Atọ́ka Àwòrán
Nọ́ńbà Dúró Fún Ojú Ìwé Tó Wà
Ẹ̀yìn ìwé Pọ́ọ̀lù, Tàbítà, Gálíò, Lúùkù, alábòójútó tẹ́ńpìlì kan wà lẹ́yìn àwọn àpọ́sítélì, Sadusí kan, wọ́n ń mú Pọ́ọ̀lù lọ sí Kesaríà, wọ́n ń fi mọ́tò tá a fi ń gbóhùn sáfẹ́fẹ́ àti ẹ̀rọ giramafóònù wàásù lóde òní.
Ojú ìwé 1 Wọ́n fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ de ọwọ́ Pọ́ọ̀lù, òun àti Lúùkù wà nínú ọkọ̀ òkun tí wọ́n fi ń kẹ́rù lọ sí Róòmù.
Ojú ìwé 2, 3 Arákùnrin J. E. Barr àti Arákùnrin T. Jaracz tí wọ́n ti fìgbà kan rí jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí ń wo máàpù àgbáyé.
Ojú ìwé 11 Jésù ń faṣẹ́ lé àwọn àpọ́sítélì mọ́kànlá tó jẹ́ olóòótọ́ lọ́wọ́ àtàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ míì lórí òkè kan nílùú Gálílì.
Ojú ìwé 14 Jésù ń gòkè lọ sí ọ̀run. Àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ń wò ó bó ṣe ń lọ.
Ojú ìwé 20 Ní ọjọ́ Àjọyọ̀ Pẹ́ńtíkọ́sì, àwọn ọmọ ẹ̀yìn bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ ní oríṣiríṣi èdè ìbílẹ̀ táwọn àlejò tó wá síbi àjọyọ̀ náà ń sọ.
Ojú ìwé 36 Àwọn àpọ́sítélì dúró níwájú Káyáfà tó ń bínú. Àwọn alábòójútó tẹ́ńpìlì ń retí kí ìgbìmọ̀ Sàhẹ́ndìrìn pàṣẹ fún wọn kí wọ́n lè mú àwọn àpọ́sítélì.
Ojú ìwé 44 Ìsàlẹ̀: Lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì, ilé ẹjọ́ kan ní Ìlà Oòrùn Jámánì fẹ̀sùn èké kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé amí àwọn ará Amẹ́ríkà ni wọ́n.—Ìwé ìròyìn Neue Berliner Illustrierte, October 3, 1950.
Ojú ìwé 46 Sítéfánù ń jẹ́jọ́ níwájú Sàhẹ́ndìrìn. Àwọn Sadusí tó jẹ́ ọlọ́rọ̀ wà lápá ẹ̀yìn àwòrán náà, àwọn Farisí tó jẹ́ agbawèrèmẹ́sìn sì wà lápá iwájú.
Ojú ìwé 54 Pétérù gbọ́wọ́ lé ẹnì kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di ọmọ ẹ̀yìn; àpò tí wọ́n ń kówó sí wà lọ́wọ́ Símónì.
Ojú ìwé 75 Pétérù àtàwọn tó ń bá a rìnrìn àjò wọnú ilé Kọ̀nílíù. Kọ̀nílíù fi aṣọ kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ sórí èjìká rẹ̀ òsì, aṣọ náà fi hàn pé ọ̀gá ọmọ ogun ni.
Ojú ìwé 83 Áńgẹ́lì kan ń mú Pétérù jáde; ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Ilé Gogoro Àǹtóníà ni wọ́n ti Pétérù mọ́.
Ojú ìwé 84 Ìsàlẹ̀: Àwọn jàǹdùkú ń fa wàhálà nítòsí ìlú Montreal, ní ìpínlẹ̀ Quebec, lọ́dún 1945.—Ìwé ìròyìn Weekend Magazine, July 1956.
Ojú ìwé 91 Wọ́n lé Pọ́ọ̀lù àti Bánábà jáde kúrò ní Áńtíókù ti Písídíà. Ọ̀nà omi tuntun tí wọ́n ṣe sí ìlú ló wà lápá ẹ̀yìn nínú àwòrán yìí, ó jọ pé ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní Sànmánì Kristẹni ni wọ́n ṣe é.
