Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 17

‘Ó Bá Wọn Fèròwérò Látinú Ìwé Mímọ́’

‘Ó Bá Wọn Fèròwérò Látinú Ìwé Mímọ́’

Ohun tó lè mú ká mọ̀ọ̀yàn kọ́ dáadáa; àpẹẹrẹ rere àwọn ará Bèróà

Ó dá lórí Ìṣe 17:1-15

1, 2. Àwọn wo ló ń ti ìlú Fílípì lọ sí Tẹsalóníkà, kí ló sì ṣeé ṣe kí wọ́n máa rò?

 ÀWỌN èèyàn máa ń gba ọ̀nà táwọn òṣìṣẹ́ onímọ̀ ẹ̀rọ ará Róòmù là gba àárín àwọn òkè gbágungbàgun kọjá. Ariwo máa ń pọ̀ gan-an lójú ọ̀nà yìí. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ máa ń pariwo, àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ máa ń dún lórí òkúta, àwọn arìnrìn-àjò, tó ṣeé ṣe kó jẹ́ àwọn ọmọ ogun, àwọn oníṣòwò, àtàwọn oníṣẹ́ ọnà máa ń bá ara wọn sọ̀rọ̀. Ojú ọ̀nà yìí ni Pọ́ọ̀lù, Sílà àti Tímótì gbà bí wọ́n ṣe ń rìnrìn àjò tó lé ní àádóje (130) kìlómítà láti ìlú Fílípì lọ sí Tẹsalóníkà. Ìrìn àjò yìí ò dẹrùn rárá pàápàá fún Pọ́ọ̀lù àti Sílà, torí egbò táwọn ará Fílípì dá sí wọn lára nígbà tí wọ́n fi ọ̀pá lù wọ́n ò tíì jinná.​—Ìṣe 16:22, 23.

2 Kí ni ò jẹ́ kí ìrìn àjò yẹn sú àwọn ọkùnrin yìí? Ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń sọ bí wọ́n ṣe ń rìn lọ lójú ọ̀nà ni. Inú wọn tún ń dùn pé ẹni tó ń ṣọ́ àwọn ẹlẹ́wọ̀n nílùú Fílípì yẹn àti ìdílé ẹ̀ di Kristẹni. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí ti jẹ́ kí wọ́n pinnu pé àwọn á máa wàásù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nìṣó. Àmọ́, bí wọ́n ṣe ń sún mọ́ ìlú Tẹsalóníkà tó wà ní etíkun, ó ṣeé ṣe kí wọ́n máa ronú nípa ohun táwọn Júù tó wà nílùú náà á ṣe sí wọn. Ṣé wọ́n á ṣe bíi tàwọn ará ìlú Fílípì, kí wọ́n gbéjà kò wọ́n, kí wọ́n sì lù wọ́n bolẹ̀?

3. Báwo ni àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ lóde òní ká lè nígboyà tá a bá fẹ́ wàásù?

3 Nígbà tó yá, Pọ́ọ̀lù sọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára ẹ̀ nínú lẹ́tà tó kọ sáwọn Kristẹni tó wà ní Tẹsalóníkà pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti kọ́kọ́ jìyà, tí wọ́n sì hùwà àfojúdi sí wa ní ìlú Fílípì, bí ẹ̀yin náà ṣe mọ̀, Ọlọ́run wa mú kí a mọ́kàn le kí a lè sọ ìhìn rere Ọlọ́run fún yín lójú ọ̀pọ̀ àtakò.” (1 Tẹs. 2:2) Ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ yìí fi hàn pé ó lè ti máa ronú nípa ìṣòro tó tún lè bá pàdé ní Tẹsalóníkà bó ṣe fẹ́ wọbẹ̀, lẹ́yìn ohun tójú ẹ̀ rí nílùú Fílípì. Ṣé o mọ bí ọ̀rọ̀ náà á ṣe rí lára Pọ́ọ̀lù? Ṣé ó máa ń ṣòro fún ẹ láti wàásù ìhìn rere? Pọ́ọ̀lù gbà pé Jèhófà máa fún òun lókun, á sì ran òun lọ́wọ́ kóun lè ní ìgboyà. Tó o bá kẹ́kọ̀ọ́ nípa Pọ́ọ̀lù, ìyẹn á ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀.​—1 Kọ́r. 4:16.

