Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 16

“Sọdá Wá sí Makedóníà”

“Sọdá Wá sí Makedóníà”

Wọ́n rí ìbùkún gbà torí pé wọ́n gba iṣẹ́ tí Ọlọ́run fún wọn, wọ́n sì ń láyọ̀ báwọn èèyàn tiẹ̀ ń ṣenúnibíni sí wọn

Ó dá lórí Ìṣe 16:6-40

1-3. (a) Báwo ni ẹ̀mí mímọ́ ṣe darí Pọ́ọ̀lù àtàwọn tí wọ́n jọ rìnrìn àjò? (b) Kí làwọn nǹkan tó ṣẹ̀lẹ̀ tá a máa gbé yẹ̀ wò?

 ÀWỌN obìnrin kan gbéra nílùú Fílípì tó wà ní Makedóníà. Kò pẹ́ tí wọ́n fi débi odò kan tó ń jẹ́ Gangites. Bí àṣà wọn, wọ́n jókòó sétí odò náà kí wọ́n lè gbàdúrà sí Ọlọ́run Ísírẹ́lì, Jèhófà sì ń wò wọ́n.​—2 Kíró. 16:9; Sm. 65:2.

2 Láàárín àkókò yẹn, àwọn ọkùnrin kan kúrò nílùú Lísírà ní gúúsù ìlú Gálátíà, tó fi nǹkan tó lé ní ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ (800) kìlómítà jìnnà sílùú Fílípì. Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀, wọ́n dé òpópónà táwọn ará Róòmù fi òkúta ṣe, ní apá ìwọ̀ oòrùn Éṣíà níbi táwọn èèyàn pọ̀ sí jù lọ. Pọ́ọ̀lù, Sílà àti Tímótì lorúkọ àwọn ọkùnrin yìí. Ara wọn ti wà lọ́nà láti rìnrìn àjò gba ọ̀nà yìí, kí wọ́n lè ṣèbẹ̀wò sílùú Éfésù àtàwọn ìlú míì tó ti yẹ kí ọ̀pọ̀ èèyàn gbọ́ nípa Kristi. Ṣùgbọ́n, kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò náà, ẹ̀mí mímọ́ dá wọn dúró. Àmọ́, Bíbélì ò ṣàlàyé ọ̀nà tí ẹ̀mí mímọ́ gbà dá wọn dúró. Ẹ̀mí mímọ́ ò gbà wọ́n láyè láti lọ wàásù ní Éṣíà. Kí nìdí? Ìdí ni pé Jésù fẹ́ fi ẹ̀mí Ọlọ́run darí Pọ́ọ̀lù àtàwọn tí wọ́n jọ ń rìnrìn àjò bí wọ́n ṣe ń gba Éṣíà Kékeré kọjá, tí wọ́n sì ń kọjá Òkun Aegean, títí wọ́n á fi dé etí odò kékeré kan tó ń jẹ́ Gangites.

3 A máa rí ẹ̀kọ́ tó ṣeyebíye kọ́ nínú bí Jésù ṣe darí Pọ́ọ̀lù àtàwọn tí wọ́n jọ rìnrìn àjò gba ibòmíì, nígbà tí wọ́n ń lọ sí Makedóníà. Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò díẹ̀ lára àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Pọ́ọ̀lù rìnrìn àjò míṣọ́nnárì ẹlẹ́ẹ̀kejì, èyí tó bẹ̀rẹ̀ ní nǹkan bí ọdún 49 Sànmánì Kristẹni.

“Ọlọ́run Ti Pàṣẹ fún Wa” (Ìṣe 16:6-15)

4, 5. (a) Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà tó kù díẹ̀ kí Pọ́ọ̀lù àtàwọn tí wọ́n jọ rìnrìn àjò dé Bítíníà? (b) Kí làwọn ọmọ ẹ̀yìn náà ṣe, kí ló sì yọrí sí?

