ORÍ 19
“Máa Sọ̀rọ̀ Nìṣó, Má sì Dákẹ́”
Pọ́ọ̀lù ṣiṣẹ́, àmọ́ iṣẹ́ ìwàásù ló fi sípò àkọ́kọ́
Ó dá lórí Ìṣe 18:1-22
1-3. Kí nìdí tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi lọ sí ìlú Kọ́ríńtì, àwọn ipò wo ló sì bá ara ẹ̀?
NÍ APÁ ìparí ọdún 50 Sànmánì Kristẹni, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wà nílùú Kọ́ríńtì. Ojúkò ìṣòwò ni ìlú Kọ́ríńtì, àwọn ará ibẹ̀ lọ́rọ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn ló sì máa ń wá ṣe káràkátà níbẹ̀, kódà ọ̀pọ̀ àwọn Gíríìkì, àwọn ará Róòmù àtàwọn Júù ló ń gbébẹ̀. a Àmọ́, kì í ṣe pé Pọ́ọ̀lù lọ síbẹ̀ láti lọ ṣòwò, bẹ́ẹ̀ sì ni kò wáṣẹ́ lọ. Ohun tó gbé e wá sílùú Kọ́ríńtì ṣe pàtàkì jùyẹn lọ, ṣe ló lọ síbẹ̀ láti lọ wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Síbẹ̀, Pọ́ọ̀lù nílò ibi táá máa gbé, ó sì ti pinnu pé òun ò ní torí ìyẹn di ẹrù ìnáwó ru ẹnikẹ́ni. Kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni rò pé òun retí kí wọ́n máa fowó ṣètìlẹyìn fún òun, torí pé òun ń wàásù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Kí ló máa wá ṣe báyìí?
2 Iṣẹ́ ọwọ́ kan wà tí Pọ́ọ̀lù mọ̀ dáadáa, ìyẹn ni iṣẹ́ àgọ́ pípa. Àgọ́ pípa ò rọrùn, àmọ́ ó fẹ́ ṣiṣẹ́ kó lè máa rówó gbọ́ bùkátà ara ẹ̀. Ṣó máa ríṣẹ́ ṣe nílùú térò ti pọ̀ bí omi yìí? Ṣó máa rí ilé tó dáa, táá sì tẹ́ ẹ lọ́rùn gbé? Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ipò tí Pọ́ọ̀lù bá ara rẹ̀ yìí kò rọrùn, kò gbàgbé iṣẹ́ pàtàkì tó gbé e dé ìlú Kọ́ríńtì, ìyẹn iṣẹ́ ìwàásù.
3 Pọ́ọ̀lù gbé ní Kọ́ríńtì fún àkókò díẹ̀, iṣẹ́ ìwàásù tó ṣe níbẹ̀ sì yọrí sí rere. Kí la lè kọ́ nínú ohun tí Pọ́ọ̀lù ṣe nígbà tó wà nílùú Kọ́ríńtì tó máa ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́rìí kúnnákúnná nípa Ìjọba Ọlọ́run ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa?
“Iṣẹ́ Àgọ́ Pípa Ni Wọ́n Ń Ṣe” (Ìṣe 18:1-4)
4, 5. (a) Ibo ni Pọ́ọ̀lù ń gbé nígbà tó wà ní Kọ́ríńtì, iṣẹ́ wo ló sì fi ń gbọ́ bùkátà ara ẹ̀? (b) Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe dẹni tó mọ̀ nípa iṣẹ́ àgọ́ pípa?
