Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọ̀nà, Òtítọ́ àti Ìyè

Ọ̀nà, Òtítọ́ àti Ìyè

Ó dájú pé inú ẹ máa dùn láti gbọ́ ìròyìn ayọ̀. A fẹ́ kó o mọ̀ pé ìròyìn ayọ̀ wà fún ìwọ àtàwọn tó sún mọ́ ẹ.

Inú Bíbélì ni ìròyìn ayọ̀ yìí wà, Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ Ẹlẹ́dàá ọ̀run àti ayé ló sì mú kí wọ́n kọ ìwé yìí ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn. Nínú ìtẹ̀jáde yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa mẹ́rin nínú àwọn ìwé tó wà nínú Bíbélì, àá sì rí ìròyìn ayọ̀ tó wà fún gbogbo èèyàn níbẹ̀. Orúkọ àwọn tí Ọlọ́run lò láti kọ ìwé mẹ́rin yìí ni wọ́n fi pè wọ́n, ìyẹn Mátíù, Máàkù, Lúùkù àti Jòhánù.

Ìwé Ìhìn Rere ni ọ̀pọ̀ sábà máa ń pe ìwé mẹ́rẹ̀ẹ̀rin yìí. Ìhìn rere tàbí ìròyìn ayọ̀ nípa Jésù làwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀, wọ́n jẹ́ ká mọ̀ pé òun ni Ọlọ́run lò láti gba aráyé là, òun ni Ọba Ìjọba Ọlọ́run, òun kan náà ni Ọlọ́run máa tipasẹ̀ rẹ̀ rọ̀jò ìbùkún ayérayé sórí gbogbo àwọn tó bá nígbàgbọ́ nínú rẹ̀.—Máàkù 10:17, 30; 13:13.

KÍ NÌDÍ TÍ WỌ́N FI JẸ́ MẸ́RIN?

Ó ṣeé ṣe kó o máa ronú pé kí nìdí tí Ọlọ́run fi lo odindi èèyàn mẹ́rin láti kọ ìtàn ìgbésí ayé Jésù àtohun tó fi kọ́ni.

Ọ̀pọ̀ àǹfààní ló wà nínú bó ṣe jẹ́ pé àwọn tó kọ ìtàn nípa Jésù ju ẹyọ kan lọ. Jẹ́ ká ṣàpèjúwe ẹ̀ báyìí, ká ní àwọn ọkùnrin mẹ́rin ń kọ ohun tí wọ́n mọ̀ nípa olùkọ́ kan sílẹ̀. Agbowó orí ni ọ̀kàn nínú wọn, èkejì jẹ́ Dókítà, Apẹja lẹnì kẹta, ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ ló sì jẹ́ sí olùkọ́ yẹn. Ẹnì kẹrin ló kéré jù láàárín wọn, ó sì ti fara balẹ̀ kíyè sí irú ẹni tí olùkọ́ náà jẹ́. Àwọn ọkùnrin mẹ́rẹ̀ẹ̀rin yìí ṣeé fọkàn tán, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ló sì sọ ohun pàtó tí wọ́n fẹ́ràn nípa olùkọ́ yẹn. Ó dájú pé àlàyé wọn máa yàtọ̀ síra. Àmọ́ tẹ́ni tó ń ka ìtàn tí wọ́n kọ bá fi sọ́kàn pé ẹnì kan ṣoṣo kọ́ ló kọ ìtàn náà, á gbà pé àlàyé wọn máa yàtọ̀ síra, ìyẹn á sì mú kó dá a lójú pé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé lòhun ní nípa olùkọ́ náà. Àpèjúwe yìí jẹ́ ká rí i pé a máa jàǹfààní gan-an bó ṣe jẹ́ pé àwọn mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló ṣàkọsílẹ̀ ìtàn nípa Jésù Olùkọ́ Ńlá náà.

Bíi ti àpèjúwe yẹn, agbowó orí ni ọ̀kan lára àwọn tó kọ ìtàn nípa Jésù, ó sì sọ ọ́ lọ́nà tó máa fa àwọn Júù mọ́ra. Èyí dókítà ní tiẹ̀ tẹnu mọ́ àwọn ìṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe. Torí náà, ọ̀pọ̀ nǹkan tí agbowó orí yẹn sọ lòun ò sọ ní tiẹ̀, bákan náà kò to ìtàn náà bí agbowó orí yẹn ṣe tò ó. Àwọn ànímọ́ Jésù àti bó ṣe ń hùwà sáwọn èèyàn ni èyí tó sún mọ́ Jésù jù lára wọn tẹnu mọ́. Ní ti ọ̀dọ́kùnrin kẹrin, ṣókí lọ̀rọ̀ tiẹ̀, àmọ́ àkọsílẹ̀ rẹ̀ wọni lọ́kàn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ wọn yàtọ̀ síra, òótọ́ lohun tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn kọ látòkèdélẹ̀, kò sí àbùmọ́ níbẹ̀. Ṣé ẹ wá rí i pé ó dáa bó ṣe jẹ́ pé ẹni mẹ́rin ló sọ̀rọ̀ nípa Jésù, torí wọ́n mú ká túbọ̀ lóye irú ẹni tí Jésù jẹ́, ohun tó fi kọ́ni àtàwọn ohun tó ṣe.