4 Torí ẹ̀mí mímọ́ ò gba Pọ́ọ̀lù àtàwọn tí wọ́n jọ ń rìnrìn àjò láyè láti lọ wàásù ní Éṣíà, wọ́n lọ sí apá àríwá láti lọ wàásù nílùú Bítíníà. Kí wọ́n tó lè débẹ̀, ó ṣeé ṣe kí wọ́n rìn ní ọ̀nà eléruku fún ọjọ́ bíi mélòó kan láàárín agbègbè ìlú Fíríjíà àti Gálátíà táwọn èèyàn tó ń gbébẹ̀ ò pọ̀. Àmọ́, nígbà tó ku díẹ̀ kí wọ́n dé ìlú Bítíníà, Jésù tún fi ẹ̀mí mímọ́ dá wọn dúró. (Ìṣe 16:6, 7) Ní báyìí, ó ṣeé ṣe kọ̀rọ̀ náà má yé wọn mọ́. Wọ́n mọ ohun tí wọ́n fẹ́ wàásù, wọ́n sì mọ wọ́n ṣe máa wàásù, àmọ́ wọn ò mọ ibi tí wọ́n ti máa wàásù. Wọ́n ti fẹ́ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù ní pẹrẹu ní Éṣíà, àmọ́ ẹ̀mí mímọ́ ò gbà wọ́n láyè. Wọ́n tún fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù ní Bítíníà, ẹ̀mí mímọ́ ò tún gbà wọ́n láyè. Síbẹ̀, Pọ́ọ̀lù pinnu pé òun ò ní jẹ́ kó sú òun títí tóun á fi ríbi tóun ti máa wàásù. Àwọn ọkùnrin náà wá ṣe nǹkan kan tó lè dà bíi pé kò bọ́gbọ́n mu. Wọ́n rin ìrìn tó tó ọgọ́rùn-ún márùn-ún ó lé àádọ́ta (550) kìlómítà lọ sí apá ìwọ̀ oòrùn, wọ́n rìn láti ìlú kan sílùú míì, títí wọ́n fi dé etíkun Tíróásì, ìyẹn ẹnubodè ìlú Makedóníà. (Ìṣe 16:8) Ìlú yìí ni ibì kẹta tí Pọ́ọ̀lù ti gbìyànjú láti wàásù, ẹ̀mí mímọ́ sì gbà wọ́n láyè láti wàásù níbẹ̀.

5 Lúùkù, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó kọ ìwé Ìhìn Rere dara pọ̀ mọ́ Pọ́ọ̀lù àtàwọn tí wọ́n jọ rìnrìn àjò ní Tíróásì. Lúùkù sọ pé: “Ní òru, Pọ́ọ̀lù rí ìran kan, ọkùnrin ará Makedóníà kan dúró, ó sì ń rọ̀ ọ́ pé: ‘Sọdá wá sí Makedóníà, kí o sì ràn wá lọ́wọ́.’ Gbàrà tí ó ti rí ìran náà, a múra láti lọ sí Makedóníà, torí a gbà pé Ọlọ́run ti pàṣẹ fún wa láti kéde ìhìn rere fún wọn.” a (Ìṣe 16:9, 10) Ní báyìí, Pọ́ọ̀lù ti mọ ibi tó ti máa wàásù. Ẹ wo bí inú Pọ́ọ̀lù á ṣe dùn tó pé òun ò jẹ́ kí ìrẹ̀wẹ̀sì mú òun torí ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn kóun sì pa dà lọ́nà! Lójú ẹsẹ̀, àwọn ọkùnrin mẹ́rin náà wá wọ ọkọ̀ òkun lọ sí Makedóníà.

“Torí náà, a wọkọ̀ òkun láti Tíróásì.”​—Ìṣe 16:11

6, 7. (a) Kí la rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Pọ́ọ̀lù nígbà tó ń rìnrìn àjò? (b) Báwo lohun tó ṣẹlẹ̀ sí Pọ́ọ̀lù ṣe fi wá lọ́kàn balẹ̀?