4 Kò pẹ́ tí Pọ́ọ̀lù dé ìlú Kọ́ríńtì tó fi rí tọkọtaya Júù kan tó lawọ́, ìyẹn Ákúílà àti ìyàwó rẹ̀ Pírísílà, tàbí Pírísíkà. Àṣẹ tí Olú Ọba Kíláúdíù pa, pé kí “àwọn Júù kúrò ní Róòmù,” ló mú kí tọkọtaya náà wá máa gbé nílùú Kọ́ríńtì. (Ìṣe 18:1, 2) Ákúílà àti Pírísílà gba Pọ́ọ̀lù sínú ilé wọn, wọ́n sì tún jẹ́ kó bá àwọn ṣiṣẹ́. Bíbélì sọ pé: “Torí pé iṣẹ́ kan náà ni wọ́n jọ ń ṣe, ó [Pọ́ọ̀lù] dúró sí ilé wọn, ó sì ń bá wọn ṣiṣẹ́, torí iṣẹ́ àgọ́ pípa ni wọ́n ń ṣe.” (Ìṣe 18:3) Bó ṣe di pé ilé àwọn tọkọtaya tó jẹ́ onínúure àti ọ̀làwọ́ yìí ni Pọ́ọ̀lù ń gbé nìyẹn ní gbogbo ìgbà tó fi wàásù nílùú Kọ́ríńtì. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìgbà tí Pọ́ọ̀lù ń gbé pẹ̀lú Ákúílà àti Pírísílà ló kọ àwọn lẹ́tà tó wá di apá kan Bíbélì lónìí. b
5 Báwo ni Pọ́ọ̀lù, ọkùnrin tó gba ẹ̀kọ́ “lọ́dọ̀ Gàmálíẹ́lì,” ṣe wá di ẹni tó ń pàgọ́? (Ìṣe 22:3) Kì í ṣe ohun ìtìjú fáwọn Júù tó gbáyé ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní láti fi iṣẹ́ ọwọ́ tí wọ́n mọ̀ kọ́ àwọn ọmọ wọn, kódà táwọn ọmọ bẹ́ẹ̀ bá tiẹ̀ kàwé. Aṣọ àgọ́ tí wọ́n ń pè ní cilicium pọ̀ ní ìlú Tásù ní Sìlíṣíà, torí pé ibẹ̀ ni Pọ́ọ̀lù sì ti wá, àfàìmọ̀ kó má jẹ́ pé àtikékeré ni wọ́n ti kọ́ ọ níṣẹ́ àgọ́ pípa. Báwo ni wọ́n ṣe ń pàgọ́? Tí wọ́n bá fẹ́ pa àgọ́, ṣe ni wọ́n máa ń hun aṣọ tàbí kí wọ́n gé àwọn aṣọ tó le bíi tapólì, kí wọ́n sì rán an láti fi ṣe àgọ́. Lọ́rọ̀ kan ṣá, iṣẹ́ tó le ni.
6, 7. (a) Ojú wo ni Pọ́ọ̀lù fi wo àgọ́ pípa, kí ló sì fi hàn pé irú ojú tí Ákúílà àti Pírísílà náà fi wò ó nìyẹn? (b) Báwo làwọn Kristẹni lónìí ṣe ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù, Ákúílà àti Pírísílà?
6 Iṣẹ́ àgọ́ pípa kọ́ ló ṣe pàtàkì jù sí Pọ́ọ̀lù. Àmọ́, ó ń ṣe é láti gbọ́ bùkátà ara ẹ̀ bó ṣe ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù, tó sì ń kéde ìhìn rere “lọ́fẹ̀ẹ́.” (2 Kọ́r. 11:7) Ojú wo ni Ákúílà àti Pírísílà fi wo iṣẹ́ àgọ́ pípa? Kristẹni làwọn náà, torí náà, ó dájú pé ojú tí Pọ́ọ̀lù fi wò ó làwọn náà fi wò ó. Kódà, nígbà tí Pọ́ọ̀lù kúrò ní Kọ́ríńtì lọ́dún 52 Sànmánì Kristẹni, Ákúílà àti Pírísílà fi iṣẹ́ wọn sílẹ̀, wọ́n sì tẹ̀ lé e lọ sí Éfésù. Ilé tí wọ́n ń gbé sì ni ìjọ tó sún mọ́ wọn ti ń ṣèpàdé. (1 Kọ́r. 16:19) Nígbà tó yá, wọ́n pa dà sí Róòmù, lẹ́yìn náà wọ́n tún pa dà sí Éfésù. Àwọn tọkọtaya tó nítara yìí fi àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run àti iṣẹ́ ìwàásù sí ipò àkọ́kọ́, wọ́n sì ń yọ̀ǹda ara wọn kí wọ́n lè ran àwọn míì lọ́wọ́, “gbogbo ìjọ àwọn orílẹ̀-èdè” sì ń dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn.—Róòmù 16:3-5; 2 Tím. 4:19.