Ó “Fèròwérò Látinú Ìwé Mímọ́” (Ìṣe 17:1-3)

4. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé Pọ́ọ̀lù lò ju ọ̀sẹ̀ mẹ́ta lọ nílùú Tẹsalóníkà?

4 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Pọ́ọ̀lù wàásù nínú sínágọ́gù fún Sábáàtì mẹ́ta nígbà tó wà nílùú Tẹsalóníkà. Àmọ́, ìyẹn ò wá túmọ̀ sí pé ọ̀sẹ̀ mẹ́ta péré ló lò nílùú yẹn. A ò mọ ìgbà tí Pọ́ọ̀lù lọ sínú sínágọ́gù lẹ́yìn tó dé ìlú Tẹsalóníkà. Yàtọ̀ síyẹn, Pọ́ọ̀lù sọ nínú lẹ́tà tó kọ pé òun àtàwọn tí wọ́n jọ rìnrìn àjò ṣiṣẹ́ káwọn lè bójú tó ara àwọn nígbà táwọn wà ní Tẹsalóníkà. (1 Tẹs. 2:9; 2 Tẹs. 3:7, 8) Bákan náà, nígbà tí Pọ́ọ̀lù ṣì wà níbẹ̀, ẹ̀ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló rí ẹ̀bùn gbà látọ̀dọ̀ àwọn ará tó wà nílùú Fílípì. (Fílí. 4:16) Torí náà, ó ṣeé ṣe kó lò ju ọ̀sẹ̀ mẹ́ta lọ nílùú Tẹsalóníkà.

5. Kí ni Pọ́ọ̀lù ṣe kí ọ̀rọ̀ ẹ̀ bàa lè wọ àwọn èèyàn lọ́kàn?

5 Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù ti ṣọkàn akin láti wàásù, ó lọ báwọn tó wà nínú sínágọ́gù sọ̀rọ̀. Bí àṣà rẹ̀, “ó . . . bá wọn fèròwérò látinú Ìwé Mímọ́, ó ń ṣàlàyé, ó sì ń tọ́ka sí àwọn ohun tó fi ẹ̀rí hàn pé ó pọn dandan kí Kristi jìyà, kí ó sì dìde kúrò nínú ikú, ó sọ pé: ‘Èyí ni Kristi náà, Jésù tí mò ń kéde fún yín.’ ” (Ìṣe 17:2, 3) Bí ẹsẹ yìí ṣe sọ, Pọ́ọ̀lù ò fọ̀rọ̀ gún àwọn èèyàn náà lára, àmọ́ ṣe ló sọ̀rọ̀ lọ́nà táá fi wọ̀ wọ́n lọ́kàn. Ó mọ̀ pé àwọn tó wá sí sínágọ́gù náà mọ Ìwé Mímọ́, wọ́n sì ń tẹ̀ lé ohun tó bá sọ. Àmọ́, ó níbi tí òye wọ́n mọ. Ìyẹn ló mú kí Pọ́ọ̀lù báwọn fèròwérò, tó ṣàlàyé, tó sì tọ́ka sí àwọn ẹ̀rí látinú Ìwé Mímọ́ tó fi hàn pé Jésù ará Násárétì ni Mèsáyà tàbí Kristi náà tí Ọlọ́run ṣèlérí.

