ́n pé: “Ṣé ohun tí mo ṣe fún yín yé yín? Ẹ̀ ń pè mí ní ‘Olùkọ́’ àti ‘Olúwa,’ òótọ́ lẹ sì sọ, torí ohun tí mo jẹ́ nìyẹn. Torí náà, tí èmi, tí mo jẹ́ Olúwa àti Olùkọ́, bá fọ ẹsẹ̀ yín, ó yẹ kí ẹ̀yin náà máa fọ ẹsẹ̀ ara yín. Torí mo fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún yín pé, bí mo ṣe ṣe fún yín gẹ́lẹ́ ni kí ẹ̀yin náà máa ṣe. Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ẹrú ò tóbi ju ọ̀gá rẹ̀ lọ, ẹni tí a rán jáde kò sì tóbi ju ẹni tó rán an. Tí ẹ bá mọ àwọn nǹkan yìí, aláyọ̀ ni yín tí ẹ bá ń ṣe wọ́n.”—Jòhánù 13:12-17.

Ohun tí Jésù ṣe yìí jẹ́ àpẹẹrẹ tó ta yọ fún wọn pé kí wọ́n lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀! Wọ́n rí i pé kò yẹ káwọn máa wá ire ara wọn ṣáájú ti ẹlòmíì tàbí kí wọ́n ka ara wọn sí pàtàkì jù, kí wọ́n sì máa retí káwọn míì sìn wọ́n. Dípò ìyẹn, ṣe ló yẹ kí wọ́n tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, kì í ṣe pé kí wọ́n máa fọ ẹsẹ̀ àwọn èèyàn àmọ́ kí wọ́n ṣe tán láti fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ran àwọn míì lọ́wọ́, kí wọ́n má sì máa wo ojú kí wọ́n tó ṣe oore.