7 Lónìí, àwọn Kristẹni máa ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù, Ákúílà àti Pírísílà. Àwọn ará tí wọ́n ń fìtara wàásù máa ń ṣiṣẹ́ kára kí wọ́n má bàa “di ẹrù wọ” àwọn míì lọ́rùn. (1 Tẹs. 2:9) Ohun tó wúni lórí ni pé ọ̀pọ̀ àwọn tó ń fi àkókò tó pọ̀ wàásù ló ń ṣe iṣẹ́ tí kò fi bẹ́ẹ̀ gba àkókò kí wọ́n lè máa fi gbọ́ bùkátà ara wọn. Ìyẹn sì ń jẹ́ kí wọ́n lè máa bá iṣẹ́ náà nìṣó. Bíi ti Ákúílà àti Pírísílà, ọ̀pọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ló fẹ́ràn láti máa ṣàlejò, kódà wọ́n máa ń gba àwọn alábòójútó àyíká sílé wọn. Àwọn tó bá sì ń “ṣe aájò àlejò” máa ń rí ìṣírí gbà, wọ́n sì máa ń láyọ̀.—Róòmù 12:13.
Ìṣe 18:5-8)
“Ọ̀pọ̀ Àwọn Ará Kọ́ríńtì . . . Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Gbà Gbọ́” (8, 9. Kí ni Pọ́ọ̀lù ṣe nígbà táwọn Júù tó fìtara wàásù fún ń ṣàtakò sí i, ibo ló sì ti lọ wàásù lẹ́yìn náà?
8 Bí Sílà àti Tímótì ṣe kó ẹ̀bùn wá fún Pọ́ọ̀lù ní Makedóníà fí hàn pé kì í ṣe gbogbo àkókò ẹ̀ ló fi ń ṣiṣẹ́ àgọ́ pípa, àmọ́ ó ń ṣe é kó lè fi gbọ́ bùkátà ara ẹ̀. (2 Kọ́r. 11:9) Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú kí ọwọ́ Pọ́ọ̀lù dí gan-an [Pọ́ọ̀lù “fi gbogbo àkókò rẹ̀ sílẹ̀ fún iwaasu,” Bíbélì Ìròhìn Ayọ̀].” (Ìṣe 18:5) Àmọ́, bó ṣe ń fìtara wàásù fáwọn Júù, ṣe ni wọ́n ń ṣenúnibíni sí i ṣáà. Wọn ò gbà gbọ́ pé Kristi lè gbà wọ́n là. Kí Pọ́ọ̀lù lè fi hàn pé òun ò lẹ́bi, ó gbọn ẹ̀wù rẹ̀, ó sì sọ fáwọn Júù tó ń ṣàtakò sí i pé: “Kí ẹ̀jẹ̀ yín wà lórí ẹ̀yin fúnra yín. Ọrùn mi mọ́. Láti ìsinsìnyí lọ, màá lọ máa bá àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè.”—Ìṣe 18:6; Ìsík. 3:18, 19.
9 Ibo ni Pọ́ọ̀lù á ti lọ wàásù báyìí o? Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Títíọ́sì Jọ́sítù, tó ṣeé ṣe kó jẹ́ aláwọ̀ṣe Júù tí ilé ẹ̀ wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ sínágọ́gù gba Pọ́ọ̀lù sílé rẹ̀. Torí náà, Pọ́ọ̀lù kúrò ní sínágọ́gù, ó sì lọ sílé Jọ́sítù. (Ìṣe 18:7) Ilé Ákúílà àti Pírísílà ni Pọ́ọ̀lù ń gbé ní gbogbo ìgbà tó fi wà ní Kọ́ríńtì, àmọ́ ilé Jọ́sítù ló ti ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù.
10. Kí ló fi hàn pé kì í ṣe àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè nìkan ni Pọ́ọ̀lù ṣe tán láti wàásù fún?