6. Báwo ni Jésù ṣe fèròwérò látinú Ìwé Mímọ́, kí lèyí sì yọrí sí?

6 Jésù máa ń fi ohun tó wà nínú Ìwé Mímọ́ kọ́ àwọn èèyàn, ohun tí Pọ́ọ̀lù náà sì ṣe nìyẹn. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Jésù wà láyé, ó sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ pé Ìwé Mímọ́ sọ pé Ọmọ èèyàn gbọ́dọ̀ jìyà, kó kú, kó sì jíǹde. (Mát. 16:21) Nígbà tí Jésù sì jíǹde, ó fara han àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀. Ohun tó ṣe yìí máa jẹ́ kó dá àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ lójú pé òótọ́ ló sọ. Síbẹ̀, Jésù tún fún wọn ní ọ̀pọ̀ ẹ̀rí kí wọ́n lè gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbọ́. Bíbélì tiẹ̀ jẹ́ ká mọ ọ̀nà tó gbà kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀, ó ní: “Ó bẹ̀rẹ̀ látọ̀dọ̀ Mósè àti gbogbo àwọn Wòlíì, ó sì túmọ̀ àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ òun fúnra rẹ̀ nínú gbogbo Ìwé Mímọ́ fún wọn.” Kí lèyí wá yọrí sí? Ẹnu ya àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà, wọ́n sì sọ pé: “Àbí ẹ ò rí i bí ọkàn wa ṣe ń jó fòfò nínú wa bó ṣe ń bá wa sọ̀rọ̀ lójú ọ̀nà, tó ń ṣàlàyé Ìwé Mímọ́ fún wa ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́!”​—Lúùkù 24:13, 27, 32.

7. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa fi ohun tó wà nínú Bíbélì kọ́ àwọn èèyàn?

7 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní agbára. (Héb. 4:12) Bíi ti Jésù, Pọ́ọ̀lù àtàwọn àpọ́sítélì, ohun tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run làwa Kristẹni fi ń kọ́ni lónìí. A máa ń bá àwọn èèyàn fèròwérò, a máa ń ṣàlàyé ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ, a sì máa ń fi ẹ̀rí ti ohun tá à ń sọ lẹ́yìn látinú Bíbélì. Ó ṣe tán, ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ là ń wàásù fáwọn èèyàn kì í ṣe ọ̀rọ̀ tiwa. Bákan náà, tá a bá ń lo Bíbélì bó ṣe yẹ, èyí máa jẹ́ ká lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ. Torí náà, á dáa ká máa fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti ohun tá à ń wàásù lẹ́yìn. Ìyẹn á jẹ́ káwọn èèyàn rí i pé òtítọ́ la fi ń kọ́ni. Yàtọ̀ síyẹn, á jẹ́ ká lè máa fìgboyà wàásù bíi ti Pọ́ọ̀lù.

“Àwọn Kan . . . Di Onígbàgbọ́” (Ìṣe 17:4-9)

8-10. (a) Kí làwọn ará Tẹsalóníkà ṣe nígbà tí wọ́n gbọ́ ìhìn rere? (b) Kí ló mú káwọn kan lára àwọn Júù bẹ̀rẹ̀ sí í jowú Pọ́ọ̀lù? (d) Kí làwọn Júù alátakò yẹn ṣe?

8 Pọ́ọ̀lù ti rí i pé òótọ́ lọ̀rọ̀ Jésù pé: “Ẹrú ò tóbi ju ọ̀gá rẹ̀ lọ. Tí wọ́n bá ti ṣe inúnibíni sí mi, wọ́n máa ṣe inúnibíni sí ẹ̀yin náà; tí wọ́n bá ti pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, wọ́n máa pa ọ̀rọ̀ yín náà mọ́.” (Jòh. 15:20) Ohun tí Pọ́ọ̀lù rí gan-an nìyẹn nílùú Tẹsalóníkà, àwọn kan fẹ́ ṣe ohun tó sọ, àwọn míì ò sì fẹ́ gbọ́. Ní tàwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́, Lúùkù sọ pé: “Àwọn kan lára wọn [àwọn Júù] di onígbàgbọ́ [Kristẹni], wọ́n sì dara pọ̀ mọ́ Pọ́ọ̀lù àti Sílà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Gíríìkì tó ń sin Ọlọ́run àti díẹ̀ lára àwọn obìnrin sàràkí-sàràkí ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú.” (Ìṣe 17:4) Ó dájú pé inú àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di Kristẹni yìí dùn pé wọ́n ran àwọn lọ́wọ́ láti lóye Ìwé Mímọ́.

