Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

102

Ọba Gun Ọmọ Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Wọ Jerúsálẹ́mù

Ọba Gun Ọmọ Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Wọ Jerúsálẹ́mù

MÁTÍÙ 21:1-11, 14-17 MÁÀKÙ 11:1-11 LÚÙKÙ 19:29-44 JÒHÁNÙ 12:12-19

  • WỌ́N YẸ́ JÉSÙ SÍ BÓ ṢE Ń WỌ JERÚSÁLẸ́MÙ

  • JÉSÙ SỌ TẸ́LẸ̀ PÉ JERÚSÁLẸ́MÙ MÁA PA RUN

Lọ́jọ́ kejì, ìyẹn Sunday, Nísàn 9, Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ kúrò ní Bẹ́tánì lọ sí Jerúsálẹ́mù. Bí wọ́n ṣe ń sún mọ́ Bẹtifágè, ní Òkè Ólífì, Jésù sọ fún méjì nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ pé:

“Ẹ lọ sínú abúlé ọ̀ọ́kán yìí, gbàrà tí ẹ bá débẹ̀, ẹ máa rí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan tí wọ́n so àti ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tó wà pẹ̀lú rẹ̀. Ẹ tú wọn, kí ẹ sì mú wọn wá fún mi. Tí ẹnì kan bá bá yín sọ ohunkóhun, kí ẹ sọ pé, ‘Olúwa fẹ́ lò wọ́n.’ Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló máa fi wọ́n ránṣẹ́.”—Mátíù 21:2, 3.

Àwọn ọmọ ẹ̀yìn yẹn ò mọ̀ pé ohun tí Jésù ní kí wọ́n ṣe yìí bá àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì mu. Ìgbà tó yá ni wọ́n wá mọ̀ pé àsọtẹ́lẹ̀ Sekaráyà ló ń ṣẹ. Ó sọ tẹ́lẹ̀ pé Ọba tí Ọlọ́run ṣèlérí máa wọ Jerúsálẹ́mù, ó “jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ó sì ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àní ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ọmọ abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.”—Sekaráyà 9:9.

Nígbà táwọn ọmọ ẹ̀yìn náà dé Bẹtifágè, wọ́n tú akọ ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà àti ìyá rẹ̀. Làwọn tó wà nítòsí bá bi wọ́n pé: “Kí ló dé tí ẹ̀ ń tú ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà?” (Máàkù 11:5) Nígbà tí wọ́n gbọ́ pé Olúwa ló fẹ́ lò ó, wọ́n gbà káwọn ọmọ ẹ̀yìn náà mú àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ yẹn lọ fún Jésù. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn wá tẹ́ aṣọ àwọ̀lékè wọn sórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà àti ọmọ rẹ̀, àmọ́ orí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ yẹn ni Jésù jókòó lé.

Bí Jésù ṣe ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ yẹn wọ Jerúsálẹ́mù, bẹ́ẹ̀ làwọn tó ń tẹ̀ lé e ń pọ̀ sí i. Àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ́ aṣọ wọn sójú ọ̀nà. Àwọn míì lára wọn gé ẹ̀ka igi “tó ní ewé látinú pápá,” wọ́n sì tẹ́ ẹ sójú ọ̀nà. Wọ́n ń pariwo pé: “A bẹ̀ ọ́, gbà là! Ìbùkún ni fún ẹni tó ń bọ̀ ní orúkọ Jèhófà! Ìbùkún ni fún Ìjọba Dáfídì bàbá wa tó ń bọ̀!” (Máàkù 11:8-10) Ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ yẹn ń bí àwọn Farisí tó wà níbẹ̀ nínú. Wọ́n wá sọ fún Jésù pé: “Olùkọ́, bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ wí.” Jésù dáhùn pé: “Mò ń sọ fún yín, tí àwọn yìí bá dákẹ́, àwọn òkúta máa ké jáde.”—Lúùkù 19:39, 40.

Bí Jésù ṣe ń wo Jerúsálẹ́mù lọ́ọ̀ọ́kán, ó bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún, ó sì sọ pé: “Ká sọ pé ìwọ, àní ìwọ, ti fòye mọ àwọn ohun tó jẹ mọ́ àlàáfíà ní ọjọ́ yìí ni, àmọ́ a ti fi wọ́n pa mọ́ kúrò ní ojú rẹ báyìí.” Àwọn ará Jerúsálẹ́mù máa jìyà bí wọ́n ṣe mọ̀ọ́mọ̀ jẹ́ aláìgbọràn. Jésù sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí wọn, ó ní: “Àwọn ọ̀tá rẹ máa fi àwọn igi olórí ṣóńṣó ṣe odi yí ọ po, wọ́n máa yí ọ ká, wọ́n á sì dó tì ọ́ yí ká. Wọ́n máa fọ́ ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ tó wà nínú rẹ mọ́lẹ̀, wọn ò sì ní fi òkúta kan sílẹ̀ lórí òkúta kan nínú rẹ.” (Lúùkù 19:42-44) Ohun tó sì ṣẹlẹ̀ nìyẹn, nígbà tó di ọdún 70 S.K. Jerúsálẹ́mù pa run.

Nígbà tí Jésù wọ Jerúsálẹ́mù, ‘ariwo sọ ní gbogbo ìlú náà, wọ́n ń sọ pé: “Ta nìyí?”’ Àwọn èèyàn kàn ń sọ pé: “Jésù nìyí, wòlíì tó wá láti Násárẹ́tì ti Gálílì!” (Mátíù 21:10, 11) Àwọn tó wà níbẹ̀ nígbà tí Jésù jí Lásárù dìde bẹ̀rẹ̀ sí í ròyìn ohun tó ṣẹlẹ̀ fáwọn míì. Bẹ́ẹ̀ ló ń ká àwọn Farisí yẹn lára pé àwọn èèyàn ò gba tàwọn mọ́. Wọ́n wá ń sọ fún ara wọn pé: “Gbogbo ayé ti gba tiẹ̀.”—Jòhánù 12:18, 19.

Jésù wá lọ sí tẹ́ńpìlì láti kọ́ àwọn èèyàn, bó ṣe máa ń ṣe tó bá ti wá sí Jerúsálẹ́mù nìyẹn. Níbẹ̀, ó la ojú àwọn afọ́jú, ó sì wo àwọn arọ sàn. Nígbà táwọn olórí àlùfáà àtàwọn akọ̀wé òfin rí gbogbo ohun tó ń ṣe, tí wọ́n sì gbọ́ táwọn ọmọdé ń kígbe nínú tẹ́ńpìlì pé: “A bẹ̀ ọ́, gba Ọmọ Dáfídì là!” inú bí wọn gidigidi. Làwọn aṣáájú ẹ̀sìn bá bi Jésù pé: “Ṣé o gbọ́ ohun tí àwọn yìí ń sọ?” Jésù dá wọn lóhùn pé: “Ṣé ẹ ò kà á rí pé, ‘Láti ẹnu àwọn ọmọdé àti àwọn ọmọ jòjòló lo ti mú kí ìyìn jáde’?”—Mátíù 21:15, 16.

Jésù wá wo àwọn ohun tó wà nínú tẹ́ńpìlì yí ká. Àmọ́ torí pé ọjọ́ ti lọ, òun àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ kúrò níbẹ̀. Kó tó di Nísàn 10, ó ti pa dà sí Bẹ́tánì. Ibẹ̀ ló sùn mọ́jú lálẹ́ Sunday yẹn.