10 Ṣé ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ pé òun máa lọ bá àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè túmọ̀ sí pé ó jáwọ́ pátápátá lọ́rọ̀ gbogbo àwọn Júù àtàwọn aláwọ̀ṣe, títí kan àwọn tó gbọ́ ìwàásù ẹ̀? Rárá o. Bí àpẹẹrẹ, “Kírípọ́sì, alága sínágọ́gù, di onígbàgbọ́ nínú Olúwa, òun pẹ̀lú gbogbo agbo ilé rẹ.” Ẹ̀rí fi hàn pé ọ̀pọ̀ lára àwọn tó wà nínú sínágọ́gù náà dara pọ̀ mọ́ Kírípọ́sì, torí Bíbélì sọ pé: “Ọ̀pọ̀ àwọn ará Kọ́ríńtì tí wọ́n gbọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í gbà gbọ́, wọ́n sì ṣèrìbọmi.” (Ìṣe 18:8) Torí náà, ilé Títíọ́sì Jọ́sítù di ibi táwọn ará tó wà ní ìjọ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ nílùú Kọ́ríńtì ti ń pàdé. Tó bá jẹ́ pé ọ̀nà tí Lúùkù gbà ń kọ̀wé ló gbà kọ ìwé Ìṣe, ìyẹn bó ṣe máa ń to àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ bó ṣe tẹ̀ léra, a jẹ́ pé lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù gbọn ẹ̀wù rẹ̀ làwọn Júù tàbí àwọn aláwọ̀ṣe yẹn yí pa dà di Kristẹni. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí fi hàn pé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù múra tán láti ṣe àwọn àyípadà tó bá yẹ kó lè wàásù fáwọn tó ṣe tán láti gbọ́.
11. Báwo làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lónìí ṣe ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù bí wọ́n ṣe ń wàásù fáwọn oníṣọ́ọ̀ṣì?
11 Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè lónìí, àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ti pọ̀ gan-an, ohunkóhun tí wọ́n bá sì sọ làwọn ọmọ ìjọ wọn máa ń ṣe. Láwọn ilẹ̀ kan, àwọn míṣọ́nnárì táwọn oníṣọ́ọ̀ṣì rán jáde ti yí ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́kàn pa dà. Ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n pera wọn ní Kristẹni ló ṣì máa ń tẹ̀ lé àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ bíi tàwọn Júù tó wà nílùú Kọ́ríńtì ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní. Àmọ́ bíi ti Pọ́ọ̀lù, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń fìtara wàásù fáwọn èèyàn, a sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè lóye ohun tí wọ́n ti kà nínú Ìwé Mímọ́. Kódà, bí wọ́n bá ta kò wá tàbí tí àwọn aṣáájú ẹ̀sìn wọn bá ṣenúnibíni sí wa, a kì í jẹ́ kó sú wa. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló fẹ́ mọ òtítọ́ nípa Ọlọ́run. Wọ́n “ní ìtara fún Ọlọ́run, àmọ́ kì í ṣe pẹ̀lú ìmọ̀ tó péye,” torí náà ó yẹ ká wá wọn lọ.—Róòmù 10:2.
“Mo Ní Ọ̀pọ̀ Èèyàn ní Ìlú Yìí” (Ìṣe 18:9-17)
12. Kí ni Jésù fi dá Pọ́ọ̀lù lójú nínú ìran?
12 Tí Pọ́ọ̀lù bá tiẹ̀ ti ń ṣiyè méjì tẹ́lẹ̀ nípa bóyá kóun máa bá iṣẹ́ òjíṣẹ́ òun lọ ní Kọ́ríńtì, ó dájú pé kò ní ṣiyè méjì mọ́ lálẹ́ ọjọ́ tí Jésù Olúwa fara hàn án nínú ìran, tó sì sọ fún un pé: “Má bẹ̀rù, máa sọ̀rọ̀ nìṣó, má sì dákẹ́, torí mo wà pẹ̀lú rẹ, ẹnikẹ́ni ò ní kọ lù ọ́ láti ṣe ọ́ léṣe; nítorí mo ní ọ̀pọ̀ èèyàn ní ìlú yìí.” (Ìṣe 18:9, 10) Ìran yẹn á mà fún un níṣìírí gan-an ni o! Jésù Olúwa fúnra rẹ̀ fi dá Pọ́ọ̀lù lójú pé òun á dáàbò bò ó lọ́wọ́ àwọn tó bá fẹ́ ṣe é léṣe àti pé ọ̀pọ̀ àwọn olóòótọ́ ọkàn ló ṣì wà ní ìlú yẹn. Kí ni Pọ́ọ̀lù ṣe lẹ́yìn tó rí ìran náà? Bíbélì sọ pé: “Ó lo ọdún kan àti oṣù mẹ́fà níbẹ̀, ó ń kọ́ni ní ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láàárín wọn.”—Ìṣe 18:11.
13. Ìṣẹ̀lẹ̀ wo ló ṣeé ṣe kí Pọ́ọ̀lù rántí nígbà tó débi ìjókòó ìdájọ́, àmọ́ kí ló fi í lọ́kàn balẹ̀ pé wọn ò ní pa òun?