9 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan mọyì ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù bá wọn sọ, ṣe làwọn tó kù bínú gan-an. Torí pé Pọ́ọ̀lù ran “ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Gíríìkì” lọ́wọ́, àwọn kan lára àwọn Júù tó wà ní Tẹsalóníkà bẹ̀rẹ̀ sí í jowú. Àwọn Júù tó ń fẹ́ láti sọ àwọn èèyàn di aláwọ̀ṣe (ìyẹn àwọn tó gba ẹ̀sìn Júù) ti fi Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù kọ́ àwọn Kèfèrí tó ń sọ èdè Gíríìkì lẹ́kọ̀ọ́, wọ́n sì ti ń wo àwọn Gíríìkì yẹn bí ọmọ abẹ́ wọn. Àmọ́ ní báyìí, lójú àwọn Júù yẹn, ó dà bíi pé Pọ́ọ̀lù ti fi ẹ̀kọ́ Bíbélì yí àwọn Gíríìkì yìí lọ́kàn pa dà, ó tún wá jẹ́ nínú sínágọ́gù! Báwọn Júù náà ṣe fàbínú yọ nìyẹn.

“Wọ́n ń wá ọ̀nà láti mú Pọ́ọ̀lù àti Sílà wá fún àwùjọ náà.”​—Ìṣe 17:5

10 Lúùkù sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà fún wa, ó sọ pé: “Inú bí àwọn Júù, wọ́n kó àwọn ọkùnrin burúkú kan jọ tí wọ́n jẹ́ aláìríkan-ṣèkan ní ibi ọjà, wọ́n di àwùjọ onírúgúdù, wọ́n sì dá ìdàrúdàpọ̀ sílẹ̀ nínú ìlú náà. Wọ́n ya wọ ilé Jásónì, wọ́n ń wá ọ̀nà láti mú Pọ́ọ̀lù àti Sílà wá fún àwùjọ náà. Nígbà tí wọn ò rí wọn, wọ́n wọ́ Jásónì àti àwọn arákùnrin kan lọ sọ́dọ̀ àwọn alákòóso ìlú, wọ́n ń pariwo pé: ‘Àwọn ọkùnrin tó ń dojú ilẹ̀ ayé tí à ń gbé dé ti wá síbí o, Jásónì sì gbà wọ́n lálejò. Gbogbo àwọn ọkùnrin yìí ló ń ta ko àwọn àṣẹ Késárì, tí wọ́n ń sọ pé ọba míì wà tó ń jẹ́ Jésù.’ ” (Ìṣe 17:5-7) Báwo lohun táwọn jàǹdùkú yìí ṣe fún Pọ́ọ̀lù àtàwọn tí wọ́n jọ rìnrìn àjò ṣe rí lára wọn?

11. Àwọn ẹ̀sùn wo ni wọ́n fi kan Pọ́ọ̀lù àtàwọn tí wọ́n jọ rìnrìn àjò, òfin wo ló sì ṣeé ṣe káwọn tó fẹ̀sùn kàn wọ́n ní lọ́kàn? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)

11 Àkòtagìrì làwọn jàǹdùkú. Bí agbami òkun ni ìbínú wọn ṣe máa ń ru gùdù, wọn ò sì ṣeé kápá. Àwọn èèyàn burúkú yìí làwọn Júù háyà pé kí wọ́n pa Pọ́ọ̀lù àti Sílà. Lẹ́yìn táwọn Júù yìí ti “dá ìdàrúdàpọ̀” sílẹ̀ nínú ìlú náà wọ́n sọ fáwọn aláṣẹ ìlú pé ẹ̀sùn tó lágbára ni wọ́n fi kan Pọ́ọ̀lù àtàwọn tí wọ́n jọ rìnrìn àjò, torí wọ́n ń wàásù Ìjọba Ọlọ́run. Ẹ̀sùn àkọ́kọ́ ni pé wọ́n ti “dojú ilẹ̀ ayé tí à ń gbé dé,” bó tilẹ̀ jẹ́ pé Pọ́ọ̀lù àtàwọn tí wọ́n jọ rìnrìn àjò kọ́ ló dá ìdàrúdàpọ̀ tó ṣẹlẹ̀ ní Tẹsalóníkà sílẹ̀. Ẹ̀sùn kejì ló wá le jù. Àwọn Júù yẹn sọ pé àwọn míṣọ́nnárì yìí ń sọ̀rọ̀ nípa Ọba míì, ìyẹn Jésù, wọ́n sì tipa báyìí rú òfin olú ọba. a

12. Kí ló fi hàn pé ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan àwọn Kristẹni tó wà ní Tẹsalóníkà lè kó wọn sínú ewu ńlá?

