Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

APÁ 6 • ÌṢE 15:36–18:22

“Ní Báyìí, Jẹ́ Ká Pa Dà Lọ Bẹ Àwọn Ará Wò”

“Ní Báyìí, Jẹ́ Ká Pa Dà Lọ Bẹ Àwọn Ará Wò”

ÌṢE 15:36

Kí ni iṣẹ́ pàtàkì táwọn alábòójútó àyíká máa ń ṣe nínú ìjọ Kristẹni? Àǹfààní wo la máa rí tá a bá fi tọkàntọkàn tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ tí wọ́n bá fún wa nínú ètò Ọlọ́run? Báwo la ṣe lè máa fèròwérò lọ́nà tó gbéṣẹ́ látinú Ìwé Mímọ́, kí sì nìdí tó fi yẹ ká jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wa bá ipò àwọn olùgbọ́ wa mu? A máa rí ìdáhùn àwọn ìbéèrè yìí àtàwọn ìbéèrè míì bá a ṣe ń ṣàyẹ̀wò ìrìn àjò míṣọ́nnárì ẹlẹ́ẹ̀kejì tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rìn.