13 Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù ti lo nǹkan bí ọdún kan nílùú Kọ́ríńtì, ó rí ẹ̀rí míì tó fi hàn pé Olúwa wà pẹ̀lú òun. Bíbélì sọ pé: “Àwọn Júù gbìmọ̀ pọ̀, wọ́n dìde sí Pọ́ọ̀lù, wọ́n sì mú un lọ síwájú ìjókòó ìdájọ́,” tí wọ́n ń pè ní beʹma. (Ìṣe 18:12) Àwọn kan sọ pé beʹma tàbí ìjókòó ìdájọ́ yìí jẹ́ pèpéle gíga tó ṣeé ṣe kó wà ní àárín ọjà Kọ́ríńtì. Òkúta iyebíye aláwọ̀ búlúù àti funfun ni wọ́n fi ṣe é, wọ́n sì gbẹ́ àwọn àwòrán tó rẹwà sí i lára. Àyè tó wà níwájú ẹ̀ fẹ̀, ó lè gba èèyàn tó pọ̀. Ìwádìí táwọn awalẹ̀pìtàn ṣe fi hàn pé ìjókòó ìdájọ́ náà ò jìnnà sí sínágọ́gù àti sí ilé Jọ́sítù. Bí Pọ́ọ̀lù ṣe dé ibi ìjókòó ìdájọ́ yìí, ó ṣeé ṣe kó rántí bí wọ́n ṣe sọ Sítéfánù lókùúta. Sítéfánù yìí làwọn èèyàn mọ̀ sí ẹni àkọ́kọ́ tí wọ́n pa torí pé ó jẹ́ ẹlẹ́rìí Jésù. Pọ́ọ̀lù, tó ń jẹ́ Sọ́ọ̀lù nígbà yẹn, “fọwọ́ sí bí wọ́n ṣe pa Sítéfánù.” (Ìṣe 8:1) Ṣé ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sóun náà nìyẹn? Rárá o, torí Jésù ti ṣèlérí fún un pé: “Ẹnikẹ́ni ò ní . . . ṣe ọ́ léṣe.”—Ìṣe 18:10.
14, 15. (a) Ẹ̀sùn wo làwọn Júù fi kan Pọ́ọ̀lù, kí ló sì fà á tí Gálíò fi tú ẹjọ́ náà ká? (b) Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Sótínésì, kí sì nìdí tá a fi rò pé ó ṣeé ṣe kó di Kristẹni?
14 Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí Pọ́ọ̀lù débi ìjókòó ìdájọ́? Gálíò tó jẹ́ alákòóso ìbílẹ̀ ìlú Ákáyà ni adájọ́ nígbà yẹn, òun ni ẹ̀gbọ́n Seneca tó jẹ́ onímọ̀ èrò orí ìlú Róòmù. Àwọn Júù fẹ̀sùn kan Pọ́ọ̀lù pé: “Ọkùnrin yìí ń yí àwọn èèyàn lérò pa dà láti máa sin Ọlọ́run lọ́nà tó ta ko òfin.” (Ìṣe 18:13) Ohun táwọn Júù yìí ń sọ ni pé ṣe ni Pọ́ọ̀lù ń sọ àwọn èèyàn di Kristẹni, èyí ò sì bófin mu. Àmọ́, Gálíò rí i pé Pọ́ọ̀lù ò hùwà “àìtọ́” rárá, kò sì jẹ̀bi “ìwà ọ̀daràn” kankan. (Ìṣe 18:14) Gálíò kò fẹ́ bá àwọn Júù yẹn fa ọ̀rọ̀, kò sì fẹ́ bá wọn jiyàn. Kódà, Pọ́ọ̀lù ò tiẹ̀ tíì sọ̀rọ̀ kankan láti gbèjà ara ẹ̀ tí Gálíò ti tú ẹjọ́ náà ká! Inú bí àwọn tó fẹ̀sùn kan Pọ́ọ̀lù gan-an. Wọ́n kanra mọ́ Sótínésì, tó ṣeé ṣe kó jẹ́ ẹni tó gbapò alága sínágọ́gù lọ́wọ́ Kírípọ́sì. Wọ́n gbá a mú, “wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í lù ú níwájú ìjókòó ìdájọ́.”—Ìṣe 18:17.