12 Ṣé ẹ rántí pé irú ẹ̀sùn yìí kan náà làwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù fi kan Jésù? Wọ́n sọ fún Pílátù pé: “A rí i pé ọkùnrin yìí fẹ́ dojú ìjọba ilẹ̀ wa dé . . . ó sì ń pe ara rẹ̀ ní Kristi ọba.” (Lúùkù 23:2) Ó ṣeé ṣe kẹ́rù máa ba Pílátù pé olú ọba lè rò pé òun ń fàyè gba àwọn tó ń dìtẹ̀ sí ìjọba. Torí náà, ó ní kí wọ́n lọ pa Jésù. Bákan náà, ó ṣeé ṣe kí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan àwọn Kristẹni tó wà nílùú Tẹsalóníkà yìí kó wọn sínú ewu. Ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ sọ pé: “Kò sí àsọdùn nínú ẹ̀ pé ewu ńlá ni ẹ̀sùn yìí ò bá kó àwọn ará yìí sí, torí ‘ikú ló sábà máa ń yọrí sí fún ẹni tí wọ́n bá fẹ̀sùn kàn pé ó dìtẹ̀ sáwọn Olú Ọba.’ ” Ṣé ọ̀nà á gba ibi táwọn alátakò yìí fojú sí ṣá?

13, 14. (a) Kí ló dé táwọn jàǹdùkú yẹn ò fi lè dá iṣẹ́ ìwàásù dúró? (b) Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe ṣe bíi ti Kristi, báwo la sì ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù?

13 Kò ṣeé ṣe fáwọn jàǹdùkú yìí láti dá iṣẹ́ ìwàásù dúró nílùú Tẹsalóníkà. Kí nìdí? Ìdí ni pé, wọn ò rí Pọ́ọ̀lù àti Sílà. Yàtọ̀ síyẹn, lójú àwọn aláṣẹ ìlú náà, ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Pọ́ọ̀lù àti Sílà ò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀. Torí náà, lẹ́yìn tí wọ́n ti gba “ohun ìdúró tí ó tó,” lọ́wọ́ wọn, wọ́n fi Jásónì àtàwọn ará tó kù sílẹ̀. (Ìṣe 17:8, 9) Pọ́ọ̀lù tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Jésù pé ká ‘máa ṣọ́ra bí ejò, síbẹ̀ ká jẹ́ ọlọ́rùn mímọ́ bí àdàbà,’ torí náà, Pọ́ọ̀lù kúrò lágbègbè eléwu yẹn kó lè lọ wàásù níbòmíì. (Mát. 10:16) Ó ṣe kedere pé bí Pọ́ọ̀lù ṣe lo ìgboyà níbí ò túmọ̀ sí pé ó fojú di àwọn jàǹdùkú yẹn. Àmọ́, báwo làwọn Kristẹni lónìí ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀?

14 Lónìí, àwọn aṣáájú ẹ̀sìn sábà máa ń lo àwọn jàǹdùkú láti gbéjà ko àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Wọ́n máa ń fẹ̀sùn kàn wá pé à ń ṣe ohun tó lòdì sí òfin ìlú, ìyẹn sì máa ń jẹ́ káwọn aláṣẹ ṣenúnibíni sí wa. Bíi tàwọn alátakò ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, àwọn èèyàn máa ń ta kò wá lónìí torí wọ́n ń jowú wa. Àmọ́ ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀, àwa Kristẹni tòótọ́ kì í ṣe ohun tó máa wu wá léwu. A máa ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká má bàa kó sọ́wọ́ irú àwọn èèyàn burúkú tínú ń bí yìí, a sì máa ń wá bí àá ṣe máa wàásù nìṣó láìsí wàhálà, títí dìgbà tí nǹkan fi máa rọlẹ̀.

