Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Tó O Bá Fẹ́ Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jésù, Ó Yẹ Kó O . . .

Tó O Bá Fẹ́ Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jésù, Ó Yẹ Kó O . . .

MÁA ṢÀÁNÚ

Àwọn èèyàn máa ń ní ẹ̀dùn ọkàn, wọ́n sì máa ń ṣàníyàn. Àmọ́ ọ̀rọ̀ Jésù ò rí bẹ́ẹ̀ torí pé ẹni pípé ni. Síbẹ̀, ó máa ń fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn dénú. Ó múra tán láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, kódà ó máa ń ṣe kọjá ohun táwọn èèyàn retí. Àánú tó ní sáwọn èèyàn ló ń sún un láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Wàá rí àpẹẹrẹ bí Jésù ṣe ṣe èyí ní Orí 32, 37, 57, 99.

JẸ́ ẸNI TÓ ṢEÉ SÚN MỌ́

Ó rọrùn fún tọmọdé tàgbà láti sún mọ́ Jésù torí pé Jésù máa ń wáyè fún wọn, kò sì ka ara rẹ̀ sí pàtàkì jù wọ́n lọ. Torí pé àwọn èèyàn mọ̀ pé Jésù ò fọ̀rọ̀ àwọn ṣeré, ara máa ń tù wọ́n tí wọ́n bá wà lọ́dọ̀ rẹ̀. Kó o lè mọ bí Jésù ṣe ṣe èyí, wo Orí 25, 27, 95.

MÁA GBÀDÚRÀ NÍGBÀ GBOGBO

Jésù máa ń gbàdúrà àtọkànwá sí Baba rẹ̀ déédéé, ó sì máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tó bá dá wà àti nígbà tó bá wà láàárín àwọn olùjọsìn tòótọ́. Gbogbo ìgbà ni Jésù máa ń gbàdúrà, kì í ṣe ìgbà tó bá fẹ́ jẹun nìkan. Nínú àdúrà rẹ̀, ó máa ń dúpẹ́, á yin Baba rẹ̀, ó sì máa ń béèrè fún ìtọ́sọ́nà Baba rẹ̀ tó bá fẹ́ ṣe àwọn ìpinnu tó lágbára. Wàá rí àpẹẹrẹ èyí ní Orí 24, 34, 91, 122, 123.

MÁA WÁ IRE ÀWỌN MÍÌ

Láwọn ìgbà tó yẹ kí Jésù sinmi kó sì gbádùn ara rẹ̀, ṣe ló máa ń wá bó ṣe máa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Kò mọ tara ẹ̀ nìkan. Àpẹẹrẹ àtàtà tó yẹ ká máa tẹ̀ lé ni Jésù jẹ́. Wàá rí bí Jésù ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀ ní Orí 19, 41, 52.

MÁA DÁRÍ JINI

Jésù ò kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa dárí jini nìkan, òun náà máa ń dárí jì wọ́n, ó sì máa ń dárí ji àwọn míì. Wàá rí bó ṣe ṣe bẹ́ẹ̀ ní Orí 26, 40, 64, 85, 131.

JẸ́ ONÍTARA

Àsọtẹ́lẹ̀ ti wà pé àwọn Júù ò ní gbà pé Jésù ni Mèsáyà àti pé àwọn ọ̀tá ló máa pa á. Torí náà Jésù lè yàn pé òun ò ní lo gbogbo okun òun fáwọn èèyàn. Àmọ́ kò ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe ló fìtara ti ìjọsìn tòótọ́ lẹ́yìn. Ó fi àpẹẹrẹ àtàtà lélẹ̀ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, kí wọ́n máa fìtara wàásù báwọn èèyàn tiẹ̀ ń ta kò wọ́n, tí wọ́n sì ń ṣenúnibíni sí wọn. Wo Orí 16, 72, 103.

NÍ Ẹ̀MÍ ÌRẸ̀LẸ̀

Jésù gbọ́n gan-an, ó sì mọ ọ̀pọ̀ nǹkan ju àwa èèyàn aláìpé lọ fíìfíì. Ẹni pípé ni, torí náà ara rẹ̀ dá ṣáṣá, ọpọlọ rẹ̀ sì pé ju tàwọn tó wà láyìíká rẹ̀ lọ. Síbẹ̀ ó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, ó sì ṣe tán láti sin àwọn míì. Wàá kẹ́kọ̀ọ́ nípa èyí ní Orí 10, 62, 66, 94, 116.

NÍ SÙÚRÙ

Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jésù máa ń mú sùúrù fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ àtàwọn míì nígbà tí wọn ò bá tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀ tàbí ṣe ohun tó sọ. Ó máa ń fara balẹ̀ kọ́ wọn kí wọ́n lè mọ ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe, kí wọ́n sì lè sún mọ́ Jèhófà. Kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí Jésù ṣe jẹ́ onísùúrù ní Orí 74, 98, 118, 135.