15 Kí nìdí tí Gálíò kò fi dá sí i nígbà táwọn èèyàn náà ń lu Sótínésì? Bóyá Gálíò rò pé Sótínésì ló wà lẹ́yìn àwọn tó ń ta ko Pọ́ọ̀lù àti pé ṣe ló ń jìyà ohun tó ṣe. Èyí ó wù kó jẹ́, ó jọ pé ọ̀rọ̀ náà yọrí sí rere. Lọ́dún mélòó kan lẹ́yìn náà, nínú lẹ́tà àkọ́kọ́ tí Pọ́ọ̀lù kọ sí ìjọ Kọ́ríńtì, ó dárúkọ arákùnrin kan tó ń jẹ́ Sótínésì. (1 Kọ́r. 1:1, 2) Ṣé Sótínésì kan náà táwọn ará Kọ́ríńtì lù yẹn ni? Tó bá jẹ́ òun ni, ó lè jẹ́ pé ohun tí wọ́n fojú ẹ̀ rí ló mú kó di Kristẹni.
16. Báwo ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa sọ pé, “máa sọ̀rọ̀ nìṣó, má sì dákẹ́, torí mo wà pẹ̀lú rẹ,” ṣe ń fún wa lókun lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa?
16 Rántí pé lẹ́yìn táwọn Júù kọ̀ láti gbọ́ ìwàásù Pọ́ọ̀lù ni Jésù Olúwa sọ ọ̀rọ̀ tó fi í lọ́kàn balẹ̀. Ó ní: “Má bẹ̀rù, máa sọ̀rọ̀ nìṣó, má sì dákẹ́, torí mo wà pẹ̀lú rẹ.” (Ìṣe 18:9, 10) Ó máa dáa ká fi àwọn ọ̀rọ̀ yìí sọ́kàn, ní pàtàkì táwọn èèyàn ò bá fẹ́ gbọ́ ìwàásù wa. Má gbàgbé láé pé ọkàn ni Jèhófà máa ń wò, òun ló sì máa ń fa àwọn tó jẹ́ olóòótọ́ ọkàn wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀. (1 Sám. 16:7; Jòh. 6:44) Ó dájú pé ọ̀rọ̀ yìí fún wa lókun ká lè máa ṣe iṣẹ́ ìwàásù wa nìṣó! Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300,000) èèyàn ló ń ṣèrìbọmi lọ́dọọdún, èyí fi hàn pé nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ (800) èèyàn ló ń ṣèrìbọmi lójúmọ́. Jésù pàṣẹ pé ká máa “sọ àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.” Ó sì fi dá gbogbo àwọn tó ń ṣègbọràn sí àṣẹ yẹn lójú pé: “Mo wà pẹ̀lú yín ní gbogbo ọjọ́ títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan.”—Mát. 28:19, 20.
“Tí Jèhófà Bá Fẹ́” (Ìṣe 18:18-22)
17, 18. Kí ló ṣeé ṣe kí Pọ́ọ̀lù máa ronú lé lórí bí ọkọ̀ òkun ṣe ń gbé e lọ sí Éfésù?
17 A ò mọ̀ bóyá ọ̀nà tí Gálíò gbà bójú tó ọ̀rọ̀ àwọn tó fẹ̀sùn kan Pọ́ọ̀lù yọrí sí àkókò àlàáfíà fún ìjọ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ ní Kọ́ríńtì. Àmọ́, Pọ́ọ̀lù ṣì “lo ọjọ́ mélòó kan sí i níbẹ̀” kó tó dágbére fáwọn ará tó wà ní Kọ́ríńtì. Nígbà ìrúwé ọdún 52 Sànmánì Kristẹni, ó ṣètò láti wọ ọkọ̀ òkun lọ sí Síríà láti etíkun Kẹnkíríà, tó jẹ́ ìrìn àjò kìlómítà mọ́kànlá (11) sí Kọ́ríńtì. Àmọ́, kí Pọ́ọ̀lù tó kúrò ní Kẹnkíríà, ó “gé irun orí rẹ̀ mọ́lẹ̀ . . . torí ó ti jẹ́ ẹ̀jẹ́ kan.” c (Ìṣe 18:18) Lẹ́yìn náà, ó mú Ákúílà àti Pírísílà, wọ́n sì wọ ọkọ̀ òkun gba orí Òkun Aegean lọ sílùú Éfésù ní Éṣíà Kékeré.