Wọ́n “Ní Ọkàn Rere” (Ìṣe 17:10-15)

15. Kí làwọn ará Bèróà ṣe nígbà tí wọ́n gbọ́ ìhìn rere?

15 Nítorí àtiyẹra fún ewu, wọ́n rán Pọ́ọ̀lù àti Sílà lọ sí Bèróà tó wà ní nǹkan bíi kìlómítà márùndínláàádọ́rin (65) sí ìlú Tẹsalóníkà. Nígbà tí wọ́n débẹ̀, Pọ́ọ̀lù lọ sínú sínágọ́gù, ó sì báwọn tó wà níbẹ̀ sọ̀rọ̀. Ẹ wo bínú ẹ̀ ṣe máa dùn tó pé àwọn tó bá sọ̀rọ̀ fetí sílẹ̀! Lúùkù sọ pé àwọn Júù tó wà ní Bèróà “ní ọkàn rere ju àwọn tó wà ní Tẹsalóníkà lọ, torí pé wọ́n gba ọ̀rọ̀ náà tọkàntọkàn wọ́n sì ń ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ kínníkínní lójoojúmọ́ láti rí i bóyá àwọn nǹkan yìí rí bẹ́ẹ̀.” (Ìṣe 17:10, 11) Àmọ́, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé àwọn tó di Kristẹni ní Tẹsalóníkà ò níwà tó dáa o! Torí pé nígbà tó yá Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí wọn, ó sọ pé: “Àwa náà ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nígbà gbogbo, torí nígbà tí ẹ gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èyí tí ẹ gbọ́ lọ́dọ̀ wa, ẹ tẹ́wọ́ gbà á, kì í ṣe bí ọ̀rọ̀ èèyàn, àmọ́ gẹ́gẹ́ bó ṣe jẹ́ lóòótọ́, bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èyí tó tún wà lẹ́nu iṣẹ́ nínú ẹ̀yin onígbàgbọ́.” (1 Tẹs. 2:13) Kí ló mú káwọn Júù tó wà ní Bèróà lọ́kàn rere tó bẹ́ẹ̀?

16. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé àwọn ará Bèróà ní “ọkàn rere”?

16 Òótọ́ ni pé ìgbà àkọ́kọ́ nìyẹn táwọn ará Bèróà máa gbọ́ ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù, wọn ò bẹ̀rẹ̀ sí í fura òdì sí i tàbí kí wọ́n máa fẹ̀sùn kàn án, bẹ́ẹ̀ sì rèé wọn kì í ṣe ẹni téèyàn lè tètè tàn jẹ. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, wọ́n fetí sílẹ̀ dáadáa sóhun tí Pọ́ọ̀lù fẹ́ sọ. Lẹ́yìn náà, wọ́n lọ ṣàyẹ̀wò àwọn nǹkan tí Pọ́ọ̀lù ti ṣàlàyé fún wọn nínú Ìwé Mímọ́. Yàtọ̀ síyẹn, ojoojúmọ́ ni wọ́n máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kì í ṣe ọjọ́ Sábáàtì nìkan. Torí náà, wọ́n gba ọ̀rọ̀ náà “tọkàntọkàn,” wọ́n sì fara balẹ̀ wo ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa àwọn nǹkan tí Pọ́ọ̀lù kọ́ wọn. Lẹ́yìn náà, wọ́n rẹ ara wọn sílẹ̀, wọ́n ṣe àwọn àyípadà tó yẹ, ìyẹn sì mú kí “ọ̀pọ̀ lára wọn di onígbàgbọ.” (Ìṣe 17:12) Ìdí nìyẹn tí Lúùkù fi sọ pé wọ́n ní “ọkàn rere.”

17. Kí ló mú kí ohun tí àwọn ará Bèróà ṣe jẹ́ àpẹẹrẹ tó dáa, báwo la ṣe lè máa fara wé wọn lẹ́yìn tá a ti di Kristẹni?

17 Àwọn ará Bèróà ò mọ̀ pé ohun táwọn ṣe nígbà tí wọ́n gbọ́ ìhìn rere máa wà lákọọ́lẹ̀ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tó sì máa jẹ́ àpẹẹrẹ tó dáa fún àwa náà lónìí. Ohun tí Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn pé wọ́n máa ṣe àti ohun tí Jèhófà Ọlọ́run fẹ́ kí wọ́n ṣe gan-an ni wọ́n ṣe. Ohun kan náà là ń gba àwọn èèyàn níyànjú pé kí wọ́n ṣe, ìyẹn ni pé kí wọ́n fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò Bíbélì, kí ìgbàgbọ́ wọn lè fẹsẹ̀ múlẹ̀ dáadáa nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé tá a bá ti di Kristẹni, kò tún yẹ ká ní ọkàn rere mọ́? Rárá o, ìgbà yẹn gan-an ló ṣe pàtàkì jù lọ pé ká máa fi tọkàntọkàn kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, ká sì tètè máa fi àwọn ohun tá à ń kọ́ sílò. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ṣe là ń jẹ́ kí Jèhófà mọ wá, tá a sì ń jẹ́ kó kọ́ wa níbàámu pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ̀. (Àìsá. 64:8) Èyí á jẹ́ ká máa bá a lọ láti jẹ́ ẹni tó wúlò, tó sì ń ṣe ohun táá múnú Baba wa ọ̀run dùn.