6 Kí la lè rí kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn? Rò ó wò ná: Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù rin ìrìn àjò lọ sí Éṣíà ni ẹ̀mí Ọlọ́run ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sí ọ̀rọ̀ náà, lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù dé ìtòsí Bítíníà ni Jésù ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sí ọ̀rọ̀ náà àti pé lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù dé Tíróásì ni Jésù ṣẹ̀sẹ̀ wá darí rẹ̀ sí Makedóníà. Lónìí, Jésù tó jẹ́ Orí ìjọ lè darí àwa náà nírú ọ̀nà yìí. (Kól. 1:18) Bí àpẹẹrẹ, a lè ti máa ronú nípa bí a ṣe máa di aṣáájú-ọ̀nà tàbí kí á lọ sí agbègbè kan tí wọ́n ti nílò àwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run. Àmọ́, ó lè jẹ́ pé lẹ́yìn tá a bá ti kọ́kọ́ gbé ìgbésẹ̀ kan tó ṣe pàtó, tó máa jẹ́ kọ́wọ́ wa tẹ àfojúsùn náà ni Jésù máa tó darí wa nípasẹ̀ ẹ̀mí Ọlọ́run. Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀? Wo àpèjúwe yìí ná: Bí ọkọ̀ kan bá wà lórí ìrìn ni awakọ̀ tó lè darí rẹ̀ sọ́tùn-ún tàbí sósì. Torí náà, ó dìgbà tá a bá sapá tá a sì gbé ìgbésẹ̀ kí Jésù tó lè darí wa láti mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa gbòòrò sí i.

7 Ká sọ pé ọwọ́ wa ò tètè tẹ àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tá a fẹ́ ńkọ́? Ṣó yẹ ká rẹ̀wẹ̀sì ká wá máa rò pé ẹ̀mí Ọlọ́run ò darí wa? Rárá o. Ó ṣe tán, Pọ́ọ̀lù náà dojú kọ àwọn ohun tó lè mú kó rẹ̀wẹ̀sì. Síbẹ̀, kò jẹ́ kó sú òun títí tó fi mọ ibi tó ti máa wàásù. Ẹ jẹ́ kó dá wa lójú pé táwa náà ò bá jẹ́ kó sú wa láti máa wá ‘ilẹ̀kùn ńlá láti ṣe iṣẹ́ púpọ̀’ sí i, a máa rí ìbùkún tó pọ̀ látọ̀dọ̀ Jèhófà.​—1 Kọ́r. 16:9.

8. (a) Ṣàlàyé bí ìlú Fílípì ṣe rí. (b) Nǹkan dáadáa wo ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí Pọ́ọ̀lù wàásù níbi ‘táwọn èèyàn ti ń gbàdúrà’?

8 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù àtàwọn tí wọ́n jọ rìnrìn àjò dé agbègbè Makedóníà, wọ́n lọ sílùú Fílípì. Ọmọ ìbílẹ̀ Róòmù làwọn ará ìlú Fílípì, ìyẹn sí máa ń jẹ́ kí wọ́n yangàn. Kódà, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ogun Róòmù tí wọ́n ti fẹ̀yìn tì ló ń gbébẹ̀ torí pé bí nǹkan ṣe rí níbẹ̀ ò yàtọ̀ sí ti ìlú Róòmù. Ní òde ìlú náà, àwọn míṣọ́nnárì yẹn rí ibì kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ odò kékeré kan, tí wọ́n rò pé “àwọn èèyàn ti ń gbàdúrà.” b Lọ́jọ́ Sábáàtì, wọ́n lọ síbẹ̀, wọ́n sì rí àwọn obìnrin bíi mélòó kan tí wọ́n kóra jọ láti sin Ọlọ́run. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà jókòó wọ́n sì bá wọn sọ̀rọ̀. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Lìdíà “ń fetí sílẹ̀, Jèhófà sì ṣí ọkàn rẹ̀ sílẹ̀.” Ọ̀rọ̀ táwọn míṣọ́nnárì yẹn sọ wọ Lìdíà lọ́kàn débi pé òun àti agbo ilé rẹ̀ ṣèrìbọmi. Lẹ́yìn náà, ó gba Pọ́ọ̀lù àtàwọn tí wọ́n jọ ń rìnrìn àjò sílé rẹ̀. c​—Ìṣe 16:13-15.

9. Báwo làwọn ará lọ́kùnrin lobìnrin ṣe ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù lónìí, àwọn ìbùkún wo ni wọ́n sì ti rí?

9 Ẹ wo bínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn ṣe máa dùn tó lọ́jọ́ tí Lìdíà ṣèrìbọmi! Ó dájú pé inú Pọ́ọ̀lù máa dùn gan-an pé òun gbà láti “sọdá wá sí Makedóníà,” tí Jèhófà sì lo òun àtàwọn tí wọ́n jọ rìnrìn àjò láti dáhùn àdúrà àwọn obìnrin tí wọ́n nírẹ̀lẹ̀ yìí! Bákan náà, lóde òní, ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin àti arábìnrin, tọmọdé tàgbà, àwọn tí kò tíì ṣègbéyàwó àtàwọn tó ti ṣègbéyàwó, ni wọ́n ń lọ síbi tí a ti nílò oníwàásù púpọ̀ sí i. Òótọ́ ni pé wọ́n láwọn ìṣòro tí wọ́n dojú kọ, àmọ́ àwọn ìṣòro yẹn ò jẹ́ nǹkan kan tí wọ́n bá fi wé ayọ̀ tí wọ́n máa ń ní nígbà tí wọ́n bá rí àwọn èèyàn bíi Lìdíà, tó gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tí wọ́n sì ń fi ohun tí wọ́n ń kọ́ sílò. Ṣé o lè ṣàwọn àyípadà kan táá jẹ́ kó o lè “sọdá” lọ síbi tí wọ́n ti nílò oníwàásù púpọ̀ sí i? Ó dájú pé Jèhófà máa bù kún ẹ tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ arákùnrin kan tó ń jẹ́ Aaron tó ti lé lógún ọdún, tó sì kó lọ sórílẹ̀-èdè kan ní Central America. Ó sọ pé: “Bí mo ṣe lọ sìn lórílẹ̀-èdè míì ti jẹ́ kí n túbọ̀ ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, kí n sì túbọ̀ sún mọ́ ọn. Mo ń gbádùn iṣẹ́ ìwàásù gan-an, kódà ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mẹ́jọ ni mò ń darí!” Bó sì ṣe rí fún ọ̀pọ̀ àwọn tó lọ síbi tí wọ́n ti nílò oníwàásù púpọ̀ sí i nìyẹn.

Báwo la ṣe lè “sọdá wá sí Makedóníà” lónìí?

“Àwọn Èrò Tó Wà Níbẹ̀ Dìde SÍ Wọn” (Ìṣe 16:16-24)

10. Báwo làwọn ẹ̀mí èṣù ṣe ta ko Pọ́ọ̀lù àtàwọn tí wọ́n jọ ń rìnrìn àjò?

10 Ó dájú pé inú máa bí Sátánì burúkú-burúkú bí àwọn èèyàn ṣe ń gbọ́ ìhìn rere, tí wọ́n sì ń ṣèrìbọmi láwọn ibi tó jẹ́ pé ohun tí Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù ẹ̀ fẹ́ làwọn èèyàn ń ṣe. Abájọ táwọn ẹ̀mí èṣù fi mú káwọn èèyàn ta ko Pọ́ọ̀lù àtàwọn tí wọ́n jọ ń rìnrìn àjò. Ìránṣẹ́bìnrin kan wà tó ní ẹ̀mí èṣù ìwoṣẹ́, tó sí máa ń pawó fún àwọn ọ̀gá rẹ̀. Nígbàkigbà tí Pọ́ọ̀lù àtàwọn tí wọ́n jọ ń rìnrìn àjò bá ń lọ síbi táwọn èèyàn ti máa ń gbàdúrà, ìránṣẹ́bìnrin yìí máa ń tẹ̀ lé wọn, ó sì máa ń ké jáde pé: “Ẹrú Ọlọ́run Ẹni Gíga Jù Lọ ni àwọn ọkùnrin yìí, wọ́n sì ń kéde ọ̀nà ìgbàlà fún yín.” Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ẹ̀mí èṣù ń mú kí ọmọbìnrin yẹn sọ ọ̀rọ̀ yìí, kó bàa lè dà bíi pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run kan náà làwọn àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ àtàwọn ohun tí Pọ́ọ̀lù ń kọ́ni ti wá. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn èèyàn tó ń rí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ò ní fi bẹ́ẹ̀ tẹ́tí sí àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi. Àmọ́, Pọ́ọ̀lù lé ẹ̀mí èṣù yẹn jáde lára ọmọbìnrin náà, ìyẹn sì pa á lẹ́nu mọ́.​—Ìṣe 16:16-18.

11. Lẹ́yìn tí ẹ̀mí èṣù ti jáde lára ìránṣẹ́bìnrin yẹn, kí ló ṣẹlẹ̀ sí Pọ́ọ̀lù àti Sílà?

11 Nígbà táwọn ọ̀gá ìránṣẹ́bìnrin yẹn rí i pé ọ̀nà ìjẹ àwọn ti dí, inú bí wọn gan-an. Ni wọ́n bá wọ́ Pọ́ọ̀lù àti Sílà lọ síbi ọjà, níbi táwọn agbófinró tó ń ṣojú fún ìlú Róòmù ti máa ń gbẹ́jọ́. Àwọn ọ̀gá ìránṣẹ́bìnrin yẹn mọ̀ pé àwọn adájọ́ yẹn máa ń yangàn torí wọ́n jẹ́ ọmọ ìlú Róòmù àti pé wọ́n kórìíra àwọn Júù, torí náà wọ́n sọ fáwọn adájọ́ yẹn pé ‘Àwọn Júù wọ̀nyí ń yọ wá lẹ́nu, nípa bí wọ́n ṣe ń kọ́ni láwọn àṣà táwa ara Róòmù kò lè tẹ́wọ́ gbà.’ Ni inú bá bí àwọn èèyàn tó wà níbẹ̀, débi pé: “Àwọn èrò [tó wà níbi ọjà] dìde sí wọn [Pọ́ọ̀lù àti Sílà] lẹ́ẹ̀kan náà,” àwọn adájọ́ sì pàṣẹ pé “kí wọ́n fi ọ̀pá nà wọ́n.” Lẹ́yìn náà, wọ́n wọ́ Pọ́ọ̀lù àti Sílà lọ sẹ́wọ̀n. Ẹni tó ń ṣọ́ àwọn ẹlẹ́wọ̀n ju àwọn ọkùnrin tí wọ́n ti fara pa náà sí ẹ̀wọ̀n inú lọ́hùn-ún, ó sì de ẹsẹ̀ wọn mọ́ inú àbà. (Ìṣe 16:19-24) Nígbà tí ẹni tó ń ṣọ́ àwọn ẹlẹ́wọ̀n ti ilẹ̀kùn, ńṣe ni inú ẹ̀wọ̀n yẹn ṣókùnkùn biribiri débi pé agbára káká ni Pọ́ọ̀lù àti Sílà fi ń ríra wọn. Àmọ́, Jèhófà ń rí wọn.​—Sm. 139:12.

12. (a) Ojú wo làwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi fi ń wo inúnibíni, kí sì nìdí? (b) Oríṣiríṣi ọ̀nà wo ni Sátánì àtàwọn èèyàn tó ń darí ṣì ń gbà ta kò wá lónìí?

12 Ní ọ̀pọ̀ ọdún ṣáájú ìgbà yẹn, Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: ‘Wọ́n máa ṣe inúnibíni sí yín.’ (Jòh. 15:20) Torí náà, nígbà tí Pọ́ọ̀lù àtàwọn tí wọ́n jọ ń rìnrìn àjò sọdá sí Makedóníà, wọ́n ti múra sílẹ̀ láti dojú kọ inúnibíni. Nígbà táwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í ṣenúnibíni sí wọn, wọ́n mọ̀ pé Sátánì ló fà á, kì í ṣe pé Jèhófà ń bínú sáwọn. Lónìí, àwọn tí Sátánì ń darí ṣì ń ṣe bíi tàwọn èèyàn tó ta ko Pọ́ọ̀lù nílùú Fílípì nígbà yẹn. Àwọn alátakò máa ń sọ ohun tí kì í ṣòótọ́ nípa wa, ìyẹn sì máa ń jẹ́ káwọn èèyàn ṣenúnibíni sí wá níléèwé àti níbiṣẹ́. Láwọn orílẹ̀-èdè kan, àwọn ẹlẹ́sìn máa ń ta kò wá nílé ẹjọ́, ńṣe ló dà bí ìgbà tí wọ́n ń sọ pé: ‘Àwọn Ẹlẹ́rìí wọ̀nyí ń yọ wá lẹ́nu, torí wọ́n máa ń kọ́ni láwọn àṣà táwọn èèyàn ò lè tẹ́wọ́ gbà.’ Láwọn ibì kan, wọ́n máa ń na àwọn tá a jọ ń sin Jèhófà, wọ́n sì máa ń jù wọ́n sẹ́wọ̀n. Ṣùgbọ́n, Jèhófà ń rí wọn.​—1 Pét. 3:12.

Wọ́n “Ṣèrìbọmi Láìjáfara” (Ìṣe 16:25-34)

13. Kí ló mú kí ẹni tó ń ṣọ́ àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà béèrè pé: “Kí ni kí n ṣe kí n lè rí ìgbàlà?”

13 Kò sí àní-àní pé ó máa gba àkókó díẹ̀ kí ara tó lè tu Pọ́ọ̀lù àti Sílà torí pé ojú wọn rí màbo lọ́jọ́ yẹn. Àmọ́, nígbà tó fi máa di àárín òru, ara ti tù wọ́n débi pé wọ́n ‘ń gbàdúrà, wọ́n sì ń fi orin yin Ọlọ́run.’ Lẹ́yìn náà, lójijì, ìmìtìtì ilẹ̀ ńlá ṣẹlẹ̀, ó sì mi ọgbà ẹ̀wọ̀n náà! Nígbà tí ẹni tó ń ṣọ́ àwọn ẹlẹ́wọ̀n ta jí, ó rí i pé àwọn ilẹ̀kùn ọgbà ẹ̀wọ̀n ti ṣí, ẹ̀rú sì bà á, torí ó rò pé àwọn ẹlẹ́wọ̀n ti sá lọ. Ẹni tó ń ṣọ́ àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà mọ̀ pé òun máa jẹ palaba ìyà torí òun jẹ́ káwọn ẹlẹ́wọ̀n náà sá lọ, ló bá “fa idà rẹ̀ yọ, ó sì fẹ́ pa ara rẹ̀.” Àmọ́, Pọ́ọ̀lù kígbe sókè pé: “Má ṣe ara rẹ léṣe o, gbogbo wa wà níbí!” Ìdààmú ti bá ẹni tó ń ṣọ́ àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà, torí náà ó béèrè pé: “Ẹ̀yin ọ̀gá, kí ni kí n ṣe kí n lè rí ìgbàlà?” Pọ́ọ̀lù àti Sílà ò lè gbà á là, àfi Jésù nìkan. Wọ́n wá sọ pé: “Gba Jésù Olúwa gbọ́, wàá sì rí ìgbàlà.”​—Ìṣe 16:25-31.

14. (a) Báwo ni Pọ́ọ̀lù àti Sílà ṣe ran ẹni tó ń ṣọ́ àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà lọ́wọ́? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe bù kún Pọ́ọ̀lù àti Sílà torí pé wọ́n ń láyọ̀ báwọn èèyàn tiẹ̀ ń ṣenúnibíni sí wọn?

14 Ṣé ìbéèrè tí ẹni tó ń ṣọ́ àwọn ẹlẹ́wọ̀n yẹn béèrè ti ọkàn rẹ̀ wá? Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé bọ́rọ̀ ṣe rí lára ẹ̀ nìyẹn. Kèfèrí ni ẹni tó ń ṣọ́ àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà, kò sì mọ Ìwé Mímọ́. Kó tó lè di Kristẹni, ó yẹ kó mọ àwọn ẹ̀kọ́ àkọ́bẹ̀rẹ̀ Ìwé Mímọ́ kó sì tẹ́wọ́ gbà á. Ìdí nìyẹn tí Pọ́ọ̀lù àti Sílà fi fara balẹ̀ ‘sọ ọ̀rọ̀ Jèhófà fún un.’ Ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kí ẹ̀kọ́ tí Pọ́ọ̀lù àti Sílà ń kọ́ ẹni tó ń ṣọ́ àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà látinú Ìwé Mímọ́ ti wọ̀ wọ́n lára débi tí wọ́n fi gbàgbé ara tó ń ro wọ́n torí ìyà tí wọ́n fi jẹ wọ́n. Ẹni tó ń ṣọ́ àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà wá kíyè sí àwọn ọgbẹ́ tó wà lẹ́yìn wọn, ó sì wẹ àwọn ọgbẹ́ náà. Lẹ́yìn náà, “òun àti . . . agbo ilé rẹ̀ ṣèrìbọmi láìjáfara.” Ẹ ò rí i pé ìbùkún ńlá ni Pọ́ọ̀lù àti Sílà rí gbà torí pé wọ́n ń láyọ̀ bí wọ́n tiẹ̀ ṣenúnibíni sí wọn!​—Ìṣe 16:32-34.

15. (a) Báwo ni ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lónìí ṣe ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù àti Sílà? (b) Kí nìdí tó fi yẹ ká máa lọ sọ́dọ̀ àwọn tá à ń wàásù fún ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa léraléra?

15 Bíi ti Pọ́ọ̀lù àti Sílà, ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà òde òní ló máa ń wàásù tí wọ́n bá fi wọ́n sẹ́wọ̀n torí ohun tí wọ́n gbà gbọ́, ọ̀pọ̀ èèyàn ló sì ń tẹ́tí gbọ́ wọn. Bí àpẹẹrẹ, lórílẹ̀-èdè kan tí wọn ò ti gbà káwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà wàásù, àsìkò kan wà tó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ìdajì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà níbẹ̀ ló jẹ́ pé ọgbà ẹ̀wọ̀n ni wọ́n ti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́! (Àìsá. 54:17) Ẹ tún kíyè sí i pé lẹ́yìn tí ìmìtìtì ilẹ̀ wáyé ní ọgbà ẹ̀wọ̀n náà ni ẹni tó ń ṣọ́ àwọn ẹlẹ́wọ̀n sọ pé kí wọ́n ran òun lọ́wọ́. Bákan náà lónìí, lẹ́yìn tí ìṣòro bá dé bá àwọn kan tí wọn ò fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run tẹ́lẹ̀ ni wọ́n ṣẹ̀sẹ̀ máa ń fetí sílẹ̀. Tá a bá ń lọ sọ́dọ̀ àwọn tá à ń wàásù fún ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa léraléra, ṣe là ń fi hàn pé a ṣe tán láti ràn wọ́n lọ́wọ́.

“Ṣé Wọ́n Wá Fẹ́ Tì Wá Jáde Ní Bòókẹ́lẹ́ Ni?” (Ìṣe 16:35-40)

16. Báwo ni nǹkan ṣe yí pa dà lọ́jọ́ kejì tí wọ́n na Pọ́ọ̀lù àti Sílà?

16 Lọ́jọ́ kejì tí wọ́n na Pọ́ọ̀lù àti Sílà, àwọn adájọ́ yẹn wá pàṣẹ pé kí wọ́n tú wọn sílẹ̀. Àmọ Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Wọ́n nà wá lẹ́gba ní gbangba láìdá wa lẹ́bi, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ará Róòmù ni wá, wọ́n jù wá sẹ́wọ̀n. Ṣé wọ́n wá fẹ́ tì wá jáde ní bòókẹ́lẹ́ ni? Rárá o! Kí àwọn fúnra wọn wá mú wa jáde.” Nígbà táwọn adájọ́ yẹn gbọ́ pé ará Róòmù ni Pọ́ọ̀lù àti Sílà, “ẹ̀rù bà wọ́n,” torí pé wọ́n ti fi ẹ̀tọ́ àwọn ọkùnrin náà dù wọ́n. d Nǹkan ti wá yí pa dà báyìí. Gbangba ni wọ́n ti fìyà jẹ àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà, àfi káwọn adájọ́ yẹn tọrọ ìdáríjì ní gbangba. Wọ́n bẹ Pọ́ọ̀lù àti Sílà pé kí wọ́n kúrò nílùú Fílípì. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn méjì yẹn gbà láti kúrò níbẹ̀, ṣùgbọ́n wọ́n kọ́kọ́ fún àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di ọmọ ẹ̀yìn níṣìírí. Lẹ́yìn náà, wọ́n kúrò níbẹ̀.

17. Ẹ̀kọ́ pàtàkì wo làwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di ọmọ ẹ̀yìn kọ́ nínú bí Pọ́ọ̀lù àti Sílà ṣe fara da ìyà?

17 Ká ní Pọ́ọ̀lù àti Sílà ti sọ pé ará Róòmù làwọn níbẹ̀rẹ̀ ni, àwọn èèyàn yẹn ì bá má fìyà jẹ wọ́n. (Ìṣe 22:25, 26) Àmọ́, èyí lè mú káwọn ọmọ ẹ̀yìn tó wà nílùú Fílípì máa rò pé ṣe ni Pọ́ọ̀lù àti Sílà lo ipò wọn kí wọ́n má báa jìyà nítorí Kristi. Ó sì lè mú kó ṣòro fáwọn ọmọ ẹ̀yìn láti jẹ́ olóòótọ́ tí wọ́n bá kojú inúnibíni torí wọn kì í ṣe ará Róòmù. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, òfin ò ní kí wọ́n má fìyà jẹ ẹni tí kì í ṣe ará Róòmù. Torí náà, bí Pọ́ọ̀lù àti Sílà ṣe jìyà tí wọ́n sì fara dà á jẹ́ káwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di Kristẹni mọ̀ pé àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi lè jẹ́ olóòótọ́ tí wọ́n bá ṣe inúnibíni sí wọn. Yàtọ̀ síyẹn, ìdí tí Pọ́ọ̀lù àti Sílà fi jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ará Róòmù làwọn ni pé wọ́n fẹ́ kí gbogbo èèyàn mọ̀ pé ìwà táwọn adájọ́ yẹn hù sáwọn ò bófin mu rárá. Ìyẹn lè má jẹ́ kí wọ́n fìyà jẹ àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó kù, ó sì lè dáàbò bò wọ́n lábẹ́ òfin, kírú nǹkan bẹ́ẹ̀ má bàa ṣẹlẹ̀ nígbà míì.

18. (a) Báwo làwọn Krístẹni alábòójútó ṣe ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù lónìí? (b) Báwo la ṣe ń ‘gbèjà ìhìn rere tá a sì ń fìdí rẹ̀ múlẹ̀ lọ́nà òfin’ lónìí?

18 Lónìí, àwọn alábòójútó nínú ìjọ máa ń fàpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀. Wọ́n máa ń ṣe ohunkóhun tí wọ́n bá retí pé káwọn Kristẹni bíi tiwọn ṣe. Bíi ti Pọ́ọ̀lù, a máa ń ronú lórí bí a ṣe lé lo ẹ̀tọ́ tá a ní lábẹ́ òfin àti ìgbà tó yẹ ká lò ó láti dáàbò bo ara wa. A lè pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn sí ilé ẹjọ́ ìbílẹ̀, ti orílẹ̀-èdè àti ti àgbáyé tó bá yẹ bẹ́ẹ̀, ká bàa lè ní ààbò lábẹ́ òfin láti máa bá ìjọsìn wa nìṣó. Bí Pọ́ọ̀lù ṣe sọ nínú lẹ́tà rẹ̀ sáwọn ará Fílípì ní nǹkan bí ọdún mẹ́wàá lẹ́yìn tó ṣẹ̀wọ̀n níbẹ̀, àfojúsùn wa kì í ṣe láti yí oun tó ń lọ ní ìlú pa dà, bí kò ṣe láti “gbèjà ìhìn rere, tí a sì ń fìdí rẹ̀ múlẹ̀ lọ́nà òfin.” (Fílí. 1:7) Síbẹ̀, ohun yòówù kó jẹ́ àbájáde àwọn ẹjọ́ náà, bíi ti Pọ́ọ̀lù àtàwọn tí wọ́n jọ rìnrìn àjò, a ti pinnu pé àá máa bá a lọ láti máa “kéde ìhìn rere” níbikíbi tí ẹ̀mí Ọlọ́run bá darí wa sí.​—Ìṣe 16:10.

a Wo àpótí náà, “ Lúùkù​—Ẹni Tó Kọ Ìwé Ìṣe.”

b Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé torí báwọn ọmọ ogun Róòmù tó ti fẹ̀yìn tì ṣe pọ̀ nílùú Fílípì ni wọn ò ṣe gba àwọn Júù láyè láti ní sínágọ́gù níbẹ̀. Ó sì lè jẹ́ pé ṣe làwọn ọkùnrin Júù tó wà níbẹ̀ ò tó mẹ́wàá, torí ìyẹn ni iye tó kéré jù lọ táwọn ọkùnrin gbọ́dọ̀ jẹ́ níbì kan kí wọ́n tó lè kọ́ sínágọ́gù síbẹ̀.

d Òfin àwọn ará Róòmù ni pé kí wọ́n gbọ́ ẹjọ́ ẹni tó bá jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ lọ́nà tó tọ́, wọn ò sì gbọ́dọ̀ fìyà jẹ ẹ́ ní gbangba láìjẹ́ pé ó jẹ̀bi.