18 Bí ọkọ̀ òkun ṣe ń gbé Pọ́ọ̀lù lọ láti Kẹnkíríà, ó ṣeé ṣe kó máa ronú lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tó wà nílùú Kọ́ríńtì. Ọ̀pọ̀ nǹkan tó ti ṣe sẹ́yìn mú inú ẹ̀ dùn, ìyẹn sì mú kí ọkàn ẹ̀ balẹ̀. Iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó fi ọdún kan àbọ̀ ṣe ti sèso rere. Ìjọ àkọ́kọ́ ti bẹ̀rẹ̀ ní Kọ́ríńtì, ilé Jọ́sítù ni wọ́n sì ti ń pàdé. Lára àwọn tó di onígbàgbọ́ ni Jọ́sítù, Kírípọ́sì àti agboolé rẹ̀ àti ọ̀pọ̀ àwọn míì. Àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di onígbàgbọ́ yẹn jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n fún Pọ́ọ̀lù, torí pé ó ràn wọ́n lọ́wọ́ láti di Kristẹni. Nígbà tó yá ó kọ lẹ́tà sí wọn, ó sì sọ pé wọ́n dà bíi lẹ́tà ìdámọ̀ràn tí wọ́n kọ sínú ọkàn òun. Àwa náà gbà pé ẹni ọ̀wọ́n làwọn tá a kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í sin Jèhófà. Inú wa máa ń dùn gan-an láti rí àwọn arákùnrin tó dà bíi “lẹ́tà ìdámọ̀ràn” bẹ́ẹ̀!—2 Kọ́r. 3:1-3.
19, 20. Kí ni Pọ́ọ̀lù ṣe nígbà tó dé Éfésù, kí la sì rí kọ́ lára ẹ̀ tá a bá láwọn ohun tó wù wá láti ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà?
19 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù dé Éfésù, ó tètè bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tó bá lọ síbẹ̀. Ó “wọ sínágọ́gù, ó sì ń bá àwọn Júù fèròwérò.” (Ìṣe 18:19) Kò dúró pẹ́ ní Éfésù nígbà yẹn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n rọ̀ ọ́ pé kó dúró, “kò gbà.” Nígbà tó ń dágbére fún wọn, ó sọ pé: “Màá tún pa dà sọ́dọ̀ yín, tí Jèhófà bá fẹ́.” (Ìṣe 18:20, 21) Pọ́ọ̀lù gbà pé ọ̀pọ̀ èèyàn ṣì wà tó yẹ kóun wàásù fún ní Éfésù. Lọ́rọ̀ kan ṣá, ó wù ú pé kó tún pa dà wá, àmọ́ ó fi gbogbo ọ̀rọ̀ náà lé Jèhófà lọ́wọ́. Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ tó dáa tó yẹ ká máa tẹ̀ lé nìyẹn jẹ́! Ó dáa tá a bá láwọn ohun tó wù wá láti ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, tá a sì ń sapá kí ọwọ́ wa lè tẹ̀ ẹ́. Àmọ́, a gbọ́dọ̀ máa gbára lé Jèhófà pé kó tọ́ wa sọ́nà, ká sì máa ṣe ohun tó bá ìfẹ́ rẹ̀ mu.—Jém. 4:15.
20 Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù fi Ákúílà àti Pírísílà sílẹ̀ ní Éfésù, ó wọ ọkọ̀ òkun lọ sí Kesaríà. Ó dà bíi pé ó “lọ” sí Jerúsálẹ́mù ó sì kí ìjọ tó wà níbẹ̀. (Ìṣe 18:22) Lẹ́yìn náà ni Pọ́ọ̀lù lọ síbi tó máa ń dé sí ní Áńtíókù ti Síríà. Bó ṣe parí ìrìn àjò míṣọ́nnárì rẹ̀ ẹlẹ́ẹ̀kejì nìyẹn o, ibi ire ló sì já sí. Ẹ jẹ́ ká wá wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i nígbà ìrìn àjò míṣọ́nnárì ẹ̀ tó kẹ́yìn.
a Wo àpótí náà, “ Èbúté Méjì Ni Ìlú Kọ́ríńtì Ní.”
b Wo àpótí náà, “ Àwọn Lẹ́tà Tí Ọlọ́run Mí Sí, Tó sì Ń Fúnni Níṣìírí.”
c Wo àpótí náà, “ Ẹ̀jẹ́ Tí Pọ́ọ̀lù Jẹ́.”