18, 19. (a) Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi kúrò ní Bèróà, báwo la sì ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀? (b) Àwọn wo ni Pọ́ọ̀lù fẹ́ lọ wàásù fún báyìí, ibo ni wọ́n sì wà?

18 Pọ́ọ̀lù ò pẹ́ púpọ̀ ní Bèróà. Bíbélì sọ pé: “Nígbà tí àwọn Júù ní Tẹsalóníkà gbọ́ pé Pọ́ọ̀lù ti ń kéde ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní Bèróà, wọ́n wá síbẹ̀ láti ru àwọn èèyàn sókè, kí wọ́n sì kó sí wọn nínú. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, àwọn ará ní kí Pọ́ọ̀lù máa lọ sí etí òkun, àmọ́ Sílà àti Tímótì dúró síbẹ̀. Nígbà tí àwọn tó wà pẹ̀lú Pọ́ọ̀lù mú Pọ́ọ̀lù dé Áténì, wọ́n pa dà lẹ́yìn tó sọ fún wọn pé kí Sílà àti Tímótì tètè wá bá òun ní kíá.” (Ìṣe 17:13-15) Ẹ ò rí i pé kò rẹ àwọn alátakò yìí! Àfi bíi pé bí wọ́n ṣe lé Pọ́ọ̀lù kúrò ní Tẹsalóníkà ò tó wọn, ṣe ni wọ́n tún bọ́ sọ́nà Bèróà tí wọ́n tún dá irú ìjàngbọ̀n kan náà tí wọ́n dá sílẹ̀ ní Tẹsalóníkà sílẹ̀ ní Bèróà, àmọ́ wọn ò ṣàṣeyọrí. Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé kì í ṣe ibẹ̀ nìkan lòun ti lè wàásù, ló bá tètè gba ibòmíì lọ. Lónìí, àwa náà ti pinnu bíi ti Pọ́ọ̀lù pé a ò ní jẹ́ kí àwọn èèyàn dá iṣẹ́ ìwàásù wa dúró.

19 Torí pé Pọ́ọ̀lù ti jẹ́rìí kúnnákúnná fáwọn Júù tó wà ní Tẹsalóníkà àtàwọn tó wà ní Bèróà, ó dájú pé ó ti mọ bó ṣe ṣe pàtàkì tó pé kéèyàn fìgboyà wàásù, kéèyàn sì bá àwọn èèyàn fèròwérò látinú Ìwé Mímọ́. Ohun tó sì yẹ káwa náà ṣe nìyẹn. Ní báyìí, àwọn èèyàn tó yàtọ̀ ni Pọ́ọ̀lù fẹ́ lọ wàásù fún, ìyẹn àwọn Kèfèrí tó wà nílùú Áténì. Báwo lọ̀hún ṣe máa rí? Orí tó kàn máa ṣàlàyé.

a Ọ̀mọ̀wé kan sọ pé, òfin Késárì kan fi dandan lé e nígbà yẹn pé ẹnikẹ́ni ò gbọ́dọ̀ sọ àsọtẹ́lẹ̀ èyíkéyìí nípa “ọba tàbí ìjọba tuntun kan pé ó ń bọ̀, pàápàá tó bá jẹ́ pé irú ọba bẹ́ẹ̀ máa ṣẹ́gun tàbí ṣèdájọ́ olú ọba tó ń ṣàkóso lọ́wọ́.” Ó ṣeé ṣe káwọn alátakò yìí ti ṣi ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù lóye, kí wọ́n sì gbà pé ó ti rú òfin yìí. Wo àpótí náà, “ Àwọn Olú Ọba Tó Ṣàkóso Lákòókò Tí Wọ́n Kọ Ìwé Ìṣe.”