Àwọn èèyàn máa ń sọ̀rọ̀ nípa ‘Ìhìn Rere Mátíù’ tàbí ‘Ìhìn Rere Jòhánù.’ Kò burú tí wọ́n bá sọ bẹ́ẹ̀, ó ṣe tán “ìhìn rere nípa Jésù Kristi” ni gbogbo wọn sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀. (Máàkù 1:1) Àmọ́ tá a bá fojú bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí gan-an wò ó, àá rí i pé ìhìn rere tàbí ìròyìn ayọ̀ nípa ẹnì kan ṣoṣo, ìyẹn Jésù làwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin sọ.

Ọ̀pọ̀ àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ló ti gbé àwọn àkọsílẹ̀ Mátíù, Máàkù, Lúùkù àti Jòhánù yẹ̀ wò, wọ́n fi ìtàn wọn wéra, wọ́n sì gbìyànjú láti tò wọ́n bí wọ́n ṣe ṣẹlẹ̀. Ọ̀kan lára àwọn tó ṣe bẹ́ẹ̀ ni òǹkọ̀wé ọmọ ilẹ̀ Síríà kan tó ń jẹ́ Tatian lọ́dún 170 S.K. Ó gbà pé ìwé mẹ́rẹ̀ẹ̀rin péye, Ọlọ́run ló sì mí sí i, ìyẹn ló mú kó ṣe ìwé tó pè ní Diatessaron, tó fi sọ ìtàn Jésù àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ bí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe ṣẹlẹ̀ tẹ̀ léra.

Ohun kan náà ni ìwé Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ àti Ìyè ṣe, àmọ́ ìwé yìí péye, ó sì kún rẹ́rẹ́ ju ìwé tí ọkùnrin yẹn ṣe lọ. Ìdí ni pé ọ̀pọ̀ lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Jésù ló ti ṣẹ, a sì ti túbọ̀ lóye àwọn àpèjúwe rẹ̀. Òye tá a ní yìí ló mú káwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ àtohun tó ṣe túbọ̀ ṣe kedere, a sì wá rí báwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe tò tẹ̀ léra. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn awalẹ̀pìtàn ti ṣàwárí àwọn nǹkan kan tó mú ká túbọ̀ lóye àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ kan àti èrò àwọn tó kọ Ìwé Ìhìn Rere náà. Ká sòótọ́, kò sẹ́ni tó lè fi gbogbo ẹnu sọ bí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn ṣe tò tẹ̀ léra. Àmọ́, a rí i pé ìwé Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ àti Ìyè sọ ìtàn náà lọ́nà tó bọ́gbọ́n mu.

Ọ̀NÀ, ÒTÍTỌ́ ÀTI ÌYÈ

Bó o ṣe ń ka ìwé yìí ní àkàgbádùn, máa wo bí ìtàn náà ṣe kan ìwọ àtàwọn tó sún mọ́ ẹ. Má sì gbàgbé ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fún àpọ́sítélì Tọ́másì pé: “Èmi ni ọ̀nà àti òtítọ́ àti ìyè. Kò sí ẹni tó ń wá sọ́dọ̀ Baba àfi nípasẹ̀ mi.”—Jòhánù 14:6.

Ìwé Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ àti Ìyè máa jẹ́ kó o túbọ̀ mọrírì bí Jésù ṣe jẹ́ “ọ̀nà.” Torí pé ipasẹ̀ rẹ̀ nìkan la fi lè gbàdúrà sí Jèhófà Ọlọ́run. Bákan náà, Jésù ló ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún wa ká lè pa dà bá Ọlọ́run rẹ́. (Jòhánù 16:23; Róòmù 5:8) Torí náà, ipasẹ̀ Jésù nìkan la lè gbà ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run.

Jésù ni “òtítọ́.” Gbogbo ìgbà ló máa ń sọ òtítọ́, gbogbo ohun tó ń ṣe ló sì jẹ́ òtítọ́ látòkèdélẹ̀, àfi bíi pé òtítọ́ ni Jésù gan-an fúnra rẹ̀. Ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ ló ṣẹ sí Jésù lára, wọ́n sì di “‘bẹ́ẹ̀ ni’ nípasẹ̀ rẹ̀.” (2 Kọ́ríńtì 1:20; Jòhánù 1:14) Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yẹn jẹ́ ká túbọ̀ mọyì ohun tí Jésù ṣe láti mú ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ.—Ìfihàn 19:10.

Yàtọ̀ síyẹn, Jésù ni “ìyè.” Òun ló fi ẹ̀mí ara rẹ̀ lélẹ̀ kó lè rà wá pa dà, ìyẹn sì mú kó ṣeé ṣe fún wa láti rí “ìyè tòótọ́,” tàbí “ìyè àìnípẹ̀kun.” (1 Tímótì 6:12, 19; Éfésù 1:7; 1 Jòhánù 1:7) Ó tún máa jẹ́ “ìyè” fún àwọn tó ti kú ní ti pé ó máa jí wọn dìde, á sì mú kí wọ́n wà láàyè títí láé nínú Párádísè.—Jòhánù 5:28, 29.

Ó ṣe pàtàkì pé kí gbogbo wa mọyì ipa ribiribi tí Jésù ń kó láti mú ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ. Torí náà, a rọ̀ ẹ́ pé kó o túbọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jésù tó jẹ́ ‘ọ̀nà, òtítọ́ àti ìyè.’