Ojú ìwé 94 Pọ́ọ̀lù àti Bánábà ò gbà kí wọ́n jọ́sìn àwọn ní Lísírà. Táwọn ará Lísírà bá ń rúbọ ní gbangba, ariwo máa ń pọ̀ gan-an, torí ṣe ni wọ́n á máa kọrin lóríṣiríṣi, tí wọ́n á máa jó tí wọ́n á sì máa yọ̀.
Ojú ìwé 100 Òkè: Sílà àti Júdásì ń fún ìjọ tó wà ní Áńtíókù ti Síríà níṣìírí. (Ìṣe 15:30-32) Ìsàlẹ̀: Alábòójútó àyíká ń bá ìjọ kan sọ̀rọ̀ lórílẹ̀-èdè Uganda.
Ojú ìwé 107 Ìjọ tó wà ní Jerúsálẹ́mù pàdé nílé ẹnì kan.
Ojú ìwé 124 Pọ́ọ̀lù àti Tímótì ń rìnrìn àjò, wọ́n wà nínú ọkọ̀ òkun táwọn ará Róòmù fi ń ṣòwò. Ilé atọ́nà ọkọ̀ òkun wà lọ́ọ̀ọ́kán.
Ojú ìwé 139 Pọ́ọ̀lù àti Sílà ń fara pa mọ́ kí ọwọ́ àwọn jàǹdùkú má bàa tẹ̀ wọ́n, wọ́n sá sínú àgbàlá kan tó nílẹ̀kùn onírin tí wọ́n tì pa.
Ojú ìwé 155 Gálíò wà níwájú àwọn tó fẹ̀sùn kan Pọ́ọ̀lù, ó ń nà wọ́n lẹ́gba ọ̀rọ̀. Ó wọ aṣọ oyè rẹ̀, ìyẹn aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ funfun tí wọ́n fi aṣọ tẹ́ẹ́rẹ́ aláwọ̀ pọ́pù sí etí ẹ̀. Ó tún wọ bàtà kan tí wọ́n ń pè ní calcei.
Ojú ìwé 158 Dímẹ́tíríù ń bá àwọn alágbẹ̀dẹ fàdákà bíi tiẹ̀ sọ̀rọ̀ nínú ṣọ́ọ̀bù wọn nílùú Éfésù. Wọ́n máa ń fi fàdákà ṣe àwọn ojúbọ Átẹ́mísì yìí, wọ́n sì ń tà á fáwọn èèyàn kí wọ́n lè fi sínú ilé wọn.
Ojú ìwé 171 Pọ́ọ̀lù àtàwọn tí wọ́n jọ ń rìnrìn àjò ń wọ ọkọ̀ òkun. Òpó kan tí wọ́n fi ń rántí Èbúté Ńlá wà lẹ́yìn wọn nínú àwòrán yìí, ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni wọ́n ṣe òpó náà.
Ojú ìwé 180 Ìsàlẹ̀: Láwọn ọdún 1940, nígbà tí wọ́n fòfin de iṣẹ́ ìwàásù lórílẹ̀-èdè Canada, ọmọkùnrin kan ń dọ́gbọ́n kó àwọn ìwé tó ṣàlàyé Bíbélì lọ sílé arákùnrin kan. (Àwòrán bó ṣe ṣe é.)
Ojú ìwé 182 Pọ́ọ̀lù gbà láti ṣe ohun táwọn alàgbà ní kó ṣe. Lúùkù àti Tímótì jókòó sápá ẹ̀yìn, wọ́n ń fi ọrẹ àwọn ará jíṣẹ́.
Ojú ìwé 190 Mọ̀lẹ́bí Pọ́ọ̀lù ń bá Kíláúdíù Lísíà sọ̀rọ̀ ní Ilé Gogoro Àǹtóníà, tó ṣeé ṣe kó jẹ́ ibi tí wọ́n ti Pọ́ọ̀lù mọ́. Tẹ́ńpìlì Hẹ́rọ́dù ló wà lápá ẹ̀yìn.
Ojú ìwé 206 Pọ́ọ̀lù ń gbàdúrà fáwọn arìnrìn-àjò níbi tí wọ́n ń kẹ́rù sí nínú ọkọ̀ òkun, ó ti rẹ gbogbo àwọn èèyàn náà.
Ojú ìwé 222 Pọ́ọ̀lù wà lẹ́wọ̀n, ó ń wo apá kan ìlú Róòmù, wọ́n sì fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ de ọwọ́ ẹ̀ mọ́ ọwọ́ ọmọ ogun